Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àmì Awọn Ọjọ Ikẹhin

Àmì Awọn Ọjọ Ikẹhin

Orí 111

Àmì Awọn Ọjọ Ikẹhin

ỌSAN Tuesday ni ó jẹ́ nisinsinyi. Bí Jesu ti jókòó sórí Òkè Olifi, tí ó ńwo tẹmpili nísàlẹ̀, Peteru, Anderu, Jakọbu, ati Johanu tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀. Wọn ńdàníyàn nipa tẹmpili naa, niwọn bi Jesu ti ṣẹ̀ṣẹ̀ sọtẹ́lẹ̀ pe ‘a kì yoo fi òkúta kan silẹ lórí èkejì ninu rẹ̀.’

Ṣugbọn bí ó ti hàn gbangba wọn tilẹ ní ohun pupọ sii lọ́kàn bí wọn ti sunmọ Jesu. Ní awọn ọsẹ diẹ ṣaaju, oun ti sọ̀rọ̀ nipa “wíwàníhìn-ín” rẹ̀, laaarin àkókò kan ‘nigba ti a o ṣí Ọmọkunrin eniyan payá.’ Ati ní àkókò kan ṣaaju, oun ti sọ fun wọn nipa “òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” Nitori naa awọn apọsiteli nífẹ̀ẹ́ ìtọpinpin gidigidi.

“Sọ fun wa,” ni wọn wí, “nigba wo ni nǹkan wọnyi yoo ṣẹ [tí yoo yọrísí ìparun Jerusalẹmu ati tẹmpili rẹ̀], ki ni yoo sì ṣe àmì wíwàníhìn-ín rẹ ati ti òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan?” Niti tootọ, ibeere wọn jẹ́ alápá mẹ́ta. Lakọọkọ, wọn fẹ́ lati mọ̀ nipa òpin Jerusalẹmu ati tẹmpili rẹ̀, lẹhin naa nipa wíwàníhìn-ín Jesu ninu agbára Ijọba, ati nikẹhin nipa òpin gbogbo ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan lódidi.

Ninu ìdáhùnpadà rẹ̀ gígùn, Jesu dáhùn gbogbo awọn apá mẹtẹẹta ibeere naa. Ó pèsè àmì kan tí ó dáfi àkókò naa hàn tí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan Juu yoo dópin; ṣugbọn ó pèsè pupọ sii. Ó tún fúnni ní àmì kan pẹlu tí yoo mú awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ọjọ iwaju wà lójúfò kí wọn baa lè mọ̀ pe awọn ńgbé ní àkókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ ati nítòsí òpin gbogbo ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan lódidi.

Bí awọn ọdun ti ńkọjá, awọn apọsiteli bẹrẹsii kíyèsí ìmúṣẹ asọtẹlẹ Jesu. Bẹẹni, awọn ohun naa gan-an tí oun sọtẹ́lẹ̀ bẹrẹsii ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọn. Nipa bayii, awọn Kristẹni tí wọn walaaye ní 37 ọdun lẹhin ìgbà naa ní 70 C.E., ni ìparun ètò-ìgbékalẹ̀ awọn Juu pẹlu tẹmpili rẹ̀ kò bá lojiji.

Bí ó ti wù kí ó rí, wíwàníhìn-ín Jesu ati òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan kò ṣẹlẹ̀ ní 70 C.E. Wíwàníhìn-ín rẹ̀ ninu agbára Ijọba ṣẹlẹ̀ ní àkókò pípẹ́ lẹhin naa. Ṣugbọn nigba wo? Ìgbéyẹ̀wò asọtẹlẹ Jesu ṣí eyi payá.

Jesu sọtẹ́lẹ̀ pe “awọn ogun ati awọn ìròhìn ogun” yoo wà. “Orílẹ̀-èdè yoo dìde sí orílẹ̀-èdè,” ni oun wí, àìtó ounjẹ yoo sì wà, ìsẹ̀lẹ̀, ati àjàkálẹ̀ àrùn. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni a ó kórìíra tí a ó sì pa. Awọn wolii eke yoo dìde wọn yoo sì ṣi ọpọlọpọ lọ́nà. Ìwà àìlófin yoo pọ̀sí i, ìfẹ́ awọn eniyan pupọ yoo sì di tútù. Ní àkókò kan naa, ihinrere Ijọba Ọlọrun ni a ó waasu gẹgẹ bi ẹ̀rí fun gbogbo orílẹ̀-èdè.

Bí ó tilẹ jẹ́ pe asọtẹlẹ Jesu ní ìmúṣẹ aláàlà ṣaaju iparun Jerusalẹmu ní 70 C.E., ìmúṣẹ titobi rẹ̀ ṣẹlẹ̀ lákòókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ ati òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan. Àtúnyẹ̀wò àfẹ̀sọṣe nipa awọn ìṣẹ̀lẹ̀ ninu ayé lati 1914 ṣípayá pe asọtẹlẹ Jesu ṣiṣe pataki yii ti bẹ̀rẹ̀ sii ní ìmúṣẹ rẹ̀ titobi lati ọdun yẹn.

