Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrékọjá Ìgbẹ̀hìn fun Jesu Kù Sí Dẹ̀dẹ̀

Ìrékọjá Ìgbẹ̀hìn fun Jesu Kù Sí Dẹ̀dẹ̀

Orí 112

Ìrékọjá Ìgbẹ̀hìn fun Jesu Kù Sí Dẹ̀dẹ̀

BÍ TUESDAY, Nisan 11, ti ńparí lọ, Jesu parí kíkọ́ awọn apọsiteli rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lori Òkè Olifi. Ẹ wo bi ọjọ naa ti kún fun iṣẹ́ àṣelàágùn tó! Nisinsinyi, boya nigba ti ó ńpadà sí Bẹtani lati lọ lò òru naa, ó sọ fun awọn apọsiteli rẹ̀ pe: “Ẹyin mọ̀ pe ọjọ́ meji sí isinsinyi ìrékọjá yoo wáyé, á ó sì fi Ọmọkunrin eniyan lé wọn lọwọ lati kànmọ́gi.”

Bi o ti han gbangba Jesu lò ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, Wednesday, Nisan 12, ni sísinmi ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀. Ní ọjọ́ tí ó ṣaaju rẹ̀, oun ti kìlọ̀ fun awọn asaaju isin ni gbangba, oun sì mọ̀ pe wọn ńwà ọ̀nà lati pa oun. Nitori naa ní Wednesday oun kò fi araarẹ̀ han ni gbangba, niwọn bi oun kò ti fẹ́ kí ohunkohun dabarú ṣíṣe ayẹyẹ Ìrékọjá pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀ ní alẹ́ tí yoo tẹ̀lé e.

Ní bayii ná, awọn olórí alufaa ati awọn àgbà ọkunrin lara awọn eniyan naa ti kórajọ sí àgbàlá alufaa àgbà, Kaifa. Ní fifarada ọ̀rọ̀ ìgbéjàkoni Jesu ní ọjọ́ tí ó ṣaaju, wọn ńṣe awọn ìwéwèé lati gbá a mú nipasẹ ìhùmọ̀ alárèékérekè kí wọn sì pa á. Síbẹ̀síbẹ̀ wọn nbaa lọ lati wipe: “Kìí ṣe ní àjọ-àríyá, kí ìrúkèrúdò má baa dide laaarin awọn eniyan.” Wọn bẹ̀rù awọn eniyan, niwọn bi Jesu ti rí ojúrere wọn gbà.

Bí awọn aṣaaju ìsìn naa ti ńgbèrò ìwà burúkú lọwọ lati pa Jesu, olùbẹ̀wò kan débá wọn. Sí ìyàlẹ́nu wọn, o jẹ́ ọ̀kan ninu awọn apọsiteli Jesu funraarẹ̀, Judasi Isikariọtu, ẹni naa tí Satani ti gbìn èrò ọkàn buburu naa sí ninu lati fi Ọ̀gá rẹ̀ lè wọn lọwọ! Bawo ni inú wọn ti dùn tó nigba ti Judasi beere pe: “Ki ni ẹyin yoo fifun mi, emi yoo sì fi i le yin lọwọ?” Wọn fi ayọ̀ gbà lati san ọgbọ̀n owó fàdákà fun un, iye owó ẹrú kan ní ìbámu pẹlu májẹ̀mú Òfin Mose. Lati akoko naa lọ, Judasi ńwá àkókò dídára lati fi Jesu lé wọn lọwọ láìsí ogunlọgọ ní àyíká.

Nisan 13 bẹ̀rẹ̀ pẹlu wíwọ̀ oòrùn ní Wednesday. Jesu ti dé lati Jẹriko ní Friday, nitori naa eyi ni òru kẹfa ati eyi tí ó kẹhin tí oun lò ní Bẹtani. Ni ọjọ́ keji, Thursday, ìmúrasílẹ̀ ìgbẹ̀hìn ni a nilati ṣe fun Ìrékọjá naa, eyi ti o bẹ̀rẹ̀ lẹhin wíwọ̀ oòrùn. Akoko yẹn ni a gbọdọ dúḿbú ọ̀dọ́-àgùtàn Ìrékọjá naa kí a yan án láyangbẹ lodidi. Nibo ni wọn yoo ti ṣayẹyẹ àsè naa, ta ni yoo sì ṣe ìmúrasílẹ̀ naa?

Jesu kò ti pèsè irufẹ awọn kulẹkulẹ bẹẹ, boya lati ṣediwọ fun Judasi lati fi tó awọn olórí alufaa létí kí wọn baa wá fagbára mú Jesu lakooko ayẹyẹ Ìrékọjá naa. Ṣugbọn nisinsinyi, boya ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán Thursday, Jesu ran Peteru ati Johanu lọ kíákíá lati Bẹtani, ní wiwi pe: “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá sílẹ̀ fun wa, ki awa ki o jẹ́.”

“Nibo ni iwọ ńfẹ́ kí a pese sílẹ̀?” ni wọn beere.

Jesu ṣalaye pe, “Nigba ti ẹyin ba nwọ ilu lọ, ọkunrin kan ti o ru iṣà omi yoo pade yin; ẹ baa lọ si ile ti o ba wọ̀. Ki ẹ sì wi fun baale ile naa pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọngan apejẹ naa gbé wà, nibi ti emi yoo gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? Oun yoo sì fi gbọngan nla kan loke hàn yin, ti a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: nibẹ ni ki ẹyin ki o pese silẹ.”

Láìsí iyèméjì onílé naa jẹ ọmọ-ẹhin Jesu kan ẹni tí ó ṣeeṣe ki o ti maa fojúlọ́nà fun ibeere Jesu lati lò ilé rẹ̀ fun ìṣẹ̀lẹ̀ àkànṣe yii. Bi o ti wu ki ó rí, nigba ti Peteru ati Johanu dé sí Jerusalẹmu, wọn bá ohun gbogbo gan-an gẹgẹ bi Jesu ti sọtẹlẹ. Nitori naa awọn mejeeji ri si i pe ọ̀dọ́-ágútán naa ni a pèsè sílẹ̀ ati pe gbogbo awọn ìṣètò miiran ni a ṣe lati bojuto àìní awọn mẹtala naa tí wọn jẹ́ olùṣayẹyẹ Ìrékọjá, Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀ mejila. Matiu 26:1-5, 14-19; Maaku 14:1, 2, 10-16; Luuku 22:1-13; Ẹkisodu 21:32.

▪ Ki ni ó han gbangba pe Jesu ṣe ní Wednesday, eeṣe?

▪ Ipade wo ni a ṣe ní ilé alufaa àgbà, fun ète wo sì ni Judasi fi ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ awọn aṣaaju ìsìn naa?

▪ Awọn wo ni Jesu ran lọ sí Jerusalẹmu ní Thursday, fun ète wo sì ni?

▪ Ki ni ohun tí awọn ẹni tí a ran wọnyi rí tí ó ṣipaya awọn agbára iṣẹ́-ìyanu Jesu lẹẹkan sii?