Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Bí Atọ́nàṣe Naa

A Bí Atọ́nàṣe Naa

Orí 3

A Bí Atọ́nàṣe Naa

OTI fẹrẹẹ tó akoko fun Elisabẹti lati bí ọmọ rẹ̀. Fun oṣu mẹta sẹhin ni Maria ti wà pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyi akoko ti tó fun Maria lati sọ pe o digboṣe ati lati rin irin ajo gígùn pada sí ile si Nasarẹti. Ni nǹkan bii oṣu mẹfa sii oun pẹlu yoo ni ọmọ-ọwọ́ kan.

Laipẹ lẹhin ti Maria ti lọ, Elisabẹti bímọ. Irú idunnu wo ni eyi jẹ́ nigba ti ibimọ naa yọrisirere tí ọmọ ké tí ìyá sì fọhùn! Nigba ti Elisabẹti fi ọmọ jòjòló naa han awọn aladuugbo ati awọn ibatan rẹ̀, gbogbo wọn bá a yọ.

Ọjọ kẹjọ lẹhin ìbí rẹ̀, ni ibamu pẹlu Òfin Ọlọrun, ọmọkunrin ni Isirẹli ni a gbọdọ kọ nila. Nitori iṣẹlẹ akanṣe yii awọn ọ̀rẹ́ ati awọn ibatan wá lati ṣe ibẹwo. Wọn sọ pe ọmọkunrin naa ni a nilati sọ ní orukọ baba rẹ̀, Sekaraya. Ṣugbọn Elisabẹti sọ̀r sókè. “Bẹẹkọ!” ni oun wí, “Johanu ni a o pè é.” Ranti pe, orukọ ti angẹli Geburẹli sọ pe a nilati fun ọmọ naa niyẹn.

Bi o ti wu ki o ri, awọn ọ̀rẹ́ wọn fi ilodisi wọn hàn: “Kò sí ọkan ninu awọn ará rẹ̀ ti a npe ni orukọ yii.” Lẹhin naa, nipa fifi ara ṣapejuwe, wọn beere orukọ ti baba rẹ̀ ńfẹ́ lati sọ ọmọkunrin naa. Ni bibeere fun wàláà kan, Sekaraya, si iyalẹnu gbogbo wọn, kọ pe: “Johanu ni orukọ rẹ̀.”

Pẹlu eyi, lọna iṣẹ iyanu, agbara isọrọ Sekaraya padabọsipo. Iwọ yoo ranti pe oun padanu agbara ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ nigba ti oun kò gba ifilọ angẹli naa gbọ́ pe Elisabẹti yoo bí ọmọ kan. Tóò, nigba ti Sekaraya sọ̀rọ̀, gbogbo awọn ti o wà ní adugbo ni ẹnu yà wọn sì nsọ fun araawọn pe: “Iru ọmọ ki ni eyi yoo jẹ́?”

Sekaraya nisinsinyi kún fun ẹmi mimọ, o sìfi ayọ rẹ̀ hàn bayii pe: “Olubukun ni Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun Isirẹli; nitori ti o ti bojuwo, ti o sì ti dá awọn eniyan rẹ̀ nídè. Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fun wa ni ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.” “Ìwo ìgbàlà” yii, dajudaju, ni Jesu Oluwa, ẹni ti a ṣẹ̀ṣẹ̀ maa bí. Nipasẹ rẹ̀, Sekaraya sọ pe, Ọlọrun yoo “fi fun wa, lati gba wa lọwọ awọn ọta wa, ki awa ki o lè maa sìn ín laifoya, ni mímọ́ ìwà ati ní òdodo niwaju rẹ̀, ni ọjọ aye wa gbogbo.”

Sekaraya lẹhin naa sọtẹlẹ nipa ọmọkunrin rẹ̀, Johanu pe: “Ati iwọ, ọmọ, wolii Ọga Ogo ni a o maa pè ọ́: nitori iwọ ni yoo ṣaaju Oluwa [“Jehofa,” NW] lati tún ọna rẹ̀ ṣe; lati fi ìmọ̀ ìgbàlà fun awọn eniyan rẹ̀ fun imukuro ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nitori ìyọ́nú Ọlọrun wa; nipa eyi tí ìlà-oòrùn lati òkè wa bojuwo wa, lati fi imọlẹ fun awọn ti o jokoo ní okunkun ati ní òjìji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa lé ọna alaafia.”

Ní akoko yii Maria, ẹni ti o han gbangba pe o ṣì jẹ́ obinrin tí a kò tíì gbé niyawo sibẹ, ti dé ile ní Nasarẹti. Ki ni ohun tí yoo ṣẹlẹ si i nigba ti o ba hàn gbangba pe o ti lóyún? Luuku 1:56-80; Lefitiku 12:2, 3.

▪ Oṣu meloo ni Johanu fi ju Jesu lọ?

▪ Ki ni awọn ohun ti o ṣẹlẹ nigba tí Johanu wà ni ọmọ ọjọ́ mẹjọ?

▪ Bawo ni Ọlọrun ṣe yí afiyesi rẹ̀ sori awọn eniyan rẹ̀?

▪ Iṣẹ́ wo ni a sọtẹlẹ pe Johanu yoo ṣe?