Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹni Ti Àríyànjiyàn Dale Lori

Ẹni Ti Àríyànjiyàn Dale Lori

Orí 41

Ẹni Ti Àríyànjiyàn Dale Lori

KÉTÉ lẹhin tí Simoni ti ṣe e lalejo ninu ile rẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò iwaasu rẹ̀ ẹlẹẹkeji sí Galili. Lasiko ìrìn àjò rẹ̀ ti tẹlẹ sí àgbègbè naa, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ àkọ́kọ́, Peteru, Anderu, Jakọbu, ati Johanu bá a rìn. Ṣugbọn nisinsinyi awọn apọsiteli 12, ati bakan naa awọn obinrin kan bayii, bá a rìn. Awọn wọnyi ní ninu Maria Magidaleni, Susana, ati Joana, ẹni tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ olóye kan fun Ọba Hẹrọdu.

Bí iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu ti ntẹsiwaju pẹlu ìgbónájanjan, bẹẹ gẹ́gẹ́ ni àríyànjiyàn nipa ìgbòkègbodò rẹ̀ pẹlu. Ọkunrin ẹlẹ́mìí èṣù kan, tí ó fọ́jú tí kò sì lè sọ̀rọ̀ pẹlu, ni a mú tọ Jesu wa. Nigba ti Jesu wò ó sàn, tí ó fi jẹ́ pe ó bọ́ lọwọ iṣakoso ẹ̀mí èṣù tí ó lè sọ̀rọ̀ tí ó sì lè ríran, awọn ogunlọgọ naa ni a wulẹ mú orí wọn wú. Wọn bẹrẹsii sọ pe: “Ó ha lè jẹ pe eyi kọ́ ni Ọmọkunrin Dafidi?”

Ọpọ rẹpẹtẹ eniyan kórajọ ní iye pupọ yíká ilé tí Jesu wọ̀ sí tí ó fi jẹ́ pe oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ kò lè jẹ ounjẹ. Ní àfikún sí awọn wọnni tí wọn ronú pe o lè jẹ́ “Ọmọkunrin Dafidi” tí a ṣèlérí naa, awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi nbẹ tí wọn wá lati ọna jijin naa ni Jerusalẹmu lati pẹ̀gàn rẹ̀. Nigba ti awọn ìbátan Jesu gbọ́ nipa ìrúkèrúdò tí ńtankalẹ yíká Jesu yii, wọn wá lati mú un. Fun ìdí wo?

Ó dára, awọn arakunrin Jesu fúnraarẹ̀ kò tíì gbàgbọ́ sibẹ pe oun jẹ́ Ọmọkunrin Ọlọrun. Pẹlupẹlu, rukerudo ati rògbòdìyàn tí oun ti dásílẹ̀ kìí ṣe ànímọ́ Jesu tí wọn mọ̀ nigba tí ó ńdàgbà ní Nasarẹti rara. Nitori naa, wọn gbàgbọ́ pe ohun kan ti nilati ṣaitọ pẹlu ọpọlọ Jesu. “Orí rẹ̀ ti dàrú,” ni wọn parí èrò sí, nitori naa wọn fẹ́ lati mú un kí wọn sì gbé e lọ.

Sibẹ ẹ̀rí naa ṣe kedere pe Jesu mú ọkunrin ti o ni ẹ̀mí èṣù naa láradá. Awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi mọ̀ pe awọn kò lè sẹ́ jíjẹ́ otitọ eyi. Nitori naa lati pẹ̀gàn Jesu wọn sọ fun awọn ènìyàn naa pe: “Ọkunrin yii kò lé awọn ẹ̀mí èṣù jáde bikoṣe nipasẹ Belisebuubu, alákòóso awọn ẹ̀mí èṣù.”

Ní mímọ ìrònú wọn, Jesu pe awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wipe: “Olukuluku ijọba tí ó yapa sí araarẹ̀ yoo di ahoro, ati olukuluku ìlú tabi ilé tí ó yapa sí araarẹ̀ kì yoo dúró. Ní ọ̀nà kan naa, bí Satani bá ńlé Satani jáde, ó ti yapa sí araarẹ̀; bawo, nigba naa, ni ijọba rẹ̀ yoo ṣe dúró?”

Irú ìrònú ti o mọgbọndani wo ni eyi! Niwọn bi awọn Farisi ti sọ pe awọn ènìyàn lati inú ẹgbẹ awọn tìkáraawọn ti lé awọn ẹ̀mí èṣù jáde, Jesu tún beere pe: “Bí mo bá ńlé awọn ẹ̀mí èṣù jáde nipasẹ Belisebuubu, nipasẹ ta ni awọn ọmọ yin fi ńlé wọn jáde?” Lédè miiran, ẹ̀sùn wọn lòdìsí Jesu ṣeé lò sí wọn gan-an gẹgẹ bi ó ti ṣeé lò sí oun. Nigba naa Jesu kìlọ̀ pe: “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ nipasẹ ẹ̀mí Ọlọrun ni mo fi ńlé awọn ẹ̀mí èṣù jáde, ijọba Ọlọrun ti lé yin bá niti gidi.”

Lati ṣe àkàwé pe lílé tí oun ńlé awọn ẹ̀mí èṣù jáde jẹ́ ẹ̀rí agbára rẹ̀ lórí Satani, Jesu wipe: “Bawo ni ẹnikan ṣe lè gbóguntì ilé ọkunrin alágbára kan kí ó sì fi agbára gba awọn ẹrù rẹ̀ tí wọn ṣeé gbé, bikoṣe pe ki ó kọ́kọ́ di ọkunrin alágbára naa? Nigba naa ni oun yoo sì ko ẹrù ilé rẹ̀. Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ mi wà lòdìsí mi, ati ẹni tí kò bá kójọpọ̀ pẹlu mi túká.” Ní kedere awọn Farisi naa lòdìsí Jesu, ní fífi araawọn hàn pe wọn jẹ́ aṣojú Satani. Wọn ńtú awọn ọmọ Isirẹli ká kuro lọ́dọ̀ rẹ̀.

Nitori naa, Jesu kìlọ̀ fun awọn alátakò oníwà èṣù wọnni pe “ọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí ni a kì yoo dárí rẹ̀ jì.” Ó ṣàlàyé pe: “Ẹni yoowu tí ó bá sọ̀rọ̀ kan lòdìsí Ọmọkunrin ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jì í; ṣugbọn ẹni yoowu tí ó bá sọ̀rọ̀ lòdìsí ẹ̀mí mímọ́, a kì yoo dárí rẹ̀ jì í, bẹẹkọ, kii ṣe ninu ètò awọn nǹkan isinsinyi tabi ninu eyi tí ńbọ̀.” Awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi wọnni ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì yẹn nipa fífi àránkan fun Satani ní ìyìn ohun tí ó hàn gbangba pe o jẹ agbara iṣẹ iyanu ti ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun. Matiu 12:22-32; Maaku 3:19-30; Johanu 7:5.

▪ Bawo ni ìrìn àjò Jesu ẹlẹẹkeji sí Galili ṣe yàtọ̀ sí ti àkọ́kọ́?

▪ Eeṣe tí awọn ìbátan Jesu fi gbìdánwò lati nawọ́ mú un?

▪ Bawo ni awọn Farisi ṣe gbìdánwò lati pẹ̀gàn awọn iṣẹ́ ìyanu Jesu, bawo sì ni Jesu ṣe já wọn nírọ́?

▪ Ki ni awọn Farisi naa jẹbi rẹ̀, eesitiṣe?