Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orisun Àrà-ọ̀tọ̀ Ti Ọgbọn Ti O Ga Ju

Orisun Àrà-ọ̀tọ̀ Ti Ọgbọn Ti O Ga Ju

Ìsọ̀rí 3

Orisun Àrà-ọ̀tọ̀ Ti Ọgbọn Ti O Ga Ju

1, 2. Eeṣe ti o fi yẹ ki a ṣayẹwo Bibeli?

1 Bibeli ha ni akọsilẹ ọgbọn ti o ga ju yẹn bi? O ha fun wa ní awọn idahun ti o kun fun otitọ si awọn ibeere pataki ti o nii ṣe pẹlu ète igbesi-aye bi?

2 Dajudaju Bibeli yẹ fun ayẹwo wa. Idi kan ni pe oun ni ìwé ti o ṣàrà-ọ̀tọ̀ julọ ti a tíì ṣàkójọ rẹ̀ rí, ti o yatọ patapata gbáà si ìwé eyikeyii. Gbe awọn kókó ti o tẹle e wọnyi yẹwo.

Ọlọjọ Lori Julọ, Tí Ipinkiri Rẹ̀ Pọ̀ Julọ

3, 4. Bawo ni Bibeli ti lọjọ lori tó?

3 Bibeli ni ìwé ti o lọjọ lori julọ ti a tíì kọ rí, tí apakan rẹ̀ jẹ eyi ti a ṣàkójọ ní nǹkan bii 3,500 ọdun sẹhin. Ọjọ ori rẹ̀ fi ọpọ ọ̀rúndún ju ti ìwé eyikeyii miiran ti a kàsí eyi ti o jẹ mímọ́. Akọkọ lara ìwé 66 ti o wà ninu rẹ̀ ni a kọ ní nǹkan bii ẹgbẹrun ọdun ṣaaju Buddha ati Confucius ati nǹkan bii ẹgbẹrun ọdun meji ṣaaju Muḥammad.

4 Itan ti a kọsilẹ ninu Bibeli lọ jìnnà sẹhin si ibẹrẹ idile iran eniyan ti o sì ṣalaye bi o ṣe di wi pe a dé ori ilẹ̀-ayé nihin-in. O tilẹ mu wa pada sẹhin si igba ti o wà ṣaaju ki a to dá awọn eniyan, ni fifun wa ni awọn otitọ iṣẹlẹ nipa bi a ṣe ṣẹda ayé.

5. Awọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ atijọ ti Bibeli meloo ni o wà, ni ifiwera pẹlu awọn ìwé akọsilẹ atijọ ti ayé?

5 Kiki ẹ̀dà melookan awọn ìwé àdàkọ aláfọwọ́kọ ogbologboo awọn ìwé isin miiran, ati awọn ti kii ṣe ti isin pẹlu, ní wọn wà lọwọ. Nǹkan bii 11,000 awọn ẹ̀dà àdàkọ aláfọwọ́kọ ti Bibeli tabi apakan rẹ̀ ni o wà ni èdè Heberu ati Griki, diẹ ninu eyi ti o sunmọ ìgbà ti a ṣakọsilẹ wọn ní ìbẹ̀rẹ̀pàá. Iwọnyi ti là á já bi o tilẹ jẹ pe àtakò ti o kira julọ ti a lè ronuwoye ni a ti gbidanwo lodisi Bibeli.

6. Bawo ni ipinkiri Bibeli ti gbooro tó?

6 Bakan naa, lọna ti o tayọ jìnnàjìnnà, Bibeli ni ìwé ti a tíì pinkiri julọ ninu itan. Nǹkan bii billion mẹta awọn Bibeli tabi apakan rẹ̀ ni a ti pinkiri ni nǹkan bii ẹgbẹrun meji èdè. A sọ pe nǹkan bii ipin 98 ninu ọgọrun-un ninu idile iran eniyan ni wọn ní Bibeli ni èdè tiwọn. Kò si ìwé miiran ti o sunmọ iye ipinkiri yẹn.

7. Ki ni a le sọ nipa ìpéye Bibeli?

7 Ni afikun, kò si ìwé atijọ ti o ṣeefiwera pẹlu Bibeli ni ìpéye. Awọn onimọ ijinlẹ, òpìtàn, awalẹ̀pìtàn, onimọ nipa ojú ilẹ̀-ayé, awọn ògbógi ninu èdè, ati awọn miiran ń baa lọ lati jẹrii si awọn akọsilẹ Bibeli.

