Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀pọ̀ Ọmọ-ẹhin Pada Lẹhin Jesu

Ọ̀pọ̀ Ọmọ-ẹhin Pada Lẹhin Jesu

Orí 55

Ọ̀pọ̀ Ọmọ-ẹhin Pada Lẹhin Jesu

JESU ńkọ́ni ninu sinagọgu kan ní Kapanaomu nipa ipa-iṣẹ́ rẹ̀ gẹgẹ bi burẹdi tootọ lati ọ̀run. Àsọyé rẹ̀ bí ó ti hàn kedere jẹ́ afikun fun ìjíròrò kan tí ó ti bẹ̀rẹ̀ pẹlu awọn ènìyàn naa nigba ti wọn rí i lẹhin tí wọn padà dé lati ìhà ìlà-oòrùn Òkun Galili, níbi tí wọn ti jẹ lati inú awọn ìṣù burẹdi ati ẹja tí a pèsè lọna iṣẹ́-ìyanu.

Jesu ńbá awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó, ní wiwi pe: “Burẹdi naa tí emi yoo fúnni ni ẹran ara mi nitori ìyè ayé.” Ní ọdun meji péré ṣaaju, ní ìgbà ìrúwé 30 C.E., Jesu sọ fun Nikodemu pe Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tobẹẹ gẹ́ẹ́ tí ó fi pèsè Ọmọkunrin rẹ̀ gẹgẹ bi Olùgbàlà kan. Nipa bayii, Jesu nisinsinyi fihàn pe ẹnikẹni ninu ayé aráyé tí ó bá jẹ ẹran ara oun lọna ìṣàpẹẹrẹ, nipa lílò ìgbàgbọ́ ninu ẹbọ tí oun yoo ru láìpẹ́, lè rí ìyè ainipẹkun gbà.

Awọn ènìyàn naa, bí ó ti wù kí ó rí, kọsẹ̀ lórí awọn ọ̀rọ̀ Jesu. “Bawo ni ọkunrin yii ṣe lè fi ẹran ara rẹ̀ fun wa lati jẹ?” ni wọn beere. Jesu fẹ́ kí awọn olùgbọ́ rẹ̀ lóye pe jíjẹ ninu ẹran ara oun ni a o ṣe lọna ìṣàpẹẹrẹ kan. Nitori naa, lati tẹnumọ́ eyi, oun sọ nǹkan tí ó tubọ yẹ ní títakò bí a bá nilati lóye rẹ̀ lọna bí a ṣe sọ ọ́ gan-an.

“Àyàfi bí ẹyin bá jẹ ẹran ara Ọmọkunrin ènìyàn kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò ní ìyè ninu araayin. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi ní ìyè ainipẹkun, emi yoo sì jí i dìde ní ọjọ ikẹhin; nitori pe ẹran ara mi ni ounjẹ tootọ, ẹ̀jẹ̀ mi sì ni ohun mímu tootọ. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu mi emi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀.”

Lóòótọ́, ẹ̀kọ́ Jesu ìbá ti dún bíi eyi ti kò báradé rara bí oun bá ti ńdámọ̀ràn ìjẹ̀nìyàn. Ṣugbọn, dajudaju, kii ṣe pe Jesu ńṣe alágbàwí jíjẹ ẹran ara tabi mímu ẹ̀jẹ̀ lọna bí a ti sọ ọ́ gan-an. Oun wulẹ ntẹnumọ́ ọn pe gbogbo awọn tí ńgba ìyè ainipẹkun gbọdọ lò ìgbàgbọ́ ninu ẹbọ tí oun yoo rú nigba ti ó bá fi ara ẹ̀dá-ènìyàn pípé rẹ̀ silẹ tí ó sì tú ẹ̀jẹ̀ iwalaaye rẹ̀ jáde. Sibẹ, àní ọpọlọpọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ kò ṣe isapa eyikeyii lati lóye ẹ̀kọ́ rẹ̀, nitori naa wọn tako o pe: “Ọ̀rọ̀ yii múnigbọ̀nrìrì; ta ni lè fetisilẹ sí i?”

Ní mímọ̀ pe ọpọlọpọ ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ńkùn sínú, Jesu wipe: “Eyi ha mú yin kọsẹ̀ bí? Njẹ, nitori naa, bí ẹyin bá rí Ọmọkunrin ènìyàn tí ńgòkè lọ sí ibi tí ó ti wà tẹlẹri ńkọ́? . . . Awọn àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yin ẹ̀mí ni wọn ìyè sì ni wọn. Ṣugbọn awọn kan wà ninu yin tí kò gbàgbọ́.”

Jesu nbaa lọ: “Ìdí niyii tí mo ṣe wí fun yin pe, Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi bikoṣe pe a bá fifun un lati ọ̀dọ̀ Baba wá.” Pẹlu iyẹn, ọpọlọpọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni wọn lọ kúrò tí wọn kò sì tọ̀ ọ́ lẹ́hìn mọ́. Nitori naa Jesu yíjú sí awọn apọsiteli rẹ̀ 12 ó sì beere pe: “Ẹyin kò fẹ́ lọ pẹlu, ẹ fẹ́ lọ bí?”

Peteru dáhùnpadà pe: “Oluwa, ọ̀dọ̀ ta ni awa yoo lọ? Iwọ ni ó ní awọn ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun; awa sì ti gbàgbọ́; a sì ti wá mọ̀ pe iwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọrun.” Ọ̀rọ̀ ìsọjáde ti o fi ìdúróṣinṣin han wo ni eyi, àní bí ó tilẹ jẹ́ pe Peteru ati awọn apọsiteli yooku lè ma lóye lẹkun-unrẹrẹ ẹ̀kọ́ Jesu lórí ọ̀ràn yii!

Bí ó tilẹ jẹ́ pe ìdáhùn Peteru tẹ́ ẹ lọrun, Jesu ṣàlàyé pe: “Mo yan ẹyin mejila, emi kò ha ṣe bẹẹ bí? Sibẹ ọ̀kan ninu yin jẹ́ olùfọ̀rọ̀ èké banijẹ́.” Oun ńsọ̀rọ̀ nipa Judasi Isikariọtu. Ó lè ṣeeṣe kí ó jẹ́ pe nisinsinyi Jesu ti jádìí “ìbẹ̀rẹ̀,” tabi ìdìde ipa-ọ̀nà àìtọ́ kan ninu Judasi.

Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ já awọn ènìyàn naa kulẹ̀ nipa yiyẹra fun awọn ìgbìdánwò wọn lati fi i jẹ ọba, tí wọn sì lè maa ronú pe, ‘Bawo ni eyi ṣe lè jẹ́ Mesaya bí oun kì yoo bá gorí ipò tí ó tọ́sí Mesaya?’ Eyi, pẹlu, yoo jẹ́ ọ̀ràn titun kan ninu èrò-inú awọn ènìyàn naa. Johanu 6:51-71; 3:16.

▪ Awọn wo ni Jesu fun ní ẹran ara rẹ̀, bawo sì ni awọn wọnyi ṣe ‘jẹ ẹran ara rẹ̀’?

▪ Awọn ọ̀rọ̀ Jesu siwaju sí i wo ni ó mú awọn ènìyàn naa gbọ̀nrìrì, sibẹ ki ni oun tẹnumọ́?

▪ Nigba ti ọpọlọpọ dẹ́kun títọ Jesu lẹhin, ki ni ìdáhùnpadà Peteru?