Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Eeṣe Tí Ijiya Ati Aisi Idajọ Òdodo Fi Pọ̀ Tobẹẹ?

Eeṣe Tí Ijiya Ati Aisi Idajọ Òdodo Fi Pọ̀ Tobẹẹ?

Ìsọ̀rí 6

Eeṣe Tí Ijiya Ati Aisi Idajọ Òdodo Fi Pọ̀ Tobẹẹ?

1, 2. Loju-iwoye iriri eniyan, awọn ibeere wo ni a lè beere?

1 Bi o ti wu ki o ri, bi Ẹni Giga Julọ naa bá pete pe ki awọn eniyan pipe gbé lori ilẹ̀-ayé titilae ninu awọn ipo paradise ati bi iyẹn bá ṣì jẹ ète rẹ̀ sibẹ, eeṣe ti kò fi sí paradise nisinsinyi? Eeṣe, dipo eyi, ti araye fi niriiri ijiya ati aisi idajọ òdodo fun awọn ọ̀rúndún ti o pọ̀ tobẹẹ?

2 Laisi iyemeji, itan iran eniyan kun fun àre ti a ṣokunfa lati ọwó ogun, iṣẹgun lati ọwọ́ ijọba agbokeere ṣakoso, ifiniṣejẹ, aisi idajọ òdodo, òṣì, ìjábá, aisan, ati iku. Eeṣe ti awọn ohun buburu pupọ tobẹẹ fi ṣẹlẹ si awọn alaimọwọmẹsẹ pupọ tobẹẹ? Bi Ọlọrun ba jẹ alagbara gbogbo, eeṣe ti oun fi yọọda fun ijiya gígadabú bẹẹ fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun? Niwọn bi Ọlọrun ti ṣètò ti o si mu ki agbaye wàlétòletò daradara tobẹẹ, eeṣe ti oun yoo fi fayegba rudurudu ati iparun lori ilẹ̀-ayé?

Apẹẹrẹ Kan

3-5. (a) Àkàwé wo ni yoo ran wa lọwọ lati loye idi ti Ọlọrun ètò yoo fi fayegba rúdurùdu lori ilẹ̀-ayé? (b) Ewo laaarin awọn ṣiṣeeṣe melookan ni o bá ipo ori ilẹ̀-ayé mu?

3 Ẹ jẹ ki a lo apẹẹrẹ kan lati ṣakawe idi ti Ọlọrun ètò kan yoo fi fayegba rudurudu lori ilẹ̀-ayé. Jọwọ foju inu yaworan rẹ̀, pe ó rìn wọnu igbó kan lọ ti o si wá ṣalabaapade ilé kan. Bi o ti ṣayẹwo ilé yẹn, o rí i pe o rí jákujàku. Awọn ferese rẹ̀ ti fọ́, àjà rẹ̀ ti bajẹ gidigidi, ìloro rẹ̀ ti a fi igi ṣe ti kun fun ihò fórofòro, ilẹkun rẹ̀ sorọ̀ sori àgbékọ́ kanṣoṣo, awọn eto-igbekalẹ omi rẹ̀ kò ṣiṣẹ.

4 Loju gbogbo awọn abuku wọnyi, iwọ yoo ha pari èrò pe kò si olóye kan ti o ṣeeṣe ki o ti gbé ilé yẹn kalẹ̀ bi? Njẹ bi o ti ri jákujàku yoo ha mu ki o gbà pe nipa èèṣì nikan ni ilé naa le fi jẹyọ bi? Tabi bi o ba pari èrò pe ẹnikan ni o gbé e kalẹ̀ ti o si kọ́ ọ, iwọ yoo ha nimọlara pe ẹni yii kii ṣe olóye ti kò si ni ironu bi?

5 Nigba ti o bá ṣayẹwo igbekalẹ rẹ̀ kínníkínní, iwọ ri i pe a so wọn pọ̀ daradara ni ibẹrẹ pẹpẹ ti o si fi ẹri ibikita ti o kun fun ironu gidi kan han. Ṣugbọn a wulẹ ti lò o ni àlòbàjẹ́ ti o sì ti fẹrẹẹ wolulẹ nisinsinyi. Ki ni awọn àbùkù ati iṣoro naa lè fihan? Wọn dabaa pe o ṣeeṣe kí (1) onílé naa ti kú; (2) o jẹ akọle ti o dangajia ṣugbọn kò nifẹẹ si ilé naa mọ; tabi (3) ó lé ti fi ilé naa háyà fun igba diẹ fun awọn ayálégbé ti kò nimọriri. Eyi ti o kẹhin jọ ipo ti o wá lori ilẹ̀-ayé.

Ohun Ti O Ṣàìtọ́

6, 7. Ki ni ṣẹlẹ si Adamu ati Efa nigba ti wọn rú ofin Ọlọrun?

