Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọ Ileri Naa

Ọmọ Ileri Naa

Orí 6

Ọmọ Ileri Naa

DIPO ki wọn pada si Nasarẹti, Josẹfu ati Maria duro si Bẹtilẹhẹmu. Nigba ti Jesu sì pe ọmọ ọjọ mẹjọ, wọn kọ ọ́ nila, gẹgẹ bi Òfin Ọlọrun fun Mose ti pa á laṣẹ. O dabi ẹni pe o jẹ́ àṣà pẹlu lati fun ọmọ ọkunrin ni orukọ ni ọjọ kẹjọ. Nipa bẹẹ wọn pe orukọ ọmọ wọn ni Jesu, gẹgẹ bi angẹli Geburẹli ti dari wọn ṣaaju.

Ohun ti o ju oṣu kan kọja lọ, Jesu ti di ọmọ ogoji ọjọ́. Nibo ni awọn òbí rẹ̀ ngbe e lọ nisinsinyi? Si tẹmpili ni Jerusalemu ni, eyi ti o wà ni iwọnba ibusọ diẹ si ibi ti wọn ngbe. Gẹgẹ bi Òfin Ọlọrun fun Mose ti wi, ogoji ọjọ́ lẹhin ti a ba ti bi ọmọkunrin kan, iya rẹ̀ ni a beere pe ki o gbe ọrẹ ẹbọ iwẹnumọ kan kalẹ ni tẹmpili.

Eyi ni ohun ti Maria ṣe. Gẹgẹ bi ọrẹ ẹbọ rẹ̀, oun mú awọn ẹyẹ keekeeke meji wá. Eyi fi ohun kan hàn nipa ipo iṣunna owo Josẹfu ati Maria. Ofin Mose fihan pe ọ̀dọ́ agutan kan, eyi ti o niyelori pupọ ju awọn ẹyẹ lọ, ni a nilati fi ṣe ọrẹ ẹbọ. Ṣugbọn bi iya naa kò bá lagbara eyi, awọn àdàbà meji tabi ẹyẹlé meji ti tó.

Ninu tẹmpili ọkunrin arúgbó kan gbé Jesu sí apa rẹ̀. Orukọ rẹ̀ ni Simioni. Ọlọrun ti ṣipaya fun un pe oun kì yoo kú ṣaaju ki o to ri Kristi tabi Mesaya naa ti Jehofa ti ṣeleri. Nigba ti Simioni wá sí tẹmpili ni ọjọ yii, ẹmi mimọ dari rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọmọ naa ti Josẹfu ati Maria gbé lọwọ.

Bí Simioni ṣe gbé Jesu lọwọ o dupẹ lọwọ Ọlọrun, ni wiwi pe: “Oluwa, nigba yii ni o tó jọwọ ọmọ ọdọ rẹ lọwọ lọ ni alaafia, gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ rẹ: nitori ti oju mi ti ri igbala rẹ̀ ná, ti iwọ ti pese silẹ niwaju eniyan gbogbo; imọlẹ lati mọ́ sí awọn keferi, ati ògo Isirẹli eniyan rẹ.”

Ẹnu ya Josẹfu ati Maria nigba ti wọn gbọ́ eyi. Nigba naa ni Simioni sure fun wọn ti o sì wi fun Maria pe ọmọkunrin rẹ̀ ni a gbé “kalẹ fun iṣubu ati idide ọpọ eniyan ni Isirẹli” ati pe ọ̀fọ̀, gẹgẹ bi idà mímú kan, yoo gún obinrin naa ní ọkàn.

Ẹnikan ti o wà nihin-in ni akoko yii ni wolii obinrin arúgbó ẹni 84 ọdun naa ti orukọ rẹ̀ ńjẹ́ Ana. Nitootọ, a kìí fẹ́ ẹ kù ni tẹmpili. Ni wakati yẹn gan-an o sunmọtosi o sì bẹrẹ sii fi ọpẹ́ fun Ọlọrun o sì nsọrọ nipa Jesu fun gbogbo awọn ti yoo fetisilẹ.

Ẹ wo bi Josẹfu ati Maria ṣe layọ to nipa awọn iṣẹlẹ wọnyi ti o ṣẹlẹ ninu tẹmpili! Dajudaju, gbogbo eyi mú un dá wọn loju pe ọmọ naa ni Ẹni naa ti Ọlọrun ti Ṣeleri. Luuku 2:21-38; Lefitiku 12:1-8.

▪ Nigba wo ni o dabi ẹni pe o jẹ àṣà lati fun ọmọ ọwọ́ kan ni orukọ rẹ̀ ni Isirẹli?

▪ Ki ni a beere lọwọ iya kan ni Isirẹli nigba ti ọmọkunrin rẹ̀ bá pe ọmọ ogoji ọjọ́, bawo sì ni imuṣẹ ohun ti a beere yii ṣe fi ipo iṣunna owó Maria hàn?

▪ Awọn wo ni o jẹwọ ẹni ti Jesu jẹ́ gan-an ni akoko iṣẹlẹ yii, bawo ni wọn sì ṣe fi eyi hàn?