Ta Ni Ó Lè Sọ Fun Wa?
Ìsọ̀rí 2
Ta Ni Ó Lè Sọ Fun Wa?
1, 2. Ki ni ọna ti o dara julọ lati ṣawari ète ohun kan ti a ṣètò?
1 Ta ni o lè sọ ohun ti ète igbesi-aye jẹ niti gidi fun wa? O dara, kí a sọ pe iwọ ṣe ibẹwo si oluṣe ẹ̀rọ kan ti o si ri i ti o ń ṣiṣẹ lọwọ lori ẹ̀rọ didiju kan ti iwọ kò mọ̀, bawo ni iwọ ṣe le ṣawari ohun ti o wà fun? Ọna ti o dara julọ ni lati beere lọwọ oluṣe ẹ̀rọ naa.
2 Ki ni nigba naa, nipa ti ìṣètò titayọlọla ti a rí yí wa ká lori ilẹ̀-ayé, iru eyi ti o wà ninu awọn ohun alaaye, titi de ori sẹẹli alaaye ti o kere julọ? Koda awọn ipin ohun tíntìntín ti o kere julọ ati ohun bíntín ti o kere julọ ninu sẹẹli ni a ṣètò lọna agbayanu ti o si wà letoleto. Bakan naa, ki ni nipa ti èrò-inú eniyan ti a ṣètò lọna agbayanu? Ki si ni nipa ti eto-igbekalẹ ti awọn planẹti ti wọn faramọ oòrùn, ìṣùpọ̀ irawọ Milky Way tiwa, ati agbaye? Njẹ awọn ìṣètò wọnyi kò ha beere fun Olùṣètò kan bi? Dajudaju oun le sọ idi ti oun fi ṣètò iru awọn nǹkan bẹẹ fun wa.
Iwalaaye Ha Pilẹṣẹ Nipasẹ Èèṣì Bi?
3, 4. Ṣiṣeeṣe wo ni o wà pe iwalaaye jẹyọ nipa èèṣì?
3 Ìwé naa The Encyclopedia Americana ṣakiyesi “idijupọ ati ìṣètò de iwọn giga rekọja ààlà ti o wà ninu awọn ẹ̀dá alaaye” o sì ṣalaye pe: “Ṣiṣe ayẹwo awọn òdòdó, kòkòrò, tabi awọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú fínnífínní fi ìṣètò awọn ẹ̀yà-ara ni kòńgẹ́ lọna ti o ṣoro lati gbagbọ han.” Ọmọ ilẹ̀ Britain onimọ ẹ̀kọ́ nipa ojude ofuurufu naa Sir Bernard Lovell, ni titọkasi awọn èròjà oogun inu ara awọn ẹ̀dá alaaye, kọwe pe: “Ṣiṣeeṣe ti . . . iṣẹlẹ nipa èèṣì kan ti yoo yọrisi imujade eyi ti o kere julọ lara ipin ohun tíntìntín inu èròjà protein ti o kere julọ kere lọna ti kò ṣeefinuwoye. . . . Niti gidi o jẹ òfo.”
4 Lọna kan naa, onimọ nipa ojude ofuurufu naa Fred Hoyle sọ pe: “Ipilẹ ti a gbe ẹ̀kọ́ nipa ẹ̀dá alaaye ti a tẹwọgba ni gbogbogboo kà gbà pe ṣe ni iwalaaye ṣadede jẹyọ lairotẹlẹ. Sibẹ
gẹgẹ bi awọn ẹlẹkọọ ijinlẹ nipa èròjà oogun inu ẹ̀dá alaaye ti ń ṣawari pupọpupọ sii nipa agbayanu idijupọ iwalaaye, o han gbangba pe ṣiṣeeṣe naa pe o pilẹṣẹ nipa èèṣì kere tobẹẹ gẹẹ ti a fi le gboju fò wọn dá. Kò jẹ́ jẹ́ bẹẹ pe iwalaaye ṣẹ́yọ lọna èèṣì.”5-7. Bawo ni ẹ̀kọ́ nipa ipin ohun tíntìntín inu ara ti o kere julọ ti ṣe jẹrii sii pe awọn ẹ̀dá alaaye kò le jẹyọ nipa èèṣì?