Ìpéye Niti Imọ Ijinlẹ

8. Bawo ni Bibeli ti péye tó niti ọran imọ ijinlẹ?

8 Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ a kò kọ Bibeli gẹgẹ bi ìwé ẹ̀kọ́ lori imọ ijinlẹ, wẹku ni o ṣe pẹlu imọ ijinlẹ tootọ nigba ti o bá sọrọ nipa awọn ọran ti o nii ṣe pẹlu imọ ijinlẹ. Ṣugbọn awọn ìwé atijọ yooku ti a kà si mímọ́ kun fun itan àròsọ, àìpéye, ati irọ́ funfun balau niti imọ ijinlẹ. Ṣakiyesi kiki mẹrin pere ninu ọpọ awọn apẹẹrẹ ìpéye Bibeli niti imọ ijinlẹ:

9, 10. Dipo ṣiṣagbeyọ awọn oju-iwoye alaiba imọ ijinlẹ mu ti akoko rẹ̀, ki ni Bibeli sọ nipa ohun ti o gbé ilẹ̀-ayé ró?

9 Bi a ṣe so ayé rọ̀ loju ofuurufu. Ni ìgbà atijọ nigba ti a ń kọ Bibeli, oriṣiriṣi àbá ni o wà nipa bi a ṣe so ayé rọ̀ loju ofuurufu. Awọn kan gbagbọ pe erin mẹrin ti o duro sori ìjàpá òkun nla kan ni o gbé ayé ró. Aristotle, ara Griki ẹlẹkọọ èrò-orí ati onimọ ijinlẹ ti ọ̀rúndún kẹrin B.C.E., kọni pe ayé kò le sorọ̀ lori ofuurufu lasan lae. Kàkà bẹẹ, o kọni pe ń ṣe ni a de awọn ẹ̀dá ọ̀run mọ ojú awọn àgbá ti o fi odikeji hàn rekete, ti a si kì wọn bọ inu araawọn, ti ayé sì wà ninu eyi ti o wọnu patapata, eyi ti o kangun si ìta ni o si gba awọn irawọ duro.

10 Sibẹ, kàkà ti ìbá fi ṣagbeyọ awọn oju-iwoye ti o fanimọra, alaiba imọ ijinlẹ mu ti o wà lakooko ti a ń kọ ọ, Bibeli wulẹ ṣalaye lọna rirọrun (ni nǹkan bi ọdun 1473 B.C.E.) pe: “[Ọlọrun] si fi ayé rọ̀ ni oju ofo.” (Jobu 26:7) Ninu èdè Heberu ipilẹṣẹ, ọ̀rọ̀ naa fun “ofo” ti a lò nihin-in tumọsi “kò si ohunkohun,” igba kanṣoṣo ti o farahan ninu Bibeli sì niyi. Aworan ti o gbeyọ nipa ilẹ̀-ayé kan tí ofuurufu ti o ṣofo yipo ni awọn ọmọwe kà sí ìrírantẹ́lẹ̀ kan ti o pẹtẹrí fun akoko rẹ̀. Ìwé naa Theological Wordbook of the Old Testament sọ pe: “Jobu 26:7 lọna ti o dayatọ yaworan ayé ti a mọ̀ nigba yẹn gẹgẹ bi eyi ti o sorọ̀ loju ofuurufu, ti o ń tipa bẹẹ wà nilẹ ni sẹpẹ ṣaaju àwárí imọ ijinlẹ lọjọ iwaju.”

11, 12. Nigba wo ni awọn eniyan wá loye otitọ inu Jobu 26:7?

11 Alaye pípéye Bibeli ti wà ṣaaju Aristotle fun eyi ti o ju 1,100 ọdun lọ. Sibẹ, oju-iwoye Aristotle ni a ṣì ń baa lọ lati fi kọni gẹgẹ bi otitọ iṣẹlẹ fun nǹkan bii 2,000 ọdun lẹhin ikú rẹ̀! Nikẹhin, ni 1687 C.E., Sir Isaac Newton tẹ awọn àwárí rẹ̀ jade pe ayé ni a sorọ̀ loju ofuurufu ni isopọ pẹlu awọn ẹ̀dá ọrun miiran nipasẹ ìfàmọ́ra ikinni-keji, eyiini ni agbara òòfà. Ṣugbọn iyẹn fẹrẹẹ tó 3,200 ọdun lẹhin ti Bibeli ti sọ lọna rirọrun tẹyẹtẹyẹ pe ayé sorọ̀ “ni oju ofo.”

