Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtáṣìrí ati Ìfàṣẹ Ọba Muni

Ìtáṣìrí ati Ìfàṣẹ Ọba Muni

Orí 118

Ìtáṣìrí ati Ìfàṣẹ Ọba Muni

OTI kọja ọganju oru daadaa nigba ti Judasi ṣamọna ogunlọgọ awọn ọmọ ogun, awọn olori alufaa, awọn Farisi, ati awọn miiran wá sinu ọgba Gẹtisemani. Awọn alufaa ti fohunṣọkan lati san 30 owó fadaka fun Judasi lati taṣiiri Jesu.

Ni iṣaaju, nigba ti a le Judasi lọ kuro nibi ounjẹ Irekọja, lọna ti o han gbangba, o ti lọ ni taarata si ọdọ awọn olori alufaa. Awọn wọnyi pe awọn oṣiṣẹ oloye wọn jọ lẹsẹkẹsẹ, pẹlu agbo awọn ọmọ ogun. Boya Judasi ti kọkọ ṣamọna wọn lọ si ibi ti Jesu ati awọn apọsiteli rẹ ti ṣayẹyẹ Irekọja naa. Ni ṣiṣawari pe wọn ti kuro, ogunlọgọ naa ti wọn ru awọn ohun ija ti wọn sì gbe awọn fitila ati awọn ògùṣọ̀ tẹle Judasi jade kuro ni Jerusalẹmu sọda Afonifoji Kidironi.

Bi Judasi ti nṣamọna ọpọ eniyan ti nto lọ naa gun Òkè Olifi, o mọ̀ daju ibi ti oun yoo ti ri Jesu. Laaarin ọsẹ ti o kọja, bi Jesu ati awọn apọsiteli ti nrinrin ajo siwasẹhin laaarin Bẹtani ati Jerusalẹmu, niye igba ni wọn maa nduro ninu ọgba Gẹtisemani lati sinmi ati lati sọrọ pọ. Ṣugbọn, nisinsinyi, bi o ti ṣeeṣe pe Jesu ti wà ni ikọkọ ninu okunkun labẹ awọn igi olifi, bawo ni awọn ọmọ ogun yoo ṣe dá a mọ? Wọn lè ma tii ri i ri ṣaaju. Nitori naa, Judasi pese ami kan, ni sisọ pe: “Ẹni yoowu ti mo ba fi ẹnu ko lẹnu, oun ni; ẹ mú un lọ sinu iṣọ ipamọ ki ẹ sì fà á lọ laisewu.”

Judasi ṣamọna ogunlọgọ naa wa sinu ọgba naa, o rí Jesu pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀, o sì lọ taarata sọdọ rẹ̀. “Pẹlẹ o, Rabi!” ni o sọ o sì fi ẹnu ko o lẹnu lọna jẹlẹnkẹ gan-an.

“Àwé, fun ète wo ni iwọ fi wà nihin-in?” ni Jesu dahun. Lẹhin naa, ni didahun ibeere oun tikaraarẹ, o sọ pe: “Judasi, iwọ ha dà Ọmọkunrin eniyan pẹlu ifẹnukonu?” Ṣugbọn o tó gẹẹ fun olutaṣiiri rẹ̀! Jesu sunmọ iwaju sinu imọlẹ awọn ògùṣọ̀ ati fitila ti njo o sì beere pe: “Ta ni ẹyin nwa?”

“Jesu ara Nasarẹti,” ni idahun ti o wá naa.

“Emi ni oun,” ni Jesu fesipada, bi o ti duro pẹlu igboya niwaju wọn. Bi ẹnu ti yà wọn nipa aiṣojo rẹ̀ ati ni ṣiṣaimọ ohun ti wọn lè fojusọna fun, awọn ọkunrin naa fa sẹhin wọn sì ṣubu lulẹ.

“Mo sọ fun yin pe emi ni oun,” ni Jesu fi pẹlẹtu nba ọrọ rẹ lọ. “Nitori naa, bi o ba jẹ pe emi ni ẹ nwa, ẹ jẹ ki awọn wọnyi maa lọ.” Kete ṣaaju ìgbà naa ninu iyara oke, Jesu ti sọ fun Baba rẹ̀ ninu adura pe oun ti pa awọn apọsiteli oun oluṣotitọ mọ ko sì sí ọkan ninu wọn ti o ti sọnu “bikoṣe ọmọ iparun.” Nitori naa, ki ọrọ rẹ̀ ba lè ni imuṣẹ, o beere pe ki a jẹ ki awọn ọmọlẹhin oun lọ.

