Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Wà Ní Ìmúratán!

Ẹ Wà Ní Ìmúratán!

Orí 78

Ẹ Wà Ní Ìmúratán!

LẸHIN kíkìlọ̀ fun ogunlọgọ naa nipa ojúkòkòrò, ati ṣíṣí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ níyè nipa fífi àfiyèsí tí kò yẹ sí awọn ohun ti ara, Jesu fúnni ní ìṣírí pe: “Ẹ má bẹ̀rù, agbo kekere, nitori pe Baba yin ti fọwọ́sí fífún yin ní ijọba naa.” Oun tipa bayii ṣíi payá pe kìkì nọmba kekere kan ní ìfiwéra (tí a fihàn lẹhin naa gẹgẹ bi 144,000) ni yoo wà ninu Ijọba ti ọ̀run. Eyi tí ó pọ̀ jùlọ ninu awọn ẹni tí wọn gba iye ayeraye yoo jẹ́ awọn ọmọ-abẹ́ Ijọba naa ti ilẹ̀-ayé.

Irú ẹ̀bùn yíyanilẹ́nu kan wo ni eyi, “ijọba”! Ní ṣíṣàpèjúwe ìdáhùnpadà títọ̀nà tí awọn ọmọ-ẹhin gbọdọ ní lẹhin tí wọn ti rí i gbà, Jesu rọ̀ wọn pe: “Ẹ ta awọn ohun tí ó jẹ́ tiyin kí ẹ sì fúnni ní awọn ẹ̀bùn àánú.” Bẹẹni, wọn gbọdọ lò awọn ohun ìní wọn lati mú awọn ẹlomiran jàǹfààní nipa tẹ̀mí kí wọn sì tipa bẹẹ tò “ìṣura tí kìí kùnà láé ninu awọn ọ̀run” jọ.

Jesu lẹhin naa ṣí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ létí lati wà ní ìmúratán fun ipadabọ rẹ̀. Oun wipe: “Ẹ di ìbàdí yin ní àmùrè kí awọn àtùpà yin sì maa jó, kí ẹyin fúnraayin sì dabi awọn ọkunrin tí ńdúró dè ọ̀gá wọn nigba ti ó padàbọ̀ lati ibi ìgbéyàwó, kí ó lè jẹ́ pe ní dídé rẹ̀ ati kíkan ilẹ̀kùn kí wọn lè ṣí i fun un ní kíámọ́sá. Aláyọ̀ ni awọn ẹrú wọnni ẹni tí ọ̀gá naa rí tí ńṣọ̀nà nigba tí ó dé! Lóòótọ́ mo wí fun yin, Oun yoo di araarẹ̀ ní àmùrè yoo sì mú kí wọn rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì yoo sì wá sí ìtòsí yoo sì ṣe iranṣẹ fun wọn.”

Ninu àkàwé yii, ìmúratán awọn iranṣẹ naa nigba ìpadàbọ̀ ọ̀gá wọn ni a fihàn nipa bíbọ́ awọn aṣọ ìgunwà wọn gígùn kuro tí wọn sì so o mọ́ ìbàdí wọn tí wọn sì nbaa lọ lati maa bójútó awọn ìlà-iṣẹ́ wọn títí di òru ninu ìmọ́lẹ̀ awọn fìtílà tí a bu epo sí daradara. Jesu ṣàlàyé pe: ‘Bí ọ̀gá naa bá sì dé ní ìṣọ́ keji [lati nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án ní alẹ́ sí ọ̀gànjọ́ òru], bí ó tilẹ ṣe ẹkẹta pàápàá [lati ọ̀gànjọ́ òru sí nǹkan bii ago mẹta ní òwúrọ̀], tí ó sì rí wọn bẹẹ, aláyọ̀ ni wọn!’

Ọ̀gá naa san ẹ̀san fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ní ọ̀nà àràmàǹdà kan. Ó mú wọn rọ̀gbọ̀kú nídìì tábìlì ó sì bẹrẹsii fun wọn ní ounjẹ. O hùwàsí wọn, kii ṣe gẹgẹ bi awọn ẹrú, bikoṣe gẹgẹ bi awọn ọ̀rẹ́ adúróṣinṣin. Ẹ wo irú ẹ̀san rere kan tí ó jẹ́ fun bibaa lọ wọn lati maa ṣiṣẹ́ fun ọ̀gá wọn jálẹ̀jálẹ̀ òru naa nigba tí wọn ńdúró dè ìpadàbọ̀ rẹ̀! Jesu pari ọrọ rẹ̀ pe: “Ẹyin pẹlu, ẹ wà ní ìmúratán, nitori pe ní wakati tí ẹyin kò rò pe ó ṣeeṣe ni Ọmọkunrin eniyan ńbọ̀.”

Peteru nisinsinyi beere pe: “Oluwa, iwọ ńsọ àkàwé yii fun wa tabi fun gbogbo ènìyàn pẹlu?”