12 Bẹẹni, ni nǹkan bii 3,500 ọdun sẹhin, Bibeli sọ lọna ti o tọ́ pe ilẹ̀-ayé kò ni ohun ti a le fojuri ti o gbe e ró, otitọ ọ̀rọ̀ kan ti o wà ni ibamu pẹlu awọn ofin agbara òòfà ati ìrìn yipo ti a ṣẹṣẹ loye wọn laipẹ yii. “Bi Jobu ti ṣe mọ otitọ naa,” ni ọmọwe kan sọ, “jẹ ibeere kan ti kò rọrun lati yanju fun awọn wọnni ti wọn sẹ́ ìmísí Ìwé Mímọ́.”

13. Ki ni awọn eniyan ka ìrísí ilẹ̀-ayé sí ni ọpọ ọ̀rúndún sẹhin, ṣugbọn ki ni o yi wọn lọkan pada?

13 Ìrísí ilẹ̀-ayé. Ìwé The Encyclopedia Americana sọ pe: “Aworan tí awọn eniyan kọ́kọ́ mọ̀ nipa ayé ni pe o jẹ pepele ti o duro gbagidi, títẹ́ pẹrẹsẹ kan laaarin agbaye. . . . Èrò ilẹ̀-ayé olóbìrípo kan ni a kò tẹwọgba lọna gbigbooro titi fi di Ìgbà Ìmúsọjí Ọ̀làjú.” Diẹ lara awọn arìnrìn àjò loju òkun ti igba laelae tilẹ ń bẹru pe awọn le lọ tukọ̀ rekọja bèbè ilẹ̀-ayé títẹ́ pẹrẹsẹ. Ṣugbọn nigba naa ibẹrẹ ìlò ẹ̀rọ atọ́nà loju òkun ati awọn itẹsiwaju yooku mu ki ìrìn àjò lọ jìnnàréré loju òkun ṣeeṣe. Awọn “ìrìn àjò loju òkun fun wíwá àwárí wọnyi,” ni ìwé gbedegbẹyọ miiran ṣalaye, “fihan pe róbótó ni ayé jẹ, kii ṣe pẹrẹsẹ bi awọn eniyan ti o pọ julọ ti gbagbọ.”

14. Bawo ni Bibeli ti ṣe ṣapejuwe ìrísí ilẹ̀-ayé, ati nigba wo?

14 Sibẹ, tipẹtipẹ ṣaaju iru awọn ìrìn àjò oju òkun bẹẹ, nǹkan bii 2,700 ọdun sẹhin, Bibeli sọ pe: “Oun ni ẹni ti o jokoo lori òbírí ayé.” (Isaiah 40:22) Ọ̀rọ̀ Heberu naa ti a tumọ nihin-in si “òbírí” tun le tumọsi “òbíríkítí,” gẹgẹ bi oniruuru awọn ìwé iwadii ti sọ. Awọn itumọ Bibeli miiran, nipa bẹẹ, sọ pe, “òbìrìkìtì ilẹ̀-ayé” (Douay Version) ati, “ilẹ̀-ayé róbótó.”—Moffatt.

15. Eeṣe ti awọn oju-iwoye alaiba imọ ijinlẹ mu nipa ilẹ̀-ayé kò fi nipa lori Bibeli?

15 Nipa bẹẹ, Bibeli ni a kò nipa le lori nipasẹ oju-iwoye aláìbá imọ ijinlẹ mu ti o wọ́pọ̀ ni igba yẹn nipa ohun ti o gbe ilẹ̀-ayé ró ati ìrísí rẹ̀. Idi rẹ̀ rọrun: Òǹṣèwé Bibeli ni Oluṣe agbaye. Oun ni o dá ilẹ̀-ayé, nitori naa o yẹ ki o mọ ohun ti o gbé e ró ati bi ìrísí rẹ̀ ṣe rí. Nitori naa, nigba ti o mísí Bibeli, ó rí i daju pe kò si oju-iwoye aláìbá imọ ijinlẹ mu ti a fi sinu rẹ̀, bi o ti wu ki awọn yooku gbà wọn gbọ́ tó ni igba naa.

16. Bawo ni awọn ohun ti o parapọ di ohun ẹlẹmii ti ṣe wà ni ibamu pẹlu alaye Bibeli?

16 Ohun ti a fi ṣẹda awọn ohun ẹlẹmii. “OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ̀ mọ eniyan,” ni Genesisi 2:7 sọ. Ìwé naa The World Book Encyclopedia sọ pe: “Gbogbo awọn èròjà oogun ti o parapọ di awọn ohun ẹlẹmii wà ninu awọn ohun alailẹmii pẹlu.” Nitori naa gbogbo èròjà oogun ipilẹ ti o parapọ di awọn ẹ̀dá ẹlẹmii, ati eniyan pẹlu, ni a rí ninu ilẹ̀-ayé fúnraarẹ̀ bakan naa. Eyi wà ni ibamu pẹlu alaye Bibeli ti o fi awọn ohun eelo ti Ọlọrun lò lati ṣẹ̀dá awọn eniyan ati gbogbo awọn ohun ẹlẹmii yooku han.

