Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Sin ín ni Friday—Iboji Rẹ̀ Ṣofo ni Sunday

A Sin ín ni Friday—Iboji Rẹ̀ Ṣofo ni Sunday

Orí 127

A Sin ín ni Friday—Iboji Rẹ̀ Ṣofo ni Sunday

NISINSINYI o ti di ọjọ́rọ̀ ni Friday, Sabaati Nisan 15 yoo sì bẹrẹ nigba ti oorun bá wọ̀. Oku Jesu sorọ̀ jọwọlọ lori opo igi naa, ṣugbọn awọn ọlọṣa meji tí ó wà lẹgbẹ rẹ̀ ṣì walaaye. Ọsan Friday ni a ńpè ni Ipalẹmọ nitori akoko yii ni awọn eniyan maa nṣe ounjẹ ti wọn sì maa npari iṣẹ kanjukanju miiran eyikeyii ti a kò le dá dúró di ẹhin Sabaati.

Sabaati ti yoo bẹrẹ laipẹ kii ṣe kiki Sabaati ti a nṣe deedee (ni ọjọ keje ọsẹ) ṣugbọn o tun jẹ Sabaati onipele meji, tabi “nla.” A pe e lọna yii nitori pe Nisan 15, eyi ti o jẹ ọjọ akọkọ Ajọdun ọlọjọ meje ti awọn Akara Aiwu (o si saba maa njẹ Sabaati kan, laika ọjọ ti o ba bọ si laaarin ọsẹ), bọ si ọjọ kan naa gẹgẹ bi Sabaati ti a nṣe deedee.

Gẹgẹ bi Ofin Ọlọrun ti wi, òkú ni a ko nilati fi silẹ ni sisorọ sori òpó igi di igba ti ilẹ ba mọ́. Nitori naa awọn Juu beere lọwọ Pilatu pe ki a tètè mu iku awọn wọnni ti a nfiya iku jẹ yara kankan nipa dida ẹsẹ wọn. Nitori naa, awọn ọmọ ogun da ẹsẹ awọn ọlọṣa mejeeji. Ṣugbọn niwọn bi Jesu ti farahan bi ẹni ti o ti ku, ẹsẹ rẹ̀ ni a ko dá. Eyi mu asọtẹlẹ iwe mimọ ṣẹ pe: “A ki yoo dá egungun rẹ̀ kankan.”

Bi o ti wu ki o ri, lati mu iyemeji yii kuro pe Jesu ti ku nitootọ, ọkan lara awọn ọmọ ogun naa fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ọ̀kọ̀ naa gun un lọ si apa iha ọkan rẹ̀, lẹsẹkẹsẹ ẹ̀jẹ̀ ati omi si jade wa. Apọsiteli Johanu, ẹni ti ọ̀ràn ṣoju rẹ̀, rohin pe eyi mu iwe mimọ miiran ṣẹ pe: “Wọn yoo maa wo Ẹni naa ti wọn gún lọ́kọ̀.”

Ẹni ti o tun wa nibi ifiya iku jẹni naa ni Josẹfu lati ilu Arimatia, mẹmba Sanhẹdrin kan ti o ni orukọ rere. Oun kọ̀ lati fọwọsi igbesẹ alaiba idajọ ododo mu ti ile-ẹjọ giga lodisi Jesu. Josẹfu jẹ ọmọ ẹhin Jesu nitootọ, bi o tilẹ jẹ pe oun ti bẹru lati fi ara rẹ̀ hàn gẹgẹ bi ọ̀kan. Bi o ti wu ki o ri, nisinsinyi oun lo igboya o si lọ sọdọ Pilatu lati beere fun oku Jesu. Pilatu ranṣẹ pe ijoye oṣiṣẹ ologun ti o wa ni abojuto, lẹhin ti ijoye oṣiṣẹ naa sì ti mú un daju pe Jesu ti ku, Pilatu jẹ ki a fa oku naa lé e lọwọ.

