Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Ọmọkunrin Tí Ó Nù

Ìtàn Ọmọkunrin Tí Ó Nù

Orí 86

Ìtàn Ọmọkunrin Tí Ó Nù

JESU ti ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ríròhìn awọn àkàwé nipa jíjèrè àgùtàn kan ati fadaka kan tí ó nù fun awọn Farisi, Jesu nbaa lọ nisinsinyi pẹlu àkàwé miiran. Eyi jẹ́ nipa bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ati ìbálò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọkunrin rẹ̀ meji, tí ọkọọkan wọn sì ní awọn àríwísí ti o jinlẹ̀.

Lákọ̀ọ́kọ́, àbúrò ọmọkunrin nbẹ, pataki ènìyàn inú ìtàn àkàwé naa. Ó gbà ogún rẹ̀, eyi tí bàbá rẹ̀ fifún un láìṣetìkọ̀. Lẹhin naa ó fi ilé sílẹ̀ ó sì lọ́wọ́ nínú igbesi-aye oníwà pálapàla gan-an. Ṣugbọn fetisilẹ sí bí Jesu ṣe sọ ìtàn naa, kí o sì rí bí iwọ bá lè pinnu awọn ẹni tí a ní lọ́kàn pé awọn ènìyàn inú ìtàn naa dúró fún.

Jesu bẹ̀rẹ̀, “Ọkunrin kan ní ọmọkunrin meji. Eyi àbúrò ninu wọn wí fun bàbá rẹ̀ pé, “Bàbá, fun mi ní ìní rẹ tí ó kàn mi.’ [Bàbá naa] sì pín ohun ìní rẹ̀ fun wọn.” Ki ni eyi àbúrò yii ṣe pẹlu nǹkan tí ó gbà?

Jesu ṣàlàyé pe, “Kò sí tó ijọ́ melookan lẹhin naa, eyi àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, nibẹ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá.” Niti tootọ, ó ná owó rẹ̀ ní gbígbé pẹlu awọn aṣẹwo. Lẹhin naa awọn àkókò ìnira dé, gẹgẹ bi Jesu ti nbaa lọ lati ròhìn:

“Nigba ti ó ti ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tán, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ naa; ó sì bẹrẹsii di aláìní. Ó sì lọ, ó da araarẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ̀tọ̀ kan ní ilẹ̀ naa; oun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ lati tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ ounjẹ tí awọn ẹlẹ́dẹ̀ ńjẹ ní àjẹyó; ẹnikẹni kò sì fun un.”

Bawo ni ó ti rẹni nípò wálẹ̀ tó lati di ẹni tí a fipámú lati gbà iṣẹ́ olùṣọ́ agbo ẹlẹ́dẹ̀, niwọn bi awọn ẹran wọnyi ti jẹ́ aláìmọ́ gẹgẹ bi Òfin ti wí! Ṣugbọn ohun tí ó dùn ọmọkunrin naa julọ ni ebi ajánijẹ tí ó pa á débi pe ó fọkànfẹ́ oúnjẹ tí a fi ńbọ́ awọn ẹlẹ́dẹ̀ naa. Nitori àjálù ibi bíbanilẹ́rù rẹ̀, Jesu wipe, “ojú rẹ̀ wálẹ̀.”

Ní bíbá ìtàn rẹ̀ lọ, Jesu ṣàlàyé pe: “Ó ní, Awọn alágbàṣe bàbá mi mélòómélòó ni ó ńjẹ oúnjẹ àjẹyó, ati àjẹtì, emi sì ńkú fun ebi níhìn-ín. Emi yoo dìde, emi yoo sì tọ bàbá mi lọ, emi yoo sì wí fun un pe, Bàbá, emi ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run ati niwaju rẹ; emi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá maa pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bí ọ̀kan ninu awọn alágbàṣe rẹ. Ó sì dìde, ó sì tọ bàbá rẹ̀ lọ.”

Ohun kan niyi lati ronú nipa rẹ̀: Kání bàbá rẹ̀ ti gbéjàkò ó tí ó sì ti fi tìbínú tìbínú kígbé mọ́ ọn nigba ti ó nfi ilé sílẹ̀, kò dabi ẹni pe ọmọkunrin naa yoo ti mọ̀ ohun tí oun nilati ṣe. Ó lè ti pinnu lati padà kí ó sì gbìyànjú lati wá iṣẹ́ sí ibòmíràn ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ kí ó ma baa kò baba rẹ̀ lójú. Bí ó ti wù kí ó rí, irúfẹ́ ìrònú bẹẹ kò wá sí ọkàn rẹ̀. Ilé ni ó sáà ńfẹ́ lati wà!

