Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìyọ́nú fun Awọn Ti A Npọnloju

Ìyọ́nú fun Awọn Ti A Npọnloju

Orí 57

Ìyọ́nú fun Awọn Ti A Npọnloju

LẸHIN fífi awọn Farisi bú nitori awọn àṣà àtọ́wọ́dọ́wọ́ tí ńṣiṣẹ́ fun àǹfààní tiwọn fúnraawọn, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi ibẹ̀ silẹ. Ṣaaju ìgbà naa, iwọ lè rántí pe ìgbìdánwò rẹ̀ lati lọ kúrò pẹlu wọn lati sinmi diẹ ni a bẹ́gidí nigba ti awọn ogunlọgọ rí wọn. Nisinsinyi pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o lọ si ẹkun Tire ati Sidoni, ọpọlọpọ ibusọ siha ariwa. Eyi ní kedere jẹ́ ìrìn àjò kanṣoṣo tí Jesu lọ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ rékọjá awọn ààlà ẹnubodè Isirẹli.

Lẹhin tí wọn ti rí ilé kan lati wọ̀ sí, Jesu jẹ́ kí ó di mímọ̀ pe oun kò fẹ́ kí ẹnikẹni mọ̀ nipa ibi tí wọn wà. Sibẹsibẹ, kódà ní ìpínlẹ̀ tí kii ṣe ti Isirẹli yii, oun kò lè bọ́ lọwọ àkíyèsí. Obinrin Giriiki kan, tí a bí ní Foẹniṣia ti Siria, wá a rí tí ó sì bẹrẹsii bẹ̀bẹ̀ pe: “Ṣàánú fun mi, Oluwa, Ọmọkunrin Dafidi. Ẹ̀mí-èṣù ńdá ọmọbinrin mi lóró buruku-buruku.” Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, kò sọ ọ̀rọ̀ kan ní ìfèsìpadà.

Ní àsẹ̀hìnwá àsẹ̀hìnbọ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọ fun Jesu pe: “Rán an lọ; nitori ó ńké tẹle wa lẹhin.” Ní ṣíṣàlàyé ìdí tí ó fi ṣàìfiyèsí obinrin naa, Jesu wipe: “A kò rán mi jáde sọ́dọ̀ ẹnikẹni bikoṣe sí awọn àgùtàn ilé Isirẹli tí wọn sọnù.”

Bí ó ti wù kí ó rí, obinrin naa kò juwọsilẹ. Ó sunmọ Jesu ó sì wólẹ̀ niwaju rẹ̀. Obinrin naa jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pe, “Oluwa, ràn mi lọwọ!”

Ẹ wo bi ọkàn-àyà Jesu ti gbọdọ rusókè nipasẹ ẹ̀bẹ̀ onífọkànsí obinrin naa! Sibẹsibẹ, Jesu lẹẹkan sí i tọ́kasí ẹrù-iṣẹ́ àkọ́kọ́, lati ṣèránṣẹ́ fun awọn ènìyàn Ọlọrun Isirẹli. Lẹsẹkan naa, ó hàn gbangba pe lati dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò, ó lò ojú ìwòye awọn Juu tí ó kún fun ẹ̀tanú si awọn orílẹ̀-èdè miiran, ní jíjiyàn pe: “Kò tọ́ kí á mú burẹdi awọn ọmọ kí á sì sọ ọ́ sí awọn ajá kéékèèké.”

Nipasẹ ìró ohùn ìyọ́nú rẹ̀ ati ìrísí ojú rẹ̀, Jesu dajudaju ńṣí awọn ìmọ̀lára jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tirẹ̀ fúnraarẹ̀ payá fun awọn tí kii ṣe Juu. Oun tilẹ tun mu afiwe naa ṣeefaramọ nipa titọkasi awọn Keferi naa gẹgẹ bi “awọn ajá kéékèèké,” tabi awọn ọmọ ajá. Kàkà kí ó tètè bínú, obinrin naa mẹnuba itọkasi Jesu si ẹtanu awọn Juu ti o sì ṣakiyesi pẹlu irẹlẹ pe: “Bẹẹni, Oluwa; ṣugbọn niti gidi awọn ajá kéékèèké a maa jẹ ninu awọn èérún tí nbọ silẹ lati orí tábìlì awọn ọ̀gá wọn.”