6 Lati ipilẹṣẹ akọsilẹ Bibeli, a kẹkọọ pe kii ṣe ète Ọlọrun pe ki awọn eniyan jiya ki wọn si kú. Awọn obi wa akọkọ, Adamu ati Efa, kú kiki nitori pe wọn ṣaigbọran si Ọlọrun. (Genesisi, ori 2 ati 3) Nigba ti wọn ṣaigbọran, wọn kò tun ṣe ifẹ-inu Ọlọrun mọ́. Wọn yọ araawọn kuro labẹ itọju Ọlọrun. Nipa bẹẹ, wọn já araawọn gbà kuro lọdọ Ọlọrun, “orisun iye.”—Orin Dafidi 36:9.

7 Gẹgẹ bi ẹ̀rọ kan ti agbara iṣiṣẹ rẹ̀ yoo maa dinku diẹdiẹ ti yoo si duro nigba ti a bá ti mu orisun agbara rẹ̀ kuro, ara ati èrò-inú wọn díbàjẹ́. Ni abajade eyi, Adamu ati Efa jórẹ̀hìn, wọn darugbo, wọn si kú lẹhin-o-rẹhin. Ki ni ṣẹlẹ nigba naa? Wọn pada si ibi ti wọn ti wá: “Erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ.” Ọlọrun ti kilọ fun wọn pe iku ni yoo jẹ abajade aigbọran si awọn ofin rẹ̀: “Kíkú ni iwọ o kú.”—Genesisi 2:17; 3:19.

8. Bawo ni ẹ̀ṣẹ̀ awọn obi wa akọkọ ṣe nipa lori idile eniyan?

8 Kii ṣe kiki pe awọn obi wa akọkọ kú nikan ni ṣugbọn ati gbogbo atọmọdọmọ wọn, gbogbo iran eniyan, ni a sọ di eyi ti o nilati kú. Eeṣe? Nitori pe ni ibamu pẹlu ofin ipilẹ àbùdá, awọn ọmọ ń jogun awọn animọ awọn obi wọn. Ohun ti gbogbo awọn ọmọ awọn obi wa akọkọ si jogun rẹ̀ ni àìpé ati iku. Romu 5:12 sọ fun wa pe: “Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ̀ ti ti ipa ọdọ eniyan kan [Adamu, babanla araye] wọ ayè, ati iku nipa ẹ̀ṣẹ̀; bẹẹ ni iku kọja sori eniyan gbogbo, lati ọdọ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹṣẹ [nipa jijogun àìpé, iyẹn ni, itẹsi siha didẹṣẹ].” Niwọn bi ẹ̀ṣẹ̀, àìpé, ati iku si ti jẹ kiki ohun ti awọn eniyan mọ̀, awọn kan kà wọn sí ohun adanida ti kò si ṣeeyẹsilẹ. Sibẹ, awọn eniyan ipilẹṣẹ ni a dá pẹlu agbara ati ifẹ-ọkan lati walaaye titilae. Idi niyẹn ti ọpọ julọ ninu awọn eniyan fi rí ṣiṣeeṣe naa pe iwalaaye wọn ni iku yoo kekuru laipẹ bi eyi ti ń janikulẹ gidigidi.

Eeṣe Ti O Fi Pẹ́ Tobẹẹ?

9. Eeṣe ti Ọlọrun fi yọnda fun ijiya lati maa baa lọ fun igba pipẹ tobẹẹ?

9 Eeṣe ti Ọlọrun fi fayegba eniyan lati ṣe ohun ti o wù wọn fun akoko pipẹ tobẹẹ? Eeṣe ti oun fi gbà ki ijiya wà ni gbogbo awọn ọ̀rúndún wọnyi? Idi pataki kan ni pe ariyanjiyan pataki kan ni a gbe dide: Ta ni o ní ẹ̀tọ́ lati ṣakoso? Ọlọrun ha ni o yẹ ki o jẹ Alakooso awọn eniyan bi, tabi wọn ha le ṣakoso araawọn pẹlu aṣeyọri laisi i bi?

10. Agbara iṣe wo ni a fifun awọn eniyan, pẹlu ẹru iṣẹ wo?

10 Awọn eniyan ni a dá pẹlu ominira ifẹ-inu, iyẹn ni pe, pẹlu agbara lati ṣe yiyan. A kò dá wọn bi awọn ẹ̀rọ robọọti tabi awọn ẹranko, ti itẹsi ìwà adanida ń dari. Nitori naa awọn eniyan le yan ẹni ti wọn yoo sìn. (Deuteronomi 30:19; 2 Korinti 3:17) Nipa bẹẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà wa nimọran pe: “Bi ominira, laisi lo ominira yin fun ohun bibo arankan yin mọlẹ, ṣugbọn bi ẹru Ọlọrun.” (1 Peteru 2:16) Bi o ti wu ki o ri, bi o ti jẹ pe awọn eniyan ni ẹbun ominira lati ṣe yiyan, wọn nilati tẹwọgba abajade ọ̀nà igbegbeesẹ ti wọn bá yàn.