17. Ki ni otitọ naa nipa bi awọn ohun ẹlẹmii ti ṣe di eyi ti o wà?

17 “Ní irú rẹ̀.” Bibeli sọ pe Ọlọrun dá tọkọtaya akọkọ, ti gbogbo iran eniyan yooku sì ti ọdọ wọn wá. (Genesisi 1:26-28; 3:20) Ó sọ pe awọn ohun alaaye yooku, iru bi ẹja, awọn ẹyẹ, ati awọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú, ṣe bakan naa, ni jijade wá “ní irú rẹ̀.” (Genesisi 1:11, 12, 21, 24, 25) Eyi gan-an ni ohun ti awọn onimọ ijinlẹ ti ṣawari ninu ẹ̀dá adanida, pe awọn ohun alaaye wá lati inu òbí irú tiwọn. Kò si eyi ti o dayatọ. Nipa eyi, onimọ physics Raymo ṣakiyesi pe: “Iwalaaye ní ń ṣẹda iwalaaye; ó ń ṣẹlẹ bẹẹ nigba gbogbo ninu gbogbo sẹẹli. Ṣugbọn bawo ni ohun alailẹmii ṣe le ṣẹda ẹlẹmii? Ọkan lara ibeere ti o tobi julọ ninu ẹ̀kọ́ nipa ohun abẹ̀mí niyẹn, titi di isinsinyi kiki àbámodá alailẹsẹnilẹ nikan ni awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ nipa ohun abẹ̀mí sì tíì le fifunni. Lọna kan ṣáá, ohun alailẹmii kàn ṣáà ko araarẹ̀ jọ lọna abẹ̀mí kan. . . . Ó ṣetan, ó ṣeeṣe ki òǹṣèwé Genesisi ti sọ ọ lọna ti o tọ̀nà.”

Ìpéye Ninu Itan

18. Ki ni agbẹjọ́rò kan sọ nipa ìpéye itan Bibeli?

18 Bibeli ní itan atijọ pípéye julọ nínú ju ìwé itan eyikeyii ti o wà. Ìwé naa A Lawyer Examines the Bible tẹnumọ ìpéye itan rẹ̀ lọna bayii pe: “Nigba ti awọn iṣẹ ìwé kikọ, itan àròsọ ati ijẹwọ èké a maa fi ìṣọ́ra fi awọn iṣẹlẹ ti a rohin si ibikan ti o jìnnà ati akoko kan ti kò ṣe gúnmọ́, ti wọn sì ń tipa bẹẹ rú awọn ofin akọkọ ti awa agbẹjọ́rò kọ́ nipa igbẹjọ ofin ile-ẹjọ daradara kan, pe ‘ipolongo naa gbọdọ funni ní akoko ati ibi iṣẹlẹ,’ irohin Bibeli fun wa ni akoko ati ibi ti awọn nǹkan ti a rohin ti ṣẹlẹ pẹlu iṣepato ti o ga julọ.”

19. Bawo ni orisun kan ti ṣe sọrọ akiyesi nipa ẹkunrẹrẹ itan inu Bibeli?

19 Ìwé naa The New Bible Dictionary sọrọ akiyesi pe: “[Òǹkọ̀wé Iṣe] gbe itan rẹ̀ kalẹ ni ọ̀nà igbekalẹ ti ode-oni; awọn oju-iwe rẹ̀ kun fun awọn itọka si awọn adajọ ilu nla, awọn gomina ẹkùn ipinlẹ, awọn ọba àrọ́ko, ati iru bẹẹ bẹẹ lọ, awọn itọkasi leralera wọnyi maa ń ṣe wẹku ni gbogbo igba pẹlu awọn ibi ati akoko ti a ń sọrọ nipa rẹ̀.”

20, 21. Ki ni akẹkọọ Bibeli kan sọ nipa itan Bibeli?