Kàkà kí ó dáhùn ní tààràtà, Jesu fúnni ní àkàwé miiran. “Niti gidi ta ni ìríjú olùṣòtítọ́,” ni oun beere, “ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ yoo yànsípò olórí ẹgbẹ́ awọn iranṣẹ onitọọju rẹ̀ lati maa fun wọn ní awọn ìpèsè ounjẹ wọn ní àkókò tí ó tọ́? Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn, tí ọ̀gá rẹ̀ nigba tí ó bá dé bá rí i tí ńṣe bẹẹ! Mo sọ fun yin tootọ tootọ, Oun yoo yàn án sípò olórí gbogbo ohun-ìní rẹ̀.”

“Ọ̀gá” naa ní kedere jẹ́ Jesu Kristi. “Ìríjú” naa yàwòrán “agbo kekere” ti awọn ọmọ-ẹhin gẹgẹ bi ẹgbẹ́ àgbájọ kan, tí “ẹgbẹ́ awọn iranṣẹ onitọọju” sì tọ́kasí 144,000 kan naa yii tí wọn gba Ijọba ti ọ̀run, ṣugbọn ọ̀rọ̀ yii tẹnumọ́ iṣẹ́ wọn gẹgẹ bi ẹnikọọkan. “Awọn ohun-ìní” tí a yan ìríjú olùṣòtítọ́ naa sípò lati ṣètọ́jú jẹ́ awọn ìpín ìṣúra kábíyèsí ti ọ̀gá naa lórí ilẹ̀-ayé, tí ó ní ninu awọn ọmọ-abẹ́ Ijọba naa ti ilẹ̀-ayé.

Ní bíbá àkàwé naa lọ, Jesu tọ́kasí ṣíṣeéṣe naa pe kii ṣe gbogbo mẹmba agbo ìríjú yẹn, tabi ẹrú, ni yoo jẹ́ adúróṣinṣin, ní ṣíṣàlàyé pe: “Ṣugbọn bí ẹrú yẹn bá nilati wí ninu ọkàn-àyà rẹ̀ lae pe, ‘Ọ̀gá mi falẹ̀ ní dídé,’ tí ó sì wá nilati bẹrẹsii lu awọn iranṣẹkunrin ati awọn iranṣẹbinrin, ati lati jẹun ati lati mu kí ó sì mutípara, ọ̀gá ẹrú yẹn yoo dé ní ọjọ́ kan tí oun kò retí rẹ̀ . . . , oun yoo sì jẹ ẹ́ níyà pẹlu ìmúná gígajùlọ.”

Jesu nbaa nìṣó lati ṣàkíyèsí pe wíwá rẹ̀ ti mú àkókò amú bí iná kan wá fun awọn Juu, bí awọn kan ti tẹ́wọ́gbà awọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí awọn miiran sì ṣá a tì. Ní eyi tí ó ju ọdun mẹta lọ ṣaaju, a baptisi rẹ̀ ninu omi, ṣugbọn nisinsinyi baptism rẹ̀ sínú ikú ńsúnmọ́tòsí ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ati gẹgẹ bi oun sì ti sọ: “Mo sì ti ńdààmú tó títí yoo fi parí!”

Lẹhin dídarí awọn ọ̀rọ̀ wọnyi sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu lẹẹkan sí i bá ogunlọgọ naa sọ̀rọ̀. O kédàárò kíkọ̀ wọn pẹlu agídí lati tẹ́wọ́gbà ẹ̀rí kedere naa nipa ẹni tí oun jẹ ati ìjẹ́pàtàkì rẹ̀. “Nigba ti ẹ bá rí ìkuùku tí ńdìde ní apá ìwọ̀-oòrùn,” ni oun ṣàlàyé, “ní kíámọ́sá ẹyin a wipe, ‘Ìjì ńbọ̀,’ a sì rí bẹẹ. Nigba ti ẹ bá sì ríi pe ẹ̀fúùfù guusu kan ńfẹ́, ẹyin a wípé, ‘Ìgbì ooru kan yoo wà,’ a sì ṣẹlẹ̀. Ẹyin àgàbàgebè, ẹyin mọ̀ bí a ti ńyẹ ìrísí-òde ilẹ̀-ayé ati òfúúrufú wò, ṣugbọn bawo ni ẹ kò ṣe mọ̀ bí a ṣe ńyẹ àkókò yii ní pàtàkì wò?” Luuku 12:32-59, NW.

▪ Awọn meloo ni wọn parapọ̀ jẹ́ “agbo kekere,” ki ni wọn sì gbà?

▪ Bawo ni Jesu ṣe tẹnumọ́ àìní-ọ̀ranyàn naa fun awọn iranṣẹ rẹ̀ lati wà ní ìmúratán?

▪ Ninu àkàwé Jesu, awọn wo ni “ọ̀gá” naa, “ìríjú” naa, “ẹgbẹ́ awọn iranṣẹ onitọọju” naa, ati “awọn ohun-ìní” naa?