Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkàwé Nipa Àsè Ìgbéyàwó

Àkàwé Nipa Àsè Ìgbéyàwó

Orí 107

Àkàwé Nipa Àsè Ìgbéyàwó

NIPASẸ awọn àkàwé meji, Jesu ti túdìí àṣírí awọn akọwe ofin ati awọn olórí alufaa, wọn sì fẹ́ lati pa á. Ṣugbọn Jesu kò tíì ṣetán pẹlu wọn rárá. Ó nbaa lọ lati sọ àkàwé miiran fun wọn sibẹsibẹ, ní wiwi pe:

“Ijọba awọn ọrun ti dabi ọkunrin kan, ọba kan, tí ó se àsè igbeyawo fun ọmọkunrin rẹ̀. Ó sì rán awọn ẹrú rẹ̀ jade lati késí awọn wọnni tí a pè sí àsè ìgbéyàwó naa, ṣugbọn wọn kò fẹ́ lati wá.”

Jehofa Ọlọrun ni Ọba naa tí ó pèsè àsè ìgbéyàwó kan silẹ fun Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi. Nikẹhin, 144,000 iyawo rẹ̀, awọn ọmọlẹhin ẹni àmì-òróró ni a ó sopọ̀ṣọ̀kan pẹlu rẹ̀ ninu ọ̀run. Awọn ọmọ-abẹ́ Ọba naa ni awọn eniyan Isirẹli, awọn ẹni tí wọn gba àǹfààní naa lati di “ijọba awọn alufaa” nigba tí a mú wọn wá sínú majẹmu Òfin ní 1513 B.C.E. Nipa bayii, ní àkókò yẹn, a nawọ́ ìkésíni sí wọn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ lati wá síbi àsè ìgbéyàwó naa.

Bí ó ti wù kí ó rí, ìpè àkọ́kọ́ sí awọn tí a késí wọnni kò jáde lọ títí di ìgbà ìwọ́wé 29 C.E., nigba ti Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ (awọn ẹrú ọba naa) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn ti wiwaasu Ijọba naa. Ṣugbọn awọn ọmọ Isirẹli àbínibí tí wọn gba ìpè tí ó jade lati ọ̀dọ̀ awọn ẹrú naa lati 29 C.E. sí 33 C.E. kò ṣetan lati wá. Nitori naa Ọlọrun fun orílẹ̀-èdè awọn ẹni tí a késí naa ní àǹfààní miiran, gẹgẹ bi Jesu ti ṣalaye:

“Oun sì tún rán awọn ẹrú miiran, wipe, ‘Ẹ sọ fun awọn wọnni tí a ti pè: “Ẹ wòó! mo ti pèsè oúnjẹ mi silẹ, a ti pa awọn akọ maluu ati awọn ẹranko àbọ́pa mi, ohun gbogbo sì ti wà ní sẹpẹ́. Ẹ wá sí àsè ìgbéyàwó naa.”’” Ìpè keji tí ó gbẹ̀hìn yii sí awọn wọnni tí a késí bẹ̀rẹ̀ ní Pẹntikọsi 33 C.E., nigba ti a tú ẹmi mimọ jáde sórí awọn ọmọlẹhin Jesu. Ìpè yii nbaa lọ títí di 36 C.E.

Eyi ti o pọ julọ ninu awọn ọmọ Isirẹli, bí ó ti wù kí ó rí, kọ ìpè yii silẹ tẹ̀gàntẹ̀gàn pẹlu. “Wọn lọ láìbìkítà,” ni Jesu ṣàlàyé, “ọ̀kan sí pápá tirẹ̀, òmíràn sí iṣẹ́ òwò rẹ̀; ṣugbọn awọn yooku, ní dídi awọn ẹrú rẹ̀ mú, hùwà àfojúdi sí wọn wọn sì pa wọn.” “Ṣugbọn,” Jesu nbaa lọ, “ọba naa kún fun ìbínú, ó sì rán awọn ọmọ-ogun rẹ̀ ó sì pa awọn àpànìyàn wọnni run ó sì fi iná sun ìlú wọn.” Eyi wáyé ní 70 C.E., nigba ti a run Jerusalẹmu délẹ̀ wómúwómú lati ọwọ́ awọn ara Roomu, tí a sì pa awọn àpànìyàn wọnni.

