Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Mú Un Lọ Sọdọ Anasi, Lẹhin Naa Sọdọ Kaifa

A Mú Un Lọ Sọdọ Anasi, Lẹhin Naa Sọdọ Kaifa

Orí 119

A Mú Un Lọ Sọdọ Anasi, Lẹhin Naa Sọdọ Kaifa

JESU, ti a de gẹgẹ bi ọdaran lasan kan, ni a muwa sọdọ Anasi, alufaa àgbà tẹlẹri ti o ni agbara idari nlanla. Anasi jẹ alufaa agba nigba ti Jesu gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ẹni ọdun 12 ya awọn olukọ rabi ninu tẹmpili lẹnu. Ọpọ lara awọn ọmọkunrin Anasi lẹhin naa ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alufaa àgbà, ọkọ ọmọbinrin rẹ̀ Kaifa ni o sì di ipo yẹn mu nisinsinyi.

O ṣeeṣe ki wọn ti kọ́kọ́ mu Jesu lọ si ile Anasi nitori ìyọrí ọlá ọlọjọ pipẹ ti olori alufaa yẹn ní ninu igbesi aye isin awọn Juu. Iduro diẹ yii lati ri Anasi yọnda fun Alufaa Agba Kaifa lati pe Sanhẹdrin jọ, ile ẹjọ giga Juu oni mẹmba 71 naa, ati pẹlu lati ko awọn ẹlẹrii eke jọ.

Olori alufaa Anasi nisinsinyi bi Jesu leere nipa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ati nipa ẹkọ rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, Jesu sọ ni idahun pe: “Emi ti sọrọ ni gbangba fun araye; nigba gbogbo ni emi nkọni ninu sinagọgu, ati ni tẹmpili nibi ti gbogbo awọn Juu npejọ si: emi kò sì sọ ohun kan ni ikọkọ. Eeṣe ti iwọ fi nbi mi leere? beere lọwọ awọn ti o ti gbọ ọrọ mi, ohun ti mo wi fun wọn: woo, awọn wọnyi mọ ohun ti emi wi.”

Nitori eyi, ọkan lara awọn oṣiṣẹ olóyè ti wọn duro nitosi Jesu gbá a ni oju, ni wiwi pe: “Olori alufaa ni iwọ nda lohun bẹẹ?”

“Bi mo ba sọrọ buburu,” ni Jesu fesi, “jẹrii si buburu naa: ṣugbọn bi rere ba ni, eeṣe ti iwọ fi nlu mi?” Lẹhin tí wọn bá ara wọn sọ ọ̀rọ̀ yii, Anasi ran Jesu lọ ni dídè si Kaifa.

Nisinsinyi gbogbo awọn olori alufaa ati awọn àgbà ọkunrin ati awọn akọwe ofin, bẹẹni, gbogbo Sanhẹdrin, bẹrẹ sii pejọ. O han gbangba pe ile Kaifa ni ibi ipade wọn. Lati ṣe irufẹ ijẹjọ bẹẹ ni alẹ Irekọja ni kedere lodisi ofin Juu. Ṣugbọn eyi ko dá awọn aṣaaju isin naa duro ninu ète buburu wọn.

Awọn ọsẹ diẹ ṣaaju, nigba ti Jesu ji Lasaru dìde, awọn Sanhẹdrin ti pinnu laaarin araawọn pe o gbọdọ ku. Ati pe ni kiki ọjọ meji ṣaaju, ni Wednesday, awọn alaṣẹ isin naa ti pete lati fipa mú Jesu nipa ihumọ alareekereke lati pa á. Ronu, niti tootọ wọn ti dá a lẹbi ṣaaju ìgbẹ́jọ́ rẹ̀!

