Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbẹ̀rẹ̀ Ọjọ́ Tí Ó Ṣekókó Naa

Ìbẹ̀rẹ̀ Ọjọ́ Tí Ó Ṣekókó Naa

Orí 105

Ìbẹ̀rẹ̀ Ọjọ́ Tí Ó Ṣekókó Naa

NIGBA ti Jesu fi Jerusalẹmu silẹ ní alẹ́ Monday, ó pada sí Bẹtani ní ìlà-oòrùn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Olifi. Ọjọ́ meji tí ó gbẹ̀hìn iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ ní Jerusalẹmu ti parí. Láìsí iyemeji Jesu tún lo alẹ́ naa lẹẹkan sii lọ́dọ̀ Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀. Lati igba tí ó ti dé lati Jẹriko ní Friday, eyi jẹ́ ọjọ́ kẹrin rẹ̀ ní Bẹtani.

Nisinsinyi, ní kùtùkùtù owúrọ̀ Tuesday, Nisan 11, oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tún wà loju ọ̀nà lẹẹkan sii. Eyi jásí ọjọ́ kan tí ó ṣekókó ninu iṣẹ-ojiṣẹ Jesu, eyi ti ó kún fun igbokegbodo julọ títí di isinsinyi. Ó jẹ́ ọjọ́ tí ó farahan kẹhin ní tẹmpili. Ó sì tún jẹ́ ọjọ́ tí ó kẹhin ninu iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ ní gbangba ṣaaju ìjẹ́jọ́ rẹ̀ ati ìfìyà ikú jẹ ẹ́.

Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gba oju ọna kan naa lórí Òkè Olifi síhà Jerusalẹmu. Ní ojú ọ̀nà tí ó ti Bẹtani wá yẹn, Peteru ṣakiyesi igi naa tí Jesu fi bú ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ó ṣaaju. “Rabi, wò bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí iwọ fi bú ti gbẹ,” ni ó ṣe sáàfúlà.

Ṣugbọn èéṣe tí Jesu fi pa igi naa? Ó ṣalaye idi eyi nigba ti ó nbaa lọ lati wipe: “Lóòótọ́ ni mo wí fun yin, bí ẹyin bá ní igbagbọ, tí ẹ kò bá sì ṣiyemeji, ẹyin kì yoo ṣe kìkì eyi ti a ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yii, ṣugbọn bí ẹyin bá tilẹ̀ wí fun òkè yii [Òkè Olifi lórí eyi ti wọn dúró sí], Ṣídìí, kí o sì bọ́ sinu òkun, yoo ṣẹ. Ohunkohun gbogbo tí ẹyin bá beere ninu adura pẹlu igbagbọ, ẹyin yoo rí i gbà.”

Nitori naa nipa mímú kí igi naa gbẹ, Jesu npese fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣeé fojúrí kan nipa àìní wọn lati ní igbagbọ ninu Ọlọrun. Gẹgẹ bi oun ti sọ: “Ohunkohun tí ẹyin bá tọrọ nigba ti ẹ bá ngbadura, ẹ gbagbọ pé ẹ ti rí wọn gbà ná, yoo sì rí bẹẹ fun yin.” Ẹ̀kọ́ ṣíṣe pàtàkì wo nìyìí fun wọn lati kọ́, paapaa lójú ìwòye awọn ìdánwò abanilẹru tí yoo dé laipẹ! Sibẹsibẹ, ìfarakọ́ra mìíràn wà láàárín gbígbẹ tí igi naa gbẹ ati animọ níní igbagbọ.

Orilẹ-ede Isirẹli, bii igi ọ̀pọ̀tọ́ yii, ní irisi ti ntannijẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orilẹ-ede naa wà ninu ibatan onímájẹ̀mú pẹlu Ọlọrun tí ó sì lè farahan lóde pe oun ńpa awọn ìlànà rẹ̀ mọ́, ó ti fi ẹ̀rí jíjẹ́ aláìní ìgbàgbọ́ hàn, tí kò lè mú èso tí ó dara jade. Nitori ṣíṣàìní igbagbọ, o tilẹ tún ńfẹ́ lati ṣá Ọmọkunrin Ọlọrun fúnraarẹ̀ tì! Nipa bayii, mímú kí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò ní eso naa gbẹ, Jesu ńfihàn ni kedere ohun tí iyọrisi ikẹhin yoo jẹ́ fun orilẹ-ede tí kò ní eso, tí kò sì ní ìgbàgbọ́ yii.

Kété lẹhin naa, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀ Jerusalẹmu, ati gẹgẹ bi àṣà wọn, wọn lọ sí tẹmpili, nibi ti Jesu ti bẹ̀rẹ̀síí kọ́ni. Awọn olórí alufaa ati awọn àgbààgbà awọn eniyan naa, laiṣiyemeji ní ìgbésẹ̀ Jesu lodisi awọn tí nṣe pàṣípààrọ̀ owó ní ọjọ́ tí ó ṣaaju lọ́kàn, pè é níjà: “Ọlá-àṣẹ wo ni iwọ fi ńṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fun ọ ní ọlá-àṣẹ yii?”

Ní fífèsìpadà Jesu wí pé: ‘Emi yoo sì bi yin léèrè ohun kan, bí ẹyin bá sọ fun mi, emi yoo sì sọ fun yin ọlá-àṣẹ tí emi fi ńṣe nǹkan wọnyi: Baptisi Johanu, níbo ni ó ti wá? Lati ọ̀run wá ni, tabi lati ọ̀dọ̀ eniyan?’

Awọn alufaa ati awọn àgbààgbà bẹ̀rẹ̀síí gbèrò láàárín araawọn niti bí awọn yoo ṣe dahun. “Bí awa bá wí pé, Lati ọ̀run wá ni, oun yoo wí fun wa pé, Èéhatiṣe tí ẹyin kò fi gbà á gbọ́? Ṣugbọn bí awa bá sì wipe, Lati ọ̀dọ̀ eniyan; awa nbẹru ìjọ eniyan, nitori gbogbo wọn kà Johanu sí wòlíì.”

Awọn aṣaaju naa kò mọ̀ ohun tí awọn yoo fi dahun. Nitori naa wọn dá Jesu lóhùn pé: “Awa kò mọ̀.”

Jesu, ẹ̀wẹ̀, wipe: ‘Nitori naa emi kì yoo sì wí fun yin ọlá-àṣẹ tí emi fi ńṣe nǹkan wọnyi.’ Matiu 21:19-27; Maaku 11:19-33; Luuku 20:1-8.

▪ Ki ni ohun tí ó jámọ́pàtàkì nipa Tuesday, Nisan 11?

▪ Awọn ẹ̀kọ́ wo ni Jesu pèsè nigba ti ó mú kí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan gbẹ?

▪ Bawo ni Jesu ṣe dá awọn wọnni tí wọn beere nipa ọlá-àṣẹ tí oun fi ńṣe awọn nǹkan lohun?