Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwàásù Tí O Lókìkí Julọ Tí A Tíì Fúnni Rí

Ìwàásù Tí O Lókìkí Julọ Tí A Tíì Fúnni Rí

Orí 35

Ìwàásù Tí O Lókìkí Julọ Tí A Tíì Fúnni Rí

IBI ìran naa jẹ́ ọ̀kan lára awọn mánigbàgbé julọ ninu ìtàn Bibeli: Jesu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè-ńlá kan, ó ńsọ Ìwàásù rẹ̀ olókìkí lórí Òkè naa. Ibi ìṣẹ̀lẹ̀ naa jẹ ìtòsí Òkun Galili, boya tí ó sunmọ Kapanaomu. Lẹhin lílò gbogbo òru ninu adura, Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn 12 lára awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati jẹ́ awọn apọsiteli. Lẹhin naa, pẹlu gbogbo wọn, oun wá sí ibi tí ó tẹ́jú yii lórí òkè-ńlá naa.

Ní bayii, ni iwọ yoo ronú, àárẹ̀ yoo ti mú Jesu gidigidi yoo sì fẹ́ oorun diẹ. Ṣugbọn awọn ogunlọgọ ńlá ti dé, awọn kan lati ibi jíjìnnà bíi Judia ati Jerusalẹmu, 60 sí 70 ibùsọ̀ sí ibẹ̀. Awọn miiran wá lati bèbè etí òkun Tire ati Sidoni tí ó wà ní ìhà àríwá. Wọn wá lati gbọ́ Jesu ati lati gba ìmúláradá fun awọn àìsàn wọn. Awọn ènìyàn kan tilẹ nbẹ tí awọn ẹ̀mí èṣù ńyọlẹ́nu, awọn angẹli buburu Satani.

Bí Jesu ti sọ̀kalẹ̀ wá, awọn aláìsàn sunmọ ọn lati fọwọ́ kàn án, ó sì mú gbogbo wọn láradá. Lẹhin eyiini, ó hàn gbangba pe Jesu gòkè lọ sí ibi tí ó ga sí i lórí òkè-ńlá naa. Nibẹ ni ó jókòó sí tí ó sì bẹrẹsii kọ́ ogunlọgọ tí wọn tẹ́rẹrẹ kárí ibi títẹ́jú naa niwaju rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Sì ronú nipa rẹ̀ ná! Nisinsinyi kò tilẹ sí eniyan kanṣoṣo ninu àwùjọ naa tí ó ńjìyà lọwọ àìlera ara kan ti o lewu rinlẹ!

Awọn ènìyàn ńháragàgà lati gbọ́ olùkọ́ naa tí ó lágbára lati ṣe awọn iṣẹ́ ìyanu tí nyanilẹnu wọnyi. Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, sọ ìwàásù rẹ̀ ní pàtàkì julọ fun àǹfààní awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, tí ó ṣeeṣe pe awọn ni wọn kórajọpọ̀ sunmọ ọn julọ. Ṣugbọn nitori kí awa pẹlu lè jàǹfààní pẹlu, Matiu ati Luuku ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀.

Akọsilẹ Matiu nipa ìwàásù naa gùn ní nǹkan bíi ìlọ̀po mẹrin ju ti Luuku lọ. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, apákan awọn ohun tí Matiu kọsílẹ̀, ni Luuku fihàn pe wọn jẹ́ eyi tí Jesu sọ ní àkókò miiran láàárín iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀, gẹgẹ bi a ti lè ṣakiyesi nipa fífi Matiu 6:9-13 wéra pẹlu Luuku 11:1-4, ati fífi Matiu 6:25-34 wéra pẹlu Luuku 12:22-31. Sibẹ kò yẹ kí eyi yanilẹ́nu. Jesu bí ó ti ṣe kedere kọ́ni ní awọn ohun kan naa ju ẹẹkanṣoṣo lọ, Luuku sì yàn lati ṣàkọsílẹ̀ lára awọn ẹ̀kọ́ wọnyi pẹlu ìgbékalẹ̀ ọ̀tọ̀.

Ohun tí ó mú kí ìwàásù Jesu ṣe iyebíye tobẹẹ kii ṣe kìkì jíjinlẹ̀ ohun tí ó ní ninu nipa tẹ̀mí ṣugbọn ọ̀nà tí ó rọrùn tí ó sì ṣe kedere tí oun gbà gbé otitọ wọnyi kalẹ̀. Oun lo awọn ìrírí tí kò ṣàjèjì ati awọn ohun tí awọn ènìyàn mọ̀ dunjú, tí ó tipa bẹẹ mú kí awọn èrò rẹ̀ rọrùn lati yé gbogbo awọn tí wọn ńwá igbesi-aye tí ó sànjù kiri lọna ti Ọlọrun.

Awọn Wo Ni Aláyọ̀ Nitootọ?

