Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmúrasílẹ̀ Lati Dojúkọ Inúnibíni

Ìmúrasílẹ̀ Lati Dojúkọ Inúnibíni

Orí 50

Ìmúrasílẹ̀ Lati Dojúkọ Inúnibíni

LẸHIN tí ó ti fun awọn apọsiteli rẹ̀ ní ìtọ́ni nipa bi wọn yoo ṣe ṣe iṣẹ́ iwaasu naa, Jesu kìlọ̀ fun wọn nipa awọn alátakò. Ó wipe: “Ẹ wòó! Mo ńrán yin jáde gẹgẹ bi àgùtàn sáàárín awọn ìkookò . . . Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ awọn ènìyàn; nitori wọn yoo fà yin lé awọn ilé-ẹjọ́ àdúgbò lọwọ, wọn yoo sì nà yin lọ́rẹ́ ninu awọn sinagọgu wọn. Eeṣe, wọn o fipá fà yin lọ siwaju awọn gómìnà ati awọn ọba nitori mi.”

Láìka inúnibíni lílekoko tí awọn ọmọlẹhin rẹ̀ yoo dojúkọ sí Jesu fi wọn lọkan balẹ pẹlu ileri naa pe: “Nigba ti wọn bá fà yin lé wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣàníyàn nipa bawo ati ki ni ẹyin yoo sọ; nitori a o fi ohun tí ẹ o sọ fun yin ní wakati yẹn; nitori kii ṣe ẹyin nikan ní ńsọ̀rọ̀, bikoṣe ẹ̀mí Baba yin ní ńsọ̀rọ̀ nipasẹ yin.”

“Siwaju sii,” ni Jesu nba ọ̀rọ̀ lọ, “arakunrin yoo fa arakunrin lé ikú lọwọ, ati baba ọmọ rẹ̀, awọn ọmọ yoo sì dìde sí awọn òbí wọn wọn yoo sì mú kí á pa wọn.” Ó fikun un pe: “Ẹyin yoo sì jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nititori orukọ mi; ṣugbọn ẹni tí ó bá ti forítì í títí dé òpin ni ẹni naa tí a o gbàlà.”

Iwaasu naa jẹ́ àkọ́kọ́ ní ìjẹ́pàtàkì. Fun ìdí yii Jesu tẹnumọ́ ijẹpataki ọgbọ́n-inú lati lè wà lómìnira lati maa bá iṣẹ́ naa lọ. “Nigba ti wọn bá ṣe inúnibíni sí yin ní ìlú-ńlá kan, ẹ sálọ sí òmíràn,” ni oun wí, “nitori lóòótọ́ ni mo wi fun yin, Ẹ kì yoo parí àyíká awọn ìlú-ńlá Isirẹli lọnakọna títí Ọmọkunrin ènìyàn yoo fi dé.”

Òótọ́ ni pe Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ 12 ni ìtọ́ni, ìkìlọ̀, ati ìgbani níyànjú, ṣugbọn yoo tun wulo pẹlu fun awọn wọnni tí yoo ṣàjọpín ninu iwaasu kárí-ayé lẹhin ikú ati ajinde rẹ̀. Eyi ni o fihàn nigba ti o sọ pe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni ‘gbogbo eniyan yoo kórìíra,’ kii ṣe kìkì awọn ọmọ Isirẹli nikan awọn ẹni tí a rán awọn apọsiteli naa sí lati waasu fun. Siwaju sí i, awọn apọsiteli naa bí ó ti hàn kedere ni a kò mú lọ siwaju awọn baalẹ ati awọn ọba nigba ti Jesu rán wọn jáde ninu ìgbétáásì iwaasu wọn kúkúrú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, awọn onígbàgbọ́ nigba naa ni awọn mẹmba idile kò fi fún ikú pa.

Nitori naa nigba ti ó sọ pe awọn ọmọ-ẹhin kì yoo lè parí àyíká iwaasu wọn “títí tí Ọmọkunrin ènìyàn yoo fi dé,” Jesu lọna asọtẹlẹ ńsọ fun wa pe awọn ọmọ-ẹhin oun kì yoo parí àyíká ilẹ̀-ayé tí awọn ènìyàn ńgbé pẹlu iwaasu nipa Ijọba Ọlọrun tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣaaju kí Ọba tí a ti ṣelógo naa Jesu Kristi tó dé gẹgẹ bi ọ̀gá amúdàájọ́ṣẹ Jehofa ní Amagẹdoni.