Apá miiran ninu àmì naa tí Jesu fúnni ni ìfarahàn “ohun ìsúni fún ìríra naa tí ńṣokùnfà ìsọdahoro.” Ní 66 C.E. ohun ìsúni fún ìríra yii farahàn ní ọna “awọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” Roomu “tí wọn pabùdó’ yí Jerusalẹmu ká tí wọn sì jin ògiri tẹmpili rẹ̀ lẹ́sẹ̀. “Ohun ìsúni fún ìríra naa” dúró sí ibi tí kò tọ́.

Ninu ìmúṣẹ titobi àmì naa, ohun ìsúni fún ìríra naa ni Imulẹ Awọn Orilẹ-ede ati olùgbapò rẹ̀, Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. Ètò-àjọ fun alaafia àgbáyé yii ni Kristẹndọmu wò gẹgẹ bi arọ́pò fun Ijọba Ọlọrun. Ẹ wo bi ó ti súni fún ìríra tó! Nitori naa bí àkókò ti ńlọ, awọn agbára ìṣèlú tí wọn bá Iparapọ Awọn Orilẹ-ede kẹ́gbẹ́ yoo yíjú sí Kristẹndọmu (Jerusalẹmu amápẹẹrẹṣẹ) yoo sì sọ ọ́ dahoro.

Nipa bayii Jesu sọtẹ́lẹ̀ pe: “Ipọnju ńlá yoo wà irú eyi tí kò wáyé rí lati ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé wá títí di isinsinyi, ó tì, bẹẹni kò tún ní wáyé mọ́.” Nigba tí ó jẹ́ pe ìparun Jerusalẹmu ní 70 C.E. jẹ́ ipọnju ńlá kan nitootọ, pẹlu iye tí ó ju million kan tí a ròhìn pe a pa, kii ṣe ipọnju kan tí ó tóbi jù Ìkún omi agbaye ní ọjọ́ Noa. Nitori naa ìmúṣẹ titobi apá yii ninu asọtẹlẹ Jesu kò tii ní ìmúṣẹ sibẹ.

Ìgbọ́kànlé Lákòókò Awọn Ọjọ́ Ìkẹhìn

Bí Tuesday, Nisan 11, tí ńparí lọ, Jesu nba ijiroro rẹ̀ pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀ nipa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ ninu agbára Ijọba ati ti opin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan niṣo. Ó kìlọ̀ fun wọn nipa sísáré tẹ̀lé awọn eke Kristi. Oun wipe awọn ìgbìdánwò ni wọn yoo ṣe, “lati ṣì lọ́nà, bí ó ba ṣeeṣe, àní awọn ẹni àyànfẹ́ pàápàá.” Ṣugbọn, bí awọn idì tí ńríran jinna, awọn ẹni àyànfẹ́ wọnyi yoo kórajọ sí ibi tí wọn ti lè rí ounjẹ ti ẹ̀mí tootọ, eyiini ni, lọ́dọ̀ Kristi tootọ naa nigba wíwàníhìn-ín rẹ̀ aláìṣeérí. A kì yoo ṣì wọn lọ́nà kí wọn sì tipa bẹẹ korajọ sọ́dọ̀ eke Kristi.

Kìkì ìfarahàn tí ó ṣeérí ni awọn eke Kristi lè ṣe. Ní ìyàtọ̀, wíwàníhìn-ín Jesu yoo jẹ́ aláìṣeérí. Yoo wáyé ní akoko oníjìnnìjìnnì ninu ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, gẹgẹ bi Jesu ti wi: “Òòrùn yoo ṣókùnkùn, òṣùpá kì yoo sì funni ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.” Bẹẹni, eyi yoo jẹ́ sáà dídúdú julọ ninu ìgbà wíwà aráyé. Yoo dabi ẹni pe oòrùn ti ṣókùnkùn ní ọ̀sán, ati bi ẹni pe òṣùpá kò funni ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ní òru.

“Jesu nbaa lọ pe, “Awọn agbára ọ̀run ni a ó mì.” Ó tipa bayii fihan pe awọn ọ̀run tí ó ṣeérí yoo ní ìfarahàn alasọtẹlẹ. Awọn ọ̀run kì yoo wulẹ̀ jẹ́ àkóso awọn ẹyẹ mọ́, ṣugbọn wọn yoo kún fun awọn ọkọ̀ òfúúrufú ti a fi njagun, awọn àgbá rọkẹẹti, ati awọn ohun èèlò tí nriran wọnú òfúúrufú. Ìbẹ̀rù ati ìwà-ipá naa yoo rékọjá ohunkohun tí a ti ní ìrírí rẹ̀ ninu ìtàn ẹ̀dá ènìyàn.

Gẹgẹ bi ìyọrísí eyi, Jesu wipe, “làásìgbò awọn orilẹ-ede yoo wà, laimọ ọ̀nà àbájáde nitori ariwo omi òkun ati ìrugùdù rẹ̀, nigba ti awọn eniyan yoo dákú lati inú ìbẹ̀rù ati ìfojúsọ́nà awọn ohun tí ńbọ̀ wá sori ilẹ̀-ayé gbígbé.” Nitootọ, sáà dídúdú julọ yii ninu ìgbà wíwà ẹ̀dá ènìyàn yoo ṣamọ̀nà sí akoko naa nigba ti, gẹgẹ bi Jesu ti wi, “àmì Ọmọkunrin eniyan yoo farahàn ní ọ̀run, nigba naa sì nì gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀-ayé yoo lù araawọn ninu ìdárò.”