20 Ni kikọwe ninu ìwé The Union Bible Companion, S. Austin Allibone sọ pe: “Sir Isaac Newton. . . jẹ ogbonkangi pẹlu gẹgẹ bi oluṣelameyitọ awọn ikọwe igba laelae, o si fi pẹlẹpẹlẹ ṣayẹwo Ìwé Mímọ́. Ki ni idajọ rẹ̀ lori kókó yii? Ó sọ pe, ‘Mo tubọ ṣawari awọn ẹri didaniloju ti ìjójúlówó tootọ ninu Majẹmu Titun ju ti itan ayé eyikeyii miiran.’ Dokita Johnson sọ pe awa ní ẹri ti o pọ̀ nipa pe Jesu Kristi kú lori Kalfari, gẹgẹ bi a ti ṣe kọ ọ́ sinu awọn Ìwé Ihinrere, ju eyi ti a ni pe Julius Caesar kú ni Capitol. A tilẹ tun ní ju bẹẹ lọ, niti tootọ.”

21 Orisun yii fikun un pe: “Beere lọwọ ẹnikẹni ti o sọ pe oun ṣiyemeji nipa otitọ itan Ìwé Ihinrere idi ti o ní lati gbagbọ pe Ceasar kú ni Capitol, tabi pe Olu-Ọba Charlemagne ni Poopu Leo III. dé ládé gẹgẹ bi Olu-Ọba Ìwọ̀-Oòrùn Ilẹ̀-Ọba Romu ni 800? . . . Bawo ni iwọ ṣe mọ̀ pe ọkunrin kan bii Charles I. [ti England] gbé láyé rí, pe a bẹ́ ẹ lori, ati pe Oliver Cromwell di alakooso ni ipo rẹ̀? . . . Sir Isaac Newton ni a gbógo fun pe ó ṣawari ofin agbara òòfà . . . A gba gbogbo awọn èròǹgbà ti a sọ nipa awọn ọkunrin wọnyi gbọ́; iyẹn sì jẹ nitori pe a ni awọn ẹri ijotiitọ wọn ninu itan. . . . Bi ẹnikẹni, lẹhin mimu iru awọn ẹri bi eyi jade, bá ṣì kọ̀ lati gbagbọ, a kọ̀ wọn silẹ bi afìwà òmùgọ̀ ṣoríkunkun tabi òpè buruku kan.”

22. Eeṣe ti awọn kan fi kọ̀ lati tẹwọgba ìjójúlówó tootọ Bibeli?

22 Lẹhin naa orisun yii pari èrò pe: “Ki ni kí a sọ, nigba naa, nipa ti awọn wọnni tí, laika ẹri jáǹtírẹrẹ ti a mu jade nisinsinyi nipa ìjójúlówó tootọ Ìwé Mímọ́ sí, wọn ṣì sọ pe awọn kò tíì gbà? . . . Dajudaju a ni idi lati pari èrò pe ọkàn-àyà ni o ní iṣoro dipo ki o jẹ orí;—pe wọn kò fẹ gbagbọ ninu ohun ti yoo rẹ̀ ìṣògo wọn silẹ, ti yoo si fi ipá mu wọn lati gbé igbesi-aye miiran.”

Ibaramu ati Àìlábòsí Inu Rẹ̀

23, 24. Eeṣe ti ibaramuṣọkan inu Bibeli fi ṣàrà-ọ̀tọ̀ tobẹẹ?

23 Ki a sọ pe a bẹrẹsii kọ ìwé kan nigba akoko Ilẹ̀-Ọba Romu, la awọn Sanmani Agbedemeji kọja, ti a sì pari rẹ̀ ni ọ̀rúndún ogun yii, ti oniruuru òǹkọ̀wé sì kopa ninu rẹ̀. Abajade wo ni iwọ yoo maa reti bi iṣẹ awọn òǹkọ̀wé naa bá jẹ oniruuru bii awọn ológun, ọba, alufaa, apẹja, darandaran, ati dokita? Iwọ yoo ha reti pe ki ìwé naa baramu ki o si sopọmọra bi? ‘Agbara káká!’ ni iwọ le sọ. Tóò, Bibeli ni a kọ labẹ awọn ipo wọnyi. Sibẹ, o baramu latokedelẹ, kii wulẹ ṣe ninu awọn èròǹgbà rẹ̀ lódindi ṣugbọn ninu awọn kulẹkulẹ keekeeke rẹ̀ pẹlu.

24 Bibeli jẹ akojọpọ awọn ìwé 66 ti a kọ ni sáà ti o ju 1,600 ọdun lati ọwọ́ 40 oniruuru òǹkọ̀wé, bẹrẹ lati 1513 B.C.E. ti o si pari ni 98 C.E. Awọn òǹkọ̀wé naa wá lati oniruuru ẹ̀ka igbesi-aye, ti ọpọ kò sì ní ìfarakanra pẹlu araawọn. Sibẹ, ìwé ti wọn mú jade ń bá lajori akori kanṣoṣo, ti o sopọmọra lọ latokedelẹ, bi ẹni pe èrò-inú kan ni o mu un jade. Ati ni odikeji si igbagbọ awọn kan, Bibeli kii ṣe ìwé ọlaju ti awọn ara Ìwọ̀-Oòrùn Ayé, ṣugbọn a kọ ọ́ lati ọwọ́ awọn ara Ìlà-Oòrùn Ayé.

