Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọ-ẹhin kan Tí A Kò Ronúkàn

Ọmọ-ẹhin kan Tí A Kò Ronúkàn

Orí 45

Ọmọ-ẹhin kan Tí A Kò Ronúkàn

IRU ìran ti nko jìnnìjìnnì báni wo ni eyi bi Jesu ti ngbẹsẹ le ebute! Awọn ọkunrin àràmàǹdà meji ti wọn rorò jáde wá lati ibi ìsìnkú kan ti o wà ní ìtòsí tí wọn sì sáré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọn jẹ́ ẹlẹ́mìí èṣù. Niwọn bi ó ti ṣeeṣe ki ọ̀kan ninu wọn ní ìwà-ipá jù tí ó sì ti jìyà fun àkókò pípẹ́ jù lábẹ́ akoso ẹ̀mí èṣù ju ekeji lọ, oun di ọ̀gangan àfiyèsí.

Fun àkókò gígùn ọkunrin tí ó ṣenilaaanu yii tí ńgbé níhòhò láàárín awọn ibojì. Nigba gbogbo, lọ́sàn-án ati lóru, ó ńkígbe ó sì ńfi awọn òkúta gé araarẹ̀ fálafàla. O jẹ́ oníwà ipá tobẹẹ tí ó fi jẹ́ pe ẹni kankan kò ní ìgboyà lati gba ojú ọ̀nà naa kọja. Ìgbìyànjú ni a ti ṣe lati dè é, ṣugbọn oun ńjá awọn ẹ̀wọ̀n sọ́tọ̀ ó sì ńṣẹ́ awọn irin kuro ní ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹni kankan tí ó lókun lati tẹ̀ ẹ́ lóríba.

Bí ọkunrin naa ti tọ Jesu wá tí ó sì wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, awọn ẹ̀mí èṣù tí wọn nṣakoso rẹ̀ mú un kígbe ní ohùn rara pe: “Ki ni emi niiṣe pẹlu rẹ, Jesu, Ọmọkunrin Ọlọrun Ọ̀gá-ògo Jùlọ? Mo fi ọ sábẹ́ ìbúra lọ́dọ̀ Ọlọrun lati maṣe mú mi joró.”

“Jáde kuro ninu ọkunrin naa, iwọ ẹ̀mí àìmọ́,” ni Jesu nbaa lọ lati sọ. Lẹhin naa Jesu beere pe: “Ki ni orukọ rẹ?”

“Lijiọni ni orukọ mi, nitori awa pọ̀,” ni èsì rẹ̀. Awọn ẹ̀mí èṣù maa ńyọ̀ṣìnṣìn ní rírí ìjìyà awọn wọnni tí wọn lè fi sabẹ ìdè, tí ó hàn gbangba pe wọn ní inúdídùn ní pípawọ́pọ̀ ṣùrùbò wọn lọna ojo. Ṣugbọn nigba ti wọn pade Jesu, wọn bẹ̀bẹ̀ pe kí o maṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun. Lẹẹkan sí i awa ríi pe Jesu ní agbára ńlá; oun lágbára lati ṣẹ́gun àní awọn ẹ̀mí èṣù abèṣe pàápàá. Eyi tún ṣí i payá pe awọn ẹ̀mí èṣù mọ̀ pe gbígbé sọ sínú ọ̀gbun pẹlu aṣaaju wọn, Satani Eṣu, jẹ́ ìdájọ́ àsẹ̀hìnwá àsẹ̀hìnbọ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun fun wọn.

Agbo ẹran kan tí iye rẹ̀ tó nǹkan bii 2,000 ẹlẹ́dẹ̀ ńjẹko nítòsí lórí òkè. Nitori naa awọn ẹ̀mí èṣù naa wipe: “Rán wa lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀, kí awa lè wọ inú wọn.” Bí ó ti hàn kedere awọn ẹ̀mí èṣù naa maa ńrí irú adùn oníwà ìkà kan tí kò bá ìwà-ẹ̀dá mu lati inú rírọ́lù awọn ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara. Nigba ti Jesu yọọda fun wọn lati wọnú agbo ẹlẹ́dẹ̀ naa, gbogbo awọn 2,000 naa sáré kọja lórí àpáta bèbè òkun naa wọn sì rì sínú òkun.