5 Ẹ̀kọ́ ijinlẹ nipa ipin ohun tíntìntín inu ara ti o kere julọ, ọkan lara ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ijinlẹ ti a ṣẹṣẹ dá silẹ laipẹ yii, jẹ ẹ̀kọ́ nipa awọn ẹ̀dá alaaye lori ipele ti ipilẹ àbùdá ẹ̀dá, ipin ohun tíntìntín ti o kere julọ, ati awọn ohun bíntín kikere julọ. Onimọ ijinlẹ nipa ipin ohun tíntìntín inu ara ti o kere julọ Michael Denton ṣalaye lori ohun ti a ti ṣawari pe: “Idijupọ sẹẹli rirọrun julọ ti a mọ̀ ga pupọ tobẹẹ gẹẹ ti o fi jẹ pe kò ṣeeṣe lati gbà pe iru ẹ̀dá kan bẹẹ jẹ eyi ti iru iṣẹlẹ ajeji kan, ti kò le ṣẹlẹ lọna gbigbooro, mú sọlu araawọn lojiji.” “Ṣugbọn kii wulẹ ṣe kiki idijupọ eto-igbekalẹ awọn ẹ̀dá alaaye ni o jẹ eyi ti ń gbe ipenija koni lọna ti o ga gidigidi tobẹẹ, ọgbọn ìhùmọ̀ ti o ṣoro lati gbagbọ tun wà pẹlu eyi ti o saba maa ń farahan ninu ọ̀nà ti a gbà ṣètò wọn.” “Ó jẹ ni ori ipele ti ipin ohun tíntìntín ni ibi ti . . . òye titayọ ti ìṣètò ẹ̀dá alaaye ati ìṣepé perepere awọn ohun ti a ṣaṣeyọri rẹ̀ ti tubọ han gbangba.”
6 Denton sọ siwaju sii pe: “Nibi gbogbo ti a bá wò, dé ibi yoowu ti a bá wò jinlẹjinlẹ to, a rí ẹwà ati ọgbọn ìhùmọ̀ tí ojulowo rẹ̀ tayọ julọ patapata, eyi ti o ń sọ èròǹgbá ti èèṣì di alailagbara. Niti tootọ, o ha yẹ ni gbigbagbọ pe awọn igbesẹ òjijì kan ni o ṣeeṣe ki o ti fètò gbe ohun gidi kan kalẹ, ninu eyi ti ohun bíńtín kekere julọ rẹ̀—èròjà protein tabi ipilẹ àbùdá rẹ̀ ti o ń ṣiṣẹ—jẹ eyi ti o dijupọ rekọja awọn agbara òye ìhùmọ̀ tiwa, otitọ iṣẹlẹ eyi ti o jẹ odikeji ọ̀rọ̀ si èèṣì, eyi ti o tayọ ohun eyikeyii ti òye eniyan ṣe jade lọnakọna bi?” Ó tun ṣalaye pe: “Ọ̀gbun ti o gbooro ti o si jẹ aláìláàlà tobẹẹ gẹẹ de ibi ti a le finuwoye dé ni o wà laaarin sẹẹli alaaye ati eto-igbekalẹ ti awọn ẹ̀dá alailẹmii ti o wà letoleto julọ, iru bii okuta kristali tabi ẹ̀gbọ̀n yìnyín kan.” Ọjọgbọn kan ninu ìmọ̀ physics, Chet Raymo, sọ pe: “Ori mi wú . . . Olukuluku ipin ohun tíntìntín ti o kere julọ dabii eyi ti a hùmọ̀ rẹ̀ lọna iyanu fun iṣẹ tirẹ̀.”
7 Onimọ ijinlẹ nipa ipin ohun tíntìntín inu ara ti o kere julọ, Denton, pari èrò pe “awọn ti wọn ṣì wonkoko mọ́ pipolongo pe gbogbo otitọ iṣẹlẹ titun yii jẹ abajade èèṣì lasan” ń gba itan àròsọ lasan gbọ. Nitootọ, o pe ẹ̀kọ́ igbagbọ Darwin nipa pe awọn ohun alaaye jẹyọ nipa èèṣì ní “itan àròsọ nla ti ọ̀rúndún ogun yii nipa ipilẹṣẹ agbaye.”
Ìṣètò Ń Beere Fun Olùṣètò Kan
8, 9. Funni ni àkàwé kan ti o ń fihan pe gbogbo ohun ti a ba ṣètò gbọdọ ni olùṣètò kan.
