Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Gbọ́ Ohùn Ọlọrun Ní Ìgbà Kẹta

A Gbọ́ Ohùn Ọlọrun Ní Ìgbà Kẹta

Orí 104

A Gbọ́ Ohùn Ọlọrun Ní Ìgbà Kẹta

NIGBA tí ó fi wà ní tẹmpili, Jesu ti nni irora ọkàn lórí ikú tí oun yoo dojúkọ láìpẹ́. Lájorí ìdàníyàn rẹ̀ ni bí ọ̀ràn naa yoo ṣe kan orukọ rere Baba rẹ̀, nitori naa ó gbadura pe: “Baba, ṣe orukọ rẹ lógo.”

Ní àkókò yẹn, ohùn alágbára ńlá kan ti ọrun jáde wá, ní pípòkìkí pe: “Emi ti ṣe é lógo ná, emi yoo sì tún ṣe é lógo.”

Ṣìbáṣìbo bá ogunlọgọ tí wọn dúró yí i ka. “Angẹli kan ni ó bá a sọ̀rọ̀,” ni awọn kan bẹrẹsii wí. Awọn miiran sọ pe ààrá ti sán. Ṣugbọn, nitootọ, Jehofa Ọlọrun ni ó sọ̀rọ̀! Eyi, bí ó ti wù kí ó rí, kii ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí a gbọ́ ohùn Ọlọrun ní ìsopọ̀ pẹlu Jesu.

Nigba baptisi Jesu, ní ọdun mẹta ati aabọ ṣaaju, Johanu Arinibọmi gbọ́ tí Ọlọrun sọ fun Jesu pe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, ààyò olùfẹ́, ẹni tí mo tẹ́wọ́gbà.” Tẹle eyi, lẹhin Irekọja tí ó ṣaaju, nigba ti a pa Jesu láradà niwaju wọn, Jakọbu, Johanu, ati Peteru gbọ́ tí Ọlọrun polongo pe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, ààyò olùfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́gbà; ẹ fetisilẹ sí i.” Ati nisinsinyi, fun ìgbà kẹta, ní Nisan 10, ọjọ mẹrin ṣaaju ikú Jesu, awọn eniyan tún gbọ́ ohùn Ọlọrun lẹẹkan sii. Ṣugbọn lọ́tẹ̀ yii Jehofa sọ̀rọ̀ kí ọpọlọpọ awọn eniyan baa lè gbọ́!

Jesu ṣàlàyé pe: “Ohùn yii dún, kii ṣe nitori mi, bikoṣe nitori yin.” Ó pèsè ẹ̀rí pe Jesu nitootọ ni Ọmọkunrin Ọlọrun, Mesaya tí a ṣèlérí naa. “Nisinsinyi ni a ńṣèdájọ́ ayé,” ni Jesu nbaa lọ, “nisinsinyi ni a ó lé olùṣàkóso ayé yii jù síta.” Ipa-ọ̀nà igbesi-aye iṣotitọ ti Jesu gbe, nitootọ, tubọ mú un fìdímúlẹ̀ pe Satani Eṣu, olùṣàkóso ayé yii, yẹ fun ‘lílé jù síta,’ fífi ìyà ikú jẹ ẹ́.

Ní titọka sí awọn àbájáde ikú rẹ̀ tí ó sunmọle, Jesu wipe: “Ati sibẹsibẹ, bí a bá gbé mi sókè kuro ní ilẹ̀-ayé, emi yoo fa awọn eniyan gbogbo oriṣiriṣi sọ́dọ̀ mi.” Ikú rẹ̀ kii ṣe ìṣẹ́gunṣẹ́tẹ̀ kan lọnakọna, nitori nipasẹ rẹ̀, oun yoo fa awọn miiran sọ́dọ̀ araarẹ̀ kí wọn baa lè gbádùn iye ainipẹkun.

Ṣugbọn ogunlọgọ naa takò ó pe: “Awa gbọ́ lati inú Òfin pe Kristi wà titilae; bawo ni iwọ sì ṣe wipe a gbọdọ gbé Ọmọkunrin eniyan sókè? Ta ni Ọmọkunrin eniyan yii?”

Láìka gbogbo ẹ̀rí naa sí, títíkan gbígbọ́ ohùn Ọlọrun fúnraarẹ̀, ọ̀pọ̀ kò gbàgbọ́ pe Jesu ni Ọmọkunrin eniyan tootọ naa, Mesaya tí a ṣèlérí. Sibẹsibẹ, gẹgẹ bi ó ti ṣe ní oṣu mẹfa ṣaaju ìgbà naa níbi Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn, Jesu lẹẹkan sii sọ̀rọ̀ nipa araarẹ̀ gẹgẹ bi ‘ìmọ́lẹ̀ naa’ ó sì fun awọn olùfetísílẹ̀ rẹ̀ ní ìṣírí pe: “Niwọn ìgbà tí ẹyin ní ìmọ́lẹ̀ naa, ẹ mú ìgbàgbọ́ lò ninu ìmọ́lẹ̀ naa, kí ẹ lè di awọn ọmọkunrin ìmọ́lẹ̀.” Lẹhin sísọ nǹkan wọnyi, Jesu lọ kuro ó sì farapamọ́, dajudaju nitori pe iwalaaye rẹ̀ wà ninu ewu.

