Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsálà Kuro Lọwọ Òǹrorò Kan

Àsálà Kuro Lọwọ Òǹrorò Kan

Orí 8

Àsálà Kuro Lọwọ Òǹrorò Kan

JOSẸFU ji Maria lati sọ awọn irohin kanjukanju fun un. Angẹli Jehofa ṣẹ̀ṣẹ̀ farahan an ni sisọ pe: “Dide gbé ọmọ-ọwọ́ naa pẹlu iya rẹ̀, ki o sì salọ si Íjíbítì, ki iwọ kí ó sì gbé ibẹ titi emi yoo fi sọ fun ọ; nitori Hẹrọdu yoo wá ọmọ-ọwọ́ naa lati pa a.”

Awọn mẹtẹẹta sì sá àsálà ni kiakia. O sì ṣe kongẹ akoko nitori pe Hẹrọdu ti mọ̀ pe awọn aworawọ naa ti lò wàyó fun oun wọn sì ti fi orilẹ-ede naa silẹ. Ranti pe, oun nreti pe ki wọn mu irohin pada wa ba oun nigba ti wọn bá rí Jesu. Hẹrọdu kún fun ehonu. Nitori naa ninu igbidanwo lati pa Jesu, o pàṣẹ pe ki a pa gbogbo awọn ọmọkunrin ni Bẹtilẹhẹmu ati ní agbegbe rẹ̀ tí ọjọ ori wọn bẹ̀rẹ̀ lati ọdun meji silẹ. O gbé iṣiro yii lé ori isọfunni ti o rí gbà ṣaaju lati ọwọ́ awọn aworawọ naa tí wọn wa lati Ila-oorun.

Ìfipápa gbogbo awọn ọmọkunrin ọmọ-ọwọ́ naa jẹ ohun ti o banilẹru lati rí! Awọn ọmọ ogun Hẹrọdu njawọ ile kan tẹle omiran. Nigba ti wọn bá sì rí ọmọkunrin ọmọ-ọwọ́ kan, wọn yoo já a gbà kuro ní apa iya rẹ̀. Awa kò mọ ní pato bi iye awọn ọmọ-ọwọ́ ti wọn pa ti pọ̀ tó, ṣugbọn ẹkún ati ìpohùnréré ẹkun gigalọla awọn iya naa mú asọtẹlẹ inu Bibeli kan lati ọwọ́ Jeremaya wolii Ọlọrun ṣẹ.

Laaarin akoko naa, Josẹfu ati idile rẹ̀ ti dé Íjíbítì laisewu, wọn sì ńgbé nibẹ nisinsinyi. Ṣugbọn ní òru ọjọ́ kan angẹli Jehofa tún farahan Josẹfu ni oju àlá. “Dide, mú ọmọ-ọwọ́ naa, ati iya rẹ̀,” ni angẹli naa wi, “ki o sì lọ sí ilẹ̀ Isirẹli, nitori awọn ti nwa ẹmi ọmọ-ọwọ́ naa lati pa ti kú.” Nitori naa ni imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli miiran ti o sọ pe Ọmọkunrin Ọlọrun ni a o pè jade lati Íjíbítì wá, idile naa pada si ilẹ ibilẹ wọn.

O han kedere pe Josẹfu fẹ lati tẹ̀dó sí Judia, nibi ti wọn ngbe ni ilẹ Bẹtilẹhẹmu kí wọn to salọ si Íjíbítì. Ṣugbọn o gbọ́ pe ọmọkunrin buburu ti Hẹrọdu ti a npe ni Akilaọsi ni ọba Judia nisinsinyi, ati ninu àlá miiran Jehofa ti kilọ fun un nipa ewu naa. Nitori naa Josẹfu ati idile rẹ̀ rin irin ajo lọ siha ariwa wọn sì tẹ̀dó sí ilu Nasarẹti ni Galili. Nihin-in laaarin awọn eniyan yii, jinna sí aarin gbungbun igbesi-aye awọn onisin Juu ni Jesu ti dàgbà. Matiu 2:13-23; Jeremaya 31:15; Hosea 11:1.

▪ Nigba ti awọn aworawọ naa kò pada wá, ki ni ohun bibanilẹru ti Ọba Hẹrọdu ṣe, ṣugbọn bawo ni a ṣe daabobo Jesu?

▪ Nigba ti wọn pada lati Íjíbítì, eeṣe ti Josẹfu kò fi duro ni Bẹtilẹhẹmu mọ́?

▪ Awọn asọtẹlẹ Bibeli wo ni o ni imuṣẹ ni saa akoko yii?