Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí

A HA lè fi pẹlu idaniloju pe ẹnikẹni ni ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbe aye ri? Bawo ni iwọ ṣe ndiwọn itobilọla ọkunrin kan? Nipa oye ogun ara ọtọ ni bi? nipa agbara ara iyara rẹ̀ ni bi? nipa agbara ironu rẹ ti o tayọlọla ni bi?

Opitan H. G. Wells sọ pe itobilọla ẹnikan ni a ndiwọn nipa ‘ohun ti o fi silẹ lati gberu lẹhin rẹ, ati boya oun sun awọn eniyan lati bẹrẹ sii ronu lori awọn ipa ọna titun pẹlu okun inu alagbara ti o nbaa lọ lẹhin rẹ.’ Wells, bi o tilẹ jẹ pe kò sọ pe oun jẹ Kristẹni, gbà pe: “Nipa idanwo yii Jesu ta gbogbo wọn yọ.”

Alexander Nla, Charlemagne (ẹni ti a pe ni “Nla naa” paapaa nigba aye oun funraarẹ), ati Napoleon Bonaparte jẹ oluṣakoso alagbara kan. Nipa irisi abanilẹru wọn, wọn lo agbara idari nla lori awọn wọnni ti wọn ṣakoso. Sibẹ, Napoleon ni a rohin pe o sọ pe: “Jesu Kristi ni agbara isunniṣe ti o sì ti dari awọn ọmọlẹhin Rẹ̀ laisi nibẹ Rẹ̀ niti ara iyara.”

Nipa ikọnilẹkọọ agbayanu rẹ̀ ati nipa ọna ti o gba gbe igbesi aye rẹ̀ ni ibamu pẹlu wọn, lọna alagbara Jesu ti nipa lori igbesi aye ọpọ eniyan fun ohun ti o to ẹgbẹrun ọdun meji. Gẹgẹ bi onkọwe kan ti sọ ọ ni taarata pe: “Gbogbo awọn ọmọ ogun ti o ti tò lọwọọwọrin rìn, ati gbogbo awọn ogun ojú omi tí a tii kọ́ rí, ati gbogbo awọn igbimọ aṣofin tí ó tii jokoo rí, gbogbo ọba tí o tii ṣakoso ri, gbogbo wọn lapapọ kò tii nipa lori igbesi aye eniyan lori ilẹ aye lọna alagbara tobẹẹ.”

Ẹni Inu Itan Kan

Sibẹ, lọna ti o ṣajeji, awọn kan sọ pe Jesu ko fi igba kan walaaye rí—pe oun, nipa bẹẹ, jẹ ìhùmọ̀ awọn eniyan ọgọrun-un ọdun kìn-ínní kan? Ní dida awọn oniyemeji wọnyi lóhùn, opitan ti a bọwọ fun naa Will Durant jiyan pe: “Pe awọn eniyan gbáàtúù kereje ninu iran kan lè ti humọ ẹni gidi ti o lagbara ti o si fanimọra bẹẹ, ti o ni iwa rere ti o galọla pẹlu aworan iṣọkan ẹgbẹ arakunrin ti o taniji bẹẹ, yoo ti jẹ iṣẹ iyanu gigadabu kan ti o tayọ rekọja eyikeyii ti a ṣakọsilẹ rẹ ninu awọn Ihinrere.”

Beere lọwọ araàrẹ: Njẹ ẹnikan ti ko tii gbe aye ri le nipa lori itan ẹda eniyan lọna ti o kọyọyọ bẹẹ? Iṣẹ itọkasi naa The Historians’ History of the World ṣakiyesi pe: “Abajade awọn igbokegbodo [Jesu] gẹgẹ bi ẹni itan kan jẹ eyi ti o ṣe pataki pupọ, loju iwoye ti kii ṣe ti isin paapaa, ju ti awọn iṣe ẹda eniyan miiran ninu itan. Sáà titun miiran, eyi ti awọn ilẹ ọlọlaju pataki ninu aye mọ daju, bẹrẹ nigba ibi rẹ.”

Bẹẹni, ronu nipa rẹ na. Ani awọn kalẹnda ti a nlo lonii paapaa ni a gbeka ori ọdun ti a lero pe a bí Jesu. “Awọn ọdun ṣaaju igba naa ni a mọ̀ sí B.C., tabi before Christ [ṣaaju ibi Kristi],” ni iwe naa The World Book Encyclopedia ṣalaye. “Awọn igba lẹhin ọdun yẹn ni a npe ni A.D., tabi anno Domini (ni ọdun Oluwa wa).”