25. Àìlábòsí ati àìṣàbòsí Bibeli ṣetilẹhin fun ohun wo ti awọn òǹkọ̀wé Bibeli sọ?

25 Nigba ti o jẹ pe eyi ti o pọ̀ ju ninu awọn òǹkọ̀wé ìgbà atijọ maa ń ṣakọsilẹ awọn aṣeyọri ati agbara itoye wọn, awọn òǹkọ̀wé Bibeli jẹwọ awọn àṣìṣe tiwọn gbangba, ati awọn ìkùnà awọn ọba ati aṣaaju wọn. Numeri 20:1-13 ati Deuteronomi 32:50-52 ṣakọsilẹ awọn ìkùnà Mose, oun ni ó sì kọ awọn ìwé wọnyẹn. Jona 1:1-3 ati 4:1 to awọn ìkùnà Jona lẹsẹẹsẹ, ẹni ti o kọ awọn akọsilẹ wọnyẹn. Matteu 17:18-20; 18:1-6; 20:20-28; ati 26:56 ṣakọsilẹ awọn animọ alaidara tó tí awọn ọmọ-ẹhin Jesu fihan. Nipa bẹẹ, àìṣàbòsí ati àìlábòsí awọn òǹkọ̀wé Bibeli ṣetilẹhin fun ijẹwọ wọn pe Ọlọrun ni o mísí wọn.

Ẹ̀ka Rẹ̀ Ti O Dayatọ Gedegbe

26, 27. Eeṣe ti Bibeli fi péye tobẹẹ ninu imọ ijinlẹ ati awọn ọran yooku?

26 Bibeli fúnraarẹ̀ fi idi rẹ̀ ti o fi péye tobẹẹ ninu imọ ijinlẹ, itan, ati awọn ọran miiran ati idi ti o fi baramu ti o si jẹ aláìlábòsí tobẹẹ han. Ó fihan pe Ẹni Giga Julọ naa, Ọlọrun Olodumare, Ẹlẹdaa naa ti o jẹ oluṣẹda agbaye ni Òǹṣèwé Bibeli. Ń ṣe ni oun wulẹ lo awọn eniyan òǹkọ̀wé Bibeli gẹgẹ bi akọwe rẹ̀, ní sísún wọn nipasẹ ipá agbékánkán ṣiṣẹ rẹ̀ alagbara lati ṣakọsilẹ awọn ohun ti oun ti mísí wọn lati kọ.

27 Ninu Bibeli aposteli Paulu sọ pe: “Gbogbo ìwé mímọ́ ti o ni ìmísí Ọlọrun ni o si ni èrè fun ẹ̀kọ́, fun ibaniwi, fun ìtọ́ni, fun ìkọ́ni ti o wà ninu òdodo: Ki eniyan Ọlọrun ki o le pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ́ rere gbogbo.” Aposteli Paulu si tun wi pe: “Nigba ti ẹyin gba ọ̀rọ̀ ti ẹyin gbọ́ lọdọ wa, ani ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ẹyin kò gbà a bi ẹni pe ọ̀rọ̀ eniyan, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti jẹ nitootọ, bi ọ̀rọ̀ Ọlọrun.”—2 Timoteu 3:16, 17; 1 Tessalonika 2:13.

28. Nigba naa, lati ibo ni Bibeli ti wá?

28 Nipa bẹẹ, Bibeli wá lati èrò-inú Òǹṣèwé kan—Ọlọrun. Pẹlu agbara amunikunfun ẹ̀rù ọlọ́wọ̀ rẹ̀, ó jẹ ohun ti o rọrun fun un lati rí i daju pe ìpé perepere awọn ohun ti oun mu ki a kọ ni a pamọ titi di ọjọ wa. Nipa eyi, òléwájú ọlọla-aṣẹ kan lori awọn ìwé àfọwọ́kọ Bibeli, Sir Frederic Kenyon, sọ ni 1940 pe: “Ipilẹ ti o kẹhin fun iyemeji eyikeyii pe Ìwé Mímọ́ ti tẹ̀ wà lọwọ ni ojulowo bi a ṣe ṣakọsilẹ wọn ni a ti mu kuro nisinsinyi.”

