Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ̀ràn Atọ́nisọ́nà Siwaju Síi

Ìmọ̀ràn Atọ́nisọ́nà Siwaju Síi

Orí 63

Ìmọ̀ràn Atọ́nisọ́nà Siwaju Síi

NIGBA tí Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀ ṣì wà ninu ilé naa ní Kapanaomu, ohun miiran yatọ sí àríyànjiyàn awọn apọsiteli lórí ta ni ó tóbi jùlọ ni wọn jíròrò. Ìṣẹ̀lẹ̀ yii pẹlu lè ti wáyé nigba tí wọn ńpadà lọ sí Kapanaomu, nigba ti Jesu fúnraarẹ̀ kò sí nibẹ. Apọsiteli Johanu ròhìn pe: “Olùkọ́, awa rí ọkunrin kan bayii tí ńlé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde nipa lílo orukọ rẹ awa sì gbìyànjú lati dena rẹ̀, nitori oun kò bá wa kẹ́gbẹ́rìn.”

Ní kedere Johanu wo awọn apọsiteli gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn oloye ti nṣiṣẹ imularada ti a yasọtọ kan. Nitori naa oun nímọ̀lára pe ọkunrin naa mú awọn iṣẹ́ alágbára ṣe láìtọ̀nà nitori pe oun kii ṣe ara àwùjọ wọn.

Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu pèsè ìmọ̀ràn pe: “Ẹ maṣe gbìyànjú lati dena rẹ̀, nitori kò sí ẹnikan tí yoo ṣe iṣẹ́ agbára lórí ìpìlẹ̀ orúkọ mi tí ó lè kẹ́gàn mi kiakia; nitori ẹni tí kò bá lòdìsí wa wà fun wa. Nitori ẹni yoowu tí ó bá fun yin ní aago omi kan lati mu nitori ìdí naa pe ẹyin jẹ́ ti Kristi, lóòótọ́ ni mo sọ fun yin, oun kì yoo pàdánù èrè rẹ̀ lọnakọna.”

Ọranyan kọ ni pe ki ọkunrin yii maa tẹle Jesu niti taarata lati fihan pe o ntẹle e. A kò tíì gbé ijọ Kristẹni kalẹ̀, nitori naa àìjẹ́ ara àwùjọ wọn kò tumọsi pe oun jẹ́ ijọ tí ó yàtọ̀ kan. Ọkunrin naa ní ìgbàgbọ́ ninu orukọ Jesu nitootọ tí ó sì tipa bẹẹ ṣàṣeyọrísírere ninu lílé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde. Oun ńṣe ohun kan tí ó ṣeéfiwéra lọna tí ó baramu pẹlu ohun tí Jesu sọ pe ó yẹ fun èrè. Jesu fihan pe fun ṣiṣe eyi, oun ki yoo padanu èrè rẹ̀.

Ṣugbọn ki ni bí ọkunrin naa bá kọsẹ̀ nipa awọn ọ̀rọ̀ ati awọn ìgbésẹ̀ awọn apọsiteli? Eyi yoo léwu gidigidi! Jesu wipe: “Ṣugbọn ẹni yoowu tí ó bá mú ọ̀kan ninu awọn kéékèèké tí wọn gbàgbọ́ wọnyi kọsẹ̀, ìbá ṣe rere jù fun un tí a bá so ọlọ irú eyi tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ maa ńyí mọ́ ọ ní ọrùn kí a sì jù ú niti gàsíkíá sínú òkun.”

Jesu wipe awọn ọmọlẹhin oun nilati mú kúrò ninu ìgbésí-ayé wọn ohunkohun tí ó ṣọ̀wọ́n sí wọn bii ọwọ́, ẹsẹ̀, tabi ojú tí ó lè ṣokùnfà ìkọ̀sẹ̀ wọn. Ó sàn lati wà láìsí ohun tí a ṣìkẹ́ yii kí wọn sì wọ inú Ijọba Ọlọrun ju lati dì í mú sibẹ kí á sì jù wọn sọnù sínú Gẹhẹna (òkìtì ààtàn kan tí ńjó nítòsí Jerusalẹmu), tí ó ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé.

