Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àríyànjiyàn Lori Ogún

Àríyànjiyàn Lori Ogún

Orí 77

Àríyànjiyàn Lori Ogún

AWỌN eniyan naa ní kedere mọ̀ pe Jesu ti ńjẹ oúnjẹ ni ilé Farisi naa. Nitori naa wọn péjọpọ̀ lóde ní ẹgbẹẹgbẹrun tí wọn sì ńdúró de ìgbà tí Jesu yoo jáde. Láìdàbí awọn Farisi tí wọn takò Jesu tí wọn sì gbìyànjú lati gbá a mú ní sísọ ohun kan tí kò tọ̀nà, awọn eniyan naa fi ìháragàgà fetisilẹ sí i pẹlu ìmọrírì.

Ní yíyíjú lákọ̀ọ́kọ́ sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu wipe: “Ẹ ṣọ́ra fun ìwúkàrà awọn Farisi, eyi tí ó jẹ́ àgàbàgebè.” Gẹgẹ bi o ti hàn lakooko ounjẹ naa, gbogbo ètò-ìgbékalẹ̀ isin awọn Farisi ni ó kún fun àgàbàgebè. Ṣugbọn bí ìwà burúkú awọn Farisi tilẹ farapamọ níkọ̀kọ̀ nipasẹ ìfihàn ẹ̀mí-ìsìn kan, asẹhinwa asẹhinbọ a o tú u fó. “Kò sí ohunkohun tí a rọra pamọ́,” ni Jesu wí, “tí a kò ní ṣípayá, ati ti ìkọ̀kọ̀ tí kì yoo di mímọ̀.”

Jesu nbaa lọ lati ṣe àtúnsọ ìṣírí naa tí oun ti fifún awọn 12 nigba ti ó rán wọn jáde lọ lórí ìrìn-àjò iwaasu kan sí Galili. Oun wipe: “Ẹ maṣe bẹ̀rù awọn wọnni tí wọn ńpa ara ati lẹhin eyi wọn kò tún lè ṣe ohunkohun mọ́.” Niwọn bi Ọlọrun kò ti gbàgbé kódà ológoṣẹ kanṣoṣo, Jesu mú un dá awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lójú pe Ọlọrun kì yoo gbàgbé wọn. Oun wipe: “Nigba ti wọn bá mú yin wá sí iwájú apejọ eniyan ati awọn ìjòyè ijọba ati awọn aláṣẹ, . . . ẹ̀mí mímọ́ yoo kọ́ yin lẹ́kọ̀ọ́ ní wakati naa gan-an awọn ohun tí ẹ gbọdọ wí.”

Ọkunrin kan lati inú ogunlọgọ naa sọ̀rọ̀ jáde. “Olùkọ́,” ni oun bẹ̀bẹ̀, “sọ fun arakunrin mi lati pín ogún fun mi.” Òfin Mose filélẹ̀ pe ọmọkunrin àkọ́bí yoo gba ipa meji ogún, nitori naa kò yẹ kí ìdí kankan wà fun aáwọ̀ kan. Ṣugbọn ọkunrin naa ní kedere ńfẹ́ pupọ sii ju ìpín tirẹ̀ ninu ogún naa lọna òfin.

Jesu lọna tí ó tọ̀nà kọ̀ lati kówọnú ọ̀ràn naa. “Ọkunrin, ta ni yàn mi sípò onídàájọ́ tabi ojúwà lórí ẹyin eniyan?” ni oun beere. Lẹhin naa oun fun ogunlọgọ naa ní ìṣílétí ṣíṣepàtàkì yii pe: “Ẹ maa ṣọ́ra gidigidi kí ẹ sì ṣọ́ra fun onírúurú ojúkòkòrò, nitori nigba ti ẹnikan bá ní ọpọlọpọ pàápàá igbesi-aye rẹ̀ kò sinmi lórí awọn ohun tí ó ní ní ìní.” Bẹẹni, láìka bí ohun tí ẹnikan lè ní ti pọ̀ tó sí, lọna ti ẹ̀dá oun yoo kú tí yoo sì fi gbogbo rẹ̀ silẹ sẹ́hìn. Lati tẹnumọ́ òtítọ́ yii, ati pẹlu lati fi ìwà ẹgọ̀ ti kíkùnà lati gbé orukọ rere kan pẹlu Ọlọrun ró han, Jesu lò àkàwé kan. Oun ṣàlàyé pe:

