Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Kan Nipa Àánú

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Kan Nipa Àánú

Orí 40

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Kan Nipa Àánú

JESU ṣì lè wà ní Naini sibẹ, níbi tí ó ti jí ọmọkunrin opó kan dìde láìpẹ́, tabi boya kí ó maa ṣe ìbẹ̀wò sí ìlú kan nítòsí. Farisi kan tí ó njẹ Simoni fẹ́ lati mọ siwaju sii nipa ẹni tí ó ńṣe irú awọn iṣẹ́ tí ó pẹtẹrí bayii. Nitori naa ó késí Jesu lati wá jẹun pẹlu rẹ̀.

Ní wíwò àkókò naa gẹgẹ bi àǹfààní kan lati ṣèránṣẹ́ fun awọn tí ó wà níbẹ̀, Jesu tẹ́wọ́gbà ìkésíni naa, àní gẹgẹ bi oun ti tẹ́wọ́gbà ìkésíni lati wá jẹun pẹlu awọn agbowó-ori ati awọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Sibẹ, nigba ti ó wọ ilé Simoni, Jesu kò rí àfíyèsí ọlọ́yàyà tí a saba maa ńfifún awọn àlejò gbà.

Awọn ẹsẹ̀ ti a wọ sálúbàtà sí maa ńdi eyi tí ó gbóná tí ó sì dọ̀tí nitori rírìn ní awọn ojú ọ̀nà eléruku, tí ó mú un ki ó jẹ́ àṣà ifẹ àlejò ṣíṣe kan lati wẹ ẹsẹ̀ awọn àlejò pẹlu omi tútù. Ṣugbọn wọn kò wẹ ẹsẹ̀ Jesu nigba ti ó dé. Bẹẹ ni oun kò sì rí ìfẹnukonu ìkínikáàbọ̀ gbà, eyi tí ó jẹ́ ìwà ọmọlúwàbí tí ó wọ́pọ̀. Òróró àlejò ṣíṣe tí ó jẹ́ àṣà ni a kò sì pèsè fun irun rẹ̀.

Nigba tí ounjẹ jijẹ naa ńlọ lọwọ, tí awọn àlejò naa sì ti rọ̀gbọ̀kú nídìí tabili, obinrin kan tí a kò késí yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wọ inú iyàrá naa. A mọ̀ ọ́n ní ìlú naa sí ẹni tí ńgbé igbesi-aye oníwà pálapàla. Ó ṣeeṣe kí o ti gbọ́ awọn ẹ̀kọ́ Jesu, títíkan ìkésíni rẹ̀ sí ‘gbogbo awọn ẹni tí a di ẹrù wíwúwo lélórí lati wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ fun ìtura.’ Niwọn bi a sì ti gún un ní kẹ́ṣẹ́ gidigidi nipasẹ ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́, oun nisinsinyi ti wá Jesu láwàárí.

Obinrin naa gba ẹ̀hìn Jesu yọ nídìí tabili naa tí ó sì kúnlẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀. Bí omijé rẹ̀ tí ńkán sí ẹsẹ̀ Jesu, ó ńfi irun rẹ̀ nù ún kuro. Ó tún mú òróró olóòórùn pẹlu lati inú ṣágo rẹ̀, bí ó sì ti fi jẹ̀lẹ́ńkẹ́ fi ẹnu ko awọn ẹsẹ̀ Jesu, ó da òróró naa sí wọn. Simoni ńwò ó lọna ti ko ṣe ìtẹ́wọ́gbà. “Ọkunrin yii, bí ó bá jẹ́ wolii,” ni oun ronú, “yoo mọ ẹni ati irú obinrin tí ó jẹ́ tí ó ńfọwọ́ kàn án, pe ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”

Ní mímọ̀ ìrònú rẹ̀, Jesu wipe: “Simoni, mo ní ohun kan lati wí fun ọ.”

“Olùkọ́, sọ ọ!” ni ó dáhùnpadà.

“Awọn ọkunrin meji kan jẹ́ ajigbèsè fun awínni kan bayii,” ni Jesu bẹ̀rẹ̀. “Ọ̀kan jẹ gbèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó dinari, ṣugbọn eyi ekeji jẹ aadọta. Nigba ti wọn kò ní ohunkohun lati fi san án padà, ó dáríjì awọn mejeeji lọ́fẹ̀ẹ́. Nitori naa, ewo ninu wọn ni yoo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jù?”

“Mo tànmọ́ọ̀ pe,” ni Simoni wí, ti o ṣeeṣe ki o dahun pẹlu iṣesi onídàágunlá sí ohun tí ó farahàn bíi ibeere tí kò ní ìsopọ̀ eyikeyii, “eyi tí ó dáríjì lọ́fẹ̀ẹ́ jù ni.”

“O ṣèdájọ́ daradara,” ni Jesu wí. Lẹhin naa ní yíyíjúsí obinrin naa, ó sọ fun Simoni pe: “Ṣe o rí obinrin yii? Mo wọ inú ilé rẹ; iwọ kò fun mi ní omi fun ẹsẹ̀ mi. Ṣugbọn obinrin yii fi omijé rẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ mi ó sì fi irun rẹ̀ nù wọn. Iwọ kò fi ẹnu kò mi ní ẹnu; ṣugbọn obinrin yii lati wakati tí mo ti wọ ilé, kò sinmi fífi jẹlẹnkẹ fi ẹnu kò mi ní ẹsẹ̀. Iwọ kò fi òróró pa mi ní orí; ṣugbọn obinrin yii fi òróró olóòórùn dídùn pa ẹsẹ̀ mi.”

Obinrin naa nipa bayii ti fi ẹ̀rí ìrònúpìwàdà àtọkànwá hàn fun igbesi-aye oníwà pálapàla rẹ̀ àtijọ́. Nitori naa Jesu pari ọ̀rọ̀ rẹ̀, ní wiwi pe: “Nitori eyi, mo sọ fun ọ, awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, bí ó tilẹ jẹ́ pe wọn pọ̀, ni a dárí wọn jì, nitori pe oun nífẹ̀ẹ́ ohun pupọ, ṣugbọn ẹni tí a dárí diẹ jì, nífẹ̀ẹ́ diẹ.”

Jesu kò yọnda tabi gbọ̀jẹ̀gẹ́ fun ìwà pálapàla lọnakọna. Kàkà bẹẹ, ìṣẹ̀lẹ̀ yii ṣípayá òye oníyọ̀ọ́nú tí oun ní fun awọn ènìyàn tí wọn ṣe awọn àṣìṣe ninu igbesi-aye tí wọn sì wá fihàn gbangba lẹhin naa pe awọn kẹ́dùn fun eyi ati nitori bẹẹ tí wọn wá sọ́dọ̀ Kristi fun ìtura. Ní pípèsè ìtura tootọ fun obinrin naa, Jesu wipe: “A dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì. . . . Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là; maa ba ọ̀nà rẹ lọ ní alaafia.” Luuku 7:36-50; Matiu 11:28-30.

▪ Bawo ni olùgbàlejò Jesu, Simoni ṣe tẹwọgba a?

▪ Ta ni ó wá Jesu rí, eesitiṣe?

▪ Àpèjúwe wo ni Jesu pèsè, ọ̀nà wo ni oun sì gbà fi i sílò?