Jesu kìlọ̀ pẹlu pe: “Ẹ ríi pe ẹyin ọkunrin wọnyi kò tẹ́ḿbẹ́lú ọ̀kan ninu awọn kéékèèké wọnyi; nitori mo sọ fun yin pe nigbagbogbo ni awọn angẹli wọn ní ọ̀run ńwo ojú Baba mi tí nbẹ ní ọ̀run.” Lẹhin naa ni ó ṣàpèjúwe iniyelori “awọn kéékèèké” nipa sísọ nipa ọkunrin kan tí ó ní ọgọ́rùn-ún àgùtàn ṣugbọn tí ó padanu ọ̀kan. Ọkunrin naa yoo fi 99 naa silẹ lati wá ọ̀kan tí ó sọnù kiri, ni Jesu ṣàlàyé, nigba tí ó bá sì rí i yoo yọ̀ lórí rẹ̀ jù lórí 99 naa. “Bẹẹ gẹ́gẹ́,” ni Jesu pari ọrọ lẹhin naa, “kii ṣe ohun tí Baba mi tí nbẹ ní ọ̀run fẹ́ fun ọ̀kan ninu awọn kéékèèké wọnyi lati ṣègbé.”

Bí ó ti ṣeeṣe kí ó ní ìjiyàn awọn apọsiteli rẹ̀ láàárín araawọn lọ́kàn, Jesu rọ̀ wọn pe: “Ẹ ní iyọ̀ ninu araayin, kí ẹ sì pa alaafia mọ́ láàárín araayin.” Awọn ounjẹ aláìládùn ni a mú kí ó tubọ ládùn lẹ́nu nipasẹ iyọ̀. Nipa bẹẹ, iyọ̀ àfiṣàpẹẹrẹ ńmú kí ohun tí ẹnikan sọ rọrùn lati tẹ́wọ́gbà. Níní irúfẹ́ iyọ̀ bẹẹ yoo ràn wa lọwọ lati pa alaafia mọ́.

Ṣugbọn nitori àìpé ẹ̀dá ènìyàn, nigba miiran aáwọ̀ tí ó tóbi yoo ṣẹlẹ̀. Jesu tun pèsè awọn amọ̀nà fun bíbójútó wọn. “Bí arakunrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan,” ni Jesu wí, “lọ ṣí àríwísí rẹ̀ payá láàárín iwọ ati oun nikan, bí ó bá fetisilẹ sí ọ, iwọ ti jèrè arakunrin rẹ̀.” Bí oun kò bá fetisilẹ, Jesu gbani nimọran pe, “mú ẹnikan tabi meji lọ pẹlu rẹ, kí o baa lè jẹ́ pe ní ẹnu ẹlẹrii meji tabi mẹta ni a lè fìdí kókó-ọ̀ràn gbogbo múlẹ̀.”

Jesu wipe kìkì gẹgẹ bi ìyíjúsí ikẹhin kan, mú ọ̀ràn naa lọ sí ọ̀dọ̀ “ijọ,” iyẹn ni pe, sí ọ̀dọ̀ awọn alaboojuto ninu ijọ tí wọn ní ẹrù-iṣẹ́ lati lè fúnni ní ipinnu ìdájọ́ kan. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ naa kò bá tẹ́wọ́gbà ipinnu wọn, Jesu pari ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe, “jẹ́ kí ó dabi eniyan awọn orílẹ̀-èdè ati gẹgẹ bi agbowó òde kan sí ọ.”

Ninu ṣíṣe irúfẹ́ ipinnu kan bẹẹ, awọn alaboojuto nilati rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ awọn ìtọ́ni inú Ọ̀rọ̀ Jehofa. Nipa bẹẹ, nigba ti wọn bá rí ẹnikan tí ó jẹ̀bi tí ó sì yẹ fun ìjìyà, ìdájọ́ naa ‘ni a o ti dè ní ọ̀run ṣaaju.’ Nigba ti wọn bá sì “tú u lórí ilẹ̀-ayé,” iyẹn ni pe, kí wọn rí ẹnikan bi aláìmọwọ́mẹsẹ̀, a o ti “tú u ní ọ̀run” ṣaaju. Ninu irúfẹ́ ayẹwo ìdájọ́ bẹẹ, Jesu wipe, “níbi tí ẹni meji tabi mẹta bá kójọpọ̀ sí ní orukọ mi, nibẹ ni emi wà láàárín wọn.” Matiu 18:6-20; Maaku 9:38-50; Luuku 9:49, 50.

▪ Eeṣe tí kò fi pọndandan ní ọjọ́ Jesu lati bá a kẹ́gbẹ́rìn?

▪ Bawo ni ọ̀ràn mímú ẹni kekere kan kọsẹ̀ ti wúwo tó, bawo sì ni Jesu ṣe ṣàpèjúwe ìjẹ́pàtàkì irúfẹ́ awọn ẹni kéékèèké bẹẹ?

▪ Ki ni ohun tí ó ṣeeṣe kí ó ti fa ìṣírí tí Jesu fun awọn apọsiteli naa lati ní iyọ̀ láàárín araawọn?

▪ Ìjámọ́pàtàkì wo ni ó wà ninu ‘dídè’ ati ‘títú’?