Ní bíbá awọn ìtọ́ni iwaasu rẹ̀ nìṣó, Jesu wipe: “Ọmọ-ẹhin kò gaju olùkọ́ rẹ̀, bẹẹ ni ẹrú kò gajù oluwa rẹ̀.” Nitori naa awọn ọmọlẹhin Jesu gbọdọ fojúsọ́nà lati gba ìlòsí buburu ati inunibini kan naa gẹgẹ bi oun ti rígbà nitori wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun. Sibẹ ó ṣínilétí pe: “Ẹ maṣe bẹ̀rù awọn ẹni tí ńpa ara ṣugbọn tí wọn kò lè pa ọkàn; ṣugbọn kàkà bẹẹ ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó pa ati ọkàn ati ara run ninu Gẹhẹna.”

Jesu yoo fi apẹẹrẹ lélẹ̀ ninu ọ̀ràn yii. Oun yoo fi pẹlu àìbẹ̀rù faradà ikú kàkà ki o juwọ́sílẹ̀ lórí ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Ẹni naa tí ó ní gbogbo agbára, Jehofa Ọlọrun. Bẹẹni, Jehofa ni ẹni naa tí ó lè pa “ọkàn” ẹnikan (tí itumọ rẹ̀ ninu apẹẹrẹ yii jẹ́ ìrètí ọjọ́-ọ̀la ẹni naa gẹgẹ bi ọkàn alaaye kan) tabi dipo bẹẹ ti o lè jí ẹnikan dìde lati gbádùn iye ainipẹkun. Ẹ wo irú Baba ọ̀run onífẹ̀ẹ́, ati oníyọ̀ọ́nú tí Jehofa jẹ́!

Tẹle eyi ni Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ní ìṣírí pẹlu àkàwé kan tí ó tẹnumọ́ ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ Jehofa fun wọn. “Ológoṣẹ́ meji kọ ni a ńtà ní ẹyọ-owó kan oní-ìníyelórí táṣẹ́rẹ́?” ni oun beere. “Sibẹ kò sí ọ̀kan ninu wọn tí yoo jábọ́ sí ilẹ̀ láìsí ìmọ̀ Baba yin. Ṣugbọn gbogbo irun orí yin pàápàá ni a kà. Nitori naa ẹ má bẹ̀rù: ẹyin níyelórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.”

Ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa ti Jesu fún awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ laṣẹ lati pòkìkí yoo pín awọn agbo-ilé níyà, niwọn bi awọn mẹmba idile kan yoo ti tẹ́wọ́gbà á tí awọn miiran yoo sì ṣá a tì. “Ẹ maṣe rò pe emi wá fi alaafia sórí ilẹ̀-ayé,” ni oun ṣàlàyé. “Mo wá lati fi, kii ṣe alaafia, bikoṣe idà sórí rẹ̀.” Nipa bayii, fun mẹmba idile kan lati gba otitọ Bibeli mọ́ra beere fun ìgboyà. “Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni títóbi fun bàbá tabi ìyá jù fun mi kò yẹ ní temi,” ni Jesu ṣàkíyèsí, “ati ẹni tí ó ní ìfẹ́ni títóbi fun ọmọkunrin tabi ọmọbinrin jù fun mi kò yẹ ní temi.”

Ní pipari awọn ìtọ́ni rẹ̀, Jesu ṣàlàyé pe awọn wọnni tí wọn gba awọn ọmọ-ẹhin gba oun pẹlu. “Ẹni yoowu tí ó bá sì fun ọ̀kan ninu awọn ẹni kekere wọnyi ní kìkì aago omi tútù kan lati mu nitori pe ó jẹ́ ọmọ-ẹhin, mo sọ fun yin nitootọ, oun kì yoo pàdánù èrè rẹ̀ lọnakọna.” Matiu 10:16-42, NW.

▪ Awọn ìkìlọ̀ wo ni Jesu pèsè fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀?

▪ Ìṣírí ati ìtùnú wo ni oun fifún wọn?

▪ Eeṣe tí awọn ìtọ́ni Jesu tun fi kàn awọn Kristẹni òde-òní?

▪ Lọna wo ni ọmọ-ẹhin Jesu kan kò fi ga jù olùkọ́ rẹ̀ lọ?