Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbí Jesu—Nibo ati Nigba Wo?

Ìbí Jesu—Nibo ati Nigba Wo?

Orí 5

Ìbí Jesu—Nibo ati Nigba Wo?

ỌLỌLA ọba Ilẹ Roomu, Kesari Ọgọsitọsi, ti ṣe ofin pe olukuluku gbọdọ pada si ilu ti a gbé bí i lati lọ fi orukọ silẹ. Nitori naa Josẹfu rin irin ajo lọ si ilu ibilẹ rẹ̀, ilu Bẹtilẹhẹmu.

Ọpọ awọn eniyan nbẹ ni Bẹtilẹhẹmu ti wọn wá lati fi orukọ silẹ, ibi kanṣoṣo ti Josẹfu ati Maria lè rí lati wọ̀ sí ni ile ẹran ọ̀sìn kan. Nihin-in, nibi ti a nko awọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati awọn ẹranko miiran sí, ni a bí Jesu sí. Maria fi ọ̀já wé e ó sì gbé e sinu ibùjẹ́ ẹran kan, nibi ti a maa nko ounjẹ awọn ẹranko sí.

Dajudaju o jẹ́ nipasẹ itọsọna Ọlọrun ni Kesari Ọgọsitọsi fi ṣe ofin iforukọsilẹ yii. Eyi mú kí o ṣeeṣe fun Jesu lati di ẹni ti a bí ní Bẹtilẹhẹmu, ilu naa ti Iwe Mimọ ti sọtẹlẹ tipẹtipẹ ṣaaju pe yoo jẹ́ ilu ibilẹ alakooso ti a ṣeleri naa.

Ẹ wo iru òru pataki ti eyi jẹ́! Lẹhin òde ninu pápá ni imọlẹ dídán kan tán yika awujọ awọn oluṣọ agutan kan. Ògo Jehofa ni eyi jẹ́! Angẹli Jehofa sì sọ fun wọn pe: “Má bẹ̀rù: sawoo, mo mú ihinrere ayọ nla fun yin wa, ti yoo ṣe ti eniyan gbogbo. Nitori a bí Olugbala fun yin lonii ni ilu Dafidi, ti nṣe Kristi Oluwa. Eyi ni yoo sì ṣe àmì fun yin; ẹyin yoo rí ọmọ ọwọ́ ti a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ́ ẹran.” Lojiji awọn angẹli pupọ sii farahan tí wọn sì nkọrin pe: “Ògo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati ní ayé alaafia, ìfẹ́ inúrere sí eniyan.”

Nigba ti awọn angẹli naa lọ tan, awọn oluṣọ agutan naa wí fun araawọn ẹnikinni keji pe: “Ẹ jẹ ki a lọ taara sí Bẹtilẹhẹmu, ki a lè rí ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa [“Jehofa,” NW] fihan fun wa.” Wọn yara lọ wọn sì rí Jesu nibi gan-an ti angẹli naa ti sọ pe wọn yoo rí i. Nigba ti awọn oluṣọ agutan naa rohin ohun ti angẹli naa ti sọ fun wọn, ẹnu ya gbogbo awọn ti wọn gbọ́ nipa rẹ̀. Maria pa gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi mọ́ o sì ṣìkẹ́ wọn ninu ọkan rẹ̀.

Ọpọ eniyan lonii gbàgbọ́ pe Jesu ni a bí ní December 25. Ṣugbọn December jẹ́ asiko òjò, ti o tutù rinrin ni Bẹtilẹhẹmu. Awọn oluṣọ agutan kò lè sí ní ìta ninu pápá ni òru pẹlu awọn agbo wọn ní akoko yẹn ninu ọdun. Ati pẹlu, kò jọ bi ẹni pe Kesari ti Roomu naa yoo beere pe ki awọn eniyan kan ti wọn ti ní èrò lati dìtẹ̀ sí i rin irin ajo naa laaarin ọ̀gìnnìtìn otutu lati lọ fi orukọ silẹ. Ẹ̀rí fihan kedere pe Jesu ni a bí ni akoko kan laaarin ibẹrẹ igba ìwọ́wé ọdun. Luuku 2:1-20; Mika 5:2.

▪ Eeṣe ti Josẹfu ati Maria fi rinrin ajo lọ si Bẹtilẹhẹmu?

▪ Ohun agbayanu wo ni o ṣẹlẹ ni oru ọjọ ti a bí Jesu?

▪ Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Jesu ni a kò bí ní December 25?