“Ilẹ̀ ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan bayii so daradara. Nitori naa ó bẹrẹsii ronú araarẹ̀, wipe, ‘Ki ni emi yoo ṣe, nisinsinyi tí emi kò ní ibi kankan lati kó awọn èso oko mi jọ sí?’ Nitori naa ó wipe, ‘Emi yoo ṣe eyi: emi yoo wó àká mi palẹ̀, emi yoo sì kọ́ awọn títóbijù, nibẹ ni emi yoo sì kó gbogbo èso mi jọ sí ati awọn ohun daradara mi gbogbo; emi yoo sì wí fun ọkàn mi pe: “Ọkàn, iwọ ní awọn ohun daradara pupọ tí a tòjọ fun ọ̀pọ̀ ọdun; farabalẹ̀, maa jẹ, maa mu, maa gbádùn araàrẹ.”’ Ṣugbọn Ọlọrun wí fun un pe, ‘Aláìlọ́gbọ́n-nínú, ní òru yii wọn yoo fi dandangbọ̀n béèrè ọkàn rẹ lọwọ rẹ. Nigba naa, ta ni yoo ni awọn ohun tí iwọ ti kójọ?’”

Ní ipari, Jesu ṣàlàyé pe: “Bẹẹ ni ó rí fun ọkunrin naa tí ó to ìṣura jọ fun araarẹ̀ ṣugbọn tí kò lọ́rọ̀ lọdọ Ọlọrun.” Nigba tí ó jẹ́ pe awọn ọmọ-ẹhin naa ni ìwà ẹgọ̀ títo ọrọ̀ jọ pelemọ lè má dẹkùn mú, a lè fi ìrọ̀rùn pín ọkàn wọn níyà kuro ninu ṣíṣisẹ́sìn Jehofa nitori awọn àbójútó ojoojumọ ti igbesi-aye. Nitori naa Jesu lo àkókò naa lati tún ìmọ̀ràn rere naa sọ tí oun ti fifún wọn ní nǹkan bii ọdun kan ati aabọ ṣaaju ninu Iwaasu orí Òkè. Ní yíyíjúsí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, oun wipe:

“Nititori eyi mo wi fun yin, Ẹ jáwọ́ ninu ṣíṣàníyàn nipa ọkàn yin nipa ohun tí ẹ o jẹ tabi nipa araayin nipa ohun tí ẹyin yoo wọ̀. . . . Ṣàkíyèsí daradara pe awọn ẹyẹ ìwó kìí gbin irúgbìn bẹẹ ni wọn kìí kórè, bẹẹ ni wọn kò sì ni abà tabi àká, sibẹ Ọlọrun sì ńbọ́ wọn. . . . Ṣàkíyèsí daradara bí awọn òdòdó lili ti ńdàgbà; wọn kìí ṣe làálàá bẹẹ ni wọn kìí rànwú; ṣugbọn mo sọ fun yin, Solomoni pàápàá ninu gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ gẹgẹ bi ọ̀kan ninu awọn wọnyi. . . .

“Nitori naa ẹ jáwọ́ ninu wíwá ohun tí ẹ lè jẹ ati ohun tí ẹ lè mu kiri, kí ẹ sì jáwọ́ ninu wíwà ninu àníyàn oníyèméjì; nitori gbogbo iwọnyi ni nǹkan tí awọn orílẹ̀-èdè ayé nfi ìháragàgà lépa, ṣugbọn Baba yin mọ̀ pe ẹ nílò nǹkan wọnyi. Bí ó tilẹ rí bẹẹ, ẹ maa wá ijọba rẹ̀ kiri nigbagbogbo, nǹkan wọnyi ni a o sì fi kún un fun yin.”

Pàápàá ní pàtàkì láàárín awọn àkókò ìnira ọrọ̀-ajé ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu yẹ fun ayẹwo kínníkínní. Ẹni naa tí ó bá di ẹni tí ó ṣàníyàn jù nipa awọn àìní ohun ti araarẹ̀ tí ó sì bẹrẹsii dẹwọ́sílẹ̀ kuro ninu awọn ìlépa tẹ̀mí, niti tootọ, ńṣàṣefihàn àìní ìgbàgbọ́ ninu agbára Ọlọrun lati pèsè fun awọn iranṣẹ Rẹ̀. Luuku 12:1-31, NW; Deutaronomi 21:17.

▪ Eeṣe, boya, tí ọkunrin naa fi beere nipa ogún, ìṣílétí wo ni Jesu sì fifúnni?

▪ Àkàwé wo ni Jesu lò, kí sì ni kókó rẹ̀?

▪ Ìmọ̀ràn wo ni Jesu ṣe àtúnsọ rẹ̀, eeṣe tí ó sì fi bamuwẹ́kú fun àkókò yii?