Awọn alatako, bi o ti wu ki o ri, tọka jade pe gbogbo ohun ti a mọ niti gidi nipa Jesu ni a ri ninu Bibeli. Ko si akọsilẹ ẹlẹrii miiran nipa rẹ ti o wa larọọwọto, ni wọn sọ. Ani H. G. Wells paapaa kọwe pe: “Awọn opitan Roomu igbaani kọ Jesu silẹ patapata; kò fi ohun iranti kankan silẹ lori akọsilẹ ọlọrọ itan ní akoko rẹ̀.” Ṣugbọn eyi ha jẹ otitọ bí?

Bi o tilẹ jẹ pe itọka si Jesu Kristi lati ọwọ awọn opitan ijimiji kere gidigidi, iru awọn itọkasi bẹẹ wa. Cornelius Tacitus, opitan Roomu ọgọrun-un ọdun kìn-ínní, ti a bọwọ fun kan kọwe pe: “Orukọ naa [Kristẹni] jẹyọ lati inu Kristi, ẹni ti gomina Pọntu Pilatu fiya iku jẹ ni igba iṣakoso Tiberiu.” Suetonius ati Pliny Kekere, awọn onkọwe ilẹ Roomu miiran ni akoko naa, tun tọkasi Kristi pẹlu. Ni afikun, Flavius Josephus, opitan Juu ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní, kọwe nipa Jakọbu, ẹni ti o fihan gẹgẹ bi “arakunrin Jesu, ẹni ti a npe ni Kristi.”

The New Encyclopædia Britannica nipa bayii pari ọrọ naa pe: “Awọn akọsilẹ olominira wọnyi jẹrii pe ni igba ijimiji awọn ọta Kristẹni paapaa ni ko ṣiyemeji jijẹ ẹni itan Jesu rara, eyi ti o wa di ọrọ ariyanjiyan fun igba akọkọ ati lori ipilẹ ti ko lẹsẹnilẹ ni opin ọgọrun-un ọdun kejidinlogun, laaarin ọgọrun-un ọdun kọkandinlogun, ati ni ibẹrẹ ọgọrun-un ọdun ogun tiwa yii.”

Bi o ti wu ki o ri, lọna ti o ṣe koko, gbogbo ohun ti a mọ nipa Jesu ni a ṣe akọsilẹ rẹ nipasẹ awọn ọmọlẹhin rẹ ọgọrun-un ọdun kìn-ínní. Awọn irohin wọn ni a ti pamọ sinu awọn Ihinrere—awọn iwe Bibeli ti a kọ lati ọwọ Matiu, Maaku, Luuku, ati Johanu. Ki ni ohun ti awọn akọsilẹ wọnyi sọ nipa ẹni ti Jesu jẹ́?

Ta Ni Oun Tilẹ Jẹ Niti Gidi?

Awọn alabaakẹgbẹpọ Jesu ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní ṣaṣaro lori ibeere yii. Nigba ti wọn ri ti Jesu fi ọna iyanu ba igbi okun wi ti o si parọrọ, wọn fi pẹlu iyalẹnu wipe: “Ta ni ẹni yii niti tootọ?” Nigba ti o ya, ni akoko iṣẹlẹ miiran, Jesu beere lọwọ awọn apọsiteli rẹ pe: “Ta ni ẹyin nfi mi pe?”—Maaku 4:41; Matiu 16:15.

Bi a ba bi ọ ni ibeere yẹn, bawo ni iwọ yoo ṣe dahun? Jesu nitootọ ha jẹ Ọlọrun bi? Ọpọlọpọ lonii sọ pe oun jẹ bẹẹ. Sibẹ, awọn alabaakẹgbẹpọ rẹ̀ ko fi igba kan ri gbagbọ pe oun ni Ọlọrun. Idahun apọsiteli Peteru si ibeere Jesu ni pe: “Iwọ ni Kristi, Ọmọkunrin Ọlọrun alaaye.”—Matiu 16:16, NW.

