Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àríyànjiyàn Lori Ipò Jijẹ Baba

Àríyànjiyàn Lori Ipò Jijẹ Baba

Orí 69

Àríyànjiyàn Lori Ipò Jijẹ Baba

NÍ ÀKÓKÒ àjọ-àríyá, ìjíròrò Jesu pẹlu awọn aṣaaju Juu tubọ gbónájanjan sii. “Mo mọ̀ pe ọmọ-inú Aburahamu ni yin,” ni Jesu mọ̀jẹ́wọ́, “ṣugbọn ẹyin ńwá ọ̀nà lati pa mi, nitori pe ọ̀rọ̀ mi kò ní itẹsiwaju láàárín yin. Awọn ohun tí mo ti rí lọ́dọ̀ Baba mi ni mo ńsọ; ẹyin, nitori naa, sì ńṣe awọn ohun tí ẹ ti gbọ́ lati ọ̀dọ̀ baba yin.”

Bí ó tilẹ jẹ́ pe kò fi baba wọn hàn, Jesu mú un ṣe kedere pe baba wọn yàtọ̀ sí tirẹ̀. Bi wọn kò ti mọ ẹni tí Jesu ní lọ́kàn, awọn aṣaaju Juu dáhùn pe: “Aburahamu ni baba wa.” Wọn nímọ̀lára pe wọn ní ìgbàgbọ́ kan naa bii ti Aburahamu, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọrun.

Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu mú wọn gbọ̀nrìrì pẹlu èsì naa pe: “Bí ẹ bá jẹ́ ọmọ Aburahamu, ẹ ṣe awọn iṣẹ́ Aburahamu.” Nitootọ, ọmọ gidi kan ńṣàfarawé baba rẹ̀. “Ṣugbọn nisinsinyi ẹyin ńwá ọ̀nà lati pa mi,” ni Jesu wí, “ọkunrin kan tí ó ti sọ otitọ tí mo ti gbọ́ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun fun yin. Aburahamu kò ṣe eyi.” Nitori naa lẹẹkan sí i Jesu wipe: “Ẹyin ńṣe awọn iṣẹ́ baba yin.”

Sibẹsibẹ wọn kò tíì finúmòye ẹni tí Jesu ńsọ̀rọ̀ nipa rẹ̀. Wọn rinkinkin mọ́ ọn pe awọn jẹ́ ọmọkunrin Aburahamu lọna òfin ní wiwi pe: “A kò fi àgbèrè bí wa.” Nitori naa, ní jíjẹ́wọ́ pe wọn jẹ́ olùjọsìn tootọ bíi Aburahamu, wọn tẹnumọ́ ọn pe: “Awa ní Baba kan, Ọlọrun.”

Ṣugbọn Ọlọrun ha jẹ́ Baba wọn nitootọ bí? “Bí ó bá jẹ́ pe Ọlọrun ni Baba yin,” ni Jesu dáhùnpadà, “ẹyin ìbá nífẹ̀ẹ́ mi, nitori lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti jáde wá mo sì wà níhìn-ín. Bẹẹni emi kò wá nipa àtinúdá ti araami rárá, ṣugbọn Ẹni yẹn ni ó rán mi wá. Eeṣe tí ẹyin kò fi mọ ohun tí emi ńsọ?”

Jesu ti gbìyànjú lati fihàn awọn aṣaaju isin wọnyi ohun tí ó jẹ́ awọn àbájáde fun ṣíṣá a tì. Ṣugbọn nisinsinyi ó sọ̀rọ̀ lọna tí ó ṣe tààràtà pe: “Lati ọ̀dọ̀ Eṣu baba yin ni ẹ ti wá, ìfẹ́-ọkàn ti baba yin ni ẹ sì ńfẹ́ ṣe.” Irú baba wo ni Eṣu jẹ́? Jesu dá a fihan gẹgẹ bi apànìyàn ó sì tún wipe: “Òpùrọ́ ni oun ati baba irọ́.” Nitori naa Jesu pari ọrọ rẹ̀ pe: “Ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá nfetisilẹ sí awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìdí niyii tí ẹ kò fi fetisilẹ, nitori ẹyin kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá.”

Bí inu ti bi wọn nipasẹ ìdálẹ́bi tí Jesu ṣe, awọn Juu dáhùn pe: “Awa kò ha wí lọna ẹ̀tọ́ pe iwọ jẹ́ ara Samaria ati pe o ní ẹ̀mí-èṣù?” Ọ̀rọ̀-èdè naa “ara Samaria” ni a ńlò gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ ìyọṣùtìsí ati ti ìpẹ̀gàn kan, nitori awọn ara Samaria jẹ́ awọn eniyan kan tí awọn Juu kórìíra.