29. Bawo ni a ṣe le ṣakawe agbara iṣe Ọlọrun lati fi isọfunni ranṣẹ?

29 Awọn eniyan ni agbara lati tàtaré ìgbì redio ati tẹlifiṣọn lati ẹgbẹẹgbẹrun ibùsọ̀ wá, koda lati ojú oṣupa. Awọn ọkọ̀ ti a fi ń ṣewadiikiri gbangba ofuurufu ti fi awọn isọfunni ati fọto ti a lè fojuri ranṣẹ si ilẹ̀-ayé lati inu awọn planẹti ti wọn wà ni araadọta ọkẹ ibùsọ̀ wá. Dajudaju Ẹlẹdaa eniyan, Ẹlẹdaa awọn ìgbì redio, le ṣe bẹẹ ó keretan. Nitootọ, ohun ti o rọrun ni fun un lati lo agbara Olodumare rẹ̀ lati tàtaré awọn ọ̀rọ̀ ati aworan sinu èrò-inú awọn wọnni ti oun yàn lati ṣakọsilẹ Bibeli.

30. Ọlọrun ha fẹ ki awọn eniyan ṣawari ohun ti ète rẹ̀ jẹ fun wọn bi?

30 Jù bẹẹ lọ, awọn ohun pupọ wà nipa ilẹ̀-ayé ati iwalaaye lori rẹ̀ ti o fi ẹri ifẹ Ọlọrun ninu araye han. Nitori naa, o ṣeeloye pe oun yoo fẹ lati ran awọn eniyan lọwọ lati ṣawari ẹni ti oun jẹ ati ohun ti ète rẹ̀ jẹ fun wọn nipa sisọ nǹkan wọnyi jade kedere ninu ìwé kan—akọsilẹ wíwà pẹtiti kan.

31. Eeṣe ti ihin-iṣẹ ti a mísí ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ fi tayọlọla gidigidi ju isọfunni ti a fi lénilọ́wọ́ lati irandiran pẹlu ọ̀rọ̀ ẹnu?

31 Tun ṣagbeyẹwo itayọlọla ti ìwé kan tí Ọlọrun jẹ òǹṣèwé rẹ̀, ní ifiwera pẹlu isọfunni tí awọn eniyan maa ń fi lénilọ́wọ́ lati irandiran pẹlu ọ̀rọ̀ ẹnu lasan. Ọ̀rọ̀ ẹnu ki yoo jẹ eyi ti o ṣeegbẹkẹle, niwọn bi awọn eniyan yoo ti tun ihin-iṣẹ naa gbekalẹ ni ọ̀nà miiran, bi akoko si ti ń lọ, awọn itumọ rẹ̀ ni wọn yoo lọ́po. Wọn yoo tàtaré isọfunni ọlọ́rọ̀ ẹnu naa ni ibamu pẹlu oju-woye wọn. Ṣugbọn ṣiṣeeṣe naa pe kí akọsilẹ tí Ọlọrun mísí, ti o wà pẹtiti ní àṣìṣe kere gidigidi. Bakan naa, ìwé kan ni a le ṣe àdàkọ ki a si tumọ rẹ̀ ki awọn eniyan ti wọn ń ka oniruuru èdè le janfaani lati inu rẹ̀. Nitori naa kò ha bọgbọnmu pe Ẹlẹdaa wa lo iru ọ̀nà bẹẹ lati pese isọfunni bi? Niti tootọ, ó bọgbọnmu, ó tilẹ tun ju bẹẹ lọ, niwọn bi Ẹlẹdaa ti sọ pe ohun ti oun ṣe niyẹn.

Asọtẹlẹ Ti A Múṣẹ

32-34. Ki ni Bibeli ní ti kò si ìwé miiran ti o tun ní i ninu?

32 Ni afikun sii, Bibeli ni àmì ẹ̀rí ìmísí atọrunwa ní ọ̀nà àrà-ọ̀tọ̀ titayọ kan: Ó jẹ ìwé awọn asọtẹlẹ ti o ti ní ti o si ń baa lọ lati ní imuṣẹ láìyingin.

33 Fun apẹẹrẹ, iparun Tire, iṣubu Babiloni, àtúnkọ́ Jerusalemu, idide ati iṣubu awọn ọba Medo-Persia ati Griki ni a sọtẹlẹ kínníkínní lẹkun-unrẹrẹ ninu Bibeli. Awọn asọtẹlẹ naa ṣe rẹ́gí tobẹẹ gẹẹ ti awọn oluṣelameyitọ kan gbiyanju, lori asan, lati sọ pe ṣe ni a kọ wọn lẹhin tí awọn iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.—Isaiah 13:17-19; 44:27–45:1; Ezekieli 26:3-6; Danieli 8:1-7, 20-22.

