Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Bọla Fun Un Ṣaaju Ìbí Rẹ̀

A Bọla Fun Un Ṣaaju Ìbí Rẹ̀

Orí 2

A Bọla Fun Un Ṣaaju Ìbí Rẹ̀

LẸHIN ìgbà ti angẹli Geburẹli sọ fun ọdọmọbinrin naa Maria pe yoo bi ọmọkunrin kan ti yoo di ọba ayeraye, Maria beere pe: “Eyi yoo ha ti ṣe ri bẹẹ, nigba ti emi kò tii mọ ọkunrin?”

“Ẹmi mimọ yoo tọ̀ ọ́ wá,” ni Geburẹli ṣalaye, “ati agbara Ọga Ogo yoo ṣíji bò ọ́. Nitori naa ohun mímọ́ ti a o ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọrun ni a o maa pè é.”

Lati ran Maria lọwọ lati gba ihin iṣẹ rẹ̀ gbọ́, Geburẹli nbaa lọ: “Sì kiyesi i, Elisabẹti ibatan rẹ̀, oun pẹlu sì loyun ọmọkunrin kan ni ògbólógbòó rẹ̀: eyi sì ni oṣu kẹfa fun ẹni ti a npe ni àgàn. Nitori kò sí ohun tí Ọlọrun kò lè ṣe.”

Maria gba ọ̀rọ̀ Geburẹli. Kí sì ni idahunpada rẹ̀? “Woo ọmọ ọ̀dọ̀ Oluwa [“Jehofa,” NW],” ni oun ṣe sáàfúlà. “Ki o rí fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ rẹ.”

Kété lẹhin ti Geburẹli lọ, Maria mura o sì lọ ṣe ibẹwo sọdọ Elisabẹti, ẹni ti o ngbe pẹlu ọkọ rẹ̀, Sekaraya, ni abule oloke ti Judia. Lati ibugbe Maria ni Nasarẹti, eyi jẹ́ irin ajo gígùn ti o lè gba boya ọjọ mẹta tabi mẹrin.

Nigba ti Maria dé sí ile Sekaraya nikẹhin, o wọle o sì kí wọn. Loju ẹsẹ, Elisabẹti kún fun ẹmi mimọ, oun sì wi fun Maria pe: “Alabukun fun ni iwọ ninu awọn obinrin, alabukun fun sì ni ọmọ inu rẹ. Nibo sì ni eyi ti wá bá mi, ti iya Oluwa mi iba fi tọ̀ mi wa? Sawoo, bi ohùn kíkí rẹ̀ ti bọ́ si mi ni eti, ọlẹ̀ sọ ninu mi fun ayọ̀.”

Ni gbígbọ́ eyi, Maria dahunpada pẹlu imọriri atọkanwa pe: “Ọkàn mi yoo yin Oluwa [“Jehofa,” NW] lógo, ẹmi mi sì yọ sí Ọlọrun olugbala mi. Nitori ti o ṣíjúwo ìwà irẹlẹ ọmọbinrin ọ̀dọ́ rẹ̀: sawoo, lati isinsinyi lọ gbogbo iran eniyan ni yoo maa pè mi ni alabukun fun. Nitori ẹni ti o ní agbara ti ṣe ohun ti o tóbi fun mi.” Sibẹ, laika ojúrere ti a fihan sí i si, Maria darí gbogbo ọlá sọdọ Ọlọrun. “Mímọ́ sì ni orukọ rẹ̀,” ni oun sọ, “aanu rẹ̀ sì nbẹ fun awọn ti o bẹru rẹ̀ lati irandiran.”

Maria nbaa lọ lati fi iyìn fun Ọlọrun ninu orin alasọtẹlẹ ti a mísí, o npolongo pe: “O ti fi agbára hàn ni apá rẹ̀; ó ti tú awọn onírera ká ni ironu ọkàn wọn. O ti mú awọn alagbara kuro lori ìtẹ́ wọn, o sì gbé awọn talaka lékè. O ti fi ohun ti o dara kún awọn tí ebi npa, o sì rán awọn ọlọ́rọ̀ pada lọwọ òfo. O ti ran Isirẹli ọmọ ọdọ rẹ̀ lọwọ, ni iranti aanu rẹ̀; bi o ti sọ fun awọn baba wa, fun Aburahamu, ati fun iru ọmọ rẹ̀ laelae.”

Maria duro ti Elisabẹti fun nnkan bii oṣu mẹta, laisi iyemeji oun jẹ iranlọwọ titobi kan fun un laaarin awọn akoko ọsẹ ikẹhin iloyun Elisabẹti yii. O jẹ ohun rere nitootọ pe awọn obinrin oloootọ meji wọnyi, ti awọn mejeeji loyun ọmọ pẹlu iranlọwọ Ọlọrun, lè wà papọ ni akoko onibukun yii ninu igbesi aye wọn!

O ha kiyesi ọlá ti a fi fun Jesu ani ṣaaju ki a tó bí i paapaa? Elisabẹti pè é ni “Oluwa mi,” ọmọ rẹ̀ ti a kò tii bí gbérasọ pẹlu idunnu nigba ti Maria kọ́kọ́ farahan. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, awọn miiran lẹhin naa kò fi ọ̀wọ̀ ti o tọ́ hàn fun Maria ati ọmọ rẹ̀ ti a o bí, gẹgẹ bi awa yoo ti rí i. Luuku 1:26-56.

▪ Ki ni ohun ti Geburẹli sọ lati ran Maria lọwọ lati loye ọna ti yoo gbà lóyún?

▪ Bawo ni a ṣe bọla fun Jesu ṣaaju ki a tó bí i?

▪ Ki ni Maria sọ ninu orin alasọtẹlẹ kan ni fifi iyìn fun Ọlọrun?

▪ Bawo ni Maria ṣe wà lọdọ Elisabẹti pẹ́ tó, eesitiṣe ti o fi baamu pe ki Maria duro ti Elisabẹti laaarin akoko yii?