Awọn isapa nlọ lọwọ nisinsinyi lati wá awọn ẹlẹrii ti wọn yoo jẹri eke ki wọn baa lè gbe ẹjọ ọdaran dide lodisi Jesu. Bi o ti wu ki o ri, wọn kò lè rí ẹlẹrii kankan ti ó wà ni iṣọkan ninu ẹri wọn. Asẹhinwa asẹhinbọ, awọn meji jade wa wọn sì tẹnumọ́ ọn pe: “Awa gbọ́ o wipe, Emi yoo wo tẹmpili yii ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ mẹta emi yoo sì kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe.”

“Iwọ kò dahun kan?” Kaifa beere. “Ki ni eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ?” Ṣugbọn Jesu wà ni idakẹjẹẹ niṣo. Ani pẹlu ẹsun eke yii paapaa, si itiju Sanhẹdrin, awọn ẹlẹrii naa kò lè mu ìtàn wọn fohunṣọkan. Nitori naa alufaa agba naa gbiyanju ọgbọ́n jìbìtì yiyatọ.

Kaifa mọ bi awọn Juu ti nnimọlara nipa ẹnikẹni ti o nsọ pe oun jẹ Ọmọkunrin Ọlọrun gan-an. Ni awọn iṣẹlẹ meji ṣaaju, wọn ti fi pẹlu iwanwara lẹ lebẹẹli asọrọ odi ti o yẹ fun iku mọ Jesu lara, nigba kan ti wọn ti fi pẹlu aṣiṣe foju inu woye pe oun nsọ pe oun dọgba pẹlu Ọlọrun. Kaifa nisinsinyi fi pẹlu arekereke beere pe: “Mo fi Ọlọrun alaaye fi ọ bú pe, ki iwọ sọ fun wa bi iwọ ba ṣe Kristi Ọmọ Ọlọrun.”

Laika ohun ti awọn Juu rò si, niti tootọ Jesu ni Ọmọkunrin Ọlọrun. Ati lati dakẹ ni a lè tumọ sí sísẹ́ jijẹ Kristi rẹ̀. Nitori naa Jesu fesipada pẹlu igboya pe: “Emi ni: ẹyin yoo sì ri Ọmọ eniyan ti o jokoo ni ọwọ ọtun agbara, yoo sì maa ti inu awọsanma ọrun wa.”

Nitori eyi, ninu ifihan amunijigiri, Kaifa gbọ́n ẹ̀wù rẹ̀ fàya ti o si ṣe saafula pe: “O sọ ọ̀rọ̀ òdì; ẹlẹrii ki ni a sì nwa? Woo, ẹyin gbọ ọ̀rọ̀ òdì naa nisinsinyi. Ẹyin ti rò ó sí?”

“O jẹ̀bi ikú,” ni awọn Sanhẹdrin pokiki. Nigba naa wọn bẹrẹ sii fi da àpárá, wọn sì sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ òdì si i. Wọn gbá oju rẹ̀ wọn sì tutọ́ sí i. Awọn miiran bo gbogbo oju rẹ̀ wọn sì fi ikuuku wọn gbà á wọn sì wi pẹlu òdì ọ̀rọ̀ ti ko barade: “Sọtẹlẹ ta ni lù ọ́?” Ihuwasi eleeebu, ti kò ba ofin mu yii waye nigba ìgbẹ́jọ́ òru naa. Matiu 26:57-68, NW; Mt 26:3, 4; Maaku 14:53-65; Luuku 22:54, 63-65; Johanu 18:13-24; 11:45-53; 10:31-39; Joh 5:16-18.

▪ Nibo ni a mu Jesu wa lakọọkọ, ki ni o sì ṣẹlẹ sí i nibẹ?

▪ Nibo ni a mu Jesu lọ tẹle e, ati fun ète wo?

▪ Bawo ni Kaifa ṣe mu ki awọn Sanhẹdrin pokiki pe Jesu lẹtọọ si iku?

▪ Ihuwasi eleeebu, ti kò ba ofin mu wo ni o waye nigba ìgbẹ́jọ́ naa?