Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣìkàpànìyàn Nigba Àpèjẹ Ọjọ́-ìbí Kan

Ìṣìkàpànìyàn Nigba Àpèjẹ Ọjọ́-ìbí Kan

Orí 51

Ìṣìkàpànìyàn Nigba Àpèjẹ Ọjọ́-ìbí Kan

LẸHIN fifun awọn apọsiteli rẹ̀ ní ìtọ́ni, Jesu rán wọn jáde sínú ìpínlẹ̀ ní meji-meji. Àfàìmọ̀ kí ó má jẹ́ pe awọn arakunrin naa Peteru ati Anderu ni wọn jìjọ lọ, gẹgẹ bi Jakọbu ati Johanu, Filipi ati Batolomiu, Tọmasi ati Matiu, Jakọbu ati Tadeọsi, ati Simoni ati Judasi Isikariọtu ti ṣe pẹlu. Àpínpọ̀ mẹfa ẹlẹ́ni meji-meji awọn ajíhìnrere polongo ihinrere Ijọba wọn sì mú ìwòsàn oníṣẹ́ ìyanu ṣe níbi gbogbo tí wọn lọ.

Láàárín àkókò yii, Johanu Arinibọmi ṣì wà ninu ẹ̀wọ̀n sibẹsibẹ. Ó ti wà níbẹ̀ fun ohun tí ó fẹrẹẹ tó ọdun meji nisinsinyi. Iwọ lè rántí pe Johanu ti polongo ní gbangba pe kò tọ́ fun Hẹrọdu Antipa lati sọ Hẹrọdiasi, iyawo arakunrin rẹ̀ Filipi, di tirẹ̀. Niwọn bi Hẹrọdu Antipa ti sọ pe oun ntẹle awọn Òfin Mose, lọna tí ó tọ̀nà, Johanu ti tú ìrẹ́pọ̀ onipanṣaga yii fó. Nitori eyi ni Hẹrọdu fi sọ Johanu sí ẹ̀wọ̀n, boya pẹlu ìrọni Hẹrọdiasi.

Hẹrọdu Antipa mọ pe Johanu jẹ́ ọkunrin olódodo kan ó sì tilẹ nfetisi i pàápàá pẹlu inúdídùn. Nitori naa, ìdààmú dé bá a niti ki ni kí oun ṣe pẹlu rẹ̀. Hẹrọdiasi, ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, kórìíra Johanu ó sì tẹramọ́ wíwá ọ̀nà pe ki a pa á. Nikẹhin, àǹfààní ti oun ti ńdúró dè naa naa dé.

Kété ṣáájú Irekọja 32 C.E., Hẹrọdu ṣètò àṣeyẹ ọjọ́-ìbí títóbi kan fun araarẹ̀. Awọn tí ó péjọ fun àpéjẹ naa jẹ́ gbogbo ìjòyè òṣìṣẹ́ onípò gíga ati awọn ọ̀gágun Hẹrọdu, ati awọn sànmànrí ìlú Galili. Bí àṣeyẹ naa ti ntẹsiwaju, Salome, ọ̀dọ́mọbìnrin kekere Hẹrọdiasi tí ó bí fun Filipi ọkọ̀ rẹ̀ tẹlẹri, ni a rán wọlé lati jó fun awọn àlejò. Eré rẹ̀ wọ awujọ awọn onworan naa lọkan ṣinṣin.

Salome mú inú Hẹrọdu dùn gidigidi. “Beere ohun yoowu tí iwọ fẹ́ lọwọ mi emi yoo sì fifun ọ,” ni oun polongo. Ó tilẹ búra pàápàá: “Ohun yoowu tí iwọ bá beere lọwọ mi, emi yoo fifun ọ, títídé ìdajì ijọba mi.”

Ṣaaju kí ó tó dáhùn, Salome jáde lọ lati fọ̀rànlọ iya rẹ̀. “Ki ni emi nilati beere?” ni ọmọbinrin naa wádìí.

Àǹfààní naa niyii nigbẹhin-gbẹhin! “Orí Johanu arinibọmi,” ni Hẹrọdiasi dáhùn láìṣetìkọ̀.

Kíá ni Salome padà sọ́dọ̀ Hẹrọdu tí ó sì beere pe: “Mo fẹ́ kí iwọ fun mi ní orí Johanu Arinibọmi ninu àwopọ̀kọ́ nisinsinyi.”

Hẹrọdu dààmú gidigidi. Sibẹ nitori awọn àlejò rẹ̀ ti gbọ́ ìbúra rẹ̀, ojú yoo tì í bí kò bá yọnda fifun un, àní bí ó tilẹ jẹ́ pe eyi tumọsi ṣíṣìkàpa ọkunrin kan tí ó jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. Abẹnilori kan ni a rán jáde lẹsẹkẹsẹ sí ẹ̀wọ̀n pẹlu awọn ìtọ́ni tí ńkó ìpayà báni rẹ̀. Kò pẹ́ pupọ tí ó padà dé pẹlu orí Johanu ninu àwopọ̀kọ́, ó sì fi i fun Salome, Oun, ẹ̀wẹ̀, gbé e tọ iya rẹ̀ lọ. Nigba ti awọn ọmọlẹhin Johanu gbọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, wọn wá wọn sì gbé òkú rẹ̀ kuro wọn sì sin ín, ati lẹhin naa wọn ròhìn ọ̀ràn naa fun Jesu.

Lẹhin naa, nigba ti Hẹrọdu gbọ́ pe Jesu ńmú awọn ènìyàn láradá tí ó sì ńlé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde, jìnnìjìnnì bò ó, ní bíbẹ̀rù pe Jesu niti tootọ jẹ́ Johanu tí a ti jí dìde kuro ninu òkú. Lẹhin ìgbà naa, oun dàníyàn gidigidi lati rí Jesu, kii ṣe lati gbọ́ iwaasu rẹ̀, ṣugbọn lati mọ̀ dájú yálà awọn ìbẹ̀rù rẹ̀ lẹ́sẹ̀nílẹ̀ tabi bẹẹkọ. Matiu 10:1-5; 11:1; 14:1-12; Maaku 6:14-29; Luuku 9:7-9.

▪ Eeṣe tí Johanu fi wà ninu ẹ̀wọ̀n, eesitiṣe tí Hẹrọdu kò fi fẹ́ lati pa á?

▪ Bawo ni ó ṣe ṣeeṣe fun Hẹrọdiasi nikẹhin lati jẹ́ kí a pa Johanu?

▪ Lẹhin ikú Johanu, eeṣe tí Hẹrọdu fi fẹ́ lati rí Jesu?