Olukuluku fẹ́ lati jẹ́ aláyọ̀. Ní mímọ eyi, Jesu bẹ̀rẹ̀ Ìwàásù rẹ̀ orí Òkè nipa ṣíṣàpèjúwe awọn wọnni tí wọn jẹ́ aláyọ̀ nitootọ. Gẹgẹ bi a ti lè foju inu wòye, eyi lẹsẹkẹsẹ gba àfiyèsí awọn olùgbọ́ rẹ̀ pupọ rẹpẹtẹ. Sibẹ awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ iṣaaju ti nilati dabi ìtakora lójú ọpọlọpọ.

Ní dídarí awọn àlàyé rẹ̀ sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ bayii: “Aláyọ̀ ni ẹyin òtòṣì, nitori tiyin ni ijọba Ọlọrun. Aláyọ̀ ni ẹyin tí ebi ńpa nisinsinyi, nitori pe ẹ ó yó. Aláyọ̀ ni ẹyin tí ńsunkún nisinsinyi, nitori pe ẹ ó rẹ́rìn-ín. Aláyọ̀ ni ẹyin nigbakigba tí awọn ènìyàn bá kórìíra yin. . . . Ẹ yọ̀ ní ọjọ́ naa kí ẹ sì fòsókè, nitori, ẹ wò ó! èrè yin pọ̀ ní ọ̀run.”

Eyi ni ìròhìn Luuku nipa ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwàásù Jesu. Ṣugbọn gẹgẹ bi akọsilẹ Matiu ti wí, Jesu tún sọ pẹlu pe awọn ọlọ́kàn tútù, awọn aláàánú, awọn tí ọkàn-àyà wọn mọ́gaara ati awọn ẹni tí ńwá alaafia jẹ́ aláyọ̀. Awọn wọnyi jẹ́ aláyọ̀, ni Jesu wi, nitori pe wọn yoo jogún ilẹ̀-ayé, a ó fi àánú hàn fun wọn, wọn yoo rí Ọlọrun, a ó sì maa pè wọn ní awọn ọmọkunrin Ọlọrun.

Ohun tí Jesu ní lọ́kàn nipa jíjẹ́ aláyọ̀, bí ó ti wù kí ó rí, kii ṣe wíwulẹ̀ jẹ́ adẹ́rìn-ínpani tabi aláwàdà, gẹgẹ bi ìgbà tí ẹnikan bá ńdá àpárá. Ayọ tootọ jinlẹ̀ jù bẹẹ lọ, ó ní ninu èrò ẹ̀mí ìtẹ́lọ́rùn, ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn ati àṣeyọrí ninu igbesi-aye.

Nitori naa awọn wọnni tí wọn jẹ́ aláyọ̀ nitootọ, ni Jesu fihàn, jẹ́ awọn ènìyàn tí wọn rí àìní wọn nipa tẹ̀mí kedere, wọn banújẹ́ nipa ipò tí ó kún fun ẹ̀ṣẹ̀ tí wọn wà, tí wọn sì wá mọ Ọlọrun tí wọn sì ńṣiṣẹ́sìn ín. Lẹhin naa, àní bí a bá tilẹ kórìíra wọn tí a sì ṣe inúnibíni sí wọn fun ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, wọn jẹ́ aláyọ̀ nitori wọn mọ̀ pe awọn ńmú inú Ọlọrun dùn tí wọn yoo sì rí èrè rẹ̀ ti ìyè ainipẹkun gbà.

Bí ó ti wù kí ó rí, ọpọlọpọ ninu awọn olùgbọ́ Jesu, gan-an gẹgẹ bi awọn ènìyàn kan ti rí lonii, gbàgbọ́ pe jíjẹ́ aláásìkí ati gbígbádùn awọn adùn ni ohun tí ó ńmú kí ẹnikan jẹ́ aláyọ̀. Jesu mọ̀ pe kò rí bẹẹ. Ní fífa ìyàtọ̀ kan jáde tí yoo ya ọpọlọpọ awọn olùgbọ́ rẹ̀ lẹ́nu, ó wipe:

“Ègbé ni fun ẹyin eniyan ọlọ́rọ̀, nitori pe ẹyin ńní ìtùnú yin ní kíkún. Ègbé ni fun ẹyin tí ẹ yó nisinsinyi, nitori ebi yoo pa yin. Ègbé, ẹyin tí ńrẹ́rìn-ín nisinsinyi, nitori ẹ o ṣọ̀fọ̀ ẹ ó sì sunkún. Ègbé, nigbakigba tí gbogbo ènìyàn bá ńsọ̀rọ̀ daradara nipa yin, nitori nǹkan bí iwọnyi ni ohun tí awọn babanla wọn ṣe sí awọn wolii èké.”