8 Ṣiṣeeṣe naa pe awọn ohun alailẹmii le walaaye nipa èèṣì, nipasẹ iṣẹlẹ èèṣì wúruwùru kan, ṣoro tobẹẹ gẹẹ ti kò fi le ṣeeṣe. Rara, gbogbo awọn ohun ẹlẹmii ti wọn wà lori ilẹ̀-ayé ti a ṣètò lọna kikọyọyọ kò le jẹyọ nipa èèṣì, niwọn bi gbogbo ohun ti a ṣètò ti gbọdọ ni olùṣètò kan. Iwọ ha mọ eyikeyii ti o dayatọ bi? Kò si eyikeyii. Bi ohun ti a ṣètò bá sì ti dijupọ tó, bẹẹ ni ẹni ti o ṣètò rẹ̀ ṣe nilati ga lọla tó.
9 A sì le ṣakawe ọran naa ni ọ̀nà yii: Nigba ti a bá ri ohun ti a kùn, a gbà pe ẹni ti o ń kùn nǹkan wà. Nigba ti a bá ka ìwé kan, a gbà pe
òǹṣèwé kan wà. Nigba ti a bá rí ilé kan, a gbà pe akọle kan wà. Nigba ti a bá rí iná ti ń darí ìrìnnà ọkọ̀ loju pópó, a mọ̀ pe ẹgbẹ aṣòfin kan wà. Gbogbo awọn nǹkan wọnyẹn ni a ṣe pẹlu ète kan lati ọdọ awọn ẹni ti o ṣe wọn. Bi o tilẹ jẹ pe a le má loye gbogbo nǹkan nipa awọn eniyan ti o ṣètò wọn, a kò ṣiyemeji pe awọn eniyan naa wà.10. Ẹ̀rí wo nipa Olúṣètò Giga Julọ kan ni a le fojuri?
10 Lọna kan naa, ẹri wíwà Olùṣètò Giga Julọ kan ni a le rí ninu ìṣètò, ìwàlétòletò, ati idijupọ awọn ohun alaaye ti o wà lori ilẹ̀-ayé. Gbogbo wọn fihan pe Olóye Giga Julọ kan wà. Eyi pẹlu jẹ otitọ nipa ìṣètò, ìwàlétòletò, ati idijupọ agbaye pẹlu awọn billion ìṣùpọ̀ irawọ rẹ̀, ti ọkọọkan rẹ̀ ní awọn billion irawọ ninu. Gbogbo awọn ẹ̀dá ọ̀run ni a ń dari nipasẹ awọn ofin ti o ṣe kòńgẹ́, iru bii fun ìrìn yipo, ooru, imọlẹ, ìró, agbara òòfà ti ina mànàmáná ati agbara òòfà. Ofin ha le wà laisi oluṣofin bi? Onimọ ijinlẹ nipa ọkọ̀ gbangba ofuurufu Dokita Wernher von Braun sọ pe: “Awọn ofin adanida ti agbaye ṣe kòńgẹ́ tobẹẹ gẹẹ ti a kò fi ni iṣoro ni ṣiṣe ọkọ̀ ofuurufu kan lati lọ si oju oṣupa ti a sì le diwọn akoko rẹ̀ wẹku dori aabọ iṣẹju àáyá. Ẹnikan ni o ti nilati gbe awọn ofin wọnyi kalẹ.”
11. Eeṣe ti kò fi yẹ ki a sẹ́ wíwà Olùṣètò Giga Julọ kiki nitori pe a kò le fojuri i?
11 Lotiitọ, awa kò le ri Olùṣètò ati Olofin Giga Julọ naa pẹlu ojúyòójú wa. Ṣugbọn a ha sẹ́ wíwà awọn nkan bii agbara òòfà, òòfà ti magnẹti, agbara mànàmáná, tabi ìgbì redio kiki nitori pe a kò rí wọn bi? Rara, a kò ṣe bẹẹ, nitori pe a le ṣakiyesi awọn iyọrisi iṣẹ wọn. Nigba naa eeṣe ti a nilati sẹ wíwà Olùṣètò ati Olofin Giga Julọ kiki nitori pe a kò le rí i, niwọn bi a ti le ṣakiyesi abajade awọn iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ yiyanilẹnu?
12, 13. Ki ni ẹ̀rí fihan nipa wíwà Ẹlẹdaa?
