Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsẹ́ni Ninu Àgbàlá

Ìsẹ́ni Ninu Àgbàlá

Orí 120

Ìsẹ́ni Ninu Àgbàlá

LẸHIN pipa Jesu tì ninu ọgbà Gẹtisemani ati sisalọ ninu ibẹru pẹlu iyoku awọn apọsiteli, Peteru ati Johanu dá sisa wọn duro. Boya wọn lé Jesu ba nigba ti a nmu un lọ si ile Anasi. Nigba ti Anasi fi i ranṣẹ sọdọ Alufaa Agba Kaifa, Peteru ati Johanu tẹle e ni okeere rere, o han gbangba pe ọkàn wọn pin laaarin ibẹru fun iwalaaye tiwọn funraawọn ati idaniyan jijinlẹ wọn niti ohun ti yoo ṣẹlẹ si Ọga wọn.

Ni dide si ile Kaifa ti o laye, Johanu lè ri aye wọle sinu agbala naa, niwọn bi oun ti jẹ ẹni mimọ alufaa àgbà. Peteru, bi o ti wu ki o ri, ni a fi silẹ ni iduro ni ẹnu ilẹkun lẹhin ode. Ṣugbọn laipẹ Johanu pada o sì ba oluṣọna naa sọrọ, iranṣẹ ọmọdebinrin kan, a sì gba Peteru laye lati wọle.

Nisinsinyi otútù nmu, awọn iranṣẹ onitọọju ile naa ati awọn oṣiṣẹ oloye alufaa agba ti dá ina eléèdú. Peteru darapọ mọ wọn lati maa mooru fẹẹrẹ nigba ti o nduro de abarebabọ iyẹwo ẹjọ Jesu. Nibẹ, ninu imọlẹ ina naa, oluṣọna ti o jẹ ki Peteru wọle wò ó daradara. “Iwọ pẹlu wa pẹlu Jesu ti Galili!” ni o ṣe saafula.

Bí inú ti bí i pe a dá a mọ̀, Peteru sẹ́ mimọ Jesu nigba kankan ri niwaju gbogbo wọn. “Emi kò mọ ohun ti iwọ nwi,” ni oun wi.

Lori koko yẹn, Peteru jade lọ si itosi ẹnubode. Nibẹ, ọmọdebinrin miiran kiyesi i, oun naa sì tun sọ fun awọn wọnni ti wọn nduro nitosi: “Ọkunrin yii wà pẹlu Jesu ti Nasarẹti.” Lẹẹkan sii, Peteru sẹ́ ẹ, ni bibura pe: “Emi kò mọ ọkunrin naa!”

Peteru duro ninu agbala naa, ni gbigbiyanju lati maṣe pe afiyesi bi o ti le ṣeeṣe tó. Boya ni ori koko yii ó tagìrì nigba ti akukọ kan kọ ninu okunkun owurọ kutukutu. Laaarin akoko naa, iyẹwo ẹjọ Jesu nlọ lọwọ, o han gbangba pe a nṣe e ni apakan ile loke àgbàlá naa. Laisi aniani Peteru ati awọn miiran ti wọn nduro nisalẹ ri wíwá ati lilọ oniruuru awọn ẹlẹrii ti wọn nwa lati jẹrii.

Nǹkan bii wakati kan ti kọja lati igba ti a ti da Peteru mọ gẹgẹ bi alabaakẹgbẹpọ Jesu. Nisinsinyi diẹ ninu awọn wọnni ti wọn duro nitosi sunmọ ọn wọn sì sọ pe: “Loootọ, ọkan ninu wọn ni iwọ nṣe, nitori pe ohùn rẹ fi ọ han.” Ọkan ninu awujọ naa jẹ ibatan Malkọs, ẹni ti Peteru gé eti rẹ̀ danu. “Emi kò ha ri ọ pẹlu rẹ̀ ní agbala?” ni oun wi.

“Emi kò mọ ọkunrin naa!” Peteru fi taratara tẹnumọ́ ọn. Niti tootọ, o gbiyanju lati mu wọn gbagbọ pe gbogbo wọn ṣe aṣiṣe nipa gígégùn ún ati bibura nipa ọran naa, ti o sì ntipa bayii pe ibi wa sori araarẹ̀ bi kii ba ṣe otitọ ni oun nsọ.

Ni gẹlẹ bi Peteru ṣe ṣe ìsẹ́ni kẹta yii, àkùkọ kọ. Ati ni iṣẹju yẹn, Jesu, ẹni ti o han gbangba pe o ti jade sita sí ọ̀dẹ̀dẹ̀ loke agbala naa, yida o sì wò ó. Lẹsẹkẹsẹ Peteru ranti ohun ti Jesu sọ ni kiki iwọnba wakati diẹ ṣaaju ninu iyara oke: “Ki àkùkọ too kọ lẹẹmeji, ani iwọ yoo sẹ́ mi ni igba mẹta.” Bi ìwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ̀ ọ́ lọ́rùn, Peteru jade sode o sì sọkun kíkorò.

Bawo ni eyi ṣe lè ṣẹlẹ? Pẹlu okun rẹ̀ nipa tẹmi ti o dá a loju tobẹẹ, bawo ni Peteru ṣe lè sẹ́ Ọ̀gá rẹ̀ lẹẹmẹta kiakia bẹẹ? Laisi iyemeji rárá ayika ipo naa ba Peteru lojiji. Wọn ti fi èrú yi otitọ po, Jesu ni wọn sì fihan gẹgẹ bi ọdaran tí ó buru jáì. Ohun ti o tọna ni a mu ki o farahan bii aitọna, alaiṣẹ alairo gẹgẹ bi ẹlẹbi ẹṣẹ. Nitori naa nitori awọn ikimọlẹ akoko naa, Peteru ṣi inu rò. Lojiji agbara òye iduroṣinṣin rẹ̀ ti o tọna dàrú: ibẹru eniyan pa á sara ti eyiini sì mu ibanujẹ wá bá a. Njẹ ki iyẹn maṣe ṣẹlẹ si wa lae! Matiu 26:57, 58, 69-75; Maaku 14:30, 53, 54, 66-72; Luuku 22:54-62; Johanu 18:15-18, 25-27.

▪ Bawo ni Peteru ati Johanu ṣe ri aye wọle sinu agbala alufaa agba?

▪ Nigba ti Peteru ati Johanu wà ninu agbala naa, ki ni o nlọ lọwọ ninu ile?

▪ Igba meloo ni àkùkọ kọ, ati niye igba meloo ni Peteru sẹ́ mimọ Kristi?

▪ Ki ni o tumọsi pe Peteru gégùn-ún o sì búra?

▪ Ki ni o mu ki Peteru sẹ́ pe oun mọ Jesu?