Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹrù-iṣẹ́ Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn

Ẹrù-iṣẹ́ Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn

Orí 84

Ẹrù-iṣẹ́ Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn

LẸ́HÌN fífi ilé sàràkí Farisi naa silẹ, ẹni tí ó jẹ́ mẹmba Sanhẹdrin ni kedere, Jesu nbaa nìṣó síhà Jerusalẹmu. Ogunlọgọ eniyan tẹle e. Ṣugbọn ki ni awọn ète wọn? Ki ni ó mú lọ́wọ́ niti gidi lati jẹ ọmọlẹhin rẹ̀ tootọ?

Bí wọn ti ńrìnrìn àjò lọ, Jesu yíjú sí ogunlọgọ naa boya ti o mú wọn gbọ̀nrìrì nigba ti ó sọ pe: “Bí ẹnikan bá tọ̀ mí wá tí kò sì kórìíra baba ati iya ati aya ati awọn ọmọ ati awọn arakunrin ati awọn arabinrin rẹ̀, bẹẹni, ati ọkàn rẹ̀ fúnraarẹ̀ pàápàá, oun kò lè jẹ́ ọmọ-ẹhin mi.”

Ki ni Jesu ní lọ́kàn? Jesu kò sọ nihin-in pe awọn ọmọlẹhin rẹ̀ gbọdọ kórìíra awọn ìbátan wọn ni taarata. Kàkà bẹẹ, wọn gbọdọ kórìíra wọn ní ìtumọ̀ níní ìfẹ́ tí ó dínkù sí wọn ju eyi ti wọn yoo ni fun oun. Babanla Jesu Jakọbu ni a sọ pe ó “kórìíra” Lea ó sì nífẹ̀ẹ́ Rakeli, tí ó tumọsi pe ifẹ ti o ni si Lea dinku si eyi ti o ni si arabinrin rẹ̀ Rakeli.

Gba eyi yẹ̀wò, pẹlu, pe Jesu sọ pe ọmọ-ẹhin kan gbọdọ kórìíra “ọkàn rẹ̀ fúnraarẹ̀,” tabi ẹ̀mí. Lẹẹkan sí i ohun tí Jesu ní lọ́kàn ni pe ọmọ-ẹhin tootọ gbọdọ nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ ju bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ẹ̀mí tirẹ̀ fúnraarẹ̀ paapaa lọ. Jesu tipa bayii tẹnumọ́ ọn pe dídi ọmọ-ẹhin rẹ̀ jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ tí ó wúwo kan. Kii ṣe ohun kan tí a lè tẹ́rígbà láìsí ìgbéyẹ̀wò tí a farabalẹ̀ ṣe.

Jíjẹ́ ọmọ-ẹhin Jesu mú ìnira ati inúnibíni lọwọ, bí oun ṣe nbaa lọ lati fihan: “Ẹni yoowu tí kò bá gbé òpó-igi ìdálóró rẹ̀ kí ó sì maa tọ̀ mí lẹ́hìn kò lè jẹ́ ọmọ-ẹhin mi.” Nipa bayii ọmọ-ẹhin tootọ kan gbọdọ múratán lati bọ́ sábẹ́ ẹrù-ìnira ẹ̀gàn kan naa tí Jesu faradà, tí ó tilẹ ní nínú, bí ó bá pọndandan, kíkú ní ọwọ́ awọn ọ̀tá Ọlọrun, eyi tí Jesu yoo ṣe láìpẹ́.

Jíjẹ́ ọmọ-ẹhin Kristi, nitori naa jẹ́ ọ̀ràn tí awọn ogunlọgọ tí ntẹle e gbọdọ gbeyẹwo pẹlu iṣọra. Jesu tẹnumọ́ otitọ yii nipasẹ àkàwé kan. “Fun apẹẹrẹ,” ni oun wí, “ta ni ninu yin tí ó fẹ́ kọ́ ilé-ìṣọ́ kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó sì ṣírò ìnáwó naa, lati ríi bí oun bá ní tó lati parí rẹ̀? Bí kò ṣe bẹẹ, oun lè fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ṣugbọn kí ó má lè parí rẹ̀, gbogbo awọn òǹwòran lè bẹrẹsii pẹ̀gàn rẹ̀, wipe, ‘Ọkunrin yii bẹrẹsii kọ́ ilé ṣugbọn kò lè parí rẹ̀.’”

