Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìyọ́nú fun Adẹ́tẹ̀ Kan

Ìyọ́nú fun Adẹ́tẹ̀ Kan

Orí 25

Ìyọ́nú fun Adẹ́tẹ̀ Kan

BI JESU ati awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ mẹrin ti nbẹ awọn ilu Galili wò, irohin nipa awọn ohun agbayanu ti o nṣe tan kalẹ jakejado agbegbe naa. Ọ̀rọ̀ nipa awọn iṣẹ rẹ̀ de ilu kan nibi ti ọkunrin kan ti o ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wa. Oniṣegun Luuku ṣapejuwe ọkunrin naa gẹgẹ bi ẹni ti “ẹ̀tẹ̀ bò.” Nigba ti o ba ti wọ́ alaisan naa lara jinna, àrùn bibanilẹru yii rọra maa nba awọn oniruuru ẹya ara jẹ. Nitori naa adẹ́tẹ̀ yii wà ninu ipo ti o ṣenilaaanu.

Nigba ti Jesu dé sí ilu naa, adẹ́tẹ̀ naa tọ̀ ọ́ wá. Gẹgẹ bi Òfin Ọlọrun ti wi, adẹ́tẹ̀ kan nilati ké jade ni kikilọ pe, “Alaimọ, alaimọ!” lati daabobo awọn miiran lati maṣe wá sí itosi rẹ̀ pupọ jù kí wọn sì fi ara wewu ìkóràn. Adẹ́tẹ̀ naa nisinsinyi kunlẹ ó sì bẹ Jesu pe: “Oluwa, bi iwọ bá fẹ́, iwọ lè sọ mi di mimọ.”

Ẹ wo iru igbagbọ ti ọkunrin naa ni ninu Jesu! Sibẹ, ẹ wo bi àrùn rẹ̀ yoo ti gbọdọ mú kí ó farahan bi ẹni ti a ba kaaanu! Ki ni Jesu yoo ṣe? Ki ni iwọ yoo ṣe? Bi a ti sún un pẹlu ìyọ́nú, Jesu na ọwọ́ rẹ̀ jade ó sì fi kan ọkunrin naa, ni wiwi pe: “Mo fẹ́: iwọ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ẹ̀tẹ̀ naa parẹ́ kuro lara rẹ̀.

Iwọ yoo ha fẹ́ ẹnikan ti o ni ìyọ́nú bí eyi gẹgẹ bi ọba rẹ bí? Ọna ti Jesu gba mu adẹtẹ yii larada pese igbọkanle pe lakooko iṣakoso Ijọba rẹ̀, asọtẹlẹ Bibeli naa yoo ni imuṣẹ pe: “Oun yoo dá talaka ati alaini sí, yoo sì gba ọkan awọn alaini là.” Bẹẹni, Jesu nigba naa yoo mú ìfẹ́-ọkàn atinuwa rẹ̀ ṣẹ lati ran gbogbo awọn ẹni ti a ńpọ́n loju lọwọ.

Ani ṣaaju mimu adẹ́tẹ̀ naa larada paapaa, iṣẹ ojiṣẹ Jesu ti ṣokunfa itara ayọ nla laaarin awọn eniyan naa. Ni imuṣẹ asọtẹlẹ Aisaya, Jesu paṣẹ fun ọkunrin ti a mú larada naa nisinsinyi pe: “Wòó, maṣe sọ ohunkohun fun ẹnikẹni.” Lẹhin naa o fun un ni itọni pe: “Lọ, fi ara rẹ̀ hàn fun alufaa, kí o sì bun ẹbun ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ ti Mose ti palaṣẹ, ní ẹ̀rí fun wọn.”

Ṣugbọn ọkunrin naa layọ tobẹẹ ti kò lè fi iṣẹ iyanu naa pamọ́ sọdọ ara rẹ̀. O jade lọ ó sì bẹrẹsii tan ihin naa kalẹ nibi gbogbo, ó hàn gbangba pe o fa ọkàn ìfẹ́ ati ìháragàgà tobẹẹ laaarin awọn eniyan naa ti Jesu kò fi lè jade ni gbangba sinu ilu naa. Nipa bẹẹ, Jesu duro ni awọn ibi àdádó nibi ti ẹni kankan kò gbé, awọn eniyan lati ibi gbogbo sí wá lati fetisi i ati lati gba imularada kuro ninu ailera wọn. Luuku 5:12-16; Maaku 1:40-45; Matiu 8:2-4; Lefitiku 13:45; 14:10-13; Saamu 72:13; Aisaya 42:1, 2.

▪ Iyọrisi wo ni ẹ̀tẹ̀ lè ní, ikilọ wo sì ni adẹ́tẹ̀ kan nilati ṣe?

▪ Bawo ni adẹ́tẹ̀ kan ṣe bẹ Jesu, ki ni a sì lè kẹkọọ lati inu idahunpada Jesu?

▪ Bawo ni ọkunrin ti a mú larada naa ṣe kuna lati ṣegbọran sí Jesu, kí sì ni awọn abajade rẹ̀?