Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrìn Àjò Iwaasu Miiran ní Galili

Ìrìn Àjò Iwaasu Miiran ní Galili

Orí 49

Ìrìn Àjò Iwaasu Miiran ní Galili

LẸHIN nǹkan bí ọdun meji iwaasu tí ó gbónájanjan, Jesu yoo ha bẹrẹsii jáwọ́ kí ó sì dẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ nisinsinyi bí? Ní òdìkejì gẹlẹ, oun mú ìgbòkègbodò iwaasu rẹ̀ gbòòrò sí i nipa mímú ọ̀nà pọ̀n sí ìrìn àjò miiran sibẹ, ìkẹ́ta ní Galili. O ṣèbẹ̀wò sí gbogbo awọn ìlú-ńlá ati awọn ìletò ní àgbègbè naa, ní kíkọ́ni ní awọn sinagọgu ati wiwaasu ihinrere Ijọba naa. Ohun tí ó rí lasiko ìrìn àjò yii mú un gbàgbọ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ nipa àìní lati mú iṣẹ́ iwaasu naa gbónájanjan sí i.

Nibikibi tí Jesu bá lọ, oun ńrí awọn ogunlọgọ tí wọn nílò ìmúláradá nipa tẹ̀mí ati ìtùnú. Wọn dabi awọn àgùtàn láìsí olùṣọ́ àgùtàn, ti wọ́n jẹ kan eegun, ti wọn sì tú káàkiri, ó káàánú fun wọn. Ó sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe kò tó nǹkan. Nitori naa, ẹ gbadura si Oluwa ìkórè lati rán awọn alagbaṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

Jesu ní ìwéwèé kan fun ìgbésẹ̀. O pe awọn apọsiteli 12, awọn ẹni tí oun ti yàn ní nǹkan bi ọdun kan ṣaaju. Ó pín wọn sí meji-meji, tí ó jásí ẹgbẹ́ mẹfa ti nwaasu, ó sì fun wọn ní ìtọ́ni. Ó ṣàlàyé pe: “Ẹ maṣe lọ sí ọ̀nà awọn keferi, ẹ má sì ṣe wọ ilú awọn ara Samaria; ṣugbọn, ẹ kúkú tọ awọn àgùtàn ilé Isirẹli tí o nù lọ. Bí ẹyin ti ńlọ, ẹ maa waasu, wipe, ‘Ijọba ọrun ku si dẹdẹ.’”

Ijọba tí wọn nilati waasu nipa rẹ̀ yii ni Jesu kọ́ wọn lati maa gbadura fun ninu adura àwòṣe naa. Ijọba naa ti sunmọle níti pe Ọba tí Ọlọrun yàn, Jesu Kristi, wà níbẹ̀. Lati fìdí ẹ̀rí ìgbáralé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ múlẹ̀ gẹgẹ bi awọn aṣoju àkóso tí ó ga ju ti ẹ̀dá-ènìyàn lọ yẹn, Jesu fun wọn lágbára lati wo awọn aláìsàn sàn ati kódà kí wọn jí òkú dìde. O fun wọn ní ìtọ́ni lati mú awọn iṣẹ́ wọnyi ṣe lọ́fẹ̀ẹ́.

Lẹhin naa ni ó sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati maṣe ṣe awọn ìmúrasílẹ̀ nipa ti ara fun ìrìn àjò wiwaasu wọn. “Ẹ maṣe pèsè wúrà tabi fàdákà tabi idẹ sinu àsùwọ̀n yin, tabi àpò fun àjò yin, tabi ẹwu meji tabi bàtà tabi ọ̀pá kan; nitori ounjẹ òṣìṣẹ́ yẹ fun un.” Awọn tí wọn mọrírì ìhìn-iṣẹ́ naa yoo dáhùnpadà wọn yoo sì fi ounjẹ ati ilé gbígbé ṣe itilẹhin. Gẹgẹ bi Jesu ti wí: “Ìlúkílùú tabi ìletò-kíletò tí ẹyin bá wọ̀, ẹ wá ẹni tí ó bá yẹ nibẹ ri, nibẹ ni ki ẹ si gbe titi ẹyin yoo fi kuro nibẹ.”

Lẹhin naa ni Jesu fun wọn ní awọn ìtọ́ni nipa bí wọn ṣe lè gbé ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa yọ sí awọn onílé. “Nigba ti ẹ bá sì wọ inú ilé kan,” ni oun fun wọn ní ìtọ́ni, “ẹ kí i; bí ilé naa bá sì yẹ, kí alaafia yin kí ó bà sórí rẹ̀; ṣugbọn bí kò bá yẹ, kí alaafia yin kí ó padà sọ́dọ̀ yin. Ẹnikẹni tí kò bá sì gbà yin, tí kò sí gbọ́ ọ̀rọ̀ yin, nigba tí ẹyin bá jáde kuro ni ilé naa tabi ní ìlú naa, ẹ gbọn ekuru ẹsẹ̀ yin silẹ.”

Nipa ìlú-ńlá kan tí ó bá ṣá ìhìn-iṣẹ́ wọn tì, Jesu ṣí i payá pe ìdájọ́ rẹ̀ yoo múná nitootọ. Ó ṣàlàyé pe: “Lóòótọ́ ni mo wí fun yin, Yoo sàn fun ilẹ̀ Sodomu ati Gomora ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù fun ìlú naa lọ.” Matiu 9:35–10:15; Maaku 6:6-12; Luuku 9:1-5.

▪ Nigba wo ni Jesu bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò kẹta fun wiwaasu ní Galili, ki ni ohun tí eyi sì mú un gbàgbọ́?

▪ Nigba ti ó rán awọn apọsiteli rẹ̀ 12 jáde lati lọ waasu, ìtọ́ni wo ni oun fun wọn?

▪ Eeṣe tí ó fi yẹ fun awọn ọmọ-ẹhin lati kọ́ni pe Ijọba naa ti súnmọ́le?