12 Paul Davies, ọjọgbọn ninu ìmọ̀ physics, pari èrò pe wíwà eniyan kii wulẹ ṣe èèṣì lati ọwọ́ ayanmọ kan. Ó wi pe: “Ibi yii gan-an ni a ṣètò fun wa.” Ó sì wá sọ nipa agbaye pe: “Nipasẹ iṣẹ imọ ijinlẹ mi, mo tubọ wá ní igbagbọ lilagbara siwaju sii pe agbaye wa ti a le fojuri ni a ṣe papọ pẹlu ọgbọn ìhùmọ̀ ti o yanilẹnu tobẹẹ ti emi kò fi le gbà á bi kiki otitọ alailọgbọn nínú kan. Si mi, o dabi ẹni pe alaye ti o tubọ jinlẹ ju bẹẹ lọ nilati wà.”
13 Nipa bẹẹ, ẹri fi yé wa pe agbaye, ilẹ̀-ayé, ati awọn ohun alaaye ori ilẹ̀-ayé kò le ṣadede wá nipa èèṣì. Gbogbo wọn ń jẹrii laisọrọ si Ẹlẹdaa, oloye, alagbara nlanla kan.
Ohun ti Bibeli Sọ
14. Ki ni Bibeli pari èrò sí nipa Ẹlẹdaa naa?
14 Bibeli, ìwé araye ti o lọjọ lori julọ, dé ori ipari èrò kan naa. Fun apẹẹrẹ, ninu ìwé Bibeli naa Heberu, ti aposteli Paulu kọ, a sọ fun wa pe: “Lati ọwọ́ eniyan kan ni a sá ti kọ́ olukuluku ilé; ṣugbọn ẹni ti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun.” (Heberu 3:4) Ìwé ti o kẹhin Bibeli, ti aposteli Johannu kọ, sọ bakan naa pe: “Oluwa, iwọ ni o yẹ lati gba ogo ati ọlá ati agbara: nitori pe iwọ ni o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni wọn fi wà ti a si dá wọn.”—Ìfihàn 4:11.
15. Bawo ni a ṣe le foyemọ diẹ lara awọn animọ Ọlọrun?
15 Bibeli fihan pe bi o tilẹ jẹ pe a kò le ri Ọlọrun, a le foyemọ iru Ọlọrun ti o jẹ nipasẹ awọn ohun ti o ṣe. Ó sọ pe: “Awọn animọ [Ẹlẹdaa] ti a kò le fojuri, iyẹn ni pe agbara ati ipo jijẹ Ọlọrun rẹ̀, ni o ti ṣeefojuri, lati igba ti ayé ti bẹrẹ, fun ojú òye, ninu awọn ohun ti ó ti dá.”—Romu 1:20, The New English Bible.
16. Eeṣe ti a fi nilati kun fun ọpẹ pe awọn eniyan ko le rí Ọlọrun?
16 Nitori naa Bibeli mu wa lọ lati okunfa si abajade. Abajade—awọn ohun àwòyanu ti a dá—jẹ ẹri Okunfa oloye, alagbara: Ọlọrun. Bakan naa, a le kun fun ọpẹ pe kò ṣeefojuri, niwọn bi o ti jẹ Ẹlẹdaa gbogbo agbaye, o daju pe oun ní agbara ńláǹlà ti o fi jẹ pe kò si eniyan ẹlẹran ara ati ẹ̀jẹ̀ ti o le reti lati rí i ki o sì yè é. Ohun ti Bibeli si sọ gan-an niyẹn: “Kò si eniyan ti i ri [Ọlọrun] ti si yè.”—17, 18. Eeṣe ti èrò nipa Ẹlẹdaa kan fi yẹ ki o ṣe pataki si wa?
17 Èrò ti Olùṣètò Nla kan, Ẹni Giga Julọ kan—Ọlọrun—yẹ ki o ṣe pataki gidigidi si wa. Bi o ba ṣe pe Ẹlẹdaa kan ni o dá wa, dajudaju nigba naa oun ti nilati ni idi kan, ète kan, ti o fi ṣẹda wa. Bi a ba ṣẹda wa lati ni ète ni igbesi-aye, nigba naa idi wà fun wa lati ni ireti pe awọn nǹkan ń bọ̀ wá sàn fun wa lọjọ iwaju. Bi bẹẹ kọ, a wulẹ ń gbe ti a si ń kú ni laisi ireti. Nitori naa o ṣe pataki pe ki a ṣawari ète Ọlọrun fun wa. Nigba naa a le wa yan boya lati gbe ni ibamu pẹlu rẹ̀ tabi bẹẹkọ.
