Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Ti Jesu Fi Wá sí Aye

Ìdí Ti Jesu Fi Wá sí Aye

Orí 24

Ìdí Ti Jesu Fi Wá sí Aye

ỌJỌ ti Jesu lò ni Kapanaomu pẹlu awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ mẹrin ti jẹ eyi ti o kún fun igbokegbodo pupọ, eyi ti o pari pẹlu awọn ara Kapanaomu tí wọn ngbe gbogbo awọn alaisan wọn wá fun un lati wò wọn sàn ni ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Kò fi igba kan sí aaye lati dánìkan wà.

Ó ti di kùtùkùtù hàì ni owurọ ọjọ keji nisinsinyi. Nigba ti òkùnkùn ṣì ṣú, Jesu dìde ó sì lọ sí òde fúnraarẹ̀. Ó rinrin ajo lọ si ibi àdádó kan nibi ti o ti lè gbadura sí Baba rẹ̀ ní ikọkọ. Ṣugbọn akoko tí Jesu fi wà ní ikọkọ kò pẹ́ rara nitori pe nigba ti Peteru ati awọn miiran mọ̀ pe kò sí laaarin wọn, wọn jade lọ wá a kiri.

Nigba ti wọn wá Jesu rí, Peteru wipe: “Gbogbo eniyan ńwá ọ.” Awọn eniyan Kapanaomu nfẹ ki Jesu duro sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọn mọriri ohun ti o ti ṣe fun wọn nitootọ! Ṣugbọn njẹ olori idi ti Jesu fi wa sori ilẹ aye ni lati ṣe imularada oniṣẹ iyanu? Ki ni oun wí nipa eyi?

Gẹgẹ bi akọsilẹ Bibeli kan ti wi, Jesu dá awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lóhùn pe: “Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miiran, ki emi ki o lè waasu nibẹ pẹlu: nitori eyi ni emi saa ṣe wá.” Ani bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan naa rọ Jesu lati duro, oun sọ fun wọn pe: “Emi kò lè ṣaima waasu ijọba Ọlọrun fun ilu miiran pẹlu: nitori naa ni a saa ṣe ran mi.”

Bẹẹni, Jesu wá sori ilẹ aye ni pataki lati waasu nipa Ijọba Ọlọrun, eyi ti yoo dá orukọ Baba rẹ̀ lare tí yoo sì yanju gbogbo awọn iyọnu ẹda eniyan lọna pipẹtiti. Bi o ti wu ki o ri, lati funni ni ẹri pe a rán an wá lati ọdọ Ọlọrun, Jesu ṣe awọn imularada oniṣẹ iyanu. Ni ọna kan naa ti Mose, ni ọpọ ọrundun ṣaaju, ṣe awọn iṣẹ iyanu lati fi ìdí rẹ̀ mulẹ gbọnyin gẹgẹ bi iranṣẹ Ọlọrun.

Nisinsinyi, nigba ti Jesu fi Kapanaomu silẹ lati lọ waasu ni awọn ilu miiran, awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ mẹrin naa baa lọ. Awọn mẹrin wọnyi ni Peteru ati arakunrin rẹ̀ Anderu, ati Johanu ati arakunrin rẹ̀ Jakọbu. Iwọ yoo ranti pe ni ọsẹ ti o ṣẹṣẹ kọja, a ti kesi wọn lati jẹ́ awọn alabaaṣiṣẹpọ arinrin ajo akọkọ fun Jesu.

Irin ajo iwaasu Jesu ní Galili pẹlu awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ mẹrin naa jẹ́ agbayanu aṣeyọri si rere kan! Nitootọ, irohin nipa awọn igbokegbodo rẹ̀ tàn ká àní dé gbogbo Siria. Awọn ogunlọgọ lati Galili, Judia, ati ni odikeji Odò Jọdani tọ Jesu ati awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lẹhin. Maaku 1:35-39; Luuku 4:42, 43; Matiu 4:23-25; Ẹkisodu 4:1-9, 30, 31.

▪ Ki ni o ṣẹlẹ ni owurọ ti o tẹle ọjọ ti o kun fun igbokegbodo ti Jesu lò ni Kapanaomu?

▪ Ki ni idi ti a fi ran Jesu wa sori ilẹ aye, ète wo sì ni awọn iṣẹ iyanu rẹ̀ ṣiṣẹ fun?

▪ Awọn wo ni o ba Jesu lọ ninu irin ajo iwaasu rẹ̀ kaakiri Galili, kí sì ni idahunpada si awọn igbokegbodo Jesu?