Ki ni Jesu ní lọ́kàn? Eeṣe tí níní ọrọ̀, fífi tẹ̀ríntẹ̀rín lépa awọn adùn, ati gbígbádùn ìhó-ìyìn awọn ènìyàn yoo fi fa ègbé? Ó jẹ́ nitori pe nigba ti ẹnikan bá ní tí ó sì ńṣìkẹ́ awọn wọnyi, nigba naa iṣẹ́-ìsìn sí Ọlọrun, tí ó jẹ́ ohun kanṣoṣo tí ńmú ayọ̀ tootọ wá, yoo yọ kúrò ninu igbesi-aye rẹ̀. Lẹsẹ kan naa, Jesu kò ní in lọ́kàn pe wíwulẹ̀ jẹ́ òtòṣì, ẹni tí ebi ńpa, tí ó kún fun ọ̀fọ̀ ńsọ ẹnikan di aláyọ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, bí ó ti wù kí ó rí, irú awọn ènìyàn tí kò ní àǹfààní bẹẹ lè dáhùnpadà sí awọn ẹ̀kọ́ Jesu tí a ó sì tipa bẹẹ bukun wọn pẹlu ayọ̀ tootọ.

Lẹhin eyiini, ní dídarí ọ̀rọ̀ sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu wipe: “Ẹyin ni iyọ̀ ilẹ̀-ayé.” Oun kò ní in lọ́kàn dajudaju, pe wọn jẹ́ iyọ̀ gidi gan-an. Kàkà bẹẹ, iyọ̀ jẹ́ ohun tí a fi ńtọ́jú nǹkan pamọ́ kuro lọwọ ìdíbàjẹ́. Òkìtì ńlá rẹ̀ nbẹ nítòsí pẹpẹ ní tẹmpili Jehofa, awọn alufaa tí wọn ńbójútó iṣẹ nibẹ sì maa ńlò ó lati fi iyọ̀ dun awọn ọrẹ ẹbọ.

Awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni “iyọ̀ ilẹ̀-ayé” niti pe wọn ní agbára ìtọ́júpamọ́ kuro lọwọ ìdíbàjẹ́ lórí awọn ènìyàn. Nitootọ, ìhìn-iṣẹ́ naa tí wọn múwá yoo tọ́jú iwalaaye gbogbo awọn ẹni tí wọn bá dáhùnpadà sí i! Yoo mú animọ ti o wà pẹ́títí, ti o dúróṣinṣin, ati ti ìṣòtítọ́ wá sínú igbesi-aye irúfẹ́ awọn ènìyàn bẹẹ, ní ṣíṣe ìdíwọ́ fun rírà nipa tẹ̀mí ti ọ̀nà ìwàhíhù eyikeyii ninu wọn.

“Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé,” ni Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Fìtílà kan ni a kìí fi sí abẹ́ agbọ̀n kan ṣugbọn a maa ńgbé ka orí ọ̀pá-fìtílà, nitori naa Jesu wipe: “Bẹẹ gẹ́gẹ́ ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yin mọ́lẹ̀ niwaju ènìyàn.” Awọn ọmọ-ẹhin Jesu ńṣe eyi nipasẹ ìjẹ́rìí wọn ní gbangba, ati pẹlu nipa ṣíṣiṣẹ́sìn gẹgẹ bi awọn apẹẹrẹ dídán ninu ìwà tí ó bá awọn ìlànà ìpìlẹ̀ Bibeli mu.

Ọ̀pá-ìdiwọ̀n Gíga kan fun Awọn Ọmọlẹhin Rẹ̀

Awọn aṣaaju ìsìn ka Jesu sí olùré Òfin Ọlọrun kọjá wọn sì dìmọ̀lù láìpẹ́ yii lati pa á. Nitori naa bí Jesu ti ńbá Ìwàásù lórí Òkè rẹ̀ nìṣó, oun ṣàlàyé pe: “Ẹ maṣe rò pe emi wá lati pa Òfin tabi awọn Wolii run. Emi wá, kii ṣe lati parun, bikoṣe lati múṣẹ.”

Jesu ní ọ̀wọ̀ tí ó ga jùlọ fun Òfin Ọlọrun ó sì rọ awọn ẹlomiran lati ní irúfẹ́ ọ̀wọ̀ kan naa pẹlu. Niti gàsíkíá, oun wipe: “Nitori naa ẹni yoowu tí ó bá rú ọ̀kan ninu awọn òfin kekere julọ wọnyi tí ó sì kọ́ aráyé lẹ́kọ̀ọ́ lati ṣe bẹẹ, oun ni a ó pè ní ‘ẹni kekere julọ’ niti ijọba awọn ọ̀run,” eyi tí ó tumọsi pe irúfẹ́ ẹni bẹẹ kì yoo wọ inú Ijọba naa rárá.

Jìnnà patapata sí ṣíṣàìka Òfin Ọlọrun sí, Jesu tilẹ ti dẹ́bi fún awọn àṣà tí ńdákún kí ẹnikan rú wọn. Lẹhin ṣíṣàkíyèsí pe Òfin naa sọ pe, “Iwọ kò gbọdọ pànìyàn,” Jesu fikun un pe: “Bí ó ti wù kí ó rí, emi wí fun un yin pe ẹnikẹni tí ó ba nbaa lọ lati kún fun ìkannúbínú sí arakunrin rẹ̀ yoo jíhìn niwaju ilé ẹjọ́ ìdájọ́ òdodo.”