Ṣugbọn kìí ṣe gbogbo eniyan ni yoo maa dárò nigba ti ‘Ọmọkunrin eniyan bá dé pẹlu agbára’ lati pa ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan buruku yii run. “Awọn ẹni àyànfẹ́,” 144,000 tí yoo ṣajọpin pẹlu Kristi ninu Ijọba rẹ̀ ọ̀run, kì yoo dárò, bẹẹ naa sì ni awọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn pẹlu, awọn ẹni tí Jesu pe ni “awọn agutan miiran” ni iṣaaju. Láìka gbigbe ti a ńgbé ni sáà dídúdú julọ ninu ìtàn ẹ̀dá ènìyàn sí, awọn wọnyi dáhùnpadà sí ìṣírí Jesu pe: “Bí awọn nǹkan wọnyi bá ti bẹ̀rẹ̀ sii wáyé, ẹ dìde duro, kí ẹ sì gbé orí yin sókè, nitori ìdáǹdè yin tí ńsúnmọ́ itòsí.”

Kí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tí yoo maa gbé ní awọn ọjọ́ ikẹhin baa lè pinnu ìsúnmọ́tòsí opin naa, Jesu funni ni àkàwé yii: “Ẹ kiyesi igi ọ̀pọ̀tọ́ ati gbogbo igi yooku: Nigba ti wọn bá ti wà ninu ìrudi, nipa kikiyesi i ẹyin mọ̀ funraayin pe nisinsinyi ìgbà ẹ̀rùn tí súnmọ́lé. Ni ọ̀nà yii pẹlu, nigba ti ẹ bá rí awọn nǹkan wọnyi tí ńṣẹlẹ̀, ẹ mọ̀ pe ijọba Ọlọrun tí súnmọ́. Nitootọ ni mo wi fun yin, Ìran eniyan yii kì yoo kọja lọ tán títí gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹlẹ.”

Nipa bayii, nigba ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bá rí onírúurú apá ẹ̀ka àmì naa tí ńṣẹ, wọn nilati mọ̀ pe opin étó-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan ti súnmọ́lé ati pe Ijọba Ọlọrun láìpẹ́ yoo nù gbogbo ìwà burúkú kúrò. Niti tootọ, opin yoo wáyé ní ìgbà ìgbésí-ayé awọn eniyan tí wọn rí ìmúṣẹ gbogbo ohun tí Jesu sọtẹlẹ! Ní ṣíṣí awọn ọmọ-ẹhin wọnni tí yoo walaaye ní awọn ọjọ́ ikẹhin oníhílàhílo naa létí, Jesu wipe:

“Ẹ kiyesi araayin kí ọkàn-àyà yin máṣe di eyi tí a fi àjẹjù ati àmujù ati àníyàn igbesi-aye dẹ́rùpa láé, lojiji kí ọjọ́ yẹn wá dé bá yin gẹgẹ bi ìkẹkùn kan. Nitori yoo dé bá gbogbo awọn wọnni tí ńgbé ní gbogbo ilẹ̀-ayé. Ẹ maa wà lójúfò, nigba naa, ní gbogbo ìgbà ní gbigba àdúrà ẹ̀bẹ̀ kí ẹ lé ṣàṣeyọrí sí rere ní sísálà kuro ninu gbogbo nǹkan wọnyi tí a ti kàdárà lati wáyé, ati ní dídúró niwaju Ọmọkunrin eniyan.”

Awọn Wundia Ọlọ́gbọ́n ati Òmùgọ̀

Jesu ti ńdáhùn ohun tí awọn apọsiteli rẹ̀ beere fun eyi tí ó jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ ninu agbára Ijọba. Nisinsinyi oun pèsè awọn apá ẹ̀ka siwaju sí i nipa àmì naa ninu awọn òwe mẹta, tabi awọn àkàwé.

Ìmúṣẹ àkàwé kọọkan ni awọn wọnni tí wọn walaaye lákòókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ lè kiyesi. Jesu nasẹ̀ àkọ́kọ́ pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi: “Nigba naa ni a o fi ijọba ọ̀run wé awọn wundia mẹ́wàá, tí wọn mú fìtílà wọn, tí o sì jáde lọ pade ọkọ ìyàwó. Márùn-ún ninu wọn ṣe ọlọgbọ́n, márùn-ún sì ṣe aláìgbọ́n.”