Nigba ti awọn tí ńbójútó agbo ẹlẹ́dẹ̀ naa rí eyi, wọn ṣíra lati lọ jábọ̀ ìròhìn yii ninu ìlú naa ati ìgbèríko tí ó yí i ká. Láìfa ọ̀rọ̀ gùn, awọn eniyan jáde lati rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nigba ti wọn dé, wọn rí ọkunrin naa tí awọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lara rẹ̀. Họ́wù, oun ti wọṣọ, orí rẹ̀ ti wálé, ó sì jókòó ní ẹsẹ̀ Jesu!

Awọn ẹlẹrii olùfojúrí ròhìn bí a ṣe mú ọkunrin naa láradá. Wọn sọ fun awọn eniyan naa pẹlu nipa ikú awọn ẹlẹ́dẹ̀ naa lọna ti o ṣajeji. Nigba ti awọn eniyan naa gbọ́ eyi, wọn bẹru gidigidi, wọn sì fi taratara rọ̀ Jesu lati fi ìpínlẹ̀ wọn silẹ. Nitori naa oun ṣègbọràn ó sì wọnú ọkọ̀ ojú omi. Ẹlẹ́mìí èṣù tẹlẹri naa bẹ Jesu lati yọnda ki oun tẹle e lọ. Ṣugbọn Jesu sọ fun un pe: “Lọ sí ilé sọ́dọ̀ awọn ìbátan rẹ, kí o sì ròhìn gbogbo ohun tí Jehofa ti ṣe fun ọ ati àánú tí ó ní lórí rẹ.”

Jesu saba maa ńfún awọn wọnni tí oun mú láradá ní ìtọ́ni lati maṣe sọ fun ẹnikẹni, niwọn bi oun kò ti fẹ́ kí awọn eniyan dé orí awọn òpin èrò lórí ìpìlẹ̀ awọn ìròhìn tí ńru ìmọ̀lára sókè. Ṣugbọn ọ̀ràn àrà ọ̀tọ̀ yii ṣe pataki nitori ẹlẹ́mìí èṣù tẹlẹri naa yoo jẹ́rìí láàárín awọn eniyan tí àkókò lè má ṣí sílẹ̀ fun Jesu mọ́ nisinsinyi lati dé ọ̀dọ̀ wọn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wíwà níbẹ̀ ọkunrin naa yoo pèsè ẹ̀rí nipa agbára Jesu lati ṣe iṣẹ́ ti o dara, tí yoo wọ́gilé ìròhìn aláìbáradé eyikeyii tí awọn eniyan lè ti tànkiri lórí ìpàdánù agbo ẹlẹ́dẹ̀ naa.

Ní títẹ̀lé ìtọ́ni Jesu, ẹlẹ́mìí èṣù tẹlẹri naa lọ kúrò. Ó bẹrẹsii pòkìkí gbogbo ohun tí Jesu ti ṣe fun un jákèjádò Dekapolisi, awọn eniyan naa sì wulẹ̀ ṣe kàyéfì ni. Matiu 8:28-34; Maaku 5:1-20; Luuku 8:26-39; Iṣipaya 20:1-3.

▪ Eeṣe, boya, tí ọ̀gangan àfiyèsí fi wà lórí ẹlẹ́mìí èṣù kanṣoṣo nigba tí ó jẹ́ pe awọn meji ni ó wà níbẹ̀?

▪ Ki ni ó fihàn pe awọn ẹ̀mí èṣù naa mọ̀ nipa gbígbé sínú ọ̀gbun ní ọjọ́ iwájú?

▪ Eeṣe, bí ó ti hàn kedere, tí awọn ẹ̀mí èṣù fi ńfẹ́ lati maa gbé awọn ẹ̀dá-ènìyàn ati awọn ẹranko dè?

▪ Eeṣe tí Jesu fi ṣe ohun tí ó yàtọ̀ pẹlu ẹlẹ́mìí èṣù tẹlẹri naa, ní fífún un ní ìtọ́ni lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa ohun tí Oun ṣe fun un?