11. Ki ni yoo jẹ ọ̀nà kanṣoṣo lati gbà fi ṣawari boya iṣakoso eniyan laisi ọwọ́ Ọlọrun nibẹ le ṣaṣeyọri?

11 Awọn obi wa akọkọ ṣe yiyan ti o lòdì. Wọn yan ipa-ọna idadurolominira kuro lọdọ Ọlọrun. Lotiitọ, Ọlọrun ti lè pa awọn ọlọ̀tẹ̀ meji akọkọ gbàrà lẹhin ti wọn ti ṣi ominira ifẹ-inu wọn lò. Ṣugbọn iyẹn kìbá ti yanju ibeere nipa ẹ̀tọ́ Ọlọrun lati ṣakoso awọn eniyan. Niwọn bi awọn eniyan meji akọkọ ti ń fẹ ominira kuro lọdọ Ọlọrun, ibeere naa ni a nilati dahun: Ipa ọ̀nà yẹn ha le yọrisi igbesi-aye alayọ, alaṣeyọri kan bi? Ọ̀nà kanṣoṣo lati gbà ṣawari iyẹn ni lati jẹ ki awọn obi wa akọkọ ati awọn ọmọ wọn ṣe ohun ti o wù wọn, niwọn bi iyẹn ti jẹ ohun ti wọn yàn. Akoko yoo fihan boya a dá awọn eniyan lati ṣaṣeyọri ni ṣiṣakoso araawọn laigbarale Ẹlẹdaa wọn.

12. Bawo ni Jeremiah ṣe diwọn iṣakoso eniyan, eesitiṣe ti eyi fi ri bẹẹ?

12 Òǹkọ̀wé Bibeli naa Jeremiah mọ̀ ohun ti abajade naa yoo jẹ. Bi ẹ̀mí mímọ́ alagbara, tabi ipá agbékánkán ṣiṣẹ Ọlọrun ti dari rẹ̀, oun fi tootọ tootọ kọwe pe: “Oluwa! emi mọ̀ pe, ọ̀nà eniyan kò si ni ipa araarẹ̀: kò si ni ipá eniyan ti ń rin, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀. [Tọ́ mi sọ́nà, NW] Oluwa.” (Jeremiah 10:23, 24) Oun mọ̀ pe awọn eniyan gbọdọ gba itọsọna ọgbọn atọrunwa Ọlọrun. Eeṣe? Kiki nitori pe Ọlọrun kò dá awọn eniyan lati ṣaṣeyọri laisi itọsọna rẹ̀.

13. Ki ni abajade ẹgbẹẹgbẹrun ọdun iṣakoso eniyan ti fihan laisi iyemeji kankan?

13 Abajade ẹgbẹẹgbẹrun ọdun iṣakoso eniyan fihan rekọja iyemeji eyikeyii pe, kò si ni agbara eniyan lati dari awọn ọran wọn laisi ọwọ́ Ẹlẹdaa wọn nibẹ. Lẹhin gbigbiyanju rẹ̀, kiki araawọn ni wọn le dẹbi awọn abajade oníjábá naa fun. Bibeli mu ki o ṣe kedere pe: “Apata naa [Ọlọrun], pipe ni iṣẹ rẹ̀; nitori pe idajọ ni gbogbo ọna rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alaiṣegbe, òdodo ati otitọ ni oun. Wọn ti ba araawọn jẹ́ lọdọ rẹ̀, wọn kii ṣe ọmọ rẹ̀, abuku wọn ni.”—Deuteronomi 32:4, 5.

Ọlọrun Yoo Dásí I Laipẹ

14. Eeṣe ti Ọlọrun ki yoo fi jẹ ki dídá ti oun yoo dásí ọran eniyan pẹ́ sii mọ́?

14 Lẹhin yiyọnda aṣefihan pupọ tó fun ìkùnà iṣakoso eniyan la ọpọ ọ̀rúndún akoko já, Ọlọrun le wá dásí ọran awọn eniyan ki o si dá ijiya, irora, aisan, ati iku duro. Ni yiyọnda fun awọn eniyan lati dori òtéńté aṣeyọri wọn ninu imọ ijinlẹ, ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ, oogun, ati ni awọn pápá miiran, kò tun si idi kankan mọ́ fun Ọlọrun lati fayegba awọn ọ̀rúndún akoko fun ìwàlómìnira awọn eniyan kuro lọdọ Ẹlẹdaa wọn lati le fihan boya wọn le mu ayé paradise, alalaafia kan wá. Wọn kò tíì ṣe bẹẹ wọn kò si le ṣe bẹẹ. Ominira kuro lọdọ Ọlọrun ti yọrisi ayé kan ti o buru jai, ti o kun fun ikoriira, ti o si jẹ aṣekupani.

15. Imọran Bibeli wo ni o yẹ ki a ṣegbọran si?

15 Bi o tilẹ jẹ pe awọn alakooso olotiitọ-inu ti wọn fẹ lati ran araye lọwọ ti wà, awọn isapa wọn kò tíì ṣaṣeyọri. Ẹri ìkùnà iṣakoso eniyan wà nibi gbogbo lonii. Idi niyẹn ti Bibeli fi gbaninimọran pe: “Ẹ maṣe gbẹkẹ yin le awọn ọmọ-alade, ani le ọmọ eniyan, lọwọ ẹni ti kò si iranlọwọ.”—Orin Dafidi 146:3.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Koda awọn alakooso ayé olotiitọ-inu kò tíì le mu ki ayé paradise, alalaafia ṣeeṣe