Nipasẹ ọ̀rọ̀ naa “a o fi ijọba ọ̀run wé awọn wundia mẹ́wàá,” Jesu kò ní in lọ́kàn pe ìdajì awọn wọnni tí wọn yoo jogún Ijọba ọ̀run naa jẹ́ awọn aláìgbọ́n eniyan tí ìdajì sì jẹ́ awọn ọlọ́gbọ́n! Bẹẹkọ, ṣugbọn ohun tí oun nílọ́kàn ni pe ní ìsopọ̀ pẹlu Ijọba awọn ọ̀run, apá kan wà tí ó rí bí eyi tabi bí iyẹn, tabi awọn ọ̀ràn ní ìsopọ̀ pẹlu Ijọba naa yoo dabi ohun bayii ati bayii.

Awọn wundia mẹ́wàá naa ṣàpẹẹrẹ gbogbo awọn Kristẹni tí wọn wà ní ìlà fun tabi tí wọn sọ pe wọn wà ní ìlà fun Ijọba ọrun. Ní Pẹntikọsi 33 C.E. ni a ṣèlérí ijọ Kristẹni ni ìgbéyàwó fun Ọkọ iyawo tí a ti ṣe lógo, tí a ti jí dìde naa, Jesu Kristi. Ṣugbọn ìgbéyàwó naa yoo ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run ní àkókò kan tí a kò sọ ní pàtó ní ẹ̀hìn-ọ̀la.

Ninu àkàwé naa, awọn wundia mẹ́wàá naa jáde lọ pẹlu ète lati kí ọkọ ìyàwó naa kaabọ ati lati darapọ̀ mọ́ ìtọ́wọ̀ọ́rìn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Nigba ti ó bá dé, wọn yoo fi awọn àtùpà wọn tànmọ́lẹ̀ sí ojú ìrìnnà ìtọ́wọ̀ọ́rìn naa, ní títipa bayii bọlá fún ọkọ ìyàwó naa bí ó ti ńmú ìyàwó rẹ bọ̀ wá sí ilé tí a ti múrasílẹ̀ fun un. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu ṣàlàyé pe: “Awọn tí ó ṣe aláìgbọ́n mú fìtílà wọn, wọn kò sì mú òróró lọ́wọ́: ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n mú òróró ninu kòlòbó pẹlu fìtílà wọn. Nigba tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé, wọn sì sùn.”

Ìdádúró ọkọ ìyàwó naa fihàn pe wíwàníhìn-ín Kristi gẹgẹ bi Ọba tí ńṣàkóso yoo jẹ́ ní ọjọ́ ọ̀la jíjìnnàréré. Oun dé nígbẹ̀hìn gbẹ́hín sí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọdun 1914. Láàárín àkókò òru gígùn tí ó ṣaaju ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, gbogbo awọn wundia naa tòògbé wọn sì sùn. Ṣugbọn a kò dá wọn lẹ́bi fun eyi. Ìdálẹ́bi awọn wundia aláìgbọ́n naa jẹ́ nitori ṣíṣàìmú òróró lọwọ ninu kòlòbó wọn. Jesu ṣàlàyé bí awọn wundia naa ṣe jí ṣaaju kí ọkọ ìyàwó tó dé: “Láàárín ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, wipe, Wòó, ọkọ ìyàwó ńbọ̀; ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀, nigba naa ni gbogbo awọn wundia wọnni dìde, wọn sì tún fìtílà wọn ṣe. Awọn aláìgbọ́n sì wí fun awọn ọlọgbọ́n pe, Fun wa ninu òróró yin; nitori fìtílà wa ńkú lọ. Ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n dá wọn lóhùn, wipe, Bẹẹkọ; kí ó má baa ṣe aláìtó fun awa ati ẹyin: ẹ kúkú tọ awọn tí ńtà lọ, kí ẹ sì rà fun ara yin.”

Òróró naa ṣàpẹẹrẹ ohun tí ó ńmú kí awọn Kristẹni maa tàn gẹgẹ bi afúnni ní ìmọ́lẹ̀. Eyi jẹ Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọrun, eyi tí awọn Kristẹni dìmú ṣinṣin, papọ̀ pẹlu ẹ̀mí mímọ́, tí ó ńràn wọn lọ́wọ́ lati lóye Ọ̀rọ̀ yẹn. Òróró tẹ̀mí naa mú awọn wundia ọlọ́gbọ́n tóótun lati tan ìmọ́lẹ̀ jáde ní kíkí ọkọ ìyàwó káàbọ̀ lákòókò ìtówọ̀ọ́rìn lọ sí àsè ìgbéyàwó. Ṣugbọn ẹgbẹ́ wundia aláìgbọ́n naa kò ní ninu araawọn, ninu kòlòbó wọn, òróró tẹ̀mí tí wọn nílò. Nitori naa Jesu ṣàpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀:

“Nigba tí [awọn wundia aláìgbọ́n naa] sì ńlọ rà [òróró], ọkọ ìyàwó dé; awọn tí ó sì múra tán bá a wọlé lọ sí ibi ìyàwó: a sì ti ilẹ̀kùn. Ní ikẹhin ni awọn wundia yooku sì dé, wọn nwipe, Oluwa, Oluwa, ṣílẹ̀kùn fun wa. Ṣugbọn ó dáhùn, wipe, Lóòótọ́ ni mo wí fun yin, emi kò mọ̀ yin.”

