Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Siwaju Síi ní Ọjọ́ Keje

Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Siwaju Síi ní Ọjọ́ Keje

Orí 68

Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Siwaju Síi ní Ọjọ́ Keje

ỌJỌ́ tí ó kẹhin Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn, ọjọ́ keje, ṣì ńlọ lọwọ. Jesu ńkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ni apá tẹmpili tí a ńpè ní “ilé-ìṣúra.” Eyi ní kedere wà ní àgbègbè tí a ńpè ní Ìgà Awọn Obinrin níbi tí awọn àpótí ìtọ́jú tí awọn eniyan ńfi ọrẹ wọn sí gbé wà.

Ní gbogbo alẹ́ nigba àjọ-àríyá naa, ìtànmọ́lẹ̀ àkànṣe ni a fihàn ní àgbègbè yii ninu tẹmpili naa. Awọn ọpa giga ti ngbe fitila ró mẹrin ni a ṣe síbẹ̀, ọkọọkan ní awọn bàsíà ńlá mẹrin tí ó kún fun òróró. Ìmọ́lẹ̀ lati inú awọn fìtílà òróró tí ńjó lati inú awọn bàsíà mẹrindinlogun wọnyi, ní agbára tí ó pọ̀ tó lati tànmọ́lẹ̀ sí gbogbo àyíká naa nasẹ̀ dé ọ̀nà jíjìn ní alẹ́. Ohun tí Jesu sọ nisinsinyi lè rán awọn olùfetisílẹ̀ rẹ̀ létí nipa ìfihàn yii. “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé,” ni Jesu pòkìkí. “Ẹni tí ó bá tọ̀ mi lẹhin kì yoo rìn ninu òkùn, ṣugbọn yoo ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

Awọn Farisi takò ó: “Iwọ ńjẹ́rìí araàrẹ; ẹ̀rí rẹ kii ṣe òtítọ́.”

Ní ìdáhùn Jesu fèsìpadà: “Bí mo tilẹ ńjẹ́rìí fun araami, otitọ ni ẹ̀rí mi: nitori tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ńlọ. Ṣugbọn ẹyin kò mọ ibi tí mo ti wá ati ibi tí mo ńlọ.” Ó fikun un pe: “Emi ni ẹni tí ó ńjẹ́rìí araami, ati Baba tí ó rán mi sì ńjẹ́rìí fun mi.”

“Nibo ni Baba rẹ wà?” awọn Farisi ńfẹ́ lati mọ̀.

“Ẹyin kò mọ̀ mi, bẹẹ ni ẹ kò mọ Baba mi,” ni Jesu dáhùn. “Ìbáṣepé ẹyin mọ̀ mi, ẹyin ìbá sì ti mọ̀ Baba mi pẹlu.” Àní bí ó tilẹ jẹ́ pe awọn Farisi ṣì ńfẹ́ fi àṣẹ ọba mú Jesu, kò sí ẹnikan tí ó fi ọwọ́ kàn án.

“Emi ńlọ,” ni Jesu wí lẹẹkan sí i. “Ibi tí emi gbé ńlọ ẹyin kì yoo lè wá.”

Ní gbígbọ́ eyi awọn Juu bẹrẹsii ṣe kàyéfì: “Oun yoo ha pa araarẹ̀ bí nitori pe ó wipe, ‘Ibi tí emi gbé ńlọ, ẹyin kì yoo lè wá.’”

“Ẹyin ti ìsàlẹ̀ wá; emi ti òkè wá: ẹyin jẹ́ ti ayé yii; emi kii ṣe ti ayé yii.” Lẹhin naa ó fikun un pe: “Bí kò ṣe pe ẹ bá gbàgbọ́ pe, emi ni, ẹ o kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ yin.”

Jesu, dajudaju, ńtọ́kasí iwalaaye rẹ̀ ṣaaju kí ó tó wá sí ayé ati jijẹ ti oun jẹ Mesaya, tabi Kristi naa tí a ti ṣèlérí. Bí eyiini tilẹ rí bẹẹ, wọn beere, laiṣiyemeji pẹlu ìyọṣùtì ńláǹlà pe: “Ta ni iwọ nṣe?”