Josẹfu gbe oku naa o sì fi aṣọ fẹlẹfẹlẹ mimọtonitoni wé e ni imurasilẹ fun isinku. Nikodemu, mẹmba Sanhẹdrin miiran, ràn án lọwọ. Nikodemu pẹlu ti kuna lati jẹwọ igbagbọ rẹ̀ ninu Jesu ni gbangba nitori ibẹru pipadanu ipo rẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyi o mu àkápọ̀ kan ti o ni òjíá ninu ti ìwọ̀n rẹ̀ to nǹkan bii pound ọgọrun-un ati aloe olowo iyebiye wá. Ara Jesu ni a fi aṣọ ti a fi ndi ọgbẹ́ ti o ni awọn oorun didun wọnyi wé, gan-an gẹgẹ bi àṣà ti awọn Juu gbà nmura oku silẹ fun sísin.

Lẹhin eyi ara naa ni a tẹ́ sinu iboji iranti titun ti Josẹfu ti a gbẹ sinu apata ninu ọgbà nitosi. Nikẹhin, okuta nla kan ni a yi bo iwaju iboji naa. Lati ṣaṣepari sisin oku naa ṣaaju Sabaati, ipalẹmọ ara oku naa jẹ kanjukanju. Nitori naa, Maria Magidaleni ati Maria iya Jakọbu Kekere, awọn ti o ṣeeṣe ki wọn ti maa ṣe itilẹhin ninu imurasilẹ naa, yara lọ si ile lati pese ohun oloorun didun ati òróró lọ́fíndà si i. Lẹhin Sabaati, wọn ṣeto lati tọju ara oku Jesu siwaju sii lati pa a mọ laidibajẹ fun saa akoko gigun kan.

Ni ọjọ ti o tẹle e, eyi ti nṣe Saturday (Sabaati), awọn olori alufaa ati Farisi lọ sọdọ Pilatu wọn si wipe: “Alagba, awa ti pe e wa si iranti pe afàwọ̀rajà yẹn wi nigba ti o ṣi walaaye pe, ‘Lẹhin ọjọ mẹta, a o ji mi dide.’ Nitori naa paṣẹ ki a mu isa oku naa wa ni aabo titi di ọjọ kẹta, ki awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ maṣe wa lae ki wọn sì ji i gbe ki wọn sì wi fun awọn eniyan pe, ‘A ti ji i dide kuro ninu oku!’ ìfàwọ̀rajà ikẹhin yii yoo sì buru ju ti akọkọ lọ.”

Pilatu dahun pe, “Ẹyin ní ẹ̀ṣọ́, ẹ lọ ki ẹ sì mú un wa ni aabo bi ẹ bá ti mọ̀ ọ́n tó.” Nitori naa wọn lọ wọn sì mu isà oku naa wa ni aabo nipa fifi okuta naa di i pa wọn sì fi awọn ọmọ ogun Roomu ṣọ́ ọ gẹgẹ bi oluṣọ.

Ni kutukutu owurọ Sunday Maria Magidaleni, Maria iya Jakọbu, papọ pẹlu Salomẹ, Joanna, ati awọn obinrin miiran, mu awọn ohun oloorun didun wá sibi iboji naa lati tọju ara oku Jesu. Loju ọna wọn sọ fun araawọn pe: “Ta ni yoo yi okuta kuro lẹnu ilẹkun iboji iranti fun wa?” Ṣugbọn nigba ti wọn de ibẹ, wọn rii pe isẹlẹ kan ti ṣẹlẹ angẹli Jehofa sì ti yi okuta naa kuro. Awọn oluṣọ ti lọ, iboji naa sì ṣofo! Matiu 27:57–28:2; Maaku 15:42–16:4; Luuku 23:50–24:3, 10; Johanu 19:14, Joh 19:31–20:1; Joh 12:42; Lefitiku 23:5-7; Deutaronomi 21:22, 23; Saamu 34:20; Sẹkaraya 12:10.

▪ Eeṣe ti a fi pe Friday ni ọjọ Ipalẹmọ, ki si ni Sábáàtì “nla”?

▪ Awọn iwe mimọ wo ni o ni imuṣẹ ni isopọ pẹlu ara oku Jesu?

▪ Ki ni Josẹfu ati Nikodemu niiṣe pẹlu isinku Jesu, ki si ni ibatan wọn pẹlu Jesu?

▪ Ki ni awọn alufaa beere fun lọdọ Pilatu, bawo ni oun si ṣe dahunpada?

▪ Ki ni ṣẹlẹ ni kutukutu owurọ ọjọ Sunday?