Lẹhin tí Kristi dé ninu Ijọba rẹ̀ ti ọ̀run, ẹgbẹ́ wundia ọlọ́gbọ́n ti awọn Kristẹni ẹni àmì-òróró tootọ jí sí àǹfààní wọn ti títan ìmọ́lẹ̀ ninu ayé tí a ti mú ṣókùnkùn yii sí ìyìn Ọkọ ìyàwó tí ó ti padà dé naa. Ṣugbọn awọn wọnni tí wundia aláìgbọ́n naa yaworan láìmúrasílẹ̀ lati pèsè ìyìn ìkínikáàbọ̀ yii. Nitori naa nigba ti àkókò dé, Kristi kò ṣí ilẹ̀kùn àsè ìgbéyàwó ní ọ̀run fun wọn. Ó fi wọn silẹ lóde ninu òru ayé tí ó ṣókùnkùn julọ, lati ṣègbé pẹlu gbogbo awọn oníṣẹ́ àìlófin yòókù. “Nitori naa, ẹ maa ṣọ́nà,” ni Jesu fi pari ọ̀rọ̀, “bí ẹyin kò ti mọ ọjọ, tabi wakati.”

Àkàwé Awọn Talẹnti

Jesu ńbá ìjíròrò pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀ lọ lórí Òkè Olifi nipa sísọ àkàwé miiran fun wọn, èkejì ninu ọ̀wọ́ mẹta. Ní awọn ọjọ diẹ ṣaaju, nigba tí ó wà ní Jẹriko, ó sọ àkàwé awọn mina lati fihàn pe Ijọba naa ṣì wà sibẹsibẹ ní àkókò gígùn kan ní ọjọ iwaju. Àkàwé tí oun sọ nisinsinyi, bí ó tilẹ ní awọn apá pupọ tí wọn farajọra, ṣàpèjúwe ninu ìmúṣẹ rẹ̀ awọn ìgbòkègbodò lákòókò wíwàníhìn-ín Kristi ninu agbára Ijọba. Ó ṣàkàwé pe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọdọ maa ṣiṣẹ́ niwọn ìgbà ti wọn bá ṣì wà níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé lati mú “awọn ohun ìní rẹ̀” pọ̀sí i.

Jesu bẹ̀rẹ̀ pe: “Nitori ńṣe ni [eyiini ni, awọn àyíká tí wọn sopọ̀ mọ́ Ijọba naa] ó dabi ìgbà tí ọkunrin kan, tí ó maa tó rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀ fi àṣẹ pè awọn ẹrú rẹ̀ wá tí ó sì fi awọn ohun ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́ lati tọ́jú.” Jesu ni ọkunrin naa ẹni tí, ṣaaju kí ó tó rìnrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀ ni ọ́run, fi awọn ohun ìní rẹ̀ lé awọn ẹrú rẹ̀ lọwọ lati tọ́jú—awọn ọmọ-ẹhin tí wọn wà ní ìlà fun Ijọba ti ọrun. Awọn ohun ìní wọnyi kii ṣe awọn ìní ti ara, ṣugbọn wọn dúró fún pápá ríro kan ninu eyi tí oun ti gbin ṣiṣeeṣe lati dàgbàsókè sí fun mímú awọn ọmọ-ẹhin pupọ sí i jáde.

Jesu fi awọn ohun ìní rẹ̀ sikaawọ awọn ẹrú rẹ̀ kété ṣaaju ki o tó gòkè re ọ̀run. Bawo ni ó ṣe ṣe iyẹn? Nipa fífún wọn ní ìtọ́ni lati maa baa lọ ní ṣíṣiṣẹ́ ninu pápá ríro naa nipa wiwaasu ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa títí dé awọn apá ibi jíjìnnà julọ lórí ilẹ̀-ayé. Gẹgẹ bi Jesu ti wí: “Ó sì fun ọ̀kan ní talẹnti márùn-ún, òmíràn meji, òmíràn sibẹ ọ̀kan, fun olukuluku gẹgẹ bi agbára tirẹ̀, ó sì lọ sí ìdálẹ̀.”

Awọn talẹnti mẹjọ naa—awọn ohun ìní Kristi—ni a tipa bayii pín ni ibamu pẹlu agbára tabi awọn ṣíṣeéṣe nipa tẹ̀mí, ti awọn ẹrú naa. Awọn ẹrú naa dúró fún awọn ẹgbẹ́ awọn ọmọ-ẹhin. Ní ọ̀rúndún kìn-ínní, ẹgbẹ tí ó rí talẹnti márùn-ún naa gbà ní awọn apọsiteli nínú lọna tí ó hàn gbangba. Jesu nbaa lọ lati sọ pe awọn ẹrú naa tí wọn rí talẹnti márùn-ún ati meji gbà ni wọn sọ wọn di ìlọ́po meji nipa iwaasu wọn nipa Ijọba ati sísọni di ọmọ-ẹhin. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹrú naa tí ó rí talẹnti kan gbà fi i pamọ́ láṣìírí ninu ilẹ.

