Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣíṣe Awọn Iṣẹ́ Rere ní Sabaati

Ṣíṣe Awọn Iṣẹ́ Rere ní Sabaati

Orí 29

Ṣíṣe Awọn Iṣẹ́ Rere ní Sabaati

ÓJẸ́ ìgbà ìrúwé 31 C.E. Oṣu diẹ ti kọjá lẹhin ìgbà tí Jesu ti bá obinrin tí nbẹ ní ibi kànga ni Samaria sọ̀rọ̀ nigba tí oun wà lójú ọ̀nà Judia sí Galili.

Nisinsinyi, lẹhin kíkọ́ni lọna gbigbooro jákèjádò Galili, Jesu tun fi ibẹ̀ silẹ lọ sí Judia, níbi tí ó ti waasu ninu awọn sinagọgu. Ní ìfiwéra pẹlu àkíyèsí tí Bibeli fun iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Galili, kò sọ pupọ nipa ìgbòkègbodò Jesu ní Judia lákòókò ìbẹ̀wò yii ati awọn oṣu tí oun lò nibẹ lẹhin Irekọja ti iṣaaju. Lọna híhàn gbangba wọn kò fi ojúrere dáhùnpadà sí iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Judia gẹgẹ bi ó ti rí ní Galili.

Láìpẹ́ Jesu wà ní ọ̀nà rẹ̀ lọ sí olú-ìlú Judia, Jerusalẹmu, fun Irekọja ti 31 C.E. Níhìn-ín, nítòsí Ibodè Àgùtàn ìlú-ńlá naa, ni adágún omi kan wà tí a ńpè ní Bẹtisata, níbi tí ọpọlọpọ awọn aláìsàn, afọ́jú, ati arọ maa ńwá. Wọn gbàgbọ́ pe awọn ènìyàn ni a lè mú láradá nipasẹ wíwọ inú omi adágún naa nigba ti ó bá rugùdù.

Ó jẹ́ Sabaati, Jesu sì rí ọkunrin kan tí ó ti ńṣàìsàn fun 38 ọdun lẹ́bàá adágún omi naa. Ní mímọ̀ gígùn àkókò tí ọkunrin naa ti ńṣàìsàn, Jesu beere pe: “Iwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”

Ó dá Jesu lóhùn pe: “Ọ̀gbẹ́ni, emi kò ní ènìyàn kankan tí yoo gbé mi sínú adágún naa nigba ti a bá rú omi naa; ṣugbọn bí emi bá ti ńbọ̀ ẹlomiran yoo ti sọ̀kalẹ̀ ṣaaju mi.”

Jesu sọ fun un pe: “Dìde, gbé àkéte rẹ kí o sì rìn.” Pẹlu iyẹn ọkunrin naa ni a mú láradá lọ́gán, ó gbé àkéte rẹ̀, ó sì bẹrẹsii rìn!

Ṣugbọn nigba ti awọn Juu rí ọkunrin naa, wọn sọ pe: “Sabaati ni òní, kò sì bá òfin mu fun ọ lati gbé àkéte.”

Ọkunrin naa dá wọn lóhùn pe: “Ẹni naa gan-an tí ó mú mi láradá wí fun mi pe, ‘Gbé àkéte rẹ kí o sì maa rìn.’”

“Ta ni ọkunrin naa tí ó sọ fun ọ pe, ‘Gbé e kí o sì maa rìn’?” ni wọn beere. Jesu ti bọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan nitori ogunlọgọ naa, ẹni tí a mú láradá naa kò sì mọ orukọ Jesu. Lẹhin naa, bí ó ti wù kí ó rí, Jesu ati ọkunrin naa pàdé ní tẹmpili, ọkunrin naa sì wá mọ ẹni tí ó mú un láradá.

Nitori naa ọkunrin tí a mú laradá wá awọn Juu rí lati sọ fun wọn pe Jesu ni ẹni tí ó mú oun láradá. Bí wọn ti gbọ́ eyi, awọn Juu naa lọ bá Jesu. Fun ìdí wo? Ṣe lati mọ ipasẹ̀ ọ̀nà tí ó gbà ṣeeṣe fun un lati ṣe awọn ohun yíyanilẹ́nu wọnyi ni bí? Bẹẹkọ. Ṣugbọn lati ṣe àríwísí sí i nitori pe oun ṣe awọn ohun rere wọnyi ní Sabaati. Àní wọn tilẹ bẹrẹsii ṣe inúnibíni sí i! Luuku 4:44; Johanu 5:1-16.

▪ Bawo ni ó ti pẹ́ tó nisinsinyi tí Jesu ti ṣe ìbẹ̀wò kẹhin sí Judia?

▪ Eeṣe tí adágún omi tí a ńpè ní Bẹtisata fi gbajúmọ̀ tobẹẹ?

▪ Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jesu múṣe lẹ́bàá adágún omi naa, kí sì ni ìhùwàpadà awọn Juu?