Niwọn bi bibaa lọ lati kún fun ìkannúbínú sí olùbákẹ́gbẹ́ kan ti léwu ninu tobẹẹ, àní boya tí ó lè ṣamọ̀nà sí ìpànìyàn, Jesu ṣàkàwé bí a ó ti lọ jìnnà tó kí ọwọ́ baa lè tẹ alaafia. Oun fúnni ní ìtọ́ni pe: “Nigba naa, bí iwọ bá mú ẹ̀bùn [ẹbọ] rẹ̀ wá sí ibi pẹpẹ tí iwọ sì ranti nibẹ pe arakunrin rẹ ní ohun kan sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ silẹ nibẹ niwaju pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá alaafia pẹlu arakunrin rẹ, ati lẹhin naa, nigba ti o bá padà dé, bun ẹ̀bùn rẹ.”

Ní pípe àfiyèsí sí ekeje ninu Òfin Mẹ́wàá naa, Jesu nbaa lọ: “Ẹyin gbọ́ tí a wipe, ‘Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣágà.’” Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu dẹ́bi fún kódà ẹ̀mí-ìrònú tí nsinni lọ siha panṣágà. “Emi wí fun yin pe olukuluku ẹni tí ó ba tẹramọ́ wíwo obinrin kan nitori kí ó baa lè ní ìfẹ́ àìníjàánu sí i ti bá a ṣe panṣágà tán ninu ọkàn-àyà rẹ̀.”

Jesu kò sọ̀rọ̀ níhìn-ín nipa èrò pálapàla ti kò dúró pẹ́ kan ṣugbọn ‘bibaa lọ ní wíwò.’ Irúfẹ́ wíwò tí ó nbaa lọ bẹẹ maa ńta ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbígbóná jí, eyi tí, bí àǹfààní rẹ̀ bá ṣísílẹ̀, lè yọrísí panṣágà. Bawo ni ẹnikan ṣe lè dènà eyi? Jesu ṣàkàwé bí awọn ìgbésẹ̀ tí ó dé góńgó ṣe lè pọndandan, ní wiwi pe: “Nisinsinyi, bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọdọ rẹ. . . . Pẹlupẹlu, bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kuro kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọdọ rẹ.”

Awọn ènìyàn saba maa ńfẹ́ lati fi ẹ̀yà ara ti nṣaisan gidi kan rúbọ lati lè gba ẹ̀mí wọn là. Ṣugbọn gẹgẹ bi Jesu ti wí, àní ó tilẹ tún ṣe pàtàkì ju lati “sọ” ohunkohun “nù,” kódà ohun kan tí ó ṣe iyebíye bí ojú kan tabi ọwọ́ kan, lati lè yẹra fún èrò ati awọn ìgbésẹ̀ pálapàla. Àìjẹ́ bẹẹ, gẹgẹ bi Jesu ti ṣàlàyé, awọn ẹni naa ni a ó jù sínú Gẹhẹna (òkìtì ààtàn kan tí ńjó nítòsí Jerusalẹmu), eyi tí ó ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé.

Pẹlupẹlu Jesu tún jíròrò bí a ó ṣe bá awọn ènìyàn tí wọn nṣe awọn ẹlomiran léṣe ti wọn sì nṣe láìfí lò. “Ẹ maṣe dènà ẹni burúkú,” ni ìmọ̀ràn rẹ̀. “Ṣugbọn ẹni yoowu tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ekeji sí i pẹlu.” Jesu kò ní in lọkan pe ẹnikan kò nilati gbèjà araarẹ̀ tabi idile rẹ̀ bí a bá gbéjàkò wọn. A kìí gbá ẹnikan lábàrá lati pa á lára niti ara-ìyára ṣugbọn, kàkà bẹẹ, lati fi ìwọ̀sí lọni. Nitori naa, ohun tí Jesu ńsọ ni pe bí ẹnikẹni bá gbìyànjú lati dá ìjà tabi àríyànjiyàn silẹ, yala nipasẹ yíyàka gbá ẹnikan lábàrá niti gidi tabi nipa kikọluni pẹlu awọn ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí, yoo ṣàìtọ́ lati gbẹ̀san.

Lẹhin pípe àfiyèsí sí òfin Ọlọrun lati fẹran aládùúgbò ẹni, Jesu wipe: “Bí ó ti wù kí ó rí, emi wí fun un yin: Ẹ maa baa lọ lati nífẹ̀ẹ́ awọn ọ̀tá yin ati lati gbàdúrà fun awọn wọnni tí ńṣe inúnibíni sí yin.” Ní pípèsè ìdí alágbára fun ṣíṣe bẹẹ, ó fikun un pe: “[Nipa bayii] ẹyin lè fi araayin hàn bíi ọmọkunrin Baba yin tí nbẹ ninu awọn ọ̀run, niwọn bi oun ti ńmú kí oòrùn rẹ̀ ran sórí awọn ènìyàn burúkú ati daradara.”