“Lẹhin àkókò gígùn kan,” ni Jesu nbaa lọ, “ọ̀gá awọn ẹrú wọnni dé ó sì ṣe ìṣirò pẹlu wọn.” Nigba tí ó di ọ̀rúndún ogún yii, nǹkan bii 1,900 ọdun lẹhin ìgbà naa, ni Kristi tó padà wá lati ṣe ìṣirò, bẹẹ ni ó rí, nitootọ, “lẹhin àkókò gígùn kan.” Lẹhin naa Jesu ṣàlàyé pe:

“Eyi tí ó ti gba talẹnti márùn-ún wá síwájú ó sì mú àfikún talẹnti márùn-ún wá, wipe, ‘Ọ̀gá, iwọ fi talẹnti márùn-ún lé mi lọ́wọ́ lati tọ́jú; wòó, mo jèrè talẹnti márùn-ún sí i.’ Ọ̀gá rẹ̀ sì wí fun un pe, ‘O ṣeun, ẹrú daradara ati olóòótọ́! Iwọ ṣe olóòótọ́ lórí awọn nǹkan diẹ. Emi yoo yàn ọ sípò lórí ọpọlọpọ nǹkan. Wọ inú ayọ̀ ọ̀gá rẹ.’” Ẹrú tí ó gba talẹnti meji bẹẹ gẹ́gẹ́ sọ talẹnti tirẹ̀ di ìlọ́po meji, oun sì rí ìyìn ati ẹ̀san kan naa gbà.

Ṣugbọn, bawo ni awọn ẹrú olùṣòtítọ́ wọnyi ṣe wọnú ayọ̀ Ọ̀gá wọn? Ó dára, ayọ̀ Ọ̀gá wọn, Jesu Kristi, jẹ́ ti rírí ìní Ijọba naa gbà nigba ti ó lọ sí ìdálẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Baba rẹ̀ ní ọ̀run. Niti awọn ẹrú olùṣòtítọ́ naa ní awọn àkókò òde-òní, wọn ní ayọ̀ ńláǹlà ti jíjẹ́ ẹni tí a fi awọn ẹrù-iṣẹ́ pupọ sí i ni isopọ pẹlu Ijọba naa sí ní ìkáwọ́, bí wọn sì ti ńparí ipa-ọ̀nà wọn lori ilẹ̀-ayé, wọn yoo ní ayọ̀ tí ó ti jíjẹ́ ẹni tí a jí dìde sí Ijọba ọ̀run naa. Ṣugbọn ki ni nipa ti ẹrú kẹta?

“Ọ̀gá, mo mọ̀ ọ ní ọkunrin kan tí ńfi ọ̀ranyàn gba nǹkan,” ni ẹrú yii ráhùn. “Nitori naa mo mo sì lọ fi talẹnti rẹ pamọ́ sínú ilẹ̀. Gba ohun tí ó jẹ́ tìrẹ nìyí.” Ẹrú naa mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ lati ṣiṣẹ́ ninu pápá ríro naa nipa wiwaasu ati sísọni di ọmọ-ẹhin. Nitori eyi ọ̀gá naa pé ẹrú yii ní “buruku ati sùẹ̀gbẹ̀” ó sì kéde ìdájọ́ naa: “Ẹ gba talẹnti naa kuro lọwọ rẹ̀ . . . Ẹ sì gbé ẹrú aláìdára fún ohunkohun naa sọ sóde ninu òkùnkùn lóde. Nibẹ ni ẹkún ati pípa ehín keke rẹ̀ yoo wà.” Awọn tí wọn jẹ́ ti ẹgbẹ́ ẹrú buburu yii, ti a gbá sọnu sóde, ni a fi ayọ̀ eyikeyii nipa tẹ̀mí dù.

Eyi gbé ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ti o ṣe pàtàkì kan kalẹ̀ fun gbogbo awọn wọnni tí wọn fẹnujẹ́wọ́ pe awọn jẹ́ ọmọlẹhin Kristi. Bí wọn yoo bá gbádùn ìgbóríyìn fúnni ati ẹ̀san rẹ̀, bí wọn yoo bá sí yẹra fún dídi ẹni tí a jù sínú òkùnkùn lóde ati ìparun ìkẹhìn, wọn gbọdọ maa ṣiṣẹ́ fun ìbísí awọn ohun ìní Ọ̀gá wọn ọ̀rún nipasẹ níní ìpín kíkún ninu iṣẹ́ wiwaasu. Iwọ ha jẹ́ aláápọn ní ọ̀nà yii bí?

Nigba Ti Kristi Dé Ninu Agbára Ijọba

Jesu ṣì wà pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀ lórí Òkè Olifi síbẹ̀. Ní ìdáhùn sí ibeere wọn fun àmì kan nipa wíwàníhìn-ín rẹ̀ ati òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan, oun nisinsinyi sọ eyi tí ó kẹhin fun wọn ninu ọ̀wọ́ awọn àkàwé mẹta. Jesu bẹrẹ nipa sisọ pe: “Nigba ti Ọmọkunrin eniyan bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli pẹlu rẹ̀, nigba naa ni yoo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.”

