Igbesi-aye Ha Ní Ète Kan Ninu Bi?
Ìsọ̀rí 1
Igbesi-aye Ha Ní Ète Kan Ninu Bi?
1. Ki ni a saba maa ń beere nipa ète igbesi-aye, bawo si ni ẹnikan ṣe sọrọ nipa rẹ̀?
Bópẹ́bóyá, o fẹrẹẹ jẹ gbogbo eniyan ni o ń ṣekayefi nipa ohun ti ète iwalaaye jẹ́. O ha jẹ lati ṣiṣẹ́ kára lati mu ki ipo igbesi-aye wa sunwọn sii, lati pese fun awọn idile wa, lati kú lẹhin boya 70 tabi 80 ọdun, ati lẹhin naa ki a di alaisi mọ titilae bi? Ọ̀dọ́ kan ti o nimọlara lọna yii sọ pe kò si ète ninu igbesi-aye ju lati “gbe láyé, lati ní awọn ọmọ, lati layọ ati lẹhin naa lati kú.” Ṣugbọn iyẹn ha jẹ otitọ bi? Ikú ha sì ni opin gbogbo rẹ̀ bi?
2, 3. Eeṣe ti kíkó dúkìá jọ kò fi tó fun ète kan ti o wà ninu igbesi-aye?
2 Ọpọlọpọ ní awọn ilẹ̀ Ìlà-Oòrùn ati Ìwọ̀-Oòrùn Ayé rò pe ète pataki fun wiwalaaye ni lati kó dúkìá jọ. Wọn gbagbọ pe eyi le ṣamọna si igbesi-aye alayọ, ti o ní itumọ. Ṣugbọn ki ni nipa awọn wọnni ti wọn ti ní dúkìá? Òǹkọ̀wé ọmọ Canada naa Harry Bruce sọ pe: “Iye yiyanilẹnu ninu awọn ọlọ́rọ̀ ni wọn ń tẹnumọ ọn pe awọn kò layọ.” O fikun un pe: “Iwadiiwo kaakiri fihan pe ipo aisi ireti ti o burujai ni o ti gba Guusu America kan . . . Ẹnikẹni ha layọ ninu ayé yii bi? Bi o bá rí bẹẹ, ki ni àṣírí rẹ̀?”
3 Ààrẹ U.S. tẹlẹri Jimmy Carter sọ pe: “A ti ṣawari pe níní awọn nǹkan ati lilo awọn nǹkan kò tẹ́ ìyánhànhàn wa fun itumọ lọ́rùn. . . . Kíkó dúkìá jọ kò le dí ofifo inu igbesi-aye ti kò ni idaniloju tabi ète.” Aṣaaju òṣèlú miiran sì tun sọ pe: “Fun ọdun melookan bayii ni mo ti kowọnu iwakiri kikankikan fun otitọ nipa araami ati igbesi-aye mi; ọpọ eniyan ti mo mọ̀ ni wọn ń ṣe ohun kan naa. Awọn eniyan pupọ sii ju ti igbakigba rí lọ ni o ń beere pe, ‘Ta ni awa jẹ? Ki ni ète wa?’”
Ipo Awọn Nǹkan Nira Sii
4. Eeṣe ti awọn kan fi ṣiyemeji nipa pe igbesi-aye ni ète eyikeyii ninu?
4 Ọpọ ṣiyemeji nipa pe igbesi-aye ni ète kan nigba ti wọn ba ríi pe ipo igbesi-aye ti di eyi ti o nira sii. Jakejado ayé, eyi ti o ju billion kan eniyan ní ń ṣaisan tabi ti wọn kò jẹunrekanu, ti eyi sì ń yọrisi iku nǹkan bi aadọta ọkẹ lọna mẹwaa awọn ọmọde lọdọọdun ní Africa nikan. Iye awọn olugbe ayé, tí ń sunmọ billion mẹfa, ń baa lọ lati ga sii ni iye ti o ju aadọta ọkẹ lọna aadọrun-un lọdun, iye ti o ju ipin 90 ninu ọgọrun-un igasoke yii jẹ ní awọn orilẹ-ede ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń goke àgbà. Iye awọn olugbe ayé tí ń bisii nigba gbogbo yii ń pakun aini fun ounjẹ, ilé gbígbé, ati ilé-iṣẹ́, eyi ti ń fa ìbàjẹ́ siwaju sii fun ilẹ̀, omi, ati atẹgun, lati ara awọn ohun abayikajẹ awọn ilé-iṣẹ́ ati awọn miiran.