Jesu kò fi igba kan sọ pe oun jẹ Ọlọrun, ṣugbọn ó gba pe oun ni Mesaya ti a ṣeleri naa tabi Kristi. O tun sọ pẹlu pe oun jẹ “Ọmọkunrin Ọlọrun,” kii ṣe Ọlọrun. (Johanu 4:25, 26; 10:36) Sibẹ, Bibeli kò sọ pe Jesu dabi eniyan eyikeyii miiran. Oun jẹ́ eniyan àrà ọ̀tọ̀ nitori pe Ọlọrun ti ṣẹda rẹ ṣaaju awọn ohun miiran gbogbo. (Kolose 1:15) Fun araadọta ọkẹ aimoye ọdun, ani ṣaaju ki a to da agbaye wa ti o ṣee fojuri paapaa, Jesu ti gbe gẹgẹ bi ẹda ẹmi ni ọrun ti o si ti gbadun ibatan timọtimọ pẹlu Baba rẹ, Jehofa Ọlọrun, Ẹlẹdaa Atobilọla.—Owe 8:22, 27-31.

Nigba naa, ni nǹkan bi ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, Ọlọrun ta atare iwalaaye ọmọ rẹ sinu ile ọlẹ̀ obinrin kan, Jesu nipa bẹẹ wa di ọmọkunrin Ọlọrun ninu ẹda eniyan, ti a bi gẹgẹ bi o ṣe yẹ ki o ri nipasẹ obinrin kan. (Galatia 4:4) Nigba ti Jesu ndagba sii ninu ile ọlẹ̀, ati nigba ti o ndagba gẹgẹ bi ọmọkunrin kan, oun gbarale awọn wọnni ti Ọlọrun ti yan lati jẹ awọn obi rẹ lori ilẹ-aye. Lẹhin-ọ-rẹhin Jesu dagba de ipo ọkunrin, ti a si fun un ni iranti ibaṣepọ rẹ ti o ti ni ṣaaju pẹlu Ọlọrun loke ọrun lẹkun-unrẹrẹ.—Johanu 8:23; 17:5.

Ohun Tí Ó Mú Kí Ó Tobilọla Julọ

Nitori pe o fi tiṣọratiṣọra ṣafarawe Baba rẹ̀ ọrun, Jesu ni ẹda eniyan titobilọla julọ ti o tii gbe ayé rí. Gẹgẹ bi ọmọkurin oluṣotitọ kan, Jesu farawe Baba rẹ lọna ti o pe perepere ti o fi le sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ pe: “Ẹni ti o ba ti ri mi, o ti ri Baba.” (Johanu 14:9, 10) Ninu oniruuru ipo nihin-in lori ilẹ-aye, oun ṣe gẹgẹ bi Baba rẹ, Ọlọrun Olodumare, yoo ti ṣe. “Emi ko da ohunkohun ṣe fun ara mi,” ni Jesu ṣalaye, “ṣugbọn bi Baba ti kọ mi, emi sọ nǹkan wọnyi.” (Johanu 8:28) Nitori naa, nigba ti awa bá kẹkọọ nipa igbesi aye Jesu Kristi, awa, nipa bẹẹ, nri ni kedere ohun tí Ọlọrun jẹ́.

Nipa bẹẹ, bi o tilẹ jẹ pe apọsiteli Johanu gbà pe “ko si ẹni ti o ri Ọlọrun ri,” oun tún lè kọwe sibẹ pe “ifẹ ni Ọlọrun.” (Johanu 1:18; 1 Johanu 4:8) Johanu le ṣe eyi nitori oun mọ ifẹ Ọlọrun nipasẹ ohun ti oun ti ri ninu Jesu, ẹni ti o jẹ aworan Baba rẹ̀ gẹ́lẹ́. Jesu jẹ oniyọọnu, alaaanu, onirẹlẹ, ati ẹni ti o ṣee sunmọ. Awọn alailera ati awọn ti a tẹ̀mọ́lẹ̀ ni imọlara ifọkan balẹ lọdọ rẹ, gẹgẹ bi oniruuru awọn eniyan ti ṣe—ọkunrin, obinrin, ọmọde, awọn ọlọrọ, awọn talaka, awọn saraki, ati awọn ti ẹ̀ṣẹ̀ wọn wuwo pẹlu. Kiki awọn tí ọkan wọn buru nikan ni kò fẹran rẹ̀.