Ní kedere, bàbá inú àkàwé Jesu dúró fun Bàbá wa ọ̀run, onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú, Jehofa Ọlọrun. Boya iwọ pẹlu sì mọ̀ pe ọmọkunrin tí ó nù tabi onínàákúnàá naa dúró fun awọn tí a mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀. Awọn Farisi, tí Jesu ńbá sọ̀rọ̀ ti bá Jesu wí niṣaaju fun bíbá awọn wọnyi jẹun. Ṣugbọn ta ni ọmọkunrin tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n dúró fun?

Nigba Ti A Rí Ọmọkunrin naa Tí Ó Nù

Nigba ti onínàákúnàá tabi ọmọkunrin tí ó nù ninu àkàwé Jesu padà lọ sí ilé bàbá rẹ̀, irú ìkínikáàbọ̀ wo ni oun rí gbà? Fetisilẹ bí Jesu ti ṣàpèjúwe rẹ̀:

“Nigba tí ó ṣì wà ní okeere, bàbá rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu.” Bàbá ọlọ́yàyà, aláàánú wo ni eyi, tí ó dúró fun Bàbá wa ọ̀run Jehofa, daradara tobẹẹ!

Ó ṣeeṣe kí bàbá naa ti gbọ́ nipa ìgbésí-ayé oníwọ̀bìà ti ọmọkunrin rẹ̀ ngbe. Sibẹ ó gbà á láìdúró fun kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé. Jesu pẹlu ní irúfẹ́ ẹ̀mí ìtẹ́wọ́gbani bẹẹ, ní gbígbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lati tọ awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ati awọn agbowó-orí lọ, awọn ẹni tí ọmọkunrin onínàáúnàá inu àkàwé naa dúró fun.

Nitootọ, bàbá olùwòyemọ̀ àkàwé Jesu láìsí iyèméjì mọ diẹ nipa ìrònúpìwàdà ọmọkunrin rẹ̀ nipa ṣíṣàkíyèsí ìrísí ojú rẹ̀ tí ó rẹ̀wẹ̀sì, tí ó sì fàro bí oun ṣe padà wá. Ṣugbọn ìdánúṣe onífẹ̀ẹ́ bàbá naa mú kí ó tubọ rọrùn fun ọmọkunrin naa lati jẹ́wọ́ awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bi Jesu ṣe ròhìn: “Ọmọ naa sì wí fun un pe, ‘Bàbá, emi ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run ati niwaju rẹ, emi kò sì yẹ ní ẹni ti a ba pè ni ọmọ rẹ mọ́ [“ṣe mí gẹgẹ bi ọ̀kan ninu awọn ọkunrin tí o háyà,” NW].’”

Sibẹ, ekukáká ni ọmọkunrin naa fi tíì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nigba ti bàbá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ní pípàṣẹ fun awọn ẹrú rẹ̀ pé: “Ẹ mu aayo aṣọ wa kankan, ki ẹ sì fi wọ̀ ọ́; ẹ sì fi oruka bọ̀ ọ́ lọwọ, ati bata si ẹsẹ rẹ̀: Ẹ sì mu ẹgbọrọ maluu abọpa wa, ki ẹ sì pa á; ki a maa jẹ, ki a sì maa ṣe ariya: Nitori ọmọ mi yii ti ku, o sì tún yè; o ti nù, a sì rí i.” Lẹhin naa wọn bẹrẹsii “ṣe ariya.”

Láàárín àkókò naa, ‘ọmọ rẹ̀ eyi ẹ̀gbọ́n’ ti bàbá naa ‘wà ni oko.’ Wò ó boya iwọ lè mọ ẹni tí oun dúró fún nipa fífetísílẹ̀ sí iyoku ìtàn naa. Jesu sọ nipa ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n naa pe: “Bí ó sì ti nbọ, ti o sunmọ eti ile, o gbọ́ orin oun ijo. O sì pe ọkan ninu awọn ọmọ ọdọ wọn, o beere, ki ni a mọ nnkan wọnyi si? O sì wi fun un pe, Aburo rẹ de; baba rẹ̀ si pa ẹgbọrọ maluu abọpa nitori ti o ri i pada ni alaafia ati ni ilera. O sì binu, o sì kọ̀ lati wọle: baba rẹ̀ sì jade, o sì wa ṣìpẹ̀ fun un. O sì dahun o wi fun baba rẹ̀ pe, Wòó, lati ọdun meloo wọnyi ni emi ti nsin ọ, emi kò sì rú ofin rẹ rí: iwọ kò sì tii fi ọmọ ewurẹ kan fun mi, lati fi ba awọn ọ̀rẹ́ mi ṣe ariya. Ṣugbọn nigba ti ọmọ rẹ yii de, ẹni ti o fi panṣaga run ọrọ̀ rẹ̀, iwọ sì ti pa ẹgbọrọ maluu abọpa fun un.”