Bi ọkàn awọn ọmọ ogun naa ti balẹ lẹẹkan sii, ti wọn dide, ti wọn sì bẹrẹsii de Jesu, awọn apọsiteli naa mọ ohun ti o fẹ ṣẹlẹ. “Oluwa, ṣe ki a fi idà kọlu wọn?” ni wọn beere. Ki Jesu to fesi pada, Peteru, ni fifi agbara lo ọkan ninu awọn idà meji ti awọn apọsiteli ti muwa, gbejako Malkọs, ẹru alufaa àgbà. Peteru tase ori ẹru naa ṣugbọn o ké eti rẹ̀ ọtun kuro.

“Ẹ jẹ ki o mọ si ibi ti o de yii,” ni Jesu sọ gẹgẹ bi o ti dasi ọran naa. Ni fifi ọwọ kan eti Malkọs, ó wo ọgbẹ́ naa sàn. Nigba naa ni o kọnilẹkọọ pataki kan, ni pipaṣẹ fun Peteru pe: “Da idà rẹ pada si aye rẹ̀, nitori gbogbo awọn wọnni ti wọn gbé idà yoo ṣegbe nipa idà. Tabi iwọ ronu pe emi kò lè beere lọdọ Baba pe ki o fun mi nisinsinyi ni ohun ti o ju lejiọnu mejila awọn angẹli?”

Jesu ṣetan fun ifaṣẹ ọba muni naa, nitori o ṣalaye pe: “Bawo ni Iwe Mimọ yoo ṣe ni imuṣẹ pe o gbọdọ ṣẹlẹ ni ọna yii?” O sì fikun un: “Ago naa ti Baba ti fifun mi, emi kò ha nilati mú un lọnakọna bi?” Oun wà ni ifohunṣọkan patapata pẹlu ifẹ inu Ọlọrun fun un!

Nigba naa ni Jesu ba ogunlọgọ naa sọrọ. “Ẹyin ha jade wa pẹlu idà ati ọ̀gọ gẹgẹ bi si ọlọṣa lati fi aṣẹ ọba mu mi?” ni oun beere. “Lati ọjọ de ọjọ ni mo ti wà pẹlu yin ninu tẹmpili ti mo nkọni, sibẹ ẹ kò sì mú mi lọ sinu àhámọ́. Ṣugbọn gbogbo eyi ti ṣẹlẹ fun iwe mimọ awọn wolii lati ni imuṣẹ.”

Lori koko yẹn agbo ẹgbẹ awọn ọmọ ogun naa ati olori awọn ologun ati awọn oṣiṣẹ olóyè awọn Juu yara gbá Jesu mu wọn sì dè é. Ni riri eyi, awọn apọsiteli pa Jesu tì wọn sì salọ. Bi o ti wu ki o ri, ọdọmọkunrin kan—o jọ bi ẹni pe ọmọ ẹhin naa Maaku ni—duro laaarin ogunlọgọ naa. O lè ti wà ninu ile nibi ti Jesu ti ṣayẹyẹ Irekọja ati lẹhin igba naa ki o tẹle ogunlọgọ naa lati ibẹ. Nisinsinyi, bi o ti wu ki o ri, wọn dá a mọ̀, igbidanwo ni wọn sì ṣe lati gbá a mu. Ṣugbọn o fi ẹwu aṣọ ọ̀gbọ̀ rẹ̀ sẹhin o sì lọ kuro. Matiu 26:47-56; Maaku 14:43-52; Luuku 22:47-53; Johanu 17:12; 18:3-12, NW.

▪ Eeṣe ti Judasi fi ni imọlara idaniloju pe oun yoo ri Jesu ni ọgba Gẹtisemani?

▪ Bawo ni Jesu ṣe fi idaniyan fun awọn apọsiteli rẹ̀ han?

▪ Igbesẹ wo ni Peteru gbe ninu ìgbèjà Jesu, ṣugbọn ki ni Jesu sọ fun Peteru nipa rẹ̀?

▪ Bawo ni Jesu ṣe ṣipaya pe oun wà ni ifohunṣọkan patapata pẹlu ifẹ inu Ọlọrun fun oun?

▪ Nigba ti awọn apọsiteli pa Jesu tì, ta ni o duro, ki ni o sì ṣẹlẹ si i?