Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ Naa ati Lasaru

Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ Naa ati Lasaru

Orí 88

Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ Naa ati Lasaru

JESU ti ńbá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọ̀rọ̀ nipa lílò awọn ohun ini ti ara lọna tí ó tọ́, ní ṣíṣàlàyé pe a kò lè jẹ́ ẹrú fun eyi ati ní àkókò kan naa kí á jẹ́ ẹrú fun Ọlọrun. Awọn Farisi pẹlu ńfetísílẹ̀, wọn sì bẹrẹsii yinmú sí Jesu nitori pe wọn jẹ́ olùfẹ́ owó. Nitori naa o sọ fun wọn pe: “Ẹyin ni awọn tí ńdáre fun araayin niwaju eniyan; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkan yin: nitori eyi tí a gbé níyì lọ́dọ̀ ènìyàn, ìríra ni niwaju Ọlọrun.”

Àkókò ti dé tí ìgbà yoo yípadà fun awọn eniyan tí wọn ní ọrọ̀ ninu awọn ohun ìní ayé, agbára ìṣèlú, ìṣàkóso ati agbára ìdarí isin. A ó rẹ̀ wọn silẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, awọn wọnni tí wọn mọ̀ àìní wọn nipa tẹ̀mí ni a ó gbéga. Jesu tọ́kasí irúfẹ́ ìyípadà bẹẹ nigba ti ó nbaa lọ lati sọ fun awọn Farisi pe:

“Òfin ati awọn Wolii nbẹ títí di ìgbà Johanu [Arinibọmi]: lati ìgbà naa wá ni a ti nwaasu ijọba Ọlọrun, olukuluku sì ńfi ipá wọ inú rẹ̀. Ṣugbọn ó rọrùn fun ọ̀run oun ayé lati kọjá lọ, ju kí ṣonṣo kan ti ofin ki o yẹ̀.”

Awọn akọwe ofin ati awọn Farisi ńgbéraga nipa sisọ wọn pe wọn ntẹle Òfin Mose pẹkipẹki. Rántí pe nigba ti Jesu la ojú ìríran ọkunrin kan bayii ní Jerusalẹmu lọna iṣẹ́ ìyanu, wọn ṣògo pe: “Ọmọ-ẹhin Mose ni awa. Awa mọ̀ pe Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀.” Ṣugbọn nisinsinyi Òfin Mose ti mú ète rẹ̀ ti ṣíṣamọ̀nà awọn onírẹ̀lẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọba tí Ọlọrun fún lóyè naa, Jesu Kristi ṣẹ. Nitori naa nigba ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ Johanu, gbogbo onírúurú ènìyàn, pàápàá awọn onírẹ̀lẹ̀ ati tálákà, ńlo araawọn dé góńgó lati di ọmọ-abẹ́ Ijọba Ọlọrun.

Niwọn bi Òfin Mose ti ńní ìmúṣẹ nisinsinyi, àìgbọdọ̀máṣe lati pa á mọ́ ni a o múkúrò. Òfin naa yọ̀ọ̀da ìkọ̀sílẹ̀ lórí onírúurú ìdí, ṣugbọn Jesu nisinsinyi wipe: “Ẹnikẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ silẹ, tí ó sì gbé òmíràn ní ìyàwó, ó ṣe panṣaga: ẹnikẹni tí ó bá sì gbé ẹni tí ọkọ rẹ̀ kọ̀sílẹ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣaga.” Bawo ni irúfẹ́ awọn ìkéde bẹẹ gbọdọ ti mú awọn Farisi bínú tó, pàápàá niwọn bi wọn ti gbà ìkọ̀sílẹ̀ láyè lórí ọ̀pọ̀ awọn ìdí!

Ní bíbá awọn àkíyèsí rẹ̀ sí awọn Farisi nìṣó, Jesu sọ àkàwé kan tí ó ni ninu awọn ọkunrin meji, tí ipò tabi ààyè wọn yípadà ní àsẹ̀hìnwá àsẹ̀hìnbọ̀ lọna tí ó múnitagìrì. Iwọ ha lè pinnu awọn tí awọn ọkunrin naa ṣojú fun ati ohun tí ìyípadà ipò wọn tumọsi?

