Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Bi Í Leere Nipa Ààwẹ̀

A Bi Í Leere Nipa Ààwẹ̀

Orí 28

A Bi Í Leere Nipa Ààwẹ̀

ÓFẸRẸẸ tó ọdun kan sẹhin bayii lati ìgbà tí Jesu ti lọ sí ibi Irekọja ti 30 C.E. Nisinsinyi, Johanu Arinibọmi ni a ti fi sẹ́wọ̀n fun ọpọlọpọ oṣu. Bí ó tilẹ jẹ́ pe ó fẹ́ kí awọn ọmọ-ẹhin oun di awọn ọmọlẹhin Kristi, kii ṣe gbogbo wọn ni wọn tíì ṣe bẹẹ.

Wàyí diẹ lára awọn ọmọ-ẹhin Johanu tí o wà ní ẹ̀wọ̀n naa wá sí ọ̀dọ̀ Jesu wọn sì beere pe: “Eeṣe tí awa ati awọn Farisi sọ ààwẹ̀ gbígbà dàṣà ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ kìí gbààwẹ̀?” Awọn Farisi sọ ààwẹ̀ gbígbà lẹẹmeji lọ́sẹ̀ dàṣà gẹgẹ bi àṣà isin wọn. Boya awọn ọmọ-ẹhin Johanu ntẹle àṣà kan tí ó farajọra. Ó sì tún lè jẹ́ pe wọn ńgbààwẹ̀ lati ṣọ̀fọ̀ ìfisẹ́wọ̀n Johanu tí wọn sì ńṣe kàyéfì ìdí tí awọn ọmọ-ẹhin Jesu kò fi darapọ̀ mọ́ wọn ninu ìfihànjáde ẹ̀dùn ọkàn yii.

Ní ìdáhùn Jesu ṣàlàyé pe: “Awọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó kò ní ìdí lati ṣọ̀fọ̀ niwọn ìgbà tí ọkọ ìyàwó wà lọ́dọ̀ wọn, wọn ha ní ìdí lati ṣe bẹẹ bí? Ṣugbọn ọjọ ńbọ̀ nigba ti a ó gba ọkọ ìyàwó lọ kuro lọ́dọ̀ wọn, nigba naa wọn yoo gbààwẹ̀.”

Awọn ọmọ-ẹhin Johanu gbọdọ rántí pe Johanu fúnraarẹ̀ sọ̀rọ̀ nipa Jesu gẹgẹ bi Ọkọ ìyàwó naa. Nitori naa nigba tí Jesu ṣì wà, Johanu kì yoo kà á sí ohun tí ó ba a mu lati gbààwẹ̀, bẹẹ sì ni awọn ọmọ-ẹhin Jesu. Lẹhin iyẹn, nigba ti Jesu kú, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ wọn sì gbààwẹ̀. Ṣugbọn nigba ti a jí i dìde tí ó sì gòkè re ọ̀run, wọn kò ní ìdí siwaju sí i fun gbígba ààwẹ̀ ọ̀fọ̀.

Lẹhin naa, Jesu fúnni ní awọn àkàwé wọnyi: “Kò sí ẹnikẹni tí ńrán àbùlẹ̀ aṣọ tí kò súnkì lórí ògbólógbòó ẹ̀wù àwọ̀lé; nitori ẹkunrẹrẹ okùn rẹ̀ a fagbára fà kuro lára ẹ̀wù àwọ̀lé, ìfàya naa a sì tubọ burú. Bẹẹ ni awọn ènìyàn kìí fi ọtí waini titun sínú ògbólógbòó awọ ọti waini; ṣugbọn bí wọn bá ṣe bẹẹ, nigba naa awọ ọti waini naa a bẹ́ ọtí waini a sì tú dànù, awọ ọti waini a sì bàjẹ́. Ṣugbọn awọn ènìyàn a maa fi ọtí waini titun sínú awọ ọti waini titun.” Ki ni awọn àkàwé wọnyi nii ṣe pẹlu gbígbààwẹ̀?

Jesu ńran awọn ọmọ-ẹhin Johanu Arinibọmi lọwọ lati mọrírì pe ẹnikẹni kò nilati reti pe ki awọn ọmọ-ẹhin oun faramọ awọn àṣà ògbólógbòó ti isin awọn Juu, irú bíi ìgbààwẹ̀ aláàtò àṣà. Oun kò wá lati ṣàbùlẹ̀ ati lati mú awọn ètò ìgbékalẹ̀ ijọsin ògbólógbòó tí o yẹ fun ìgbésọnù pẹ́. Isin Kristẹni ni a kì yoo mú bá isin awọn Juu ti àkókò ìgbà naa mú pẹlu awọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn rẹ̀. Rárá, kò ní dabi àbùlẹ̀ titun lórí ẹ̀wù àwọ̀lé ògbólógbòó tabi gẹgẹ bi ọtí waini titun ninu awọ ọtí waini ògbólógbòó kan. Matiu 9:14-17; Maaku 2:18-22; Luuku 5:33-39; Johanu 3:27-29.

▪ Awọn wo ni wọn sọ ààwẹ̀ gbígbà dàṣà, fun ète wo sì ni?

▪ Eeṣe tí awọn ọmọ-ẹhin Jesu kò fi gbààwẹ̀ nigba tí oun wà pẹlu wọn, ati nigbẹhin bawo ni ìdí fun gbígbààwẹ̀ yoo ṣe dàwátì láìpẹ́?

▪ Awọn àkàwé wo ni Jesu sọ, ki ni wọn sì tumọsi?