Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrẹ̀lẹ̀ Lakooko Ìrékọjá Ikẹhin

Ìrẹ̀lẹ̀ Lakooko Ìrékọjá Ikẹhin

Orí 113

Ìrẹ̀lẹ̀ Lakooko Ìrékọjá Ikẹhin

PETERU ati Johanu, pẹlu ìtọ́ni lati ọ̀dọ̀ Jesu, ti dé sí Jerusalẹmu bayii lati ṣe awọn ìmúrasílẹ̀ fun Ìrékọjá. Jesu, bí o ti han gbangba papọ pẹlu awọn apọsiteli mẹwaa yooku, dé lẹhin igba naa ní ọ̀sán. Oòrùn ti ńlọsílẹ̀ ní ọkankan bí Jesu ati ẹgbẹ́ rẹ̀ ti ńsọ̀kalẹ̀ Òkè Olifi. Eyi ni ìgbà ikẹhin tí Jesu maa rí ìlú naa ní ọ̀sán títí di ẹhin ajinde rẹ̀.

Láìpẹ́ Jesu ati ẹgbẹ́ rẹ̀ dé sí ìlú naa wọn sì ba ọ̀nà wọn lọ sí ilé naa nibi ti wọn yoo ti ṣayẹyẹ Ìrékọjá. Wọn goke ajà pẹ̀tẹ́ẹ̀sì naa lọ sí iyàrá ńlá loke, nibi ti wọn ti bá gbogbo ìpèsè tí wọn ṣe fun ayẹyẹ abẹ́lé Ìrékọjá wọn. Jesu ti ńwọ̀nà fun àkókò yii, gẹgẹ bi oun ti wi: “Emi ti fẹ́ gidigidi lati jẹ ìrékọjá yii pẹlu yin kí emi tó jìyà.”

Gẹgẹ bi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ife ọti waini mẹrin ni awọn olùkópa ninu Ìrékọjá maa ńmu. Lẹhin títẹ́wọ́gbà ohun tí ó han gbangba pe ó jẹ́ ife kẹta, Jesu dupẹ ó sì wipe: “Ẹ gba eyi kí ẹ sì gbé e lati ọ̀dọ̀ ẹnikan sí ẹlomiran laaarin araayin; nitori mo sọ fun yin, Lati isinsinyi lọ emi kì yoo tún mu lati inu èso àmújáde àjàrà títí ijọba Ọlọrun yoo fi dé.”

Lakooko kan laaarin ounjẹ naa, Jesu dìde dúró, o fi ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó mú aṣọ ìnura, o sì fi omi kún bàsíà kan. Bi o ti saba maa nri, olùgbàlejò kan yoo ri sii pe ẹsẹ̀ àlejò kan ni a wẹ̀. Ṣugbọn niwọn bi ó ti jẹ́ pe kò sí olùgbàlejò kankan níbẹ̀ ní àkókò yii, Jesu bojuto iṣẹ́-ìsìn àṣefúnni yii. Eyikeyii ninu awọn apọsiteli naa ti lè gbá àǹfààní naa mú lati ṣe e; síbẹ̀síbẹ̀, o han gbangba pe nitori ìbánidíje ti o ṣì wà láàárín wọn sibẹ, kò sí ẹni tí ó ṣe e. Nisinsinyi ojú tì wọn bí Jesu ti bẹ̀rẹ sí i fọ̀ ẹsẹ̀ wọn.

Nigba ti Jesu dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Peteru ṣàtakò: “Dajudaju iwọ kì yoo wẹ̀ ẹsẹ̀ mi láé.”

“Àyàfi bí mo bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ní ipa kankan lọ́dọ̀ mi,” ni Jesu wi.

“Oluwa,” ni Peteru dahunpada, “kìí ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, bikoṣe ọwọ mi ati orí mi pẹlu.”

“Ẹni tí ó ti wẹ̀,” ni Jesu dáhùn, “kò nílò ju kí ó wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ó mọ́tónítóní lodidi. Ẹyin ọkunrin wọnyi sì mọ́tónítóní, ṣugbọn kìí ṣe gbogbo yin.” Oun sọ eyi nitori ó mọ̀ pé Judasi Isikariọtu ńwéwèé lati dà oun.

Nigba ti Jesu ti fọ̀ ẹsẹ̀ gbogbo awọn 12 naa, títíkàn ẹsẹ̀ ẹni tí yoo fi i hàn, Judasi, ó wọ̀ awọn ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ ó sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tabili lẹẹkan sii. Lẹhin naa ó beere pe: “Ǹjẹ́ ẹyin mọ ohun tí mo ṣe sí yin? Ẹyin ńpè mi ní, ‘Olukọ,’ ati, ‘Oluwa,’ ẹyin sì sọ̀rọ̀ lọ̀nà tí ó tọ̀nà, nitori iru bẹẹ ni mo jẹ́. Nitori naa, bí emi, tí mo jẹ́ Oluwa ati Olukọ, bá fọ̀ ẹsẹ̀ yin, ó yẹ kí ẹyin pẹlu maa fọ̀ ẹsẹ̀ araayin ẹnikiini keji. Nitori mo fi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fun yin, pe, gan-an gẹgẹ bi bí mo ti ṣe sí yin, ni ẹyin nilati maa ṣe pẹlu. Loootọ dajudaju ni mo wi fun yin, Ẹrú kò tóbi jù ọ̀gá rẹ̀, bẹẹni ẹni tí a rán jade kò tobi ju ẹni tí ó rán an. Bí ẹyin bá mọ̀ awọn nǹkan wọnyi aláyọ̀ ni yin bí ẹ bá ńṣe wọn.”

Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ẹlẹ́wà wo ni eyi jẹ́ ninu iṣẹ́-ìsìn onírẹ̀lẹ̀! Awọn apọsiteli naa kò nilati maa wá ibi àkọ́kọ́ kiri, ní ríronú pe wọn ṣe pataki tobẹẹ tí awọn ẹlomiran fi nilati maa ṣiṣẹsin wọn nigba gbogbo. Wọn nilati tẹ̀lé apẹẹrẹ tí Jesu filélẹ̀. Eyi kìí ṣe ti fífọ̀ ẹsẹ̀ lọna àṣà. Bẹẹkọ, ṣugbọn ó jẹ ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ìmúratán lati ṣiṣẹsin láìsí ìṣègbè, láìkà bí iṣẹ́ naa ti lè jẹ́ yẹpẹrẹ ati aláìgbádùnmọ́ni tó. Matiu 26:20, 21; Maaku 14:17, 18; Luuku 22:14-18; 7:44; Johanu 13:1-17.

▪ Ki ni ó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nipa rírí tí Jesu rí Jerusalẹmu bí oun ti ńwọ̀ ibẹ̀ lati ṣayẹyẹ Ìrékọjá?

▪ Lakooko Ìrékọjá naa, ní kedere ife wo ni Jesu gbé fun awọn apọsiteli 12 naa lẹhin sísúre?

▪ Iṣẹ́-ìsìn àṣefúnni wo ni ó jẹ́ àṣà lati maa pèsè fun awọn àlejò nigba ti Jesu wà lori ilẹ̀-ayé, eeṣe tí a kò fi pèsè rẹ̀ ní akoko Ìrékọjá ti Jesu ati awọn apọsiteli ṣayẹyẹ rẹ̀?

▪ Ki ni ète Jesu ni ṣiṣe iṣẹ́-ìsìn yẹpẹrẹ ti fífọ̀ ẹsẹ̀ awọn apọsiteli rẹ̀?