Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Walaaye Titilae Ninu Paradise Ori Ilẹ̀-ayé Kan

Walaaye Titilae Ninu Paradise Ori Ilẹ̀-ayé Kan

Ìsọ̀rí 8

Walaaye Titilae Ninu Paradise Ori Ilẹ̀-ayé Kan

1, 2. Bawo ni igbesi-aye yoo ṣe rí labẹ iṣakoso Ijọba Ọlọrun?

1 Ki ni igbesi-aye yoo ti rí nigba ti Ọlọrun bá mu ìwà-ibi ati ijiya kuro ni ilẹ̀-ayé ti o sì mu ayé titun rẹ̀ wọle wá labẹ idari onifẹẹ ti Ijọba rẹ̀ ọrun? Ọlọrun ṣeleri lati ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀ lati tẹ́ ifẹ gbogbo ohun alaaye lọ́rùn.’—Orin Dafidi 145:16.

2 Ki ni awọn ohun bibọgbọnmu ti o jẹ ifẹ-ọkan rẹ? Wọn kii ha ṣe fun igbesi-aye alayọ, iṣẹ ti o gbámúṣé, ọpọ ohun-ìní, awọn ayika ti o rẹwà, alaafia laaarin gbogbo eniyan, ati ominira kuro lọwọ aisi idajọ òdodo, aisan, ijiya, ati iku? Ki si ni nipa oju-iwoye alayọ nipa tẹmi? Gbogbo awọn nǹkan wọnyẹn ni ọwọ́ yoo tẹ̀ laipẹ labẹ iṣakoso Ijọba Ọlọrun. Ṣakiyesi ohun ti awọn asọtẹlẹ Bibeli sọ nipa awọn ibukun agbayanu ti yoo dé ninu ayé titun yẹn.

Araye Wà Ni Alaafia Pípé

3-6. Idaniloju wo ni a ní pe awọn eniyan yoo ni alaafia ninu ayé titun?

3 “[Ọlọrun] mu ki ogun dẹ́kun titi de ipẹkun ilẹ̀-ayé. O ṣẹ́ ọrun si ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ o si ké ọ̀kọ̀ si wẹ́wẹ́; awọn kẹ̀kẹ́ [ogun] ni oun fi jóná.”—Orin Dafidi 46:9, NW.

4 “Wọn o fi idà won rọ ọbẹ-plau, wọn o si fi ọ̀kọ̀ wọn rọ doje; orilẹ-ede kì yoo gbe idà soke si orilẹ-ede; bẹẹ ni wọn kì yoo kọ́ ogun jija mọ́.”—Isaiah 2:4.

5 “Awọn ọlọkan tutu ni yoo jogun ayé; wọn o si maa ṣe inu didun ninu ọpọlọpọ alaafia.”—Orin Dafidi 37:11.

6 “Gbogbo ayé sinmi, wọn sì gbé jẹ́: wọn bú jade ninu orin kikọ.”—Isaiah 14:7.

Eniyan ati Ẹranko Wà Ni Alaafia

7, 8. Alaafia wo ni yoo wà laaarin awọn eniyan ati ẹranko?

7 “Ikooko pẹlu yoo maa bá ọdọ-agutan gbé pọ̀, kinniun yoo si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ maluu ati ọmọ kinniun ati ẹgbọrọ ẹran abọpa yoo maa gbé pọ̀; ọmọ kekere yoo si maa dà wọn. Maluu ati beari yoo maa jẹ pọ̀; ọmọ wọn yoo dubulẹ pọ̀; kinniun yoo si jẹ koriko bi maluu. Ọmọ ẹnu-ọmu yoo si ṣire ni ihò paramọlẹ, ati ọmọ ti a já lẹnu-ọmu yoo si fi ọwọ́ rẹ̀ si ihò gunte. Wọn ki yoo panilara, bẹẹ ni wọn ki yoo panirun.”—Isaiah 11:6-9.

8 “Ni ọjọ naa ni emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹyẹ oju ọrun, ati ohun ti ń rákò lori ilẹ̀ dá majẹmu fun wọn . . . emi o si mu wọn dubulẹ ni ailewu.”—Hosea 2:18.

Ilera Pípé, Ìyè Ayeraye

9-14. Ṣapejuwe awọn ipo ilera ninu ayé titun.

9 “Ni igba naa ni oju awọn ti wọ́n jẹ́ afọju yoo là, etí ìyétí awọn aditi yoo sì ṣí. Ni igba naa ni ẹni ti o jẹ arọ yoo goke gan-an gẹgẹ bi agbọnrin kan ti ń ṣe, ati ahọn ẹni ti o jẹ odi yoo kigbe jade fun inudidun.”—Isaiah 35:5, 6 NW.

10 “Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo sì sí iku mọ́, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ́.”—Ìfihàn 21:4.

11 “Awọn ará ibẹ̀ ki yoo wi pe, Oótù ń pa mi.”—Isaiah 33:24.

12 “Ara rẹ̀ yoo si já yọ̀yọ̀ ju ti ọmọ kekere, yoo si tun pada si ọjọ igba ewe rẹ̀.”—Jobu 33:25.

13 “Ẹ̀bùn ọfẹ Ọlọrun ni ìyè ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.”—Romu 6:23.

14 “Ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ́ [yoo] . . . ni ìyè ainipẹkun.”—Johannu 3:16.

A Mú Awọn Oku Padabọ Si Ìyè

15-17. Ireti wo ni o wà fun awọn ti wọn ti kú?

15 “Ajinde oku ń bọ̀, ati ti oloootọ, ati ti alaiṣootọ.”—Iṣe 24:15.