Gẹgẹ bi ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n naa, ta ni ó ti ńṣe atako àánú ati àfiyèsí tí a fifún awọn ẹlẹ́ṣẹ̀? Kìí ha ṣe awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi ni bí? Niwọn bi ó ti jẹ́ pe atako ti wọn ṣe si Jesu nitori pe o tẹ́wọ́gbà awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó fà àkàwé yii, ní kedere wọn gbọdọ jẹ́ awọn tí ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n naa dúró fun.

Jesu pari ìtàn rẹ̀ pẹlu ẹ̀bẹ̀ tí bàbá naa ṣe fun ọmọkunrin rẹ̀ àgbà pé: “Ọmọ, nígbà gbogbo ni iwọ nbẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo si ni, tìrẹ ni; ó yẹ ki a ṣe ariya kí á sì yọ̀, nitori aburo rẹ yii ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù a sì rí i.”

Jesu tipa bayii fi ohun tí ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n naa ṣe silẹ láìyanjú. Nitootọ, lẹhin naa, lẹhin ikú ati ajinde Jesu, “ọpọ ninu ẹgbẹ awọn alufaa si fetisilẹ sí ìgbàgbọ́ naa,” tí ó ṣeeṣe kí ó ní diẹ lára ẹgbẹ́-agbo “ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n” tí Jesu ńbá sọ̀rọ̀ níhìn-ín ninu.

Ṣugbọn awọn wo ni awọn ọmọkunrin mejeeji naa dúró fún ní àkókò tiwa? Ó gbọdọ jẹ́ awọn wọnni tí wọn ti mọ̀ tó nipa awọn ète Jehofa lati ní ìpilẹ̀ fun wíwọ̀ inú ìbátan kan pẹlu rẹ̀. Ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n naa dúró fun diẹ lára awọn mẹmba “agbo kekere,” tabi “ijọ àkọ́bí tí a ti kọ orukọ wọn ní ọ̀run.” Awọn wọnyi ní ìrònú tí ó jọra pẹlu ti ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n naa. Wọn kò ní ìfẹ́-ọkàn kankan lati tẹ́wọ́gbà ẹgbẹ́ ti ayé kan, “awọn àgùtàn miiran,” tí wọn nímọ̀lára pe wọn ńjí àfiyèsí wọn gbà.

Ọmọkunrin onínàákúnàá naa, ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, dúró fun awọn wọnni ninu awọn eniyan Ọlọrun tí wọn lọ lati gbádùn awọn adùn tí ayé ńfi fúnni. Láìpẹ́, bí ó ti wù kí ó rí, awọn wọnyi fi ìrònúpìwàdà padà wọn sì di iranṣẹ alákitiyan lẹẹkan sí i fun Ọlọrun. Nitootọ, bawo ni Bàbá naa ti jẹ́ aláàánú ati onífẹ̀ẹ́ tó síhà awọn wọnni tí wọn mọ̀ àìní wọn fun ìdáríjì tí wọn sì padà sọ́dọ̀ rẹ̀! Luuku 15:11-32; Lefitiku 11:7, 8; Iṣe 6:7; Luuku 12:32; Heberu 12:23; Johanu 10:16.

▪ Awọn wo ni Jesu sọ àkàwé tabi ìtàn yii fun, eesitiṣe?

▪ Ta ni ènìyàn pataki inú ìtàn naa, ki ni ó sì ṣẹlẹ̀ sí i?

▪ Ta ni ní ọjọ́ Jesu ni bàbá ati ọmọkunrin tí ó jẹ́ àbúró dúró fun?

▪ Bawo ni Jesu ṣe ṣàfarawé apẹẹrẹ bàbá oníyọ̀ọ́nú inu àkàwé rẹ̀ naa?

▪ Ki ni ojú ìwòye ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n naa nipa títẹ́wọ́gbà arakunrin rẹ̀, bawo sì ni awọn Farisi ṣe hùwà bí ọmọkunrin ẹ̀gbọ́n naa?

▪ Ìfisílò wo ni àkàwé Jesu ní ní ọjọ́ wa?