Jesu pari apá ìwàásù rẹ̀ yii nipa ṣíṣínilétí pe: “Bẹẹ gẹ́gẹ́ ẹyin gbọdọ pé, bí Baba yin ọ̀run ti pé.” Jesu kò ní in lọ́kàn pe awọn ènìyàn lè jẹ́ pípé ní ìtumọ̀ rẹ̀ patapata. Kàkà bẹẹ, wọn lè jẹ́ bẹẹ, nipa ṣíṣàfarawé Ọlọrun, mímú ìfẹ́ wọn gbòòrò àní dé ọ̀dọ̀ awọn ọ̀tá wọn. Ìròhìn Luuku lórí ọ̀ràn yii ṣàkọsílẹ̀ awọn ọ̀rọ̀ Jesu lọna yii: “Ẹ maa baa lọ lati jẹ́ aláàánú gẹgẹ bi Baba yin ti jẹ́ aláàánú.”

Adura, ati Ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ Ninu Ọlọrun

Bí Jesu ti ntẹsiwaju pẹlu ìwàásù rẹ̀, oun dá àgàbàgebè awọn ènìyàn tí wọn nṣe àṣehàn ìwà-bí-Ọlọrun ti a fi ẹnu pe bẹẹ lẹ́bi. “Nigba ti iwọ bá lọ bùn ẹ̀bùn àánú,” ni oun wí, “maṣe fun ìpè ṣaaju rẹ, gan-an gẹgẹ bi awọn àgàbàgebè ti ńṣe.”

“Pẹlupẹlu,” ni Jesu nbaa nìṣó, “nigba ti ẹyin bá ńgbàdúrà, ẹ kò gbọdọ dabi awọn àgàbàgebè; nitori wọn fẹ́ lati gbàdúrà ní ìdúró ninu sinagọgu ati ní igun awọn ọ̀nà fífẹ̀ kí awọn ènìyàn ba lè rí wọn.” Kàkà bẹẹ, ó fúnni ní ìtọ́ni pe: “Nigba ti ẹyin bá ńgbàdúrà, ẹ lọ sinú iyàrá àdání yin ati, lẹhin tí ẹyin bá ti sé ilẹ̀kùn, ẹ gbàdúrà sí Baba yin tí nbẹ ní ìkọ̀kọ̀.” Jesu fúnraarẹ̀ gba awọn adura ìta gbangba, nitori naa oun kò dá awọn wọnyi lẹ́bi. Ohun tí oun kọ̀ ni awọn adura tí a gbà lati wú awọn olùfetísílẹ̀ lórí ti a sì fi fa ìyìn ìkésáàfúlà wọn mọ́ra.

Jesu gbani nímọ̀ràn siwaju síi: “Nigba ti iwọ bá ńgbàdúrà, maṣe wí ohun kan naa ní àwítúnwí, gan-an gẹgẹ bi awọn ènìyàn awọn orílẹ̀-èdè ti ńṣe.” Jesu kò ní in lọ́kàn pe àtúnwí ninu araarẹ̀ ṣàìtọ́. Nigba kan ri, Jesu fúnraarẹ̀ ti lò “ọ̀rọ̀ kan naa” leralera nigba ti ó ngbadura. Ṣugbọn ohun tí oun kò tẹ́wọ́gbà ni sisọ awọn gbólóhùn tí a ti há sórí “ní àwítúnwí,” gẹgẹ bi awọn wọnni tí wọn maa ńfi ìka ka ìlẹ̀kẹ̀ ti maa ńṣe bí wọn ti ńsọ àtúnsọ awọn adura wọn nipasẹ àkàsórí.

Lati ran awọn olùfetísílẹ̀ rẹ̀ lọwọ lati gbadura, Jesu pèsè adura àwòṣe kan tí ó ní awọn ibeere meje ninu. Awọn mẹta àkọ́kọ́ gẹgẹ bi ó ti tọ́ jẹ́wọ́ ẹ̀tọ́ Ọlọrun gẹgẹ bi ọba-aláṣẹ ati awọn ète rẹ̀. Wọn jẹ́ awọn ibeere pe kí a sọ orukọ Ọlọrun di mímọ́, pe kí Ijọba rẹ̀ dé, kí ìfẹ́-inú rẹ̀ sì di ṣíṣe. Awọn mẹrin tí ó ṣẹ́kù jẹ́ awọn ibeere ara-ẹni, eyiini ni, fun ounjẹ ojoojumọ, ìdáríjì awọn ẹ̀ṣẹ̀, kí a máṣe dẹniwò rékọjá ìfaradà ẹni, ati pe kí a maṣe fi wá lé ẹni burúkú nì lọwọ.

Ní titẹsiwaju, Jesu darí àfiyèsí sí ìdẹkùn fífi ìtẹnumọ́ tí kò yẹ sórí awọn ohun ìní ti ara. Ó rọni pe: “Ẹ dẹkun títo ìṣura jọ fun araayin lórí ilẹ̀-ayé, níbi tí kòkòrò ajẹgijaṣọ ati ìpẹta ńjẹ ẹ́ run, ati níbi tí awọn olè ńfọ́lé tí wọn sì ńjalè.” Kii ṣe kìkì pe irúfẹ́ awọn ìṣura bẹẹ lè parun nikan ni ṣugbọn wọn kìí gbé iyì kankan ró pẹlu Ọlọrun.