Awọn ènìyàn kò lè rí awọn angẹli ninu ògo wọn ti ọ̀run. Nitori naa dídé Ọmọkunrin eniyan naa, Jesu Kristi, pẹlu awọn angẹli gbọdọ jẹ́ aláìṣeérí fun ojú ènìyàn. Dídé naa ṣẹlẹ̀ ní ọdun 1914. Ṣugbọn fun ète wo ni? Jesu ṣàlàyé pe: “A ó sì kó gbogbo awọn orílẹ̀-èdè jọ sí iwaju rẹ̀, oun yoo sì ya awọn eniyan sọ́tọ̀ kuro ninu araawọn, gan-an gẹgẹ bi olùṣọ́ àgùtàn ti ńya àgùtàn sọ́tọ̀ kuro ninu ewúrẹ́. Oun yoo sì fi awọn àgùtàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì rẹ̀.”

Ní ṣíṣàpèjúwe ohun tí yoo ṣẹlẹ̀ sí awọn wọnni tí ó wà ní ìhà tí a ṣojúrere sí, Jesu wipe: “Nigba naa ni ọba yoo wí fun awọn wọnni tí wọn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ pe, ‘Ẹ wá, ẹyin tí Baba mi ti bùkún fun, ẹ jogún ijọba naa tí a ti pèsè sílẹ̀ dè yin lati ìgbà pípilẹ̀ ayé.’” Awọn àgùtàn inu akawe yii kì yoo ṣàkóso pẹlu Kristi ní ọ̀rún ṣugbọn wọn yoo jogún Ijọba naa ní ìtumọ̀ ti jíjẹ́ ọmọ-abẹ́ rẹ̀ ti ilẹ̀-ayé. “Ìgbà pípilẹ̀ ayé” ṣẹlẹ̀ nigba ti Adamu ati Efa kọ́kọ́ mú awọn ọmọ jáde tí wọn lè jàǹfààní lati inú ìpèsè Ọlọrun lati tún aráyé ràpadà.

Ṣugbọn eeṣe tí a fi ya awọn àgùtàn naa sọ́tọ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún ojúrere Ọba naa? “Nitori ebí pa mí,” ni èsì ọba naa wipe, “ẹyin sì fun mi ní nǹkan lati jẹ; oungbẹ gbẹ mí ẹyin sì fun mi ní nǹkan lati mu. Mo jẹ́ àjèjì ẹyin sì gbà mi pẹlu ẹ̀mí àlejò ṣíṣe; mo wà ní ìhòhò, ẹyin sì daṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn ẹyin sì bójútó mi. Mo wà ní ẹ̀wọ̀n ẹyin sì wá sọ́dọ̀ mi.”

Niwọn bi awọn àgùtàn naa ti wà lórí ilẹ̀-ayé, wọn fẹ́ lati mọ̀ bí wọn lè ṣe irúfẹ́ awọn iṣẹ́ rere bẹẹ fun Ọba wọn ọrun. “Oluwa, nigba wo ni awa rí ọ tí ebi ńpa ọ́ tí a sì bọ́ ọ,” ni wọn beere, “tabi tí oungbẹ ńgbẹ ọ́, tí a sì fun ọ ní nǹkan lati mu? Nigba wo ni awa rí ọ ní àjèjì tí a sì gbà ọ́ pẹlu ẹ̀mí àlejò ṣíṣe, tabi tí o wà ní ìhòhò, tí awa sì daṣọ bò ọ́? Nigba wo ni awa rí ọ tí o ṣàìsàn tabi wà ní ẹ̀wọ̀n tí awa sì lọ sọ́dọ̀ rẹ?”

“Lóòótọ́ ni mo wí fun yin,” ni Ọba naa fèsìpadà, “títí dé ìwọ̀n tí ẹ ṣe é fun ọ̀kan tí ó kéré jùlọ ninu awọn arakunrin mi wọnyi, ẹ ti ṣe é fun mi.” Awọn arakunrin Kristi jẹ́ awọn 144,000 tí wọn ṣẹ́kù lórí ilẹ̀-ayé tí wọn yoo ṣàkoso pẹlu rẹ̀ ni ọ̀run. Ati pe ṣíṣe dáradára sí wọn, ni Jesu wi, jẹ́ ọ̀kan naa gẹgẹ bi ṣíṣe daradara sí oun.

Tẹle eyi, Ọba naa darí ọ̀rọ̀ sí awọn ewúrẹ́. “Ẹ mú ọ̀nà yin pọ̀n kuro lọdọ mi, ẹyin tí a ti gégùn-ún fun, sínú iná ainipẹkun tí a ti pese sílẹ̀ fun Eṣu ati awọn angẹli rẹ̀. Nitori ebi pa mi, ṣugbọn ẹyin kò fun mi ní nǹkan lati jẹ, oungbẹ sì gbẹ mi, ṣugbọn ẹyin kò fun mi ní nǹkan lati mu. Mo jẹ́ àjèjì, ṣugbọn ẹyin kò gbà mi pẹlu ẹ̀mí àlejò ṣíṣe; mo wà ní ìhòhò, ṣugbọn ẹyin kò daṣọ bò mi; mo ṣàìsàn mo sì wà ninu ẹ̀wọ̀n, ṣugbọn ẹyin kò bojuto mi.”

