Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjiyàn kan Bẹ Silẹ

Ìjiyàn kan Bẹ Silẹ

Orí 115

Ìjiyàn kan Bẹ Silẹ

ṢAAJU ní alẹ́ naa, Jesu kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ẹlẹ́wà kan tí ó niiṣe pẹlu iṣẹ́-ìsìn onírẹ̀lẹ̀ nipasẹ wíwẹ ẹsẹ̀ awọn apọsiteli rẹ̀. Lẹhin naa, ó nasẹ̀ Iṣe-iranti ikú rẹ̀ tí ó sunmọle. Nisinsinyi, pàápàá ní pàtàkì lójú ìwòye ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ ojiji kan wáyé. Awọn apọsiteli rẹ̀ kówọnú ìjiyàn gbígbóná kan lórí ta ni ẹni naa ninu wọn tí ó tóbi jùlọ! Ní kedere, eyi jẹ́ apákan aáwọ̀ tí ó ti ńbáa nìṣó.

Rántí pe lẹhin tí a ti pa Jesu láradà lórí òkè naa, awọn apọsiteli jiyàn lórí ta ni ẹni tí ó tóbi jùlọ láàárín wọn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jakọbu ati Johanu beere fun awọn ipò ọlá ninu Ijọba naa, eyi tí ó yọrísí àríyànjiyàn siwaju sí i láàárín awọn apọsiteli. Nisinsinyi, ní òru rẹ̀ tí ó kẹhin pẹlu wọn, ẹ wo bí inú Jesu ti gbọdọ bàjẹ́ tó lati rí wọn tí wọn tún ńṣaáwọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i! Ki ni oun ṣe?

Kàkà kí ó bá awọn apọsiteli naa wí fun ìhùwàsí wọn, lẹẹkan sí i Jesu fi pẹlu sùúrù fọ̀rọ̀wérọ̀ pẹlu wọn: “Awọn ọba awọn orílẹ̀-èdè maa ńjẹgàba lórí wọn, awọn wọnni tí wọn sì ní ọlá-àṣẹ lórí wọn ni a ńpè ní Olóore. Ṣugbọn, ẹyin kò nilati rí bí eyiini. . . . Nitori ewo ni ó tóbi jù, ẹni naa tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì tabi ẹni tí ńṣèránṣẹ́? Kìí ha ṣe ẹni naa tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì?” Lẹhin naa, ni rírán wọn létí apẹẹrẹ tirẹ̀, ó wipe: “Ṣugbọn emi wà láàárín yin gẹgẹ bi ẹni naa tí ńṣèránṣẹ́.”

Láìka àìpé wọn sí, awọn apọsiteli ti rọ̀ mọ́ Jesu lákòókò awọn àdánwò rẹ̀. Nitori naa ó wipe: “Mo sì dá majẹmu kan pẹlu yin, gan-an gẹgẹ bi Baba mi ti dá majẹmu kan pẹlu mi, fun ijọba kan.” Majẹmu ara-ẹni yii láàárín Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ adúróṣinṣin so wọn papọ̀ pẹlu rẹ̀ lati ṣàjọpín àṣẹ kábíyèsí rẹ̀. Kìkì iye tí ó láàlà ti 144,000 ni a mú wọlé nikẹhin sínú majẹmu yii fun Ijọba kan.

Bí ó tilẹ jẹ́ pe a gbé ìrètí yíyanilẹ́nu ti ṣíṣàjọpín pẹlu Kristi ninu iṣakoso Ijọba kalẹ̀ fun awọn apọsiteli naa, wọn jẹ́ aláìlera nipa tẹ̀mí nisinsinyi. “Gbogbo yin ni yoo kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹlu mi ní alẹ́ yii,” ni Jesu wí. Bí o ti wu ki o ri, ní sísọ fun Peteru pe Oun ti gbàdúrà nitori rẹ̀, Jesu rọ̀ ọ́ pe: “Kété lẹhin ti o bá ti padà, fun awọn arakunrin rẹ lókun.”