18 Bakan naa, Bibeli sọ pe Ẹlẹdaa jẹ Ọlọrun onifẹẹ ti o bikita gidigidi nipa wa. Aposteli Peteru sọ pe: “Oun ń ṣe itọju yin.” (1 Peteru 5:7; tun wo Johannu 3:16 ati 1 Johannu 4:8, 16 pẹlu.) Ọna kan ti a fi le rí bi Ọlọrun ti bikita fun wa tó ni ọna iyanu ti oun gbà dá wa, niti èrò-orí ati ara-ìyára.
‘Tí A Dá Tiyanu-Tiyanu’
19. Otitọ wo ni olorin naa Dafidi pe wá si afiyesi wa?
19 Ninu Bibeli, olorin naa Dafidi jẹwọgba pe: “Tiyanu-tiyanu ni a dá mi.” (Orin Dafidi 139:14) Dajudaju otitọ ni iyẹn jẹ, nitori pe a ṣètò ọpọlọ ati ara eniyan lọna agbayanu lati ọwọ́ Olùṣètò Giga Julọ naa.
20. Bawo ni ìwé gbedegbẹyọ kan ṣe ṣapejuwe ọpọlọ eniyan?
20 Fun apẹẹrẹ, ọpọlọ rẹ dijupọ jìnnàjìnnà ju ẹ̀rọ kọmputa eyikeyii lọ. Ìwé gbedegbẹyọ The New Encyclopædia Britannica ṣakiyesi pe: “Fifi isọfunni ranṣẹ laaarin eto-igbekalẹ iṣan imọlara jẹ eyi ti o dijupọ pupọ ju ti ìṣètò ẹ̀rọ ibanisọrọpọ ti o tobi julọ; iṣoro yíyanjú nipasẹ ọpọlọ eniyan tayọ agbara iṣe ti ẹ̀rọ kọmputa ti o lagbara julọ jìnnàjìnnà.”
21. Nigba ti a bá rí ohun ti ọpọlọ ń ṣe, ipari èrò wo ni a nilati dé?
21 Araadọta ọkẹ lọna ọgọrọọrun awọn iṣẹlẹ ati awọn aworan inu ọpọlọ ni a tojọ pamọ sinu ọpọlọ rẹ, ṣugbọn kò wulẹ jẹ ilé ìkó awọn iṣẹlẹ pamọ sí lasan. Pẹlu rẹ̀ iwọ le kọ́ bi a ti ń súfèé, ṣe burẹdi, sọ awọn èdè àjèjì, lo ẹ̀rọ kọmputa, tabi wa ọkọ̀ ofuurufu. Iwọ le finuwoye bi lilo akoko isinmi kuro lẹnu iṣẹ yoo ṣe rí tabi bi ìtọ́wò eso ti o gbamuṣe kan yoo ṣe rí. Iwọ le ṣe ìtúpalẹ̀ ki o sì ṣe awọn nǹkan. Iwọ pẹlu le ṣe ìwéwèé, mọriri, nifẹẹ, ati ki o so awọn èrò rẹ pọ̀ mọ́ ti igba atẹhinwa, isinsinyi, ati ọjọ iwaju. Niwọn bi awa eniyan kò ti le ṣètò iru awọn nǹkan bii ọpọlọ eniyan agbayanu, dajudaju nigba naa Ẹni naa ti o ṣètò rẹ̀ ní ọgbọn ati agbara iṣe ti o ga ju ti eniyan eyikeyii lọ.
22. Ki ni awọn onimọ ijinlẹ gbà nipa ọpọlọ eniyan?
22 Nipa ti ọpọlọ, awọn onimọ ijinlẹ jẹwọ pe: “Bi ẹ̀rọ ti a ṣe lọna ti o ga lọla, ti o wà letoleto ti o si dijupọ lọna agbayanu yii ti ń ṣe awọn iṣẹ wọnyi jẹ eyi ti o rúnilójú gidigidi. . . . Awọn ẹ̀dá eniyan lè má lè ri ojútùú gbogbo ọkọọkan oriṣiriṣi àdìtú tí ọpọlọ ń mu wá lae.” (Scientific American) Ọjọgbọn ninu imọ ijinlẹ physics Raymo sọ pe: “Bi a bá ni ki a sootọ, awa kò tii mọ ohun pupọ nipa bi ọpọlọ eniyan ti ń fi isọfunni pamọ, tabi bi o ṣe ń pe e jade nigba ti o bá fẹ. . . . Ohun ti o pọ̀ to ọgọrun-un billion sẹẹli iṣan imọlara ni o wà ninu ọpọlọ eniyan.
