Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n kan Nipa Ìdáríjì

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n kan Nipa Ìdáríjì

Orí 64

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n kan Nipa Ìdáríjì

JESU lọna híhàn gbangba ṣì wà ninu ilé ní Kapanaomu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Ó ti ńjíròrò pẹlu wọn bí wọn ṣe le bójútó awọn ìṣòro láàárín awọn ará, nitori naa Peteru beere pe: “Oluwa, ìgbà meloo ni arakunrin mi yoo ṣẹ̀ mi tí emi sì nilati dáríjì í?” Niwọnbi awọn olùkọ́ ìsìn Juu ti dábàá dídáríjìni kiki ní ìgbà mẹta, ó ṣeeṣe kí Peteru ronu pe ó jẹ́ ìwà ọ̀làwọ́ gan-an lati dámọ̀ràn “títí di ìgbà meje?”

Ṣugbọn èrò-ọkàn pípa irúfẹ́ akọsilẹ bẹẹ mọ kò tọ̀nà. Jesu tọ́ Peteru sọ́nà pe: “Emi wí fun ọ, kii ṣe, Títí di ìgbà meje, bikoṣe, Títí di igba aadọrin lé méje.” Oun ńfihàn pe Peteru kò gbọdọ fi ààlà kankan sí iye ìgbà tí Peteru dáríji arakunrin rẹ̀.

Lati tẹ̀ ẹ́ mọ́ awọn ọmọ-ẹhin lọ́kàn àìgbọdọ̀máṣe wọn lati maa dáríjini, Jesu sọ àkàwé kan fun wọn. Ó jẹ́ nipa ọba kan tí ó fẹ́ lati yanjú awọn akọsilẹ ìṣirò-owó pẹlu awọn ẹrú rẹ̀. A mú ẹrú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ gbèsè tabua 60,000,000 dinari. Kò sí ọ̀nà tí o ṣeeṣe kankan tí oun lè gbà san án. Nitori naa, gẹgẹ bi Jesu ti ṣàlàyé, ọba pàṣẹ pe kí a ta oun ati iyawo rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ lati fi san gbèsè naa.

Ni gbigbọ eyi ẹrú naa wolẹ́ sí ẹsẹ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì bẹ̀bẹ̀ pe: “Mú sùúrù fun mi emi yoo sì san ohun gbogbo padà fun ọ.”

Bí ikaaanu ti sún un fun ẹru naa, ọ̀gá naa fi pẹlu àánú fagilé gbèsè tabua tí ẹrú naa jẹ. Ṣugbọn kò pẹ́ kò jìnnà sí ìgbà tí ó ṣe bẹẹ, ni Jesu nbaa lọ, ẹrú yii lọ ó sì rí ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó jẹ́ ẹ ní gbèsè kìkì 100 dinari. Ọkunrin naa rá ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mú lọ́fun ó sì bẹrẹsii fún un pa, ní wiwi pe: “San ohun yoowu tí iwọ jẹ padà.”

Ṣugbọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ naa kò ní owó naa lọwọ. Nitori naa oun wólẹ̀ fun ẹrú tí o jẹ ní gbèsè naa, ní bíbẹ̀bẹ̀: “Mú sùúrù fun mi emi yoo sì san án padà fun ọ.” Láìdàbí ọ̀gá rẹ̀, ẹrú naa kò láàánú, ó sì mú kí a ju ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sínú ẹ̀wọ̀n.

Tóò, Jesu nbaa lọ pe, awọn ẹrú yooku tí wọn rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ lọ tí wọn sì sọ fun ọ̀gá naa. Oun fi pẹlu ìbínú pe ẹrú naa wa si iwaju rẹ̀. “Ẹrú burúkú,” ni oun wí, “Mo fagilé gbogbo gbèsè yẹn fun ọ, nigba ti iwọ pàrọwà fun mi. Kò ha yẹ kí iwọ, ẹ̀wẹ̀, ti ṣàánú fun ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹgẹ bi emi pẹlu ti ṣàánú fun ọ?” Bi ibinu rẹ̀ ti de ògógóró, ọ̀gá naa fa ẹrú aláìláàánú naa lé awọn onítúbú lọwọ títí oun yoo fi san gbogbo ohun tí ó jẹ padà.

Lẹhin naa Jesu pari rẹ̀ pe: “Ní irú ọ̀nà kan naa ni Baba mi ọ̀run pẹlu yoo ṣe sí yin bí olukuluku yin kò bá dáríji arakunrin rẹ̀ lati inú ọkàn-àyà yin wá.”

Wo bí eyi ti jẹ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n dídára kan nipa ìdáríjì! Ní ìfiwéra pẹlu gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ ńláǹlà tí Ọlọrun ti dárí rẹ̀ jì wá, ẹ̀ṣẹ̀ eyikeyii ti Kristẹni arakunrin wa lè ṣẹ wa kéré nitootọ. Siwaju sii, Jehofa Ọlọrun ti dáríjì wá ní ẹgbẹẹgbẹrun ìgbà. Níye ìgbà a kò tilẹ mọ̀ pe awa ti ṣẹ lòdìsí i. Nitori naa, kò ha yẹ kí a dáríjì arakunrin wa ni igba melookan, kódà bí a bá ní ìdí tí ó tọ̀nà kan fun ìráhùn? Ranti, gẹgẹ bi Jesu ti fi kọ́ni ninu Iwaasu orí Òkè, Ọlọrun yoo “dárí awọn gbèsè wa jì wá, gẹgẹ bi awa pẹlu ti ńdáríjì awọn ajigbèsè wa.” Matiu 18:21-35; 6:12, NW; Kolose 3:13.

▪ Ki ni ó fa ibeere Peteru nipa dídáríjì arakunrin rẹ̀, eesitiṣe tí oun fi lè ka ìdámọ̀ràn rẹ̀ fun didariji ẹnikan ni ìgbà meje sí eyi tí ó jẹ́ ọ̀lọ́làwọ́?

▪ Bawo ni ìhùwàpadà ọba naa sí ẹ̀bẹ̀ fun àánú ti ẹrú rẹ̀ fi yàtọ̀ sí ìhùwàpadà ẹrú naa sí ẹ̀bẹ̀ ẹrú ẹlẹgbẹ́ kan?

▪ Ẹkọ wo ni a kọ lati inu àkàwé Jesu?