16 “Wakati ń bọ̀, ninu eyi ti gbogbo awọn ti o wà ni isa oku [iranti Ọlọrun] yoo gbọ́ ohùn rẹ̀. Wọn o si jade wá.”—Johannu 5:28, 29.

17 “Okun si jọ awọn oku ti ń bẹ ninu rẹ̀ lọwọ; ati iku ati ipo-oku si jọ oku ti o wà ninu wọn lọwọ.”—Ìfihàn 20:13.

Ilẹ̀-Ayé, Paradise Ọlọ́pọ̀ Yanturu Kan

18-22. Ki ni a o yí gbogbo ayé pada si?

18 “Òjò ibukun yoo wà. Igi ìgbẹ́ yoo si so eso rẹ̀, ilẹ̀ yoo si maa mu àsunkún rẹ̀ wá, wọn o si wà ni alaafia ni ilẹ̀ wọn.”—Esekieli 34:26, 27.

19 “Nigba naa ni ilẹ̀ yoo to maa mu àsunkún rẹ̀ wá; Ọlọrun, Ọlọrun wa tikaraarẹ yoo si busi i fun wa.”—Orin Dafidi 67:6.

20 “Aginju ati ilẹ̀ gbigbẹ yoo yọ̀ fun wọn; ijù yoo yọ̀, yoo si tanna bi lili.”—Isaiah 35:1.

21 “Awọn oke-nla ati awọn oke kéékèèké funraawọn yoo bú si ayọ niwaju yin pẹlu igbe orin ayọ, gbogbo awọn igi ìgbẹ́ funraawọn yoo si ṣapẹ́. Dípò igi ẹlẹ́gùn-ún igi junipa ni yoo hù jade soke. Dípò òṣùṣú olóró igi mirtili yoo hù jade.”—Isaiah 55:12, 13 NW.

22 “Iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.”—Luku 23:43.

Ibùgbé Didara fun Gbogbo Eniyan

23, 24. Idaniloju wo ni o wà pe ibùgbé ti o pọ̀ to yoo wà fun gbogbo eniyan?

23 “Wọn o si kọ ilé, wọn o si gbé inu wọn . . . Wọn ki yoo kọ́ ilé fun ẹlomiran igbe, wọn ki yoo gbìn fun ẹlomiran ijẹ. . . . Awọn iyanfẹ mi yoo si jìfà iṣẹ ọwọ́ wọn. Wọn ki yoo ṣiṣẹ lasan, wọn ki yoo bimọ fun wahala.”—Isaiah 65:21-23.

24 “Wọn o jokoo olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan ki yoo si dáyàfò wọn.”—Mika 4:4.

Iwọ Le Walaaye Titilae Ninu Paradise

25. Ifojusọna agbayanu wo ni a ni fun ọjọ-ọla?

25 Ẹ wo iru ifojusọna agbayanu ti o wà ni ọjọ-ọla! Ẹ wo iru ète tootọ ti iwalaaye le ní nisinsinyi nigba ti a bá so o rọ̀ mọ́ ireti didaju pe ninu ayé titun Ọlọrun gbogbo awọn iṣoro ayé isinsinyi yoo di ohun atijọ laelae! “A ki yoo si ranti awọn ti iṣaaju, bẹẹ ni wọn ki yoo wá si àyà.” (Isaiah 65:17) Ẹ si wo bi o ti tuninínú to lati mọ̀ pe igbesi-aye nigba naa yoo jẹ titi ayeraye: “[Ọlọrun] o gbe iku mì laelae.”—Isaiah 25:8.

26. Ki ni kọkọrọ naa si wiwalaaye titilae ninu ayé titun Ọlọrun?

26 Iwọ ha fẹ lati walaaye titilae ninu Paradise ayé titun ti o ti sunmọle gírígírí nisinsinyi bi? ‘Ki ni emi yoo nilati ṣe lati jere ojurere Ọlọrun nigba opin ayé yii ki n si walaaye wọ inu ayé titun rẹ̀?’ ni iwọ le beere. Iwọ nilati ṣe ohun ti Jesu fihan ninu adura si Ọlọrun pe: “Ìyè ainipẹkun naa si ni eyi, ki wọn ki o le mọ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ rán.”—Johannu 17:3.

27. Ki ni o gbọdọ ṣe lati le nipin-in ninu ète Ọlọrun?

27 Nitori naa, wá Bibeli kan ní, ki o si rí àrídájú ohun ti o ti kà ninu ìwé pẹlẹbẹ yii. Wá awọn ẹlomiran ti wọn ń kẹkọọ ti wọn si ń kọni ni awọn otitọ Bibeli wọnyi rí. Já ara rẹ gbà lọwọ awọn agabagebe isin ti ń kọni ti wọn si ń ṣe awọn ohun ti o lòdìsí Bibeli. Kẹkọọ bi iwọ, papọ pẹlu awọn araadọta ọkẹ miiran ti wọn ti ń ṣe ifẹ-inu Ọlọrun nisinsinyi, ṣe le nipin-in ninu ète Ọlọrun pe ki awọn ẹda-eniyan walaaye titilae ninu paradise ori ilẹ̀-ayé. Ki o si fi ohun ti Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọrun polongo nipa ọjọ-ọla ti o sunmọle sọkan pe: “Ayé sì ń kọja lọ, ati ifẹkufẹẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹni ti o bá ń ṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo duro laelae.”—1 Johannu 2:17.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ète Ọlọrun lati mu paradise ori ilẹ̀-ayé padabọ yoo ni imuṣẹ laipẹ