Olukuluku sẹẹli ni o wà ni oju ọ̀nà ibanisọrọpọ pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn sẹẹli yooku, nipasẹ awọn ìsokọ́ra atatare isọfunni ti wọn tẹ́wọ́ jade bi igi. Ṣiṣeeṣe ti isopọmọra laaarin araawọn jẹ eyi ti o takoko lọna ti o yanilẹnu gidigidi.”23, 24. Darukọ diẹ lara awọn ẹ̀yà ara ti a ṣètò lọna agbayanu, alaye wo ni onimọ ẹ̀rọ kan ṣe?
23 Awọn ojú rẹ ṣe kòńgẹ́ laitase ti o si le mu araarẹ̀ ba ayika mu ju kamẹra eyikeyii lọ; nitootọ, wọn jẹ kamẹra ayaworan aláwọ̀ àràbarà ti ń rìn, ti o ń dá ṣiṣẹ, ti o fúnraarẹ̀ ń yan ọ̀gangan ìfojúsùn rẹ̀. Etí rẹ le dá oniruuru ìró mọ̀ ki o si fun ọ ni òye ìha ibi ti nǹkan wà ati òye iduro lọna ti o wà deedee. Ọkàn-àyà rẹ jẹ ẹ̀rọ ti ń tú nǹkan jade ti o ni agbara iṣe tí awọn oniṣẹ ẹ̀rọ tí wọn dara julọ kò tíì le ṣe ẹ̀dà rẹ̀. Awọn ẹ̀yà ara yooku: imú rẹ, ahọ́n, ati awọn ọwọ́ rẹ, ati awọn eto-igbekalẹ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ yipo ara ati ti òòlọ̀ rẹ, lati mẹnukan iwọnba diẹ jẹ eyi ti o kọyọyọ pẹlu.
24 Nipa bayii, onimọ ẹ̀rọ kan ti a háyà lati ṣètò ẹ̀rọ kọmputa kan ki o sì ṣe e sọ èrò rẹ̀ jade pe: “Bi kọmputa mi ba beere fun oluṣe kan, meloomeloo ni yoo ti jẹ bẹẹ niti ẹrọ didiju ti ara-oun-eroja abẹ̀mí eyi tí í ṣe ara eniyan temi—eyi ti o tun jẹ apá ti o kere pupọ julọ lara eto-igbekalẹ letoleto ti agbaye ti o wà lailopin naa?”
25, 26. Ki ni o yẹ ki Olùṣètò Giga Julọ naa le sọ fun wa?
25 Gan-an gẹgẹ bi awọn eniyan ti ni ète kan lọkan nigba ti wọn ṣe awọn ọkọ̀ ofuurufu, ẹ̀rọ kọmputa, kẹ̀kẹ́, ati awọn ohun eelo miiran, bẹẹ ni Olùṣètò ọpọlọ ati ara awọn eniyan ti nilati ni ète kan ní ṣíṣètò wa. Olùṣètò yii sì nilati ni ọgbọn ti o ga ju ti eniyan lọ, niwọn bi kò ti si eyikeyii ninu wa ti o le ṣe ẹ̀dà awọn ìṣètò rẹ̀. O bọgbọnmu, nigba naa, pe oun ni Ẹni naa ti o le sọ fun wa idi ti oun fi ṣètò wa, idi ti oun fi fi wa sori ilẹ̀-ayé, ati ibi ti a ń lọ.
26 Nigba ti a bá kọ́ awọn nǹkan wọnyẹn, nigba naa a le lo ọpọlọ ati ara agbayanu ti Ọlọrun fun wa si ìhà ṣiṣaṣeyọri ète wa ni igbesi-aye. Ṣugbọn nibo ni a ti le kẹkọọ nipa awọn ète rẹ̀? Nibo ni oun ti fun wa ni isọfunni yẹn?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọna ti o dara julọ lati ṣawari idi ti a fi ṣètò ohun kan ni lati beere lọwọ olùṣètò naa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Idijupọ ati ìṣètò awọn ẹ̀dá alaaye ni a le rí ninu ipin ohun tíntìntín ti o kere julọ inu DNA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
“Iṣoro yíyanjú nipasẹ ọpọlọ eniyan tayọ agbara iṣe ti ẹ̀rọ kọmputa ti o lagbara julọ jìnnàjìnnà”