Nitootọ, Jesu kò wulẹ kọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati nifẹẹ araawọn, ṣugbọn ó fi hàn wọn bi wọn ṣe lè ṣe é. “Ẹyin nilati fẹran ọmọnikeji yin,” ni oun wi, “gẹgẹ bi emi ti fẹran yin.” (Johanu 13:34) Mimọ “ifẹ Kristi,” ni ọkan ninu awọn apọsiteli rẹ̀ ṣalaye, “ta imọ gbogbo yọ.” (Efesu 3:19) Bẹẹni, ifẹ ti Kristi fihan tayọ rekọja imọ ori ẹkọ iwe, ó sì “ńrọ” awọn ẹlomiran lati dahunpada sí i. (2 Kọrinti 5:14) Nipa bayii, apẹẹrẹ ifẹ Jesu tí ó tayọ, ní pataki, ni ohun tí ó mú kí o jẹ ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbé ayé rí. Ifẹ rẹ̀ ti nipa lori ọkàn ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan la ọ̀pọ̀ ọgọrọọrun ọdun ja ó sì ti nipa lori igbesi aye wọn fun rere.

Sibẹ, awọn kan le ṣatako: ‘Wo gbogbo awọn iwa ọdaran ti a ti ṣe ni orukọ Kristi—awọn Ogun Mimọ, awọn Iwadii Onika, ati awọn ogun ti ó ti ri araadọta ọkẹ ti wọn npe araawọn ni Kristẹni ti wọn npa ẹnikinni keji wọn ninu ikọ awọn ọmọ ogun ti o doju kọ araawọn.’ Ṣugbọn otitọ naa ni pe, awọn eniyan wọnyi mu ki ijẹwọ wọn pe wọn jẹ ọmọlẹhin Jesu Kristi di irọ. Awọn ẹkọ ati ọna igbesi-aye rẹ dẹbi fun iwa wọn. Ani Mohandas Gandhi, ti o jẹ Hindu kan paapaa, ni a sun lati sọ pe: ‘Mo fẹran Kristi, ṣugbọn emi koriira awọn Kristẹni nitori wọn ko gbé igbesi aye wọn gẹgẹ bi Kristi ti gbe tirẹ.’

Janfaani Nipa Kikẹkọọ Nipa Rẹ̀

Dajudaju ko si iwadii ti o lè ṣe pataki lonii ju ti igbesi aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu Kristi. “Ki a maa wo Jesu,” ni apọsiteli Pọọlu rọ̀ wá. “Niti tootọ, saa ro ti [ẹni] yii daradara.” Ọlọrun funraarẹ sì paṣẹ nipa Ọmọkunrin rẹ pe: “Ẹ maa gbọ tirẹ.” Eyi ni ohun tí iwe naa Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí yoo ran ọ lọwọ lati ṣe.—Heberu 12:2, 3; Matiu 17:5.

Isapa ni a ti ṣe lati gbe gbogbo iṣẹlẹ ninu igbesi aye Jesu lori ilẹ-aye kalẹ, gẹgẹ bi a ti ṣe akọsilẹ wọn ninu awọn Ihinrere mẹrin naa, titi kan gbogbo awọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ ati awọn apejuwe ati iṣẹ iyanu rẹ. De iwọn ti o ṣeeṣe, ohun gbogbo ni a ṣe akọsilẹ wọn ni ibamu pẹlu akoko ti wọn ṣẹlẹ. Ni opin akori kọọkan ni a ṣe akọsilẹ awọn ẹsẹ Bibeli lori eyi ti a gbe akori naa kà. A rọ̀ ọ́ lati ka awọn ẹsẹ Bibeli wọnyi ki o si dahun awọn ibeere atunyẹwo ti a pese sibẹ.

Ọmọwe kan lati University of Chicago sọ laipẹ yii pe: “Pupọ ni a ti kọ nipa Jesu ni kiki ogún ọdun ti o kọja ju ní ẹgbẹrun ọdun meji ti o ṣaaju.” Sibẹ aini pataki wà lati ṣagbeyẹwo awọn akọsilẹ Ihinrere naa fúnraàrẹ, nitori gẹgẹ bi The Encyclopædia Britannica ti wi: “Ọpọ awọn akẹkọọ ode oni ni àbá ti o takora nipa Jesu ati awọn Ihinrere ti gbà lọ́kàn ti o fi jẹ pe wọn ti kọ̀ lati kẹkọọ awọn orisun ipilẹ wọnyi funraawọn.”

Lẹhin igbeyẹwo kinnikinni ti kò ní ẹ̀tanú nipa awọn akọsilẹ Ihinrere, a nimọlara pe iwọ yoo fohunṣọkan pe iṣẹlẹ titobilọla julọ ninu gbogbo ọrọ itan ẹda eniyan ṣẹlẹ lakooko iṣakoso Kesari Roomu naa Ọgọsitọsi, nigba ti Jesu ara Nasarẹti farahan lori ilẹ-aye ti o si fi ẹmi rẹ lelẹ nitori wa.