Láìfiyèsí ọrọ arifin ti wọn mẹnuba fẹ́ẹ́rẹ́ nipa jíjẹ́ ara Samaria, Jesu dáhùnpadà pe: “Emi kò ní ẹ̀mí-èṣù, ṣugbọn emi ńbọlá fún Baba mi, ẹyin sì ńtàbùkù sí mi.” Ní bíbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, Jesu ṣe ìlérí amúnitagìrì naa pe: “Bí ẹnikẹni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ, oun kì yoo rí ikú rárá láé.” Dajudaju, Jesu kò ní in lọ́kàn pe gbogbo awọn wọnni tí ntẹle e kì yoo rí ikú láé niti tootọ gan-an. Kàkà bẹẹ, oun ní lọ́kàn pe wọn kì yoo rí ìparun ayérayé láé, tabi “ikú keji,” lati inú eyi tí kò sí ajinde.

Bí ó ti wù kí ó rí, awọn Juu mú awọn ọ̀rọ̀ Jesu lóréfèé. Nitori naa, wọn wipe: “Nisinsinyi ni awa mọ̀ pe iwọ ní ẹ̀mí-èṣù. Aburahamu kú, bakan naa ni awọn wolii; ṣugbọn iwọ wipe, ‘Bí ẹnikẹni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ oun kì yoo tọ́ ikú wò rárá láé.’ Iwọ kò tóbijù Aburahamu baba wa, tí ó ti kú, iwọ ha tóbijù ú bí? Pẹlupẹlu, awọn wolii kú. Ta ni iwọ ńfi araàrẹ pè?”

Ninu gbogbo ìjíròrò yii, ó hàn gbangba pe Jesu tọ́ka awọn eniyan wọnyi sí otitọ naa pe oun jẹ́ Mesaya tí a ṣèlérí naa. Ṣugbọn dípò dídáhùn ibeere wọn ní tààràtà niti ẹni tí oun jẹ́, Jesu wipe: “Bí emi bá yin araami lógo, ògo mi kò jẹ́ ohunkohun. Baba mi ní ńṣe mi lógo, ẹni tí ẹ wipe oun ni Ọlọrun yin; sibẹ ẹyin kò sì tíì mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn emi mọ̀ ọ́n. Bí emi bá sì wipe emi kò mọ̀ ọ́n, emi ìbá dabi ẹyin, òpùrọ́.”

Ní bíbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, Jesu lẹẹkan sí i tọ́kasí Aburahamu olùṣòtítọ́, ní wiwi pe: “Aburahamu baba yin yọ gidigidi ninu ìfojúsọ́nà lati rí ọjọ́ mi, ó rí i ó sì yọ.” Bẹẹni, pẹlu awọn ojú ìríran ìgbàgbọ́, Aburahamu fojúsọ́nà fun dídé Mesaya tí a ti ṣèlérí. Ninu àìgbàgbọ́, awọn Juu dáhùnpadà pe: “Iwọ kò tíì dàgbà tó aadọta ọdun sibẹ, sibẹsibẹ iwọ sì ti rí Aburahamu?”

“Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fun yin,” ni Jesu dáhùnpadà, “ṣaaju kí Aburahamu tó wà, emi ti wà.” Jesu, nitootọ, ńtọ́kasí iwalaaye rẹ̀ gẹgẹ bi ẹni ẹ̀mí alágbára ńlá kan ní ọ̀run ṣaaju kí ó tó di ẹ̀dá-ènìyàn.

Bí ìrunú ti bò wọn nipasẹ ìjẹ́wọ́sọ Jesu pe oun ti wà ṣaaju Aburahamu, awọn Juu mú òkúta lati sọ lù ú. Ṣugbọn ó farapamọ́ ó sì jáde kuro ninu tẹmpili láìní ìpalára kankan. Johanu 8:37-59, NW; Iṣipaya 3:14; 21:8.

▪ Bawo ni Jesu ṣe fihàn pe oun ati awọn ọ̀tá rẹ̀ ní awọn baba tí ó yàtọ̀?

▪ Ki ni ìjámọ́pàtàkì bí awọn Juu ti pe Jesu ní ara Samaria?

▪ Èrò ìtumọ̀ wo ni Jesu nílọ́kàn nigba ti o sọ pe awọn ọmọlẹhin rẹ̀ kì yoo rí ikú láé?