Lẹhin naa Jesu ṣalaye ohun tí ó wáyé láàárín àkókò naa: “Nigba naa [ni ọba] wí fun awọn ẹrú rẹ̀ pe, ‘Àsè ìgbéyàwó naa ti wà ní sẹpẹ́, ṣugbọn awọn tí a ti pè jẹ́ aláìyẹ. Nitori naa ẹ lọ sí ojú ọ̀nà tí ó jade kuro ní ìlú naa, ẹnikẹni tí ẹyin bá sì rí ni kí ẹ pè wá sí àsè ìgbéyàwó naa.’” Awọn ẹrú naa ṣe eyi, “iyàrá fun ayẹyẹ ìgbéyàwó naa sì kún fun awọn wọnni tí wọn ńrọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì.”

Iṣẹ́ kíkó awọn àlejò jọ yii lati awọn ojú ọ̀nà ní òde ìlú awọn ẹni tí a késí naa bẹ̀rẹ̀ ní 36 C.E. Ọ̀gágun ara Roomu naa, Kọniliu ati idile rẹ̀ ni awọn aláìkọlà ti kii ṣe Juu àkọ́kọ́ tí a kójọ. Ìkówọlé awọn ẹni tí kii ṣe Juu wọnyi, gbogbo awọn ẹni tí wọn jẹ́ arọ́pò fun awọn wọnni tí wọn kọ ìpè naa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀, tí nbaa lọ wọnú ọ̀rúndún ogún yii.

Ó jẹ́ láàárín ọ̀rúndún ogún yii ni iyàrá fun ayẹyẹ ìgbéyàwó naa kún. Jesu sọ ohun tí ó wáyé lẹhin naa, ni wiwi pe: “Nigba ti ọba wọlé wá lati ṣe àyẹ̀wò awọn àlejò naa ó rí ọkunrin kan nibẹ tí kò wọ ẹ̀wù ìgbéyàwó. Nitori naa ó wí fun un pe, ‘Àwé, bawo ni iwọ ṣe wọ ìhín wá láìwọ ẹ̀wù ìgbéyàwó?’ Oun kò sì lè fèsì. Nigba naa ni ọba wí fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, ‘Ẹ dì í tọwọ́tẹsẹ̀ kí ẹ sì sọ ọ́ sínú òkùnkùn lóde. Nibẹ ni sísunkún ati pípahínkeke rẹ̀ yoo wà.’”

Ọkunrin tí kò wọ ẹ̀wù ìgbéyàwó naa ṣàpẹẹrẹ awọn fàwọ̀rajà Kristẹni ti Kristẹndọmu. Ọlọrun kò fi ìgbà kankan wò wọn gẹgẹ bi awọn tí wọn ní àmì ìdánimọ̀ títọnà gẹgẹ bi ọmọ Isirẹli tẹmi. Ọlọrun kò fi igba kankan fòróró yàn wọn pẹlu ẹ̀mí mímọ́ gẹgẹ bi awọn ajogún Ijọba. Nitori naa a jù wọn sóde sínú òkùnkùn níbi tí wọn yoo ti jìyà ìparun.

Jesu pari àkàwé rẹ̀ nipa wíwí pe: “Nitori ọpọlọpọ ni a késí, ṣugbọn diẹ ni a yàn.” Bẹẹni, ọpọlọpọ ni a késí lati inú orílẹ̀-èdè Isirẹli lati di mẹmba iyawo Kristi, ṣugbọn kìkì iwọnba diẹ awọn ọmọ Isirẹli àbínibí ni a yàn. Ọ̀pọ̀ jùlọ ninu awọn 144,000 àlejò naa tí wọn rí èrè ti ọ̀run gbà fi ẹ̀rí hàn pe wọn kii ṣe ọmọ Isirẹli. Matiu 22:1-14; Ẹkisodu 19:1-6; Iṣipaya 14:1-3, NW.

▪ Awọn wo ni a késí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ síbi àsè aṣeyẹ ìgbéyàwó naa, nigba wo ni a sì nawọ́ ìkésíni naa sí wọn?

▪ Nigba wo ni ìpè naa kọ́kọ́ jáde lọ fun awọn tí a késí, awọn wo sì ni awọn ẹrú tí a lò lati mú ìpè naa jáde?

▪ Nigba wo ni a nawọ́ ìpè keji, awọn wo ni a sì késí nígbẹ̀hìn gbẹ́hín?

▪ Awọn wo ni ọkunrin tí kò ní ẹ̀wù aṣeyẹ ìgbéyàwó naa ṣapẹẹrẹ?

▪ Awọn wo ni ọpọlọpọ tí a késí, ati iwọnba diẹ tí a yàn?