Igbesi-aye Ni Ète Ọlọ́láńlá Kan Ninu
Ìsọ̀rí 5
Igbesi-aye Ni Ète Ọlọ́láńlá Kan Ninu
1, 2. Bawo ni a ṣe le mọ daju pe Ọlọrun bikita nipa wa, nibo ni o sì yẹ ki a yiju si fun awọn idahun si awọn ibeere igbesi-aye?
1 Ọ̀nà ti a gbà dá ayé ati awọn ohun alaaye inu rẹ̀ fihan pe Ẹlẹdaa wọn jẹ Ọlọrun ifẹ, ti o bikita gidigidi. Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, fihan pe oun bikita; ó fun wa ni awọn idahun ti o dara julọ nipa awọn ibeere naa: Eeṣe ti a fi wà lori ilẹ̀-ayé nihin-in? ati, Nibo ni a ń lọ?
2 A nilati wá inu Bibeli fun awọn idahun wọnyẹn. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pe: “Bi ẹyin ba si ṣafẹri rẹ̀, ẹyin o rí i; ṣugbọn bi ẹyin bá kọ̀ ọ́, oun o si kọ̀ yin.” (2 Kronika 15:2) Nitori naa, ki ni iwadii Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣipaya nipa ète rẹ̀ fun wa?
Idi ti Ọlọrun Fi Dá Awọn Eniyan
3. Eeṣe ti Ọlọrun fi dá ilẹ̀-ayé?
3 Bibeli fihan pe Ọlọrun mura ayé silẹ pẹlu níní awọn eniyan lọkan ni pataki. Isaiah 45:18 sọ nipa ilẹ̀-ayé pe Ọlọrun “kò dá a lasan, [ṣugbọn] o mọ ọn ki a le gbe inu rẹ̀.” Ó si pese ohun gbogbo ti awọn eniyan yoo nilo sinu ilẹ̀-ayé, kii ṣe lati fi le wulẹ walaaye, ṣugbọn lati gbadun iwalaaye dé ẹkunrẹrẹ.—Genesisi, ori 1 ati 2.
4. Eeṣe ti Ọlọrun fi ṣẹda awọn eniyan akọkọ?
4 Ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọlọrun sọ nipa ṣiṣẹda awọn eniyan akọkọ, Adamu ati Efa, ó si ṣi ohun ti oun ni lọkan fun idile eniyan paya. Ó wi pe: “Jẹ ki a dá eniyan ni aworan wa, gẹgẹ bi ìrí wa: ki wọn ki ó si jọba lori ẹja òkun, ati lori ẹyẹ oju ọrun ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ̀, ati lori ohun gbogbo ti ń rákò lori ilẹ̀.” (Genesisi 1:26) Awọn eniyan ni yoo bojuto “gbogbo ilẹ̀” ati awọn ẹ̀dá ẹranko ti o wà ninu rẹ̀.
5. Nibo ni a fi awọn eniyan akọkọ si?
5 Ọlọrun ṣe ọgbà ńla, bii ọgbà-ìtura si agbegbe kan ti a pe ni Edeni, ti o wà ni Àárín Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn Ayé. Nigba naa “o si fi [ọkunrin naa] sinu ọgbà Edeni lati maa ro ó ati lati maa ṣọ́ ọ.” O jẹ paradise kan ti o ní gbogbo ohun ti awọn eniyan akọkọ yoo nilo lati jẹ ninu. Ó si ní ninu “oniruuru igi . . . ti o dara ni wíwò, ti o si dara fun ounjẹ,” ati bakan naa gbogbo awọn eweko ati ọpọ oniruuru awọn ẹranko ti o fanimọra.—Genesisi 2:7-9, 15.
6. Animọ ti ọpọlọ ati ti ara-iyara wo ni a dá mọ́ awọn eniyan?
6 A dá ara awọn eniyan akọkọ ni pipe, nitori naa wọn kò ni ṣaisan, darugbo, ki wọn sì kú. A tun fun wọn ni ẹbun awọn animọ miiran pẹlu, iru bii ti ominira ifẹ-inu. Ọ̀nà ti a gbà fi dá wọn ni a mẹnukan ninu Genesisi 1:27: “Ọlọrun dà eniyan ni aworan rẹ̀, ni aworan Ọlọrun ni o dá a; ati akọ ati abo ni o dá wọn.” Niwọn bi a ti dá wa ni aworan Ọlọrun, o tumọsi pe kii ṣe pe a ni awọn animọ niti ara-iyara ati ọpọlọ nikan ni ṣugbọn pe a ni ti ẹ̀ka iwarere ati tẹmi ti a si gbọdọ tẹ́ iwọnyi lọ́rùn bi a o bá layọ nitootọ. Ọlọrun ni yoo pese ọ̀nà lati gbà tẹ́ awọn aini wọnni lọrun bakan naa sì ni aini fun ounjẹ, omi, ati atẹ́gùn. Gẹgẹ bi Jesu Kristi ti wi, “eniyan ki yoo walaaye nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ̀ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá.”—Matteu 4:4.