Nitori bẹẹ, Jesu wipe: “Kàkà bẹẹ, ẹ to ìṣura jọ fun araayin ní ọ̀run.” Eyi ni a ńṣe nipasẹ fífi iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun ṣaaju ninu igbesi-aye. Kò sí ẹnikẹni tí ó lè gba iyì-ẹ̀yẹ ti a tipa bayii tojọ pẹlu Ọlọrun tabi èrè rẹ̀ gigalọla kuro. Lẹhin naa ni Jesu fikun un pe: “Níbití ìṣura rẹ bá wà, nibẹ ni ọkàn-àyà rẹ yoo wà pẹlu.”

Ní ṣiṣalaye siwaju sí i lórí ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, Jesu fúnni ní àkàwé naa: “Fìtílà ara ni ojú ìríran. Nigba naa, bí ojú ìríran rẹ bá gbébìkan, gbogbo ara rẹ ni yoo mọ́lẹ̀; ṣugbọn bí ojú ìríran rẹ bá jẹ́ buruku, gbogbo ara rẹ ni yoo ṣókùnkùn.” Ojú ìríran tí ńṣiṣẹ́ lọna títọ̀nà fun ara dabi fìtílà kan tí a tàn ní ibi òkùnkùn. Ṣugbọn lati lè ríran lọna tí ó tọ̀nà, ojú ìríran gbọdọ gbébìkan, eyiini ni pe, ó gbọdọ kóríjọ sórí ohun kan. Ojú ìríran tí kìí kóríjọ maa ńṣamọ̀nà sí àṣìṣe ìdíyelé awọn nǹkan, lati fi awọn ìlépa ohun ti ara ṣaaju iṣẹ́-ìsìn sí Ọlọrun, eyi tí ó maa ńyọrísí sísọ “gbogbo ara” di òkùnkùn.

Jesu mú kókó ọ̀rọ̀ yii wá sí òtéńté pẹlu àkàwé alágbára kan: “Kò sí ẹni kankan tí ó lè sinrú fun ọ̀gá meji; nitori yálà oun yoo kórìíra ọ̀kan yoo sì nífẹ̀ẹ́ ekeji, tabi oun yoo faramọ́ ọ̀kan yoo sì tẹ́ḿbẹ́lú ekeji. Ẹyin kò lè sinrú fun Ọlọrun ati fun Ọrọ̀.”

Lẹhin fífúnni ní ìmọ̀ràn yii, Jesu fun awọn olufetisilẹ rẹ̀ ní ìdánilójú pe kò yẹ kí wọn ṣàníyàn nipa awọn àìní ti ara tí wọn bá fi iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun ṣaaju. “Ẹ fi tọkàntọkàn ṣàkíyèsí awọn ẹyẹ ojú ọ̀run,” ni oun wí, “nitori pe wọn kìí fúnrúgbìn tabi kórè tabi kójọ sínú àká; sibẹ Baba yin ọ̀run ńbọ́ wọn.” Lẹhin naa ni ó beere pe: “Ẹyin kò ha níyelórí jù wọn lọ?”

Lẹhin naa Jesu tọ́kasí awọn òdòdò lili inú pápá, ó sì ṣàkíyèsí pe “Solomoni pàápàá ninu gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ gẹgẹ bi ọ̀kan ninu awọn wọnyi. Nisinsinyi,” ni oun nbaa lọ, “bi Ọlọrun bá wọ ewéko ìgbẹ́ ní aṣọ bayii, . . . oun kì yoo ha kúkú wọ̀ yin ní aṣọ jù bẹẹ lọ, ẹyin oní-kékeré ìgbàgbọ́?” Nitori naa Jesu pari ọ̀rọ̀ rẹ bayii: “Nitori naa ẹ maṣe ṣàníyàn láé kí ẹ sì wipe, ‘Ki ni awa yoo jẹ?’ tabi, ‘Ki ni awa yoo mu?’ tabi, ‘Ki ni awa yoo wọ̀?’ . . . Nitori Baba yin ọ̀run mọ̀ pe ẹ nílò gbogbo nǹkan wọnyi. Ẹ maa baa nìṣó, nigba naa, ní wíwá ijọba naa lákọ̀ọ́kọ́ ati òdodo rẹ̀, gbogbo nǹkan miiran wọnyi ni a ó sì fikun un fun yin.”

Ọ̀nà sí Ìyè

Ọ̀nà sí ìyè jẹ́ fífi ìṣòtítọ́ tẹle awọn ẹ̀kọ́ Jesu. Ṣugbọn eyi kò rọrùn lati ṣe. Awọn Farisi, fun apẹẹrẹ, ní ìtẹ̀sí lati ṣè ìdájọ́ awọn ẹlomiran lọna lílekoko, ṣiṣeeṣe naa si wà pe ọpọlọpọ ṣàfarawé wọn. Nitori naa bí Jesu ti ńbá Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè nìṣó, oun funni ni ìṣínilétí yii pe: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣèdájọ́ kí a ma baa ṣèdájọ́ yin; nitori irú ìdájọ́ tí ẹyin bá ńṣe, ni a ó fi ṣèdájọ́ yin.”