Laika ìṣátì wọn si, Jesu dáhùn: ‘Eeṣe tí emi fi nba yin sọ̀rọ̀ gan-an pàápàá?’ Sibẹ ó nbaa lọ lati sọ pe: “Olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí emi sì ti gbọ́ lati ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, iwọnyi ni emi sọ fun aráyé.” Jesu nbaa lọ pe: “Nigba ti ẹ bá gbé Ọmọkunrin eniyan sókè, nigba naa ni ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun araami; ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi, emi ńsọ nǹkan wọnyi. Ẹni tí ó rán mi sì nbẹ pẹlu mi: kò jọ̀wọ́ emi nikan sí; nitori tí emi ṣe ohun tí ó wù ú nigba gbogbo.”

Nigba ti Jesu nsọ awọn nǹkan wọnyi, ọ̀pọ̀ eniyan gbà á gbọ́. Ó sọ fun awọn wọnyi pe: “Bí ẹyin bá dúró ninu ọ̀rọ̀ mi, nigba naa ni ẹyin jẹ́ ọmọ-ẹhin mi nitootọ. Ẹ o sì mọ otitọ, otitọ yoo sì sọ yin di òmìnira.”

“Irú-ọmọ Aburahamu ni awa ńṣe,” ni awọn alátakò rẹ̀ jálu ọ̀rọ̀ naa, “awa kò sì ṣe ẹrú fun ẹnikẹni rí láé: Iwọ ha ṣe wipe, ‘Ẹ o di òmìnira?’”

Bí ó tilẹ jẹ́ pe awọn Juu ti fi ìgbàgbogbo wà lábẹ́ ìjẹgàba awọn àjòjì, wọn kò mọ aninilára eyikeyii gẹgẹ bi ọ̀gá. Wọn kọ̀ lati jẹ́ kí a pè wọn ní ẹrú. Ṣugbọn Jesu tọ́ka jáde pe awọn niti tootọ jẹ́ ẹrú. Ní ọ̀nà wo? “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fun yin,” ni Jesu wí, “ẹnikẹni tí ó bá ńdẹ́ṣẹ̀, oun ni ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.”

Kíkọ̀ lati tẹ́wọ́gbà ìsìnrú wọn fun ẹ̀ṣẹ̀ fi awọn Juu sínú ipò eléwu kan. “Ẹrú kìí sìí gbé ilé titilae,” ni Jesu ṣàlàyé. “Ọmọ ní ńgbé ilé titilae.” Niwọn bi ó ti jẹ́ pe ẹrú kan kò ní awọn ẹ̀tọ́ ogún kankan, ó lè wà ninu ewu lílélọ ní ìgbà eyikeyii. Kìkì ọmọkunrin naa tí a bí tabi tí a gbàṣọmọ niti gàsíkíá sínú agbo-ilé naa ní ńgbé nibẹ “titilae,” eyi ni pe, niwọn ìgbà tí ó bá ṣì walaaye.

“Nitori naa bí Ọmọ bá sọ yin di òmìnira,” ni Jesu nbaa lọ, “ẹyin yoo di òmìnira nitootọ.” Nipa bayii, otitọ naa tí ńsọ eniyan dòmìnira jẹ́ otitọ nipa Ọmọkunrin, Jesu Kristi. Kìkì nipasẹ ẹbọ iwalaaye ẹ̀dá-ènìyàn rẹ̀ pípé ni ẹnikẹni lè fi dòmìnira kuro lọwọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ńṣekúpani. Johanu 8:12-36.

▪ Nibo ni Jesu ti kọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ní ọjọ́ keje? Ki ni ṣẹlẹ̀ nibẹ ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, bawo sì ni eyi ṣe tanmọ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jesu?

▪ Ki ni ohun tí Jesu sọ nipa ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí sì ni eyi nilati ṣípayá nipa ẹni tí oun jẹ́?

▪ Ní ọ̀nà wo ni awọn Juu fi jẹ́ ẹrú, ṣugbọn otitọ wo ni yoo sọ wọn di òmìnira?