Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Fà Á Lé Wọn Lọwọ Wọn Si Mu Un Lọ

A Fà Á Lé Wọn Lọwọ Wọn Si Mu Un Lọ

Orí 124

A Fà Á Lé Wọn Lọwọ Wọn Si Mu Un Lọ

NIGBA ti Pilatu, ẹni ti ìwà jẹ́jẹ́ Jesu ti a ti daloro wú lori, gbiyanju lẹẹkan sii lati tú u silẹ, ibinu awọn olori alufa tún peleke sii. Wọn ti pinnu lati maṣe jẹ ki ohunkohun ṣedilọwọ fun ète buruku wọn. Nitori naa wọn tun bẹrẹ ariwo yèè lẹẹkan sii: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”

Pilatu dahunpada pe: “Ẹ mú un funra yin ki ẹ si kàn án mọ́gi.” (Ni odikeji si ohun ti wọn sọ ni iṣaaju, awọn Juu le ni aṣẹ lati fiya iku jẹ awọn ọdaran fun awọn ẹṣẹ ti o jẹmọ ijọsin ti iwuwo rẹ̀ pọ dé ààyè kan.) Lẹhin naa, fun o keretan igba karun-un, Pilatu sọ ni gbangba pe Jesu jẹ alaiṣẹ alairo, ni wiwi pe: “Emi ko ri ariwisi eyikeyii ninu rẹ.”

Awọn Juu, ni ririi pe awọn ẹ̀sùn oṣelu wọn ti kuna lati mu eso jade, yipada si ẹ̀sùn ọrọ odi nipa isin tí wọn ti lo ni ọpọlọpọ wakati ṣaaju nibi ìgbẹ́jọ́ Jesu niwaju awọn Sanhẹdrin. Wọn wipe, “Awa ni ofin kan, ati ni ibamu pẹlu ofin naa oun yẹ si iku, nitori pe oun fi araarẹ ṣe ọmọkunrin Ọlọrun.”

Ẹ̀sùn yi jẹ titun si Pilatu, o si mu ki o bẹru. Nisinsinyi oun mọ daju pe Jesu kii ṣe eniyan lasan, ani gẹgẹ bi àlá aya rẹ ati bi agbara animọ ara ọtọ ti Jesu ni ti fihan. Ṣugbọn “ọmọkunrin Ọlọrun” kẹ̀? Pilatu mọ pe Jesu wa lati Galili. Sibẹ, o ha le ṣeeṣe pe oun ti walaaye ṣaaju bi? Ni mimu un pada sinu aafin lẹẹkan sii, Pilatu beere pe: “Nibo ni iwọ ti wa?”

Jesu dakẹ jẹẹ. Ṣaaju isinsinyi oun ti sọ fun Pilatu pe ọba ni oun, ṣugbọn pe ijọba oun kii ṣe apakan aye yii. Nisinsinyi alaye eyikeyii siwaju sii ki yoo ṣiṣẹ fun ète wiwulo kankan. Bi o ti wu ki o ri, abuku ba ọ̀wọ̀ ara ẹni Pilatu nipa aidahun naa, ibinu rẹ̀ si ru si Jesu pẹlu awọn ọrọ naa: “Iwọ ko ha ni ba mi sọrọ bi? Iwọ ko ha mọ pe emi ni aṣẹ lati tu ọ silẹ mo si ni aṣẹ lati kan ọ mọgi?”

Jesu dahun tọwọtọwọ pe: “Iwọ ki yoo ni aṣẹ eyikeyii lodisi mi ayafi bi a ba ti yọnda fun ọ lati oke wa.” Oun ntọkasi aṣẹ ti Ọlọrun yọnda fun awọn oluṣakoso ẹda-eniyan lati bojuto awọn àlámọ̀rí lori ilẹ-aye. Jesu fikun un pe: “Idi niyi ti ọkunrin naa ti o fa mi le ọ lọwọ fi ni ẹṣẹ giga ju.” Nitootọ, alufaa agba naa Kaifa ati awọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati Judasi Iskariọtu ru ẹrù wiwuwo ju ti Pilatu fun iwa ti ko ba idajọ-ododo mu ti wọn hù si Jesu.

Bí Jesu ti tubọ wú u lórí ti o si kun fun ibẹru pe Jesu le ni ipilẹṣẹ atọrunwa, Pilatu sọ awọn isapa rẹ lati tú U silẹ dọtun. Bi o ti wu ki o ri, awọn Juu kọ̀ fun Pilatu. Wọn tun ẹ̀sùn oṣelu wọn sọ, ni hihalẹ lọna arekereke pe: “Bi iwọ ba tu ọkunrin yii silẹ, iwọ kii ṣe ọrẹ Kesari. Olukuluku ẹni ti o nsọ ara rẹ di ọba sọrọ lodisi Kesari.”