“Ẹyin ọmọ kéékèèké,” ni Jesu ṣàlàyé, “emi wà pẹlu yin fun ìgbà diẹ sí i. Ẹyin yoo wá mi; gan-an gẹgẹ bi mo sì ti wí fun awọn Juu, ‘Ibi tí emi ńlọ ẹyin kò lè wá,’ ni mo wí fun un yin pẹlu nisinsinyi. Emi ńfún yin ní òfin titun kan, pe kí ẹ nífẹ̀ẹ́ araayin; gan-an gẹgẹ bi emi ti nífẹ̀ẹ́ yin, pe kí ẹyin pẹlu nífẹ̀ẹ́ araayin. Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ̀ pe ẹyin jẹ́ ọmọ-ẹhin mi, bí ẹyin bá ní ìfẹ́ láàárín araayin.”

“Oluwa, nibo ni iwọ ńlọ?” ni Peteru beere.

“Ibi tí emi ńlọ iwọ kò lè bá mi lọ nisinsinyi,” ni Jesu fèsìpadà, “ṣugbọn iwọ yoo tọ̀ mi wá nikẹhin.”

“Oluwa, eeṣe tí emi kò fi lè bá ọ lọ nisinsinyi?” ni Peteru fẹ́ lati mọ̀. “Emi yoo fi ọkàn mi lélẹ̀ nitori rẹ.”

“Iwọ yoo ha fi ọkàn rẹ lélẹ̀ nitori mi?” ni Jesu beere. “Lóòótọ́ ni mo wí fun ọ, Iwọ lonii, bẹẹni, ní alẹ́ yii, kí àkùkọ tó kọ lẹẹmeji, àní iwọ yoo sẹ́ mi ní ìgbà mẹta.”

“Àní bí mo bá tilẹ nilati bá ọ kú,” ni Peteru ṣàtakò, “emi kì yoo sẹ́ ọ́ lọnakọna.” Nigba ti awọn apọsiteli yooku sì darapọ̀ ninu sísọ ohun kan naa, Peteru fọ́nnu pe: “Àní bí gbogbo awọn yooku kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹlu rẹ, emi kì yoo kọsẹ̀ lae!”

Ní títọ́kasí àkókò naa nigba ti oun rán awọn apọsiteli naa jáde fun ìrìn àjò iwaasu kan ní Galili láìsí àsùnwọ̀n ati àpò ounjẹ, Jesu beere pe: “Ẹ kò ṣe aláìní ohunkohun, ẹ ṣe bẹẹ bí?”

“Bẹẹkọ!” ni èsì wọn.

“Ṣugbọn nisinsinyi jẹ́ kí ẹni tí ó ní àsùnwọ̀n mú un, bẹẹ gẹ́gẹ́ sì ni àpò ounjẹ,” ni ó wí, “sì jẹ́ kí ẹni tí kò ní idà ta ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ kí ó sì ra ọ̀kan. Nitori mo sọ fun un yin pe eyi tí a kọ ni a gbọdọ ṣeparí ninu mi, eyiini ni, ‘A sì kà á kún awọn aláìlófin.’ Nitori eyiini tí ó kàn mi ńní àṣeparí.”

Jesu ntọkasi sí àkókò naa nigba ti a o kàn án mọ́gi pẹlu awọn olùṣe buburu, tabi awọn aláìlófin. Oun tún ńfihàn pẹlu pe awọn ọmọlẹhin oun yoo dojúkọ inúnibíni mímúná lẹhin ìgbà naa. “Oluwa, wò ó! idà meji niyii níhìn-ín,” ni wọn wí.

“Ó ti tó,” ni ó dáhùn. Gẹgẹ bi awa yoo ti rí, níní awọn idà naa pẹlu wọn yoo yọnda fun Jesu láìpẹ́ lati kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ ṣíṣe pàtàkì miiran. Matiu 26:31-35; Maaku 14:27-31; Luuku 22:24-38; Johanu 13:31-38, NW; Iṣipaya 14:1-3.

▪ Eeṣe tí ìjiyàn awọn apọsiteli naa fi yanilẹ́nu?

▪ Bawo ni Jesu ṣe mójútó ìjiyàn naa?

▪ Ki ni majẹmu naa tí Jesu dá pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣaṣepari rẹ̀?

▪ Òfin titun wo ni Jesu fifúnni, bawo ni ó sì ti ṣe pàtàkì tó?

▪ Ìgbọ́kànlé ara-ẹni jù wo ni Peteru fihàn, ki ni ohun tí Jesu sì sọ?

▪ Eeṣe tí awọn ìtọ́ni Jesu nipa gbígbé àsùnwọ̀n ati àpò ounjẹ fi yàtọ̀ sí iwọnyi tí oun fúnni ní iṣaaju?