“Njẹ ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà,” ni Jesu ṣàlàyé, “tí ó ńwọ̀ aṣọ elésè àlùkò ati aṣọ àlà daradara, a sì maa jẹ dídùndídùn lojoojumọ: Alágbe kan sì wà tí a ńpè ní Lasaru, tí wọn maa ńgbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fun òóju. Oun a sì maa fẹ́ kí a fi ẹ̀rún tí ó ti orí tabili ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ oun: awọn ajá sì wá, wọn sì fá a ní òóju lá.”

Jesu níhìn-ín lò ọkunrin ọlọ́rọ̀ lati ṣojú fun awọn aṣaaju isin Juu, títí kan kii ṣe awọn Farisi ati awọn akọ̀wé òfin nikan ṣugbọn awọn Sadusi ati awọn olórí alufaa pẹlu. Wọn lọ́rọ̀ ninu awọn àǹfààní ati awọn ire tẹ̀mí, wọn sì ńhùwà bii ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa ti ṣe. Aṣọ elésè àlùkò kábíyèsí wọn dúró fun ipò wọn olójúrere, aṣọ àlà daradara sì ṣàpẹẹrẹ òdodo ara-ẹni wọn.

Ẹgbẹ́ agbéraga ọkunrin ọlọ́rọ̀ yii ńwò awọn tálákà ati gbáàtúù ènìyàn pẹlu ìyọṣùtì sí patapata, ní pípè wọn ní ‛am ha·’aʹrets, tabi awọn ènìyàn ilẹ̀-ayé. Lasaru alágbe tipa bayii ṣojú fun awọn ènìyàn tí awọn aṣaaju isin fi oúnjẹ ati awọn àǹfààní tẹ̀mí dù. Fun ìdí yii, bíi Lasaru tí òóju bò ara rẹ̀, awọn ènìyàn gbáàtúù ni a nfi ojú tẹ̀ mọ́lẹ̀ bi ẹni pe wọn jẹ́ olókùnrùn nipa tẹ̀mí tí wọn sì yẹ kìkì lati bá awọn ajá kẹ́gbẹ́pọ̀. Sibẹsibẹ, awọn tí wọn jẹ́ ti ẹgbẹ Lasaru ni ebi ńpa tí òùngbẹ sì ńgbẹ́ fun oúnjẹ tẹ̀mí tí wọn sì tipa bẹẹ wà ní ẹnu bodè tí wọn ńwá ọ̀nà lati gbà awọn òkèlè oúnjẹ tẹ̀mí yoowu bi o tilẹ kere tí ó lè bọ́ sílẹ̀ lati orí tábìlì ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa.

Jesu nisinsinyi nbaa nìṣó lati ṣàpèjúwe awọn ìyípadà ninu ipò ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa ati Lasaru. Ki ni awọn ìyípadà wọnyi, kí ni wọn sì dúró fun?

Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ ati Lasaru Nírìírí Ìyípadà Kan

Ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa duro fun awọn aṣaaju isin tí a fi awọn àǹfààní ati ire nipa tẹ̀mí ṣojúrere sí, Lasaru sì ṣàpẹẹrẹ awọn gbáàtúù ènìyàn tí ebi oúnjẹ nipa tẹ̀mí ńpa. Jesu ńbá ìtàn rẹ lọ, ní ṣíṣàpèjúwe ìyípadà amúnitagìrì kan ninu ipò awọn ọkunrin naa.

Jesu wipe, “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ awọn angẹli gbé e lọ sí oókan-àyà Aburahamu: ọlọ́rọ̀ naa sì kú pẹlu, a sì sin ín. Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó nbẹ ninu iṣẹ́ oró, ó sì rí Aburahamu ní okeere ati Lasaru ní oókan-àyà rẹ̀.”