Awọn ewurẹ naa, bí ó ti wù kí ó rí, ráhùn pe: “Oluwa, nigba wo ni awa rí ọ tí ebi ńpa ọ́ tabi tí oungbẹ ńgbẹ ọ tabi ní àjèjì tabi wà ní ìhòhò tabi ṣàìsàn tabi wà ninu ẹ̀wọ̀n tí awa kò sì ṣèránṣẹ́ fun ọ?” Awọn ewúrẹ́ naa gba ìdájọ́ aláìbáradé lórí ìpìlẹ̀ kan naa tí a fi dájọ́ tí ó báradé fun awọn àgùtàn naa. “Títí dé ìwọ̀n tí ẹ kò ṣé e fun ọ̀kan lára awọn tí wọn kéré jùlọ wọnyi [ti awọn arakunrin mi],” ni Jesu dáhùn, “ẹyin kò ṣe é fun mi.”

Nitori naa wíwàníhìn-ín Kristi ninu agbára Ijọba, kété ṣaaju òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan buruku yii ninu ipọnju nla, yoo jẹ́ àkókò ìdájọ́ kan. Awọn ewúrẹ́ “yoo lọ kúrò sínú ìkékúrò ainipẹkun, ṣugbọn awọn olódodo [awọn àgùtàn] sínú iye ainipẹkun.” Matiu 24:2–25:46, NW; 13:40, 49; Maaku 13:3-37; Luuku 21:7-36, NW; Lk 19:43, 44, NW; Lk 17:20-30, NW; 2 Timoti 3:1-5; Johanu 10:16; Iṣipaya 14:1-3.

Ki ni ta ibeere awọn apọsiteli naa jí, ṣugbọn bi ó ti hàn gbangba ohun miiran wo ni wọn ní lọ́kàn?

▪ Apa wo ninu asọtẹlẹ Jesu ni ó ni ìmúṣẹ ní 70 C.E., ṣugbọn ki ni kò wáyé nigba naa?

▪ Nigba wo ni asọtẹlẹ Jesu ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́, ṣugbọn nigba wo ni ó ní ìmúṣẹ titobi?

▪ Ki ni ohun ìsúni fún ìríra naa ninu ìmúṣẹ rẹ àkọ́kọ́ ati ti ìkẹhìn?

▪ Eeṣe tí ipọnju ńlá naa kò fi ní ìmúṣẹ rẹ̀ tí ó kẹ́hìn nigba ìparun Jerusalẹmu?

▪ Awọn ipò wo ninu ayé ni wọn sàmì sí wíwàníhìn-ín Kristi?

▪ Nigba wo ni ‘gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀-ayé yoo lu araawọn ninu ìdárò,’ ṣugbọn ki ni awọn ọmọlẹhin Kristi yoo maa ṣe?

▪ Àkàwé wo ni Jesu pèsè lati ran awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ọjọ́ ọ̀la lọ́wọ́ lati mọ̀ ìgba tí opin naa bá súnmọ́lé?

▪ Ìṣínilétí wo ni Jesu pèsè fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọnni tí wọn yoo walaaye ní awọn ọjọ́ ikẹhin?

▪ Ta ni awọn wundia mẹ́wàá naa ṣàpẹẹrẹ?

▪ Nigba wo ni a ṣe ìlérí ijọ Kristẹni ní ìgbéyàwó fun ọkọ ìyàwó, ṣugbọn nigba wo ni ọkọ iyawo dé lati mú ìyàwó rẹ̀ lọ sí àsè ìgbéyàwó?

▪ Ki ni òróró naa dúró fún, kí sì ni níní in lọwọ mú awọn wundia ọlọ́gbọ́n naa tóótun lati ṣe?

▪ Nibo ni àsè ìgbéyàwó naa ti ṣẹlẹ̀?

▪ Ẹ̀san títóbilọ́lá wo ni awọn wundia naa pàdánù rẹ̀, kí sì ni òpin wọn?

▪ Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni àkàwé nipa talẹnti fikọ́ni?

▪ Ta ni awọn ẹrú naa jẹ́, kí sì ni awọn ohun ìní naa tí a fi sí ìkáwọ́ wọn?

▪ Nigba wo ni ọ̀gá naa dé lati ṣè ìṣirò, ki ni ohun tí oun sì rí?

▪ Ki ni ayọ̀ naa tí ẹrú olùṣòtítọ́ naa wọ inú rẹ̀, ki ni ó sì ṣẹlẹ̀ sí ẹrú burukú naa?

▪ Eeṣe tí wíwàníhìn-ín Kristi fi gbọdọ jẹ́ aláìṣeérí, iṣẹ́ wo ni oun sì ṣe ní àkókò yẹn?

▪ Ní ìtumọ̀ wo ni awọn àgùtàn fi jogún Ijọba naa?

▪ Nigba wo ni “ìgbà pípilẹ̀ ayé” ṣẹlẹ̀?

▪ Ki ni ìpìlẹ̀ ti a fi dájọ́ awọn eniyan yálà gẹgẹ bi àgùtàn tabi gẹgẹ bi ewúrẹ́?