Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí fun Adura ati fun Ìrẹ̀lẹ̀

Ìdí fun Adura ati fun Ìrẹ̀lẹ̀

Orí 94

Ìdí fun Adura ati fun Ìrẹ̀lẹ̀

NÍ IṢAAJU, nigba ti ó wà ní Judia, Jesu sọ àkàwé kan nipa ìjẹ́pàtàkì títẹpẹlẹmọ́ adura gbígbà. Nisinsinyi, ninu ìrìn àjò rẹ̀ tí ó kẹhin sí Jerusalẹmu, oun lẹẹkan sí i tẹnumọ́ ìdí naa lati maṣe juwọsilẹ ni gbigba adura. O ṣeeṣe ki Jesu ṣì wà ní Samaria tabi Galili sibẹ nigba ti ó sọ àkàwé miiran yii fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀:

“Ni ilu kan bayii onidaajọ kan bayii wà ti kò ní ibẹru Ọlọrun tí kò sì ní ọ̀wọ̀ fun eniyan. Ṣugbọn opó kan wà ni ilu yẹn o sì nlọ sọdọ rẹ̀ ṣaa, wipe, ‘Rii pe mo ri idajọ ododo gba lori elénìní mi.’ Too, fun akoko kan kò fẹ́ ṣe ṣugbọn nigbẹhin o wi fun ara rẹ̀, ‘Bi o tilẹ jẹ pe emi kò bẹru Ọlọrun tabi bọwọ fun eniyan, bi o ti wu ki o ri, nitori ti obinrin yii nda mi láàámú nigba gbogbo, emi yoo rii pe o ri idajọ ododo gbà, ki oun ma baa maa wá kí ó sì maa gèjíà mi de ipari.’”

Jesu lẹhin naa fi ìtàn rẹ̀ sílò ní wiwi pe: “Ẹ gbọ́ ohun ti onídàájọ́ naa wí, bi o tilẹ jẹ alaiṣododo. Dajudaju, nigba naa, Ọlọrun ko ha ni mu ki a ṣe idajọ ododo fun awọn ayanfẹ rẹ̀ ti nke jade pè é ni ọsan ati ni òru, ani bi o tilẹ jẹ pe oun ni ipamọra fun wọn?”

Jesu kò ní in lọ́kàn lati pẹ́ ẹ sọ pe Jehofa Ọlọrun ní ọ̀nà eyikeyii dàbí onídàájọ́ aláìṣòdodo yẹn. Kàkà bẹẹ, bí ó bá ṣe pe kódà onídàájọ́ aláìṣòdodo pàápàá yoo dáhùnpadà sí ìpàrọwà tí a tẹpẹlẹmọ́, kò yẹ kí iyèméjì kankan wà pe Ọlọrun, tí ó jẹ́ olódodo ti o sì jẹ ẹni rere pẹlu, yoo dáhùn bí awọn eniyan rẹ̀ kò bá juwọ́sílẹ̀ ninu gbígbàdúrà. Nitori naa Jesu nbaa lọ pe: “Mo sọ fun yin, [Ọlọrun] yoo mu ki a ṣe idajọ ododo fun wọn kóyákóyá.”

Ìdájọ́ òdodo ni a saba maa ńfi dù awọn ẹni rírẹlẹ̀ ati tálákà, nigba tí ó sì jẹ́ pé awọn alágbára ati ọlọ́rọ̀ ni a sábà maa ńṣe ojúrere sí. Ọlọrun, bí ó ti wù kí ó rí, kì yoo wulẹ̀ rí sí i pe awọn ẹni buburu ni a jẹníyà lọna tí ó bá idajọ ododo mu nikan ni ṣugbọn yoo tún rí sí i pe awọn iranṣẹ rẹ̀ ni a lò sí lọna tí ó bá idajọ ododo mu nipa fífún wọn ní ìyè ainipẹkun. Ṣugbọn awọn ẹni meloo ni wọn gbàgbọ́ dajudaju pe Ọlọrun yoo mú kí a ṣe idajọ ododo ni kóyákóyá?

Ní títọ́ka ní pàtàkì sí ìgbàgbọ́ tí ó bá agbára adura tan, Jesu beere pe: “Nigba ti ọmọkunrin ènìyàn bá dé, niti gidi oun yoo ha rí ìgbàgbọ́ lori ilẹ̀-ayé?” Bí ó tilẹ jẹ́ pe a fi ibeere naa silẹ̀ láìdáhùn, ó lè dọ́gbọ́n túmọ̀sí pe irúfẹ́ ìgbàgbọ́ bẹẹ kì yoo wọ́pọ̀ nigba ti Kristi bá dé ninu agbára Ijọba.