Niwọn bi ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa ati Lasaru kìí tií ṣe awọn ènìyàn gidi ṣugbọn tí wọn ṣàpẹẹrẹ ẹgbẹ́ awọn ènìyàn, lọna tí ó bọ́gbọ́nmu ikú wọn pẹlu nilati jẹ́ àpẹẹrẹ. Ki ni ikú wọn ṣàpẹẹrẹ, tabi dúró fún?

Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ parí títọ́ka sí ìyípadà kan ninu awọn ipò nipa wiwi pe ‘Òfin ati awọn Wolii nbẹ títí di ìgbà Johanu Arinibọmi; lati ìgbà naa wá ni a ti nwaasu ijọba Ọlọrun.’ Fun ìdí yii, o jẹ iwaasu Johanu ati Jesu Kristi ni o mu ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa ati Lasaru kú sí awọn ipò wọn iṣaaju.

Awọn wọnni tí wọn jẹ́ ti ẹgbẹ́ Lasaru onírẹ̀lẹ̀ ati onírònúpìwàdà kú sí ipò àìní tẹ̀mí tí a fi wọn sí tẹlẹri, wọn sì wá sí ipò ojúrere atọrunwa. Bí ó tilẹ jẹ́ pe wọn ti kọ́kọ́ gbójúlé awọn aṣaaju isin fun nǹkan kekere tí ńjábọ́ lati orí tábìlì nipa tẹ̀mí naa, nisinsinyi awọn otitọ Iwe Mimọ tí Jesu ńpín fúnni ńkún awọn àìní wọn. A tipa bayii mú wọn wá sí oókan-àyà, tabi ipò ojúrere, ti Aburahamu Títóbijù naa, Jehofa Ọlọrun.

Ní ọwọ́ keji, awọn wọnni tí wọn parapọ̀ di ẹgbẹ́ ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa wá sábẹ́ ojúbi atọrunwa nitori fífi ìtẹpẹlẹmọ́ kọ̀ lati tẹ́wọ́gbà ìhìn-iṣẹ́ Ijọba tí Jesu fikọ́ni. Wọn tipa bayii kú sí ipò wọn olójúrere ti iṣaaju. Niti tootọ, a sọ̀rọ̀ wọn bí ẹni pe wọn wà ninu ìmújoró àfiṣàpẹẹrẹ. Fetisilẹ nisinsinyi sí bí ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa ti ńsọ̀rọ̀:

“Baba Aburahamu, ṣàánú fun mi kí o sì rán Lasaru kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọmi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nitori emi ńjoró ninu ọwọ́ iná yii.” Awọn ìhìn-iṣẹ́ ìdájọ́ amúbíiná Ọlọrun tí awọn ọmọ-ẹhin Kristi pòkìkí ni ohun tí awọn ẹnikọọkan ninu ẹgbẹ́ ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa joró. Wọn ńfẹ́ kí awọn ọmọ-ẹhin naa juwọsilẹ ninu pípolongo awọn ìhìn-iṣẹ́ wọnyi, kí wọn sì tipa bayii pèsè ìwọ̀n ìtura diẹ fun wọn kuro ninu ìmújoró wọn.

“Ṣugbọn Aburahamu wipe, ‘Ọmọ, ranti pe, nigba ayé rẹ, iwọ ti gbà ohun rere tìrẹ, ati Lasaru ohun buburu: ṣugbọn nisinsinyi ará rọ̀ ọ́, iwọ sì ńjoró. Ati pẹlu gbogbo eyi, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbedeméjì awa ati ẹyin, kí awọn tí ńfẹ́, ma baa lè rekọja lati ìhín lọ sọ́dọ̀ yin, kí ẹnikẹni má sì lè ti ọ̀hún rekọja tọ̀ wá wá.’”