7. Aṣẹ wo ni a fifun awọn tọkọtaya akọkọ naa?
7 Jù bẹẹ lọ, Ọlọrun fun awọn tọkọtaya akọkọ ni àṣẹ agbayanu kan nigba ti wọn wà Genesisi 1:28) Nitori naa wọn yoo le mu iru-ọmọ jade ki wọn si bí awọn ọmọ pípé. Bi iye eniyan sì ti ń pọ̀ sii, wọn yoo ni iṣẹ alayọ ti mimu ki awọn ààlà agbegbe paradise Edeni ipilẹṣẹ, ti o dabi ọgbà-ìtura naa gbooro siwaju sii. Ni opin rẹ̀ patapata, gbogbo ayé ni a o sọ di paradise, tí awọn eniyan pipe, alayọ tí wọn walaaye titilae, yoo maa gbé. Bibeli sọ fun wa pe lẹhin mimu ki gbogbo eyi bẹrẹ iṣẹ, “Ọlọrun si rí ohun gbogbo ti o dá, si kiyesii, daradara ni.”—Genesisi 1:31; tun wo Orin Dafidi 118:17 pẹlu.
ni Edeni pe: “Ẹ maa bí si i, ki ẹ si maa rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ.” (8. Bawo ni awọn eniyan yoo ṣe bojuto ilẹ̀-ayé?
8 O ṣe kedere pe awọn eniyan ìbá lo ayé ti a ṣekawọ rẹ̀ naa fun anfaani tiwọn. Ṣugbọn a o nilati ṣe eyi lọna ti o mọgbọndani. Awọn eniyan yoo nilati jẹ ìríjú ọlọ́wọ̀ fun ilẹ̀-ayé, kii ṣe awọn ti yoo jẹ ẹ́ ni àjẹrun. Iparun ilẹ̀-ayé ti a ń niriiri rẹ̀ lonii lodisi ifẹ-inu Ọlọrun, awọn ti wọn si ń lọwọ ninu rẹ̀ ń ṣe ohun ti o lodisi ète iwalaaye lori ilẹ̀-ayé. Wọn yoo nilati san ìtanràn nitori iyẹn, nitori Bibeli sọ pe Ọlọrun yoo “run awọn ti ń pa ayé run.”—Ìfihàn 11:18.
Ó Ṣì Jẹ Ète Ọlọrun
9. Eeṣe ti a fi ni idaniloju pe ète Ọlọrun ni a o muṣẹ?
9 Nipa bẹẹ, lati iḅerẹ pẹpẹ ó jẹ ète Ọlọrun pe ki idile eniyan pipe gbe nihin-in lori ilẹ̀-ayé titilae ninu paradise. Ète rẹ̀ ni o ṣì jẹ sibẹ! Ète yẹn, yoo ṣẹ, láìkùnà. Bibeli sọ pe: “Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bura, wi pe, Loootọ gẹgẹ bi mo ti gbèrò, bẹẹ ni yoo rí, ati gẹgẹ bi mo ti pinnu, bẹẹ ni yoo si duro.” “Emi ti sọ ọ, emi o si mu un ṣẹ; emi ti pinnu rẹ̀, emi o si ṣe e pẹlu.”—Isaiah 14:24; 46:11.
10, 11. Bawo ni Jesu, Peteru, ati olorin naa Dafidi ṣe sọrọ nipa Paradise?
10 Jesu Kristi sọ nipa ète Ọlọrun lati mu paradise kan padabọsipo lori ilẹ̀-ayé nigba ti o sọ fun ọkunrin kan ti o ń fẹ ireti fun ọjọ-ọla: “Iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.” (Luku 23:43) Aposteli Peteru, pẹlu, sọrọ nipa ayé titun ti ń bọ̀ nigba ti o sọ tẹ́lẹ̀ pe: “Gẹgẹ bi ileri [Ọlọrun], awa ń reti awọn ọrun titun [ìṣètò ijọba titun ti yoo ṣakoso latọrun-wa] ati ayé titun [awujọ eniyan titun lori ilẹ̀-ayé], ninu eyi ti òdodo ń gbé.”—2 Peteru 3:13.
11 Olorin naa Dafidi kọwe bakan naa nipa ayé titun ti ń bọ̀ naa ati bi yoo ti wà pẹ titi tó. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pe: “Olododo ni yoo jogun ayé, yoo si ma gbe inu rẹ̀ laelae.” (Orin Dafidi 37:29) Idi niyẹn ti Jesu fi ṣeleri pe: “Alabukun fun ni awọn ọlọkan tutu: nitori wọn o jogún ayé.”—Matteu 5:5.
12, 13. Ṣakopọ ète ọlọ́láńlá Ọlọrun fun araye.
12 Ẹ wo iru ifojusọna agbayanu ti iyẹn jẹ, wiwalaaye titilae ninu paradise ori ilẹ̀-ayé kan ti o bọ lọwọ gbogbo ìwà-ibi, ìwà ọdaran, aisan, ibanujẹ, ati irora! Ninu ìwé ti o kẹhin Bibeli, Ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ Ọlọrun ṣakopọ ète ńláǹlà yii nipa pipolongo pe: “Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo sì sí iku mọ, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkún, bẹẹ ni ki yoo sí irora mọ́: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.” Ó fikun pe: “Ẹni ti o jokoo lori ìtẹ́ nì si wi pe, Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtun. Ó sì wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀: nitori ọ̀rọ̀ wọnyi òdodo ati otitọ ni wọn.”—Ìfihàn 21:4, 5.
13 Bẹẹni, Ọlọrun ni ète ọlọ́láńlá kan lọkan. Yoo jẹ ayé titun òdodo kan, paradise ayeraye kan, ti a sọtẹlẹ lati ọdọ Ẹni naa ti o lè ti yoo si ṣe awọn ohun ti o ṣelẹri, nitori “ọ̀rọ̀” rẹ̀ “òdodo ati otitọ ni.”
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Ọlọrun pete ki awọn eniyan gbé titilae lori paradise ilẹ̀-ayé. Ète rẹ̀ ṣì niyẹn sibẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Onílé kan le kesi awọn ayálégbé ti wọn ba ilé rẹ̀ jẹ lati jẹ́jọ́