Ó léwu lati tẹ̀lé apẹẹrẹ awọn Farisi ti nfi òfíntótó bániwí lọna àṣejù. Ní ìbamu pẹlu ìròhìn Luuku, Jesu ṣàkàwé ewu yii nipa wiwi pe: “Afọ́jú kò lè ṣamọ̀nà afọ́jú, ó lè ṣe bẹẹ bí? Awọn mejeeji yoo ṣubú sínú kòtò, wọn kì yoo ha ṣe bẹẹ bí?”

Jíjẹ́ ẹni olofintoto nipa awọn ẹlomiran lọna àṣejù, sísọ awọn àṣìṣe di bàbàrà kí a sì yàn wọn sọjú, jẹ́ láìfí wíwúwo kan. Nitori naa Jesu beere pe: “Bawo ni iwọ ṣe lè wí fun arakunrin rẹ̀, ‘Yọnda fun mi lati yọ ègé-koríko kuro ní ojú ìríran rẹ’; nigba ti, wòó! Ìtì igi kan nbẹ ní ojú ìríran iwọ fúnraàrẹ? Àgàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ ìtì igi kuro ní ojú ìríran tìrẹ fúnraàrẹ, nigba naa ni iwọ yoo sì ríran ní kedere bí iwọ yoo ṣe yọ ègé-koríko kuro ní ojú ìríran arakunrin rẹ.”

Eyi kò tumọsi pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu kò nilati lò ìwòyemọ̀ ninu ibalo wọn pẹlu awọn ẹlomiran, nitori oun wipe: “Ẹ maṣe fi ohun mímọ́ fun awọn ajá, bẹẹ ni kí ẹ má sì sọ peali yin síwájú awọn ẹlẹ́dẹ̀.” Otitọ lati inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ mímọ́. Wọn dabi awọn peali ìṣàpẹẹrẹ. Ṣugbọn bí awọn kan, tí wọn dabi ajá tabi ẹlẹ́dẹ̀, kò bá fi ìmọrírì hàn fun awọn otitọ iyebíye wọnyi, awọn ọmọ-ẹhin Jesu nilati fi awọn ènìyàn bẹẹ silẹ kí wọn sì wá awọn wọnni tí wọn ṣetán láti gbà.

Bí ó tilẹ jẹ́ pe Jesu ti jíròrò adura ṣaaju ninu Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, oun wá tẹnumọ́ àìní naa lati tẹramọ́ ṣíṣe é nisinsinyi. “Ẹ maa baa nìṣó ní bibeere,” ni oun rọni, “a ó sì fifún un yin.” Lati ṣe àkàwé ìmúratán Ọlọrun lati dáhùn awọn adura, Jesu beere pe: “Ta ni ọkunrin naa láàárín yin tí ọmọ rẹ beere búrẹ́dì—oun kì yoo fi òkúta lé e lọ́wọ́, oun yoo ṣe bẹẹ bí? . . . Nitori naa bí ẹyin, tí ẹ tilẹ jẹ́ ènìyàn buruku, bá mọ bí a ti ńfi ẹ̀bùn daradara fun awọn ọmọ yin, meloomeloo ju bẹẹ lọ ni Baba yin tí nbẹ ninu awọn ọ̀run yoo fi awọn nǹkan daradara fun awọn wọnni tí nbeere lọdọ rẹ̀?”

Lẹhin eyi ni Jesu pèsè ohun tí ó wá di òfin ìdiwọ̀n olókìkí nipa ìwà, eyi tí a saba maa ńpè ní Òfin ìdiwọ̀n Oníwúrà. Oun wipe: “Gbogbo nǹkan tí ẹyin bá ńfẹ́ kí awọn ènìyàn ṣe sí yin, ni ẹyin pẹlu gbọdọ ṣe sí wọn gẹ́gẹ́.” Gbígbé ní ìbámu pẹlu òfin ìdiwọ̀n yii wémọ́ ìgbésẹ̀ pàtó ní ṣíṣe daradara sí awọn ẹlomiran, híhùwà sí wọn gẹgẹ bi awa yoo ti fẹ́ kí á hùwà sí wa.

Pe ọ̀nà sí ìyè kò rọrùn ni a ṣípayá nipa ìtọ́ni Jesu naa: “Ẹ bá ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé; nitori fífẹ̀ ati fífẹjú ni ojú ọ̀nà tí ó sínni lọ sínú ìparun, ọpọlọpọ ni awọn tí wọn sì ńbá ibẹ̀ wọlé; nigba tí ó jẹ́ pe tóóró ni ẹnu ọ̀nà naa ati híhá ni ojú ọ̀nà naa tí ó sinni lọ sí ìyè, diẹ sì ni awọn tí wọn ńrí i.”

Ewu dídi ẹni tí a ṣìlọ́nà ga pupọ, nitori naa Jesu kìlọ̀ pe: “Ẹ maa ṣọ́nà fun awọn wolii èké tí wọn ńwá sọ́dọ̀ yin ní àwọ̀ àgùtàn ṣugbọn ní inú ọ̀yánnú ìkòokò ni wọn.” Àní gẹgẹ bi a ti lè dá igi rere ati buburu mọ̀ nipa eso wọn, Jesu sọ pe, awọn èké wolii ni a lè dámọ̀ nipa ìwà ati ẹ̀kọ́ wọn.