Bawo ni irúfẹ́ ìyípòpadà amúnitagìrì bẹẹ yẹn ti bá ìdájọ́ òdodo mu tó tí ó sì bọ́sí i lati ṣẹlẹ̀ láàárín ẹgbẹ́ Lasaru ati ọkunrin ọlọ́rọ̀! Ìyípadà ninu awọn ipò ni a ṣàṣeparí rẹ̀ niwọnba oṣu diẹ lẹhin naa ní Pẹntikọsti 33 C.E., nigba ti a fi majẹmu titun rọ́pò ògbólógbòó majẹmu Òfin. Nigba naa ni ó wá di eyi tí ó ṣe kedere láìṣeéṣìmú pe awọn ọmọ-ẹhin naa, kii ṣe awọn Farisi ati awọn aṣaaju isin miiran, ni Ọlọrun ti ṣojúrere sí. “Ọ̀gbun ńlá” naa tí ó pín ọkunrin ọlọ́rọ̀ afàmìṣàpẹẹrẹ naa níyà kuro lọ́dọ̀ awọn ọmọ-ẹhin Jesu dúró fun ìdájọ́ òdodo aláìṣeéyípadà ti Ọlọrun.

Lẹhin naa ni ọkunrin ọlọ́rọ̀ beere lọwọ “Aburahamu bàbá” pe: “Rán [Lasaru] lọ sí ilé baba mi: nitori pe mo ní arakunrin márùn-ún.” Ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa tipa bayii jẹ́wọ́ pe oun ní ìbátan kan tí ó tubọ ṣe tímọ́tímọ́ pẹlu bàbá miiran, ẹni tii ṣe Satani Eṣu niti tootọ. Ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa beere pe kí Lasaru fi omi là awọn ìhìn-iṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun kí ó má baa fi awọn “arakunrin” rẹ̀ “márùn-ún,” awọn alájọṣe onísìn rẹ̀, sínú “ibi oró yii.”

“Aburahamu sì wi fun un pe, ‘Wọn ní Mose ati awọn wolii; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’” Bẹẹni, bí awọn “arakunrin márùn-ún” naa yoo bá bọ́ lọwọ ìmújoró, gbogbo ohun tí wọn nilati ṣe ni lati kọbiara sí awọn ìwé tí Mose ati awọn Wolii kọ tí ó fi Jesu hàn gẹgẹ bi Mesaya naa, lẹhin naa kí wọn sì di ọmọ-ẹhin rẹ̀. Ṣugbọn ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa takò eyi: “Bẹẹkọ, Aburahamu bàbá; ṣugbọn bí ẹnikan bá ti inú òkú tọ̀ wọn lọ, wọn yoo ronúpìwàdà.”

Bí ó ti wù kí ó rí, a sọ fun un pe: “Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose ati ti awọn wolii, a kì yoo yí wọn lọ́kàn padà bí ẹnikan bá tilẹ ti inú òkú dìde.” Ọlọrun kì yoo pèsè awọn àkànṣe àmì tabi iṣẹ́ ìyanu lati lè mú awọn eniyan gbàgbọ́. Wọn gbọdọ kà kí wọn sì fi Iwe Mimọ sílò bí wọn yoo bá ri ojúrere rẹ̀. Luuku 16:14-31; Johanu 9:28, 29; Matiu 19:3-9; Galatia 3:24; Kolose 2:14; Johanu 8:44.

▪ Ki ni idi rẹ̀ tí ikú ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa ati Lasaru fi gbọdọ jẹ́ àpẹẹrẹ, kí sì ni ikú wọn yàwòrán?

▪ Ni ibẹrẹ iṣẹ́-òjíṣẹ́ Johanu, ìyípadà wo tí Jesu fihàn ni ó ṣẹlẹ̀?

▪ Ki ni a o múkúrò lẹhin ikú Jesu, bawo sì ni eyi yoo ṣe nípa lórí ọ̀ràn ìkọ̀sílẹ̀?

▪ Ninu àkàwé Jesu, awọn wo ni ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa ati Lasaru ṣojú fun?

▪ Awọn ìmújoró wo ni ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa jìyà, kí sì ni ohun tí oun beere pe kí á lò lati fi mú ìtura bá oun?

▪ Ki ni “ọ̀gbun ńlá” naa dúró fun?

▪ Ta ni bàbá ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa niti gidi, awọn wo sì ni arakunrin rẹ̀ márùn-ún?