5. Ki ni o ń ṣẹlẹ si awọn eweko lori ilẹ̀-ayé?
5 Ìwé naa World Military and Social Expenditures 1991 rohin pe: “Lọdọọdun ni a ń pa àyè igbó ti o tó oju ilẹ̀ [Great Britain] run. Ni idiwọn (bi a ti ń rẹ́ wọn lulẹ̀) ni lọọlọọ, ni nǹkan bii ọdun 2000, a o ti mu ipin 65 ninu ọgọrun-un igbó awọn agbegbe ilẹ̀ olooru kuro.” Ni awọn agbegbe wọnyẹn, gẹgẹ bi aṣoju ajọ Iparapọ Awọn Orilẹ-Ede kan ti wi, lori igi 1 ti a bá gbìn a ń gé 10 dipo; ni Africa ipindọgba rẹ̀ ju 20 si 1. Nitori naa ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń gbilẹ sii, ati lọdọọdun agbegbe ilẹ̀ ti o tó oju ilẹ̀ Belgium ni a ń padanu rẹ̀ nitori ìlò iṣẹ́ àgbẹ̀.
6, 7. Ki ni diẹ lara awọn iṣoro ti awọn aṣaaju eniyan kò le yanju, nitori naa awọn ibeere wo ni o ń beere pe ki a dahun?
6 Bakan naa, awọn oku ogun ní ọ̀rúndún ogun yii jẹ ilọpo mẹrin iye ti ọ̀rúndún mẹrin sẹhin lapapọ. Ìwà-ọ̀daràn ti bisii nibi gbogbo, paapaa ìwà-ọ̀daràn oníkà. Ìwólulẹ̀ idile, ilokulo oogun, arun AIDS, arun abẹ́, ati awọn okunfa buruku miiran pẹlu ń mu ki igbesi-aye nira sii. Awọn aṣaaju ayé kò sì tíì le pese ojútùú si ọpọlọpọ iṣoro yii tí ń yọ idile araye lẹnu. Ó yeni, nigba naa, idi rẹ̀ ti awọn eniyan fi ń beere pe, Ki ni ète igbesi-aye?
7 Bawo ni awọn ọmọwe ati aṣaaju isin ṣe dahun ibeere naa? Lẹhin ọpọ ọ̀rúndún akoko, wọn ha ti pese idahun ti o tẹnilọrun bi?
Ohun Ti Wọn Sọ
8, 9. (a) Ki ni ọmọwe ara China kan sọ nipa ète igbesi-aye? (b) Ki ni olùla àgọ́ ìfìṣẹ́-ṣekúpani ti Nazi já kan sọ?
8 Ọmọwe ilé-ẹ̀kọ́ Confucius naa Tu Wei-Ming sọ pe: “Paríparì itumọ igbesi-aye patapata ni a rí ninu wíwà ti awa eniyan wà lasan.” Gẹgẹ bi oju-iwoye yii ti wi, a o maa baa lọ lati bí eniyan, lati jìjàdù fun iwalaaye, ati lati kú. Kò si ireti gidi kan ninu iru oju-iwoye bẹẹ. O ha tilẹ jẹ otitọ bi?
9 Elie Wiesel, olùla àgọ́ ìfìṣẹ́-ṣekúpani ti Nazi lakooko Ogun Agbaye Keji já, sọrọ akiyesi pe: “‘Eeṣe ti a fi wà nihin-in?’ ni ibeere pataki julọ ti ẹda eniyan kan nilati kojú. . . . Mo gbagbọ pe igbesi-aye ní itumọ laika awọn ikú alainitumọ ti mo ti rí sí.” Ṣugbọn oun kò le sọ ohun ti itumọ igbesi-aye jẹ́.
10, 11. (a) Bawo ni oluyẹwoṣatunṣe ìwé kan ṣe fihan pe eniyan kò ní idahun naa? (b) Eeṣe ti oju-iwoye onimọ ijinlẹ nipa ẹfoluṣọn kan kò fi tẹnilọrun?
10 Oluyẹwoṣatunṣe ìwé, Vermont Royster sọ pe: “Ninu ìṣàṣàrò nipa eniyan fúnraarẹ̀, . . . nipa àyè rẹ̀ ninu agbaye yii, a kò tíì fi bẹẹ rìn jìnnà ju ìgbà tí akoko bẹrẹ lọ. Ibeere nipa ẹni ti a jẹ ati idi ti a fi wà ati ibi ti a ń lọ ṣì wa nibẹ fun wa lati dahun.”
11 Onimọ ijinlẹ nipa ẹfoluṣọn naa Stephen Jay Gould ṣakiyesi pe: “Awa lè yánhànhàn fun idahun ‘giga ju’ kan—ṣugbọn kò si eyikeyii ti o wà.” Fun iru awọn ẹlẹkọọ ẹfoluṣọn bẹẹ, igbesi-aye jẹ ìjìjàdù ti alágbára-ní-ń-ṣayé, ikú sì ni paríparí rẹ̀. Kò si ireti ninu oju-iwoye yẹn pẹlu. Lẹẹkan sii, o ha jẹ otitọ bi?
12, 13. Ki ni awọn oju-iwoye awọn aṣaaju ṣọọṣi, wọn ha si tẹnilọrun ju ti awọn alakiyesi ti ayé bi?