34 Awọn asọtẹlẹ ti Jesu funni nipa iparun Jerusalemu ní 70 C.E. ni a muṣẹ láìtàsé. (Luku 19:41-44; 21:20, 21) Awọn asọtẹlẹ nipa “ikẹhin ọjọ” ti Jesu ati aposteli Paulu fifunni ni a muṣẹ lẹkun-unrẹrẹ ni akoko tiwa gan-an.—2 Timoteu 3:1-5, 13; Matteu 24; Marku 13; Luku 21.

35. Eeṣe ti awọn asọtẹlẹ Bibeli fi le wá kiki lati ọdọ Ẹlẹdaa naa?

35 Kò si èrò-inú eniyan kankan, bi o ti wu ki o jẹ olóye tó, ti o le sọ awọn iṣẹlẹ ọjọ iwaju tẹlẹ lọna ti o pe ṣanṣan tobẹẹ. Kiki èrò-inú Ẹlẹdaa agbaye alagbara gbogbo ati ọlọgbọn gbogbo ni o le ṣe bẹẹ, gẹgẹ bi a ṣe kà á ninu 2 Peteru 1:20, 21: “Kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu ìwé mímọ́ ti o ni itumọ ikọkọ. Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ eniyan wá rí; ṣugbọn awọn eniyan ń sọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ń dari wọn lati ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́ wá.”

O Funni Ni Idahun Naa

36. Ki ni Bibeli sọ fun wa?

36 Nitori naa, fun ọpọlọpọ idi, Bibeli ní ẹri ti jijẹ Ọ̀rọ̀ Ẹni Giga Julọ naa. Nipa bẹẹ, o sọ fun wa idi ti eniyan fi wà lori ilẹ̀-ayé, idi ti ijiya fi pọ̀ tobẹẹ, ibi ti a ń lọ, ati bí ipo awọn nǹkan yoo ṣe yipada di eyi ti o tubọ dara sii. Ó ṣí i paya fun wa pe Ọlọrun giga julọ kan wà ti o dá awọn eniyan ati ilẹ́-ayé yii fun ète kan ati pe ète rẹ̀ ni a o muṣẹ. (Isaiah 14:24) Bibeli pẹlu ṣipaya ohun ti isin tootọ jẹ fun wa ati bi a ṣe le wá a rí. Nipa bẹẹ, o jẹ orisun ọgbọn giga julọ ti o le sọ otitọ fun wa nipa gbogbo awọn ibeere pataki nipa igbesi-aye.—Orin Dafidi 146:3; Owe 3:5; Isaiah 2:2-4.

37. Ki ni a gbọdọ beere nipa Kristẹndọm?

37 Nigba ti o jẹ pe a ní awọn ẹri pelemọ nipa ìjójúlówó tootọ ati ijotiitọ Bibeli, gbogbo awọn ti wọn sọ pe awọn tẹwọgba a ha tẹle ẹ̀kọ́ rẹ̀ bi? Ṣagbeyẹwo, fun apẹẹrẹ, awọn orilẹ-ede ti wọn sọ pe awọn ń ṣe isin Kristian, eyiini ni Kristẹndọm. Bibeli wà larọọwọto wọn fun ọpọ ọ̀rúndún. Ṣugbọn njẹ ọ̀nà ironu ati iṣe wọn ha ṣagbeyọ ọgbọn giga julọ ti Ọlọrun bi?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Sir Isaac Newton gbagbọ pe a gbé ayé ró ni ofuurufu ní isopọ pẹlu awọn ẹ̀dá ọrun yooku nipasẹ agbara òòfà

Aworan ti Bibeli gbeyọ nipa ilẹ̀-ayé kan tí ofuurufu ti o ṣofo yipo ni awọn ọmọwe kà sí ìrírantẹ́lẹ̀ kan ti o pẹtẹrí fun akoko rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Diẹ lara awọn arìnrìn àjò loju òkun ti igba laelae tilẹ ń bẹru pe awọn le lọ tukọ̀ rekọja bèbè ayé títẹ́ pẹrẹsẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ẹri pe Jesu Kristi wà pọ̀ ju eyi ti o wà pe Julius Caesar, Olú-Ọba Charlemagne, Oliver Cromwell tabi Poopu Leo III wà lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Imuṣẹ awọn asọtẹlẹ ti Jesu funni nipa iparun Jerusalemu ní 70 C.E. ni Ẹnu Ọ̀nà Àbáwọlé Rìbìtì ti Titus ni Romu jẹrii sí