Níní tí awọn Juu kò ní ìgbàgbọ́ ninu Jesu mú awọn ọ̀rọ̀ Aisaya ṣẹ nipa ‘ojú awọn eniyan ti o fọ́ ati ọkàn-àyà wọn tí a sé le kí wọn ma baa ṣẹ́rípadà kí a sì mú wọn láradá.’ Aisaya rí ìgà Jehofa ní ọ̀run ninu ìran, títíkan Jesu ninu ògo rẹ̀ pẹlu Jehofa ṣaaju kí ó tó di ẹ̀dá-ènìyàn. Sibẹsibẹ, awọn Juu, ní ìmúṣẹ ohun tí Aisaya kọwe, fi pẹlu agídí ṣá ẹ̀rí naa tì pe Ẹni yii ni Olùdáǹdè wọn tí a ṣèlérí.

Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, ọpọlọpọ kódà ninu awọn olùṣàkóso naa (dajudaju awọn mẹmba ilé-ẹjọ́ gíga ti awọn Juu, Sanhẹdrin) niti tootọ lo ìgbàgbọ́ ninu Jesu. Nikodemu ati Josẹfu ara Arimatia jẹ́ meji ninu awọn olùṣàkóso wọnyi. Ṣugbọn awọn olùṣàkóso wọnyi, ó kérépin ní lọwọlọwọ yii, kùnà lati polongo ìgbàgbọ́ wọn, nitori ìbẹ̀rù kí a maṣe gba ipò wọn ninu sinagọgu kuro lọwọ wọn. Wo ọpọlọpọ ohun tí irúfẹ́ awọn ẹni bẹẹ pàdánù!

Jesu tẹsiwaju lati wipe: “Ẹni tí ó ba lò ìgbàgbọ́ ninu mi lo ìgbàgbọ́, kii ṣe ninu mi nìkan, bikoṣe ninu ẹni naa pẹlu tí ó rán mi; ẹni tí ó sì rí mi rí ẹni tí ó rán mi pẹlu. . . . Ṣugbọn bí ẹnikẹni bá gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ mi tí kò sì pa wọn mọ́, emi kò ṣèdájọ́ rẹ̀; nitori emi wá, kii ṣe lati ṣèdájọ́ ayé, bikoṣe lati gba ayé là. . . . Ọ̀rọ̀ naa tí mo ti sọ ni ohun tí yoo ṣèdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ikẹhin.”

Ìfẹ́ Jehofa fun ayé aráyé sún un lati ran Jesu kí awọn wọnni tí wọn bá lò ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀ baa lè ní ìgbàlà. Boya a ó gbà awọn eniyan là ni a ó pinnu nipasẹ boya wọn ṣègbọràn sí awọn ohun tí Ọlọrun fun Jesu ní itọni lati sọ. Ìdájọ́ naa yoo ṣẹlẹ̀ “ní ọjọ ikẹhin,” lákòókò Àkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdun Kristi.

Jesu pari ọ̀rọ̀ rẹ̀ nipa wiwi pe: “Emi kò sọ̀rọ̀ nipa àtinúdá araami, ṣugbọn Baba tìkáraarẹ̀ tí ó rán mi ti fun mi ní òfin-àṣẹ niti ohun tí emi yoo sọ ati ohun tí emi yoo wí. Pẹlupẹlu, emi mọ̀ pe òfin rẹ̀ tumọsi ìyè ainipẹkun. Nitori naa awọn nǹkan tí mo sọ, gan-an gẹgẹ bi Baba ti sọ wọn fun mi, bẹẹ ni mo sọ wọn.” Johanu 12:28-50; 19:38, 39, NW; Matiu 3:17, NW; Mt 17:5, NW; Aisaya 6:1, 8-10.

▪ Lakooko awọn ìṣẹ̀lẹ̀ mẹta wo ni a gbọ́ ohùn Ọlọrun ní ìsopọ̀ pẹlu Jesu?

▪ Bawo ni wolii Aisaya ṣe rí ògo Jesu?

▪ Awọn olùṣàkóso wo ni wọn lò ìgbàgbọ́ ninu Jesu, ṣugbọn eeṣe tí wọn kò fi jẹ́wọ́ rẹ̀ ní gbangba?

▪ Ki ni “ọjọ́ ikẹhin” naa jẹ́, nipasẹ ki sì ni a ó ṣèdájọ́ awọn eniyan lákòókò naa?