“Óò obinrin, ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ,” ni Jesu dáhùnpada. “Kí ó ṣẹlẹ sí ọ gẹgẹ bi iwọ ti fẹ́.” Ó sì rí bẹẹ! Nigba ti ó padà de ilé rẹ̀, ó rí ọmọbinrin rẹ̀ lórí ibùsùn, tí ara rẹ̀ ti yá gágá.

Lati ẹkùn-ilẹ̀ etíkun Sidoni, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ forílé ìsọdá ilẹ̀ orílẹ̀-èdè naa, síhà orísun Odò Jọdani. Ní kedere wọn fẹsẹ̀wọ́ omi rékọjá Jọdani níbì kan ní apá òkè Òkun Galili wọn sì wọnú ẹkùn-ilẹ̀ Dekapolisi ti o jẹ ìlà-oòrùn òkun naa. Nibẹ wọn gun òkè kan, ṣugbọn awọn ogunlọgọ rí wọn wọn sì mú awọn arọ, amúkùn-ún, afọ́jú, ati odi ati ọpọlọpọ tí ó ní àìlera miiran ati àbùkù wá sí ọ̀dọ̀ Jesu. Wọn rọ́ra gbé wọn kalẹ̀ lẹba ẹsẹ̀ Jesu, ó sì wò wọn sàn. Ẹnu ya awọn ènìyàn naa, bí wọn ti rí awọn odi tí wọn ńsọ̀rọ̀, tí arọ ńrìn, tí afọ́jú sì ńríran; wọn sì yin Ọlọrun Isirẹli lógo.

Jesu fun ọkunrin kan tí ó jẹ́ adití tí ó sì jẹ́ pe agbárakáká ni ó fi lè sọ̀rọ̀ ní àkànṣe àfiyèsí. Awọn aditi maa nyara nimọlara itiju lọpọ ìgbà pàápàá ní pàtàkì láàárín ogunlọgọ. Jesu lè ti ṣàkíyèsí ojora ọkunrin yii ni pataki. Nitori naa Jesu fi ìyọ́nú mú un kuro láàárín ogunlọgọ naa lọ sí ìkọ̀kọ̀. Nigba ti wọn wà ní awọn nìkan, Jesu tọ́ka ohun tí oun ńfẹ́ lati ṣe fun un. Ó ki awọn ìka rẹ̀ bọ inu etí ọkunrin naa, lẹhin títu itọ́, ó fi ọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀. Nigba naa, ní wíwo ọ̀run, Jesu mí ìmí-ẹ̀dùn jíjinlẹ̀ ó sì wipe: “Ṣí.” Bí ó ti sọ eyi, agbára ìgbọràn ọkunrin naa ni a múpadàbọ̀sípò, ó sì ṣeeṣe fun un lati sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ.

Nigba ti Jesu ti mú ọ̀pọ̀ awọn ìwòsàn wọnyi ṣeníṣẹ́, awọn ogunlọgọ naa dáhùnpadà pẹlu ìmọrírì. Wọn wipe: “Ó ti ṣe ohun gbogbo daradara. Ó tilẹ mú kí awọn adití gbọ́ràn kí awọn aláìlèsọ̀rọ̀ sì sọ̀rọ̀.” Matiu 15:21-31; Maaku 7:24-37.

▪ Eeṣe tí Jesu kò fi mú ọmọ obinrin Giriiki naa láradá lójú ẹsẹ̀?

▪ Nigbẹhin, ibo ni Jesu mú awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ?

▪ Bawo ni Jesu ṣe fi ìyọ́nú hùwàsí ọkunrin adití tí ó jẹ́ pe ekukáká ni ó fi lè sọ̀rọ̀?