Lára awọn wọnni tí nfetisilẹ sí Jesu ní awọn kan tí wọn dá araawọn lójú nipa ìgbàgbọ́ wọn. Wọn nígbẹkẹ̀lé ninu araawọn pe awọn jẹ́ olódodo, wọn sì ńfojútẹ̀ awọn ẹlomiran mọ́lẹ̀. Awọn kan lára awọn ọmọ-ẹhin Jesu lè wà lára àwùjọ naa pàápàá. Nitori naa o darí àkàwé tí ó tẹle e yii ní tààràtà sí irúfẹ́ awọn ẹni bẹẹ:

“Ọkunrin meji goke lọ sinu tẹmpili lati gbadura, ọkan Farisi ekeji sì jẹ agbowo-ori. Farisi naa dide duro o sì bẹrẹ sii gbadura nnkan wọnyi fun ara ara rẹ̀, ‘Óò Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ pe emi kò ri bi awọn eniyan yooku, alọnilọwọgba, alaiṣododo, panṣaga, tabi gẹgẹ bi agbowo-ori yii paapaa. Mo ngbaawẹ lẹẹmeji ni ọsẹ, mo nfunni ni idamẹwaa gbogbo nnkan ti mo ni.’”

Awọn Farisi lokiki lọpọlọpọ fun awọn àṣehàn òdodo wọn ní gbangba lati wú awọn ẹlomiran lórí. Monday ati Thursday ni awọn ọjọ́ tí wọn saba maa ńlò fun awọn ààwẹ̀ ti wọn gbeka araawọn lori, tí wọn sì ńsan ìdámẹ́wàá ani awọn ewé egbòogi kéékèèké inú pápá dórí bín-ńtín. Ní awọn oṣu diẹ ṣaaju, ìyọṣùtì wọn sí awọn eniyan gbáàtúù ti farahàn gbangba lákòókò Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn nigba ti wọn wipe: “Ogunlọgọ yii tí wọn kò mọ Òfin [eyiini ni, ìtumọ̀ tí awọn Farisi fi fun un] jẹ́ ẹni ègún.”

Ní bíbá àkàwé rẹ̀ lọ, Jesu sọ nipa irú “ẹni ègún” bẹẹ pe: “Ṣugbọn agbowó-orí ti o duro ni okeere naa kò tilẹ fẹ lati gbe oju rẹ̀ soke ọrun paapaa, ṣugbọn o lu aya rẹ̀, wipe, ‘Óò Ọlọrun, ṣoore-ọfẹ fun mi emi ẹlẹṣẹ.’” Nitori agbowó-orí naa ti fi pẹlu irẹlẹ fi awọn àìdójú-ìwọ̀n rẹ̀ hàn, Jesu wipe: “Mo sọ fun yin, ọkunrin yii sọkalẹ lọ sí ilé rẹ̀ ní olódodo ju ọkunrin yẹn lọ, nitori olukuluku ẹni tí ó bá gbé araarẹ̀ ga, ni a o rẹ̀ sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá rẹ araarẹ̀ silẹ ni a ó gbéga.”

Nipa bayii Jesu lẹẹkan sí i tẹnumọ́ ìdí naa lati jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Niwọn bi a ti tọ́ wọn dàgbà ninu àwùjọ kan tí awọn Farisi olódodo lójú ara-ẹni ńdarí tí itẹnumọ sì wà lori ipò, kò yanilẹnu pe o ti ran awọn ọmọ-ẹhin Jesu paapaa pẹlu. Sibẹ, ẹ wo ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n rere nipa ìrẹ̀lẹ̀ ti Jesu fi kọ́ni! Luuku 18:1-14; Johanu 7:49.

▪ Eeṣe tí onídàájọ́ aláìṣòdodo naa fi yọnda ohun tí opó naa beere fun, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni àkàwé Jesu sì fi kọni?

▪ Ìgbàgbọ́ wo ni Jesu yoo wọ̀nà fun nigba ti ó bá dé?

▪ Awọn wo ni Jesu darí àkàwé rẹ̀ nipa Farisi ati agbowó-orí sí?

▪ Ẹ̀mí-ìrònú awọn Farisi wo ni a gbọdọ yẹra fun?