12 Ọpọlọpọ awọn aṣaaju isin sọ pe ète igbesi-aye ni lati gbé ìgbé-ayé rere ti o fi jẹ pe nigba ikú ọkàn ẹni yoo le lọ si ọrun ki o si wà nibẹ titi ayeraye. Yíyàn keji ti wọn fun awọn ẹni buruku ni idaloro ayeraye ninu iná ọrun apaadi. Sibẹ, ni ibamu pẹlu igbagbọ yii, lori ilẹ̀-ayé, pupọ sii ipo airi itẹlọrun ninu igbesi-aye kan naa ti o ti gbodekan jálẹ̀ inu itan ni yoo maa baa lọ lati wà. Ṣugbọn bi o bá ṣe pe ète Ọlọrun ni lati mu ki awọn eniyan gbé ni ọrun gẹgẹ bi awọn angẹli, eeṣe ti oun kò fi ti kúkú dá wọn bẹẹ, bi oun ti ṣe dá awọn angẹli?
13 Koda iru oju-iwoye bẹẹ jẹ iṣoro fun ẹgbẹ awọn alufaa. Dokita W. R. Inge, alufaa agba tẹlẹri ni Katidira ti St. Paul ni London, sọ nigbakan pe: “Mo ti jìjàdù ni gbogbo igbesi-aye mi lati wá ète wiwalaaye rí. Mo ti gbiyanju lati
dahun awọn iṣoro mẹta ti o saba maa ń dabi eyi ti o ṣekoko loju mi: iṣoro wíwà titi ayeraye; iṣoro akopọ-animọ eniyan; ati iṣoro ìwàibi. Mo ti kùnà. Kò si eyikeyii ninu wọn ti mo yanju.”Iyọrisi Rẹ̀
14, 15. Ki ni iyọrisi tí awọn oju-iwoye titakora naa ní lori ọpọ eniyan?
14 Ki ni iyọrisi oriṣiriṣi awọn èròǹgbà awọn ọmọwe ati aṣaaju isin lori ibeere ète igbesi-aye? Ọpọ dahun bi ọkunrin agbalagba kan ti o sọ pe: “Mo ti ń beere idi ti mo fi wà nihin-in ni eyi ti o pọ̀ julọ ninu igbesi-aye mi. Bi ète kan bá wà emi kò bikita mọ́.”
15 Iye pupọ kan ti wọn ṣakiyesi ọpọ yamùrá oju-iwoye laaarin awọn aṣaaju isin ayé dori opin èrò naa pe ohun ti ẹnikan gbagbọ kò ṣe pataki. Wọn lérò pe isin wulẹ jẹ ohun àyàbá fun ọkàn, ohun kan lati mu alaafia ọkàn ati ìtura diẹ wà ki o baa lè ṣeeṣe funni lati kojú awọn iṣoro igbesi-aye. Awọn miiran lérò pe isin kò ju igbagbọ ninu ohun asan lọ. Wọn ni èrò pe ìméfò isin fun ọgọrọọrun ọdun kò tíì dahun ibeere nipa ète igbesi-aye, bẹẹ si ni kò mu ki igbesi-aye awọn gbáàtúù eniyan sunwọn sii. Nitootọ, itan fihan pe isin ayé yii ti saba maa ń fa ifasẹhin ninu ilọsiwaju iran eniyan ti wọn si ti jẹ okunfa ikoriira ati awọn ogun.
16. Bawo ni ṣiṣawari ète igbesi-aye ti le ṣe pataki to?
16 Sibẹ, o ha tilẹ ṣe pataki lati wá otitọ nipa ète igbesi-aye rí bi? Ọjọgbọn nipa ilera ọpọlọ naa Viktor Frankl dahun pe: “Ìlàkàkà lati rí itumọ ninu igbesi-aye ẹni ni agbara isunniṣe ipilẹ ninu eniyan. . . . Kò si ohunkohun ninu ayé, ni mo fi igboya sọ, ti o le ṣeranlọwọ fun ẹnikan lọna ti o gbeṣẹ tobẹẹ lati la koda awọn ipo ti o buru julọ já, bii imọ naa pe igbesi-aye ẹni ní itumọ.”
17. Awọn ibeere wo ni o yẹ ki a wá beere nisinsinyii?
17 Niwọn bi awọn ẹ̀kọ́ èrò-orí ati isin eniyan kò ti ṣalaye lọna ti o tẹnilọrun nipa ohun ti ète igbesi-aye jẹ, nibo ni a le lọ lati rí ohun ti o jẹ? Orisun ọgbọn ti o ga ju ha wà ti o le sọ otitọ fun wa nipa ọran yii bi?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“Lọdọọdun ni a ń pa àyè igbó ti o tó oju ilẹ̀ [Great Britain] run”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
“Mo ti ń beere idi ti mo fi wà nihin-in ni eyi ti o pọ̀ julọ ninu igbesi-aye mi”