Laika ewu ńláǹlà naa si, Pilatu mu Jesu jade lẹẹkan sii “Ẹ woo! Ọba yin!” ni oun tun sọ fun wọn lẹẹkan sii.

“Mu un lọ! Mu un lọ! Kàn án mọgi!”

“Ṣe ki emi kan ọba yin mọgi?” Pilatu beere pẹlu ìgbékútà.

Awọn Juu ti ṣaini itẹlọrun labẹ iṣakoso awọn ara Roomu. Nitootọ, wọn koriira ijẹgaba Roomu tẹgantẹgan! Sibẹ, pẹlu àgàbàgebè awọn olori alufa wipe: “Awa ko ni ọba kan bikoṣe Kesari.”

Ni bibẹru ipo oṣelu ati ifusi rẹ, Pilatu juwọsilẹ labẹ awọn ibeere dandangbọn aláìsimi awọn Juu. Oun fa Jesu le wọn lọwọ. Awọn ọmọ-ogun bọ aṣọ elese-aluko lọrun Jesu wọn si fi ẹwu àwọ̀lékè rẹ wọ̀ọ́. Bi wọn ti ńmú Jesu lọ lati kan an mọgi, wọn mu ki o ru igi idaloro ti oun funrarẹ.

Ṣugbọn nisinsinyi o ti di ìyálẹ̀ta ọjọ Friday, Nisan 14; boya ọjọ́kanrí ti nsunmọ. Jesu kò sùn rárá lati kutukutu owurọ ọjọ Thursday, oun si ti jiya iriri onirora kan tẹ̀lé omiran. Bi o ti lè yéni, okun rẹ tan laipẹ labẹ ẹru igi naa. Nitori naa ẹnikan ti nkọja lọ, Simoni kan bayii ara Kirene ni Africa, ni wọn fipá mu wọnú iṣẹ-isin lati bá a rù ú. Bi wọn ti nlọ, ọpọ awọn eniyan tẹle wọn, ti o ni-ninu ọpọlọpọ awọn obinrin ti wọn nlu ara wọn ninu ẹdun ọkan ti wọn si ńpohùnréré ẹkun nitori Jesu.

Ni yiyiju si awọn obinrin naa Jesu wipe: “Ẹyin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ dakẹ sisunkun fun mi. Dipo bẹẹ, ẹ sunkun fun ara yin ati fun awọn ọmọ yin; nitori pe, woo! ọjọ nbọ ninu eyi ti awọn eniyan yoo wipe, ‘Alayọ ni awọn obinrin ti wọn yàgàn, ati awọn ile-ọlẹ ti ko bimọ ati ọmu ti ko fi ọyàn fun ọmọ mu!’ . . . Nitori pe bi wọn ba ṣe awọn nǹkan wọnyi nigba ti igi jẹ tutu, ki ni yoo waye nigba ti o ba gbẹ?”

Jesu ntọkasi igi orilẹ-ede Juu, tí ọ̀rinrin iwalaaye ṣi nbẹ ninu rẹ nitori wiwanibẹ Jesu ati ti awọn aṣẹku ti wọn gbagbọ ninu rẹ̀. Ṣugbọn nigba ti a ba mu awọn wọnyi jade kuro ninu orilẹ-ede naa, kiki igi kan ti o ti kú nipa tẹmi ni yoo ṣẹ́kù, bẹẹni, eto-ajọ orilẹ-ede kan ti o ti gbẹ. Óò, iru idi fun sisunkun wo ni yoo wa nigba ti awọn ọmọ-ogun Roomu, ti wọn nṣiṣẹ gẹgẹ bi awọn olùmúdàájọ́ ṣẹ Ọlọrun, ba pa orilẹ-ede Juu run patapata! Johanu 19:6-17; 18:31; Luku 23:24-31; Matiu 27:31, 32; Maaku 15:20, 21, NW.

▪ Ẹ̀sùn wo lodisi Jesu ni awọn aṣaju isin fisun nigba ti awọn ẹ̀sùn oṣelu wọn kuna lati mu eso jade?

▪ Eeṣe ti Pilatu fi tubọ kun fun ibẹru sii?

▪ Ta ni o ru ẹṣẹ titobi ju fun ohun ti o ṣẹlẹ si Jesu?

▪ Nikẹhin bawo ni awọn alufa ṣe mu ki Pilatu fa Jesu le wọn lọwọ fun ìyà ikú?

▪ Ki ni Jesu sọ fun awọn obinrin ti wọn nsunkun fun un, ki ni oun si ni lọkan nipa titọkasi igi naa gẹgẹ bi eyi ti o “tutu” ati lẹhin naa gẹgẹ bi eyi ti o “gbẹ”?