Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbàgbọ́ Títóbi Ọ̀gágun Kan

Ìgbàgbọ́ Títóbi Ọ̀gágun Kan

Orí 36

Ìgbàgbọ́ Títóbi Ọ̀gágun Kan

NIGBA ti Jesu sọ Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, oun ti dé nǹkan bíi ìlàjì ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ní gbangba. Eyi tumọsi pe oun ní kìkì ọdun kan ati nǹkan bíi oṣu mẹ́sàn-án sí i lati parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé.

Jesu nisinsinyi wọ ìlú-ńlá Kapanaomu lọ, tí ó jẹ́ irú ibujokoo kan fun awọn ìgbòkègbodò rẹ̀. Níhìn-ín ni awọn àgbààgbà ọkunrin Juu ti tọ̀ ọ́ wá pẹlu ibeere kan. A ti rán wọn wá lati ọ̀dọ̀ ọ̀gágun Roomu kan tí ó jẹ́ Keferi, ọkunrin kan tí ìran rẹ̀ yàtọ̀ sí ti awọn Juu.

Ààyò olùfẹ́ ọmọ-ọdọ ọ̀gágun naa ńkú lọ lati ọwọ́ àmódi eléwu kan, oun sì ńfẹ́ kí Jesu mú ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ láradá. Awọn Juu fi tọkàntọkàn jírẹ̀ẹ́bẹ̀ nitori ọ̀gágun naa: “Ó yẹ ní ẹni tí iwọ ìbá fi ọlá yii fun,” ni wọn wí, “nitori ó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wa oun fúnraarẹ̀ sì kọ́ sinagọgu fun wa.”

Láìsí ìlọ́tìkọ̀, Jesu bá awọn ọkunrin naa lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, nigba ti wọn sunmọ ibẹ̀, ọ̀gágun naa rán awọn ọ̀rẹ́ lati wí fun un pe: “Ọ̀gbẹ́ni, maṣe ìyọnu, nitori emi kò yẹ lati mú kí o wá sí abẹ́ òrùlé mi. Nitori ìdí eyiini emi kò ka araami sí ẹni yiyẹ lati tọ̀ ọ́ wá.”

Irú ìsọjáde onírẹ̀lẹ̀ wo ni eyi fun ọ̀gágun kan tí ó ti mọ́ lára lati maa pàṣẹ fun awọn ẹlomiran! Ṣugbọn boya oun pẹlu tún ńronú nipa Jesu, ní mimọ pe àṣà kọ̀ fun Juu kan lati ní ìbáṣepọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà pẹlu awọn tí kii ṣe Juu. Peteru pàápàá sọ pe: “Ẹ mọ̀ daradara bí kò ti bófinmu fun Juu kan lati da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ tabi sunmọ ènìyàn kan tí ó jẹ́ ti ìran miiran.”

Boya nitori àìfẹ́ kí Jesu jìyà àbájáde ṣíṣẹ̀ sí àṣà yii, ọ̀gágun naa rán awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ lati beere lọwọ rẹ̀ pé: “Sọ ọ̀rọ̀ naa, kí á sì mú iranṣẹ [“ọmọ-ọdọ,” NW] mi láradá. Nitori emi pẹlu jẹ́ ọkunrin kan tí ó wà lábẹ́ ọlá-àṣẹ, tí mo ní awọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi, emi a sì wí fun eyi, ‘Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n!’ oun a sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ, ati fun òmíràn pe, ‘Wá!’ oun a sì wá, ati fun ẹrú mi, ‘Ṣe eyi!’ oun a sì ṣe é.”

Tóò, nigba ti Jesu gbọ́ eyi, ẹnu yà á. “Mo sọ otitọ fun yin,” ni oun wí, “emi kò tíì rí irú ìgbàgbọ́ títóbi tobẹẹ lọ́dọ̀ ẹni kankan ní Isirẹli.” Lẹhin mímú ọmọ ọdọ ọ̀gágun naa láradá, Jesu lo àǹfààní naa lati sọ bí a ó ṣe fi ibukun tí awọn Juu aláìnígbàgbọ́ kọ̀sílẹ̀ ṣojúrere sí awọn tí kii ṣe Juu tí wọn ní ìgbàgbọ́.

“Ọpọlọpọ,” ni Jesu wí, “lati awọn apá ìlà-oòrùn ati apá ìwọ̀-oòrùn yoo wá tí wọn yoo rọ̀gbọ̀kù nídìí tabili pẹlu Aburahamu ati Isaki ati Jakọbu ní ijọba awọn ọ̀run; nigba tí ó jẹ́ pe awọn ọmọ ijọba naa ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde. Nibẹ ni sísunkún ati pípahínkeke wọn yoo wà.”

“Awọn ọmọ ijọba naa . . . [tí a] sọ sínú òkùnkùn lóde” ni awọn Juu àbínibí tí wọn kò tẹ́wọ́gbà àǹfààní naa tí a kọ́kọ́ nawọ́ rẹ̀ sí wọn ti jíjẹ́ awọn olùṣàkóso pẹlu Kristi. Aburahamu, Isaki, ati Jakọbu dúró fun ìṣètò Ijọba Ọlọrun. Nipa bẹẹ Jesu ńròhìn bí a ó ti tẹ́wọ́gbà awọn Keferi lati rọ̀gbọ̀kú yíká tabili ti ọ̀run naa gẹgẹ bi ọ̀nà ìsọ̀rọ̀, “ni ijọba ọ̀run.” Luuku 7:1-10; Matiu 8:5-13, NW; Iṣe 10:28.

▪ Eeṣe tí awọn Juu fi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ nitori ọ̀gágun Keferi kan?

▪ Ki ni lè jẹ́ idi tí ọ̀gágun naa kò fi késí Jesu lati wọ inú ilé rẹ̀?

▪ Ki ni Jesu ní lọ́kàn nipa awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ipari?