Nipa bayii Jesu ńṣàkàwé fun awọn ogunlọgọ tí wọn ntẹle e naa pe ṣaaju dídi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wọn gbọdọ pinnu lọna tí ó fìdímúlẹ̀ gbọnyin pe wọn lè mú ohun tí ó mú lọ́wọ́ ṣẹ, gan-an gẹgẹ bi ọkunrin kan tí ó fẹ́ lati kọ́ ilé-ìṣọ́ kan ṣe gbọdọ rí àrídájú ṣaaju kí o tó bẹ̀rẹ̀ pe oun ní ohun àmúṣọrọ̀ ti o tó lati fi parí rẹ̀. Ní pípèsè àkàwé miiran, Jesu nbaa lọ pe:

“Tabi ọba wo, tí ó ńlọ lati pade ọba miiran lójú ogun tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó sì gbà ìmọ̀ràn yálà ó lè fi ẹgbẹrun mẹ́wàá ọmọ-ogun dojúkọ kí ó sì ṣẹ́gun ẹni naa tí ó wá bá a jà pẹlu ẹgbàá mẹ́wàá? Niti tootọ, bí oun kò bá lè ṣe bẹẹ, nigba naa nigba tí onítọ̀hún ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn oun yoo rán ẹgbẹ́ awọn ikọ̀ jáde yoo sì bẹ̀bẹ̀ fun alaafia.”

Jesu lẹhin naa tẹnumọ́ kókó awọn àkàwé rẹ̀, ní sísọ pe: “Nipa bayii, ó lè dá yin lójú pe, kò sí ọ̀kan ninu yin tí kò wipe ó dìgbóṣe fun gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó lè jẹ́ ọmọ-ẹhin mi.” Iyẹn jẹ́ ohun tí awọn ogunlọgọ tí wọn ntẹle e, ati, bẹẹni, olukuluku awọn miiran tí wọn kẹ́kọ̀ọ́ nipa Kristi, gbọdọ múratán lati ṣe. Wọn gbọdọ múratán lati fi ohun gbogbo tí wọn ní rúbọ—gbogbo awọn ohun ìní wọn, títíkan iwalaaye fúnraarẹ̀—bí wọn yoo bá jẹ́ ọmọ-ẹhin rẹ̀. Iwọ ha múratán lati ṣe eyi bí?

“Dajudaju, iyọ̀ jẹ́ rere,” ni Jesu nbaa lọ. Ninu Iwaasu rẹ̀ orí Òkè oun sọ pe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ jẹ́ “iyọ̀ ilẹ̀-ayé,” tí ó tumọsi pe wọn ní agbára ìtọ́júpamọ́ lórí awọn eniyan, kódà bí iyọ̀ gidi ti jẹ́ ohun tí a fi ńtọ́jú nǹkan pamọ́ kuro lọwọ idibajẹ. “Ṣugbọn bí iyọ̀ pàápàá bá sọ okun rẹ̀ nù, ki ni a ó fi mú un dùn? Kò yẹ fun ilẹ̀ tabi fun ìlẹ̀dú,” ni Jesu pari rẹ̀. “Awọn eniyan a dà á nù sóde. Jẹ́ kí ẹni tí ó ní etí lati fetisilẹ, fetisilẹ.”

Nitori naa Jesu fihàn pe kódà awọn wọnni tí wọn ti jẹ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tẹlẹ kò gbọdọ di aláìlágbára ninu ìpinnu wọn lati maa baa nìṣó. Bí wọn bá ṣe bẹẹ, wọn yoo di aláìwúlò, ohun ìpẹ̀gàn kan fun ayé yii ati aláìyẹ niwaju Ọlọrun, niti tootọ, ẹ̀gàn kan lórí Ọlọrun. Nitori bẹẹ, gẹgẹ bi iyọ̀ aláìlókun, tí a kó-èérí-bá, a ó dà wọn nù sóde, bẹẹni, pa wọn run. Luuku 14:25-35, NW; Jẹnẹsisi 29:30-33; Matiu 5:13, NW.

▪ Ki ni ó tumọsi lati “kórìíra” awọn ìbátan ẹni ati ara-ẹni?

▪ Awọn àkàwé meji wo ni Jesu fifúnni, ki ni wọn sì tumọsi?

▪ Ki ni awọn kókó ọrọ tí Jesu sọ ní ipari nipa iyọ̀?