Ní bíbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó, Jesu ṣàlàyé pe kii wulẹ ṣe ohun tí ẹnikan sọ ni ó sọ ọ́ di ọmọ-ẹhin Rẹ̀ bikoṣe ohun tí ó ṣe. Awọn ènìyàn kan sọ pe Jesu ni Oluwa wọn, ṣugbọn bí wọn kò bá ńṣe ìfẹ́-inú Baba rẹ̀, oun wipe: “Emi yoo jẹ́wọ́ fun wọn pe: Emi kò mọ̀ yin rí! Ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹyin òṣìṣẹ́ ìwà àìlófin.”

Ní àkótán, Jesu fun iwaasu rẹ̀ ni ipari ti a o maa ranti titilọ. Oun sọ pe: “Olukuluku ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ temi wọnyi tí ó sì ńṣe wọn ni a ó fi wé olóye ọkunrin kan, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. Òjò sì rọ̀, ìkun omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọn sì kọlù ilé naa, ṣugbọn kò wó, nitori a ti pilẹ̀ rẹ̀ lórí àpáta ràbàtà.”

Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, Jesu polongo pe: “Olukuluku ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ temi wọnyi tí kò sì ṣe wọn ni a ó fiwé òmùgọ̀ ọkunrin kan, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Òjò sì rọ̀, ìkun omi sì dé ẹ̀fúùfù sì fẹ́ wọn sì kọlu ilé naa, ó sì wó, ìwólulẹ̀ rẹ̀ sì pọ̀.”

Nigba ti Jesu parí ìwàásù rẹ̀, ogunlọgọ naa ni háà ṣe sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, nitori oun kọ́ wọn bi ẹnikan tí ó ní ọlá-àṣẹ kii ṣe bi awọn aṣaaju isin wọn. Luuku 6:12-23; Matiu 5:1-12; Luuku 6:24-26; Matiu 5:13-48; 6:1-34; 26:36-45; 7:1-29; Luuku 6:27-49, NW.

▪ Nibo ni Jesu wà nigba ti ó sọ ìwàásù mánigbàgbé rẹ̀, awọn wo ní wọn pesẹ, ki ni ó sì ti ṣẹlẹ̀ kété ṣaaju kí ó tó sọ ọ́?

▪ Eeṣe tí kò fi yanilẹ́nu pe Luuku ṣàkọsílẹ̀ awọn ìkọnilẹ́kọ̀ọ́ kan ninu ìwàásù naa ninu ìgbékalẹ̀ miiran?

▪ Ki ni ó mú kí ìwàásù Jesu ṣe iyebíye tobẹẹ?

▪ Awọn wo ni aláyọ̀ nitootọ, eeṣe?

▪ Awọn wo ni wọn ńgba ègbé, eeṣe?

▪ Bawo ni awọn ọmọ-ẹhin Jesu ṣe jẹ́ “iyọ̀ ilẹ̀-ayé” ati “ìmọ́lẹ̀ ayé”?

▪ Bawo ni Jesu ṣe fi ọ̀wọ̀ gíga hàn fun Òfin Ọlọrun?

▪ Ìtọ́ni wo ni Jesu pèsè lati fi hú gbòǹgbò awọn okùnfà ìṣìkàpànìyàn ati panṣaga sọnu?

▪ Ki ni Jesu ní lọ́kàn nigba ti ó sọ̀rọ̀ nipa yíyí ẹ̀rẹ̀kẹ́ keji padà?

▪ Bawo ni awa ṣe lè jẹ́ pípé gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe jẹ́ pípé?

▪ Awọn ìtọ́ni wo nipa adura ni Jesu pèsè?

▪ Eeṣe tí awọn ìṣúra ti ọ̀run fi lọ́lájù, bawo ni a sì ṣe ńrí wọn gbà?

▪ Awọn àkàwé wo ni a funni lati ṣeranwọ fun ẹnikan ni yíyẹra fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì?

▪ Eeṣe tí Jesu fi sọ pe kò si idi fun ṣíṣàníyàn?

▪ Ki ni Jesu sọ nipa ṣíṣe ìdájọ́ awọn ẹlomiran, sibẹsibẹ bawo ni oun ṣe fihàn pe ó yẹ ki awọn ọmọ-ẹhin oun lo ìwòyemọ̀ ni biba awọn ẹlomiran lò?

▪ Ki ni ohun tí Jesu sọ siwaju sí i nipa adura, òfin ìdiwọ̀n ìwàhíhù wo ni oun sì pèsè?

▪ Bawo ni Jesu ṣe fihàn pe ọ̀nà sí ìyè kì yoo rọrùn ati pe ewu dídi ẹni tí a ṣìlọ́nà nbẹ?

▪ Bawo ni Jesu ṣe pari ìwàásù rẹ̀, ipa wo ni ó sì ní?