Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsè Alẹ́ Ìṣe-ìrántí

Àsè Alẹ́ Ìṣe-ìrántí

Orí 114

Àsè Alẹ́ Ìṣe-ìrántí

LẸHIN tí Jesu wẹ̀ ẹsẹ̀ awọn apọsiteli rẹ̀, ó fa ọ̀rọ̀ iwe mimọ tí ó wà ní Saamu 41:9 yọ, ní wiwi pe: “Ẹni tí ó ti maa ńjẹ ounjẹ mi tẹ́lẹ̀rí ti gbé gìgìísẹ̀ rẹ̀ soke lodisi mi.” Lẹhin naa, bí ìdààmú ti bá ẹ̀mí rẹ̀, ó ṣalaye pe: “Ọ̀kan ninu yin yoo da mí.”

Awọn apọsiteli naa bẹ̀rẹ̀ sí i ní ẹ̀dùn ọkàn wọn sì ńsọ fun Jesu ọkan tẹle omiran pe: “Kìí ṣe emi, àbí emi ni bi?” Koda Judasi Isikariọtu darapọ ninu bibeere bẹẹ. Johanu, ẹni tí ó wà nílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jesu nibi tabili, fẹhinti Jesu ó sì beere pe: “Oluwa, ta ni?”

“Ọ̀kan ninu awọn mejila naa ni, ẹni tí ńtọwọ́bọ̀ inu àwo pẹlu mi,” ni Jesu dahun. “Loootọ, Ọmọkunrin eniyan ńlọ, gan-an gẹgẹ bi a ti kọwe nipa rẹ̀, ṣugbọn ègbé ní fun ọkunrin yẹn nipasẹ ẹni tí a dà Ọmọkunrin eniyan! Ìbá ti ṣe rere ju fun ọkunrin yẹn bí a kò bá ti bí i.” Lẹhin iyẹn, Satani tún wọ inú Judasi lẹkan sii, ní lílò ibi tí ó ṣisilẹ ninu ọkàn-àyà, rẹ̀ tí o ti di buburu lọna àìtọ́ fun èrè. Nigba ti ó ṣe ni òru yẹn, lọna yíyẹ ni Jesu pe Judasi ní “ọmọkunrin ìparun.”

Jesu nisinsinyi sọ fun Judasi pe: “Ohun tí iwọ ńṣe tubọ yára ṣe e kíákíá.” Kò sí eyikeyii ninu awọn apọsiteli yooku tí ó loye ohun tí Jesu ní lọ́kàn. Awọn kan ronú pe niwọn bi àpótí owó ti wà lọwọ Judasi, Jesu ńsọ fun un pe: “Ra awọn nǹkan tí a nílò fun àjọ-àríyá naa,” tabi pe kí oun lọ fi nǹkan fun awọn òtòṣì.

Lẹhin tí Judasi ti lọ́ kuro, Jesu mú àṣeyẹ, tabi ìṣè-ìrántí kan wọlé dé tí ó jẹ́ titun patapata, pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀ olùṣòtítọ́. Ó mú ìṣù kan, ó gbà adura ìdúpẹ́, ó bù ú, o fi i fun wọn, ni wiwi pe: “Ẹ gbà, ẹ jẹ́.” Ó ṣalaye pe: “Eyi tumọsi ará mi tí a ó fi funni nítori yin. Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.”

Nigba ti olukuluku ti jẹ́ burẹdi naa, Jesu mú ife ọti waini kan, dajudaju ife kẹrin tí a lò ninu iṣẹ́-ìsìn Ìrékọjá. Pẹlupẹlu oun gbà adura ọpẹ́ sori rẹ̀, ó gbé e fun wọn, o sọ fun wọn pe kí wọn mu lati inú rẹ̀, ó sì wipe: “Ife yii tumọsi májẹ̀mú titun nipa agbára ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ó tú jáde nitori yin.”

Nitori naa eyi, niti tootọ, jẹ́ ìṣe-ìrántí ikú Jesu. Ní ọdọọdun ní Nisan 14 ni a ó maa ṣe àtúnṣe rẹ̀, gẹgẹ bi Jesu ti sọ, ní ìrántí rẹ̀. Yoo pè padà sinu iyè ìrántí awọn olùṣàṣeyẹ naa ohun tí Jesu ati Baba rẹ̀ ọ̀run ti ṣe lati pèsè àsálà fun ìran aráyé kuro ninu ìdálẹ́bi ikú. Fun awọn Juu tí wọn di ọmọlẹhin Kristi, ìṣàṣeyẹ naa yoo rọ́pò Ìrékọjá.

Májẹ̀mú titun naa, eyi tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nipasẹ ẹ̀jẹ́ Jesu tí a tasílẹ̀, rọ́pò májẹ̀mú Òfin ti láéláé. A ṣalárinà rẹ̀ nipasẹ Jesu Kristi laaarin awọn olùlọ́wọ́sí meji—ní ọwọ́ kan Jehofa Ọlọrun, ní ọwọ́ keji, 144,000 awọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí. Yàtọ̀ sí pípèsè fun idariji awọn ẹ̀ṣẹ̀, májẹ̀mú naa yọnda fun ìdásílẹ̀ orilẹ-ede awọn ọba-oun-alufaa kan ti ọ̀run. Matiu 26:21-29; Maaku 14:18-25; Luuku 22:19-23; Johanu 13:18-30; 17:12; 1 Kọrinti 5:7.

▪ Asọtẹlẹ Bibeli wo ni Jesu fayọ nipa alábàákẹ́gbẹ́ kan, ìfisílo wo ni oun sì ṣe nipa rẹ̀?

▪ Eeṣe tí awọn apọsiteli naa fi ní ẹ̀dùn ọkàn jíjinlẹ̀, kí sì ní ohun tí olukuluku wọn beere?

▪ Ki ni Jesu sọ fun Judasi lati ṣe, ṣugbọn bawo ni awọn apọsiteli yooku ṣe tumọ awọn itọni wọnyi?

▪ Àṣeyẹ wo ni Jesu mú wọlé lẹhin tí Judasi ti lọ kuro, ète wo ni ó sì ṣiṣẹ fun?

▪ Awọn wo ni olùlọ́wọ́sí májẹ̀mú titun naa, ki ni májẹ̀mú naa si ṣàṣeparí rẹ̀?