Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ará Samaria Aládùúgbò Rere Kan

Ará Samaria Aládùúgbò Rere Kan

Orí 73

Ará Samaria Aládùúgbò Rere Kan

BOYA Jesu ti wà nítòsí Bẹtani, abúlé kan tí ó wà ní nǹkan bíi ibùsọ̀ meji sí Jerusalẹmu. Ọkunrin kan tí ó jẹ́ ògbógi ninu Òfin Mose tọ̀ ọ́ wá pẹlu ibeere kan, ní bibeere pe: “Olukọni, ki ni emi yoo ṣe kí emi kí ó lè jogún iye ainipẹkun?”

Jesu jádìí rẹ̀ pe ọkunrin naa, ti o jẹ amòfin, kò wulẹ beere fun ìsọfúnni ṣugbọn, kaka bẹẹ, pe ó ní ìfẹ́-ọkàn lati dán an wò. Èrò amòfin naa lè jẹ́ lati mú kí Jesu dáhùn ní ọ̀nà kan tí yoo ṣe láìfí sí agbára ìmòye awọn Juu. Nitori naa Jesu mú kí amòfin naa sọ èrò araarẹ̀, ní bibeere pe: “Ki ni a kọ sínú ìwé Òfin? Bí iwọ ti kà á?”

Ní ìfèsìpadà, amòfin naa, ní lílò òye-inú àràmàǹdà, ṣàyọlò lati inú awọn òfin Ọlọrun ní Deutaronomi 6:5 ati Lefitiku 19:18 (NW), ní wiwi pe: “‘Iwọ gbọdọ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ ati pẹlu gbogbo ọkàn rẹ ati pẹlu gbogbo okun rẹ ati pẹlu gbogbo èrò-inú rẹ,’ ati, ‘aládùúgbò rẹ gẹgẹ bi araàrẹ.’”

“Iwọ dahun rere,” ni Jesu dáhùnpadà. “Maa ṣe eyi, iwọ yoo sì yè.”

Amòfin naa, bí ó ti wù kí ó rí, kò ní ìtẹ́lọ́rùn. Ìdáhùn Jesu kò ṣe taarata tó fun un. Ó ńfẹ́ itilẹhin lati ọ̀dọ̀ Jesu pe awọn ojú ìwòye ti oun fúnraarẹ̀ tọ̀nà ati nipa bẹẹ pe oun jẹ́ olódodo ninu ìbálò rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran. Nitori naa, ó beere pe: “Ta ha sì ni aládùúgbò mi?”

Awọn Juu gbàgbọ́ pe èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “aládùúgbò” ni a lè lò fun kìkì awọn Juu ẹlẹgbẹ́ wọn, gẹgẹ bi àyíká ọ̀rọ̀ Lefitiku 19:18 ti dàbí ẹni pe ó fihàn. Nitootọ, lẹhin ìgbà naa apọsiteli Peteru wipe: “Ẹ mọ̀ daradara bí kò ti bófinmu fun Juu kan lati da araarẹ̀ pọ̀ tabi súnmọ́ eniyan kan tí ó jẹ́ ti ìran miiran.” Nitori bẹẹ, amòfin naa, ati boya awọn ọmọ-ẹhin Jesu gbàgbọ́ pe wọn jẹ́ olódodo bí wọn bá lò sí kìkì Juu ẹlẹgbẹ́ wọn pẹlu inúrere, niwọnbi ó ti jẹ́ pe, ní ojú ìwòye wọn, awọn tí kii ṣe Juu kii ṣe awọn aládùúgbò wọn niti gidi.

Láìṣe láìfí sí awọn olùgbọ́ rẹ̀, bawo ni Jesu ṣe lè tún ojú-ìwòye wọn ṣe? Ó sọ ìtàn kan, tí ó ṣeeṣe kí ó dálórí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ niti gidi. “[Juu] kan bayii,” ni Jesu ṣàlàyé, “ńsọ̀kalẹ̀ lọ lati Jerusalẹmu sí Jẹriko ó sì bọ́ sọ́wọ́ awọn ọlọ́ṣà, tí wọn tú u sí ìhòhò tí wọn sì lù ú ni ẹṣẹ, wọn sì lọ, ní fífi i silẹ ní àpaìpatán.”

“Nisinsinyi, ní ìṣekòńgẹ́,” ni Jesu nbaa lọ, “alufaa kan bayii ńsọ̀kalẹ̀ lọ ní ojú-ọ̀nà naa, ṣugbọn, nigba ti ó rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdìkejì lọ, bẹẹ gẹ́gẹ́, ọmọ Lefi kan pẹlu, nigba ti ó sọ̀kalẹ̀ dé ibẹ̀ tí ó sì rí i, gba ẹ̀gbẹ́ òdìkejì kọjá lọ. Ṣugbọn ara Samaria kan bayii tí ńrin ìrìn àjò ní ojú ọ̀nà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti rí i, àánú ṣe é.”

Ọpọlọpọ awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi tí wọn jẹ́ igbakeji wọn ní tẹmpili ńgbé ní Jẹriko, tí ó jẹ́ ibùsọ̀ 14 ní jíjìn lójú ọ̀nà eléwu kan tí ó daagun wálẹ̀ ní 3,000 ẹsẹ̀-bàtà lati ibi tí wọn ti ńṣiṣẹ́sìn ní tẹmpili ní Jerusalẹmu. Alufaa ati ọmọ Lefi ni a o ti reti pe ki o ṣèrànwọ́ fun Juu ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó wà ninu ìdààmú. Ṣugbọn wọn kò ṣe bẹẹ. Dípò bẹẹ, ara Samaria kan ni ó ṣe bẹẹ. Awọn Juu kórìíra awọn ara Samaria tobẹẹ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pe lẹnu aipẹ yii wọn fi ìwọ̀sí kan Jesu pẹlu èdè lílekoko julọ naa nipa pípè é ní “ara Samaria kan.”

Ki ni ara Samaria naa ṣe lati ran Juu naa lọwọ? “Ó súnmọ́ ọn,” ni Jesu wí, “ó sì di awọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró ati ọtí waini sí i. Nigba naa ni ó gbé e gun orí ẹranko tirẹ̀ fúnraarẹ̀ ó sì gbé e lọ sí ilé-èrò kan ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Ati ní ọjọ keji ó mú owó dinari meji [nǹkan bii owó-ọ̀yà ọjọ́ meji] jáde, ó fi wọn fun olùtọ́jú ilé-èrò naa, ó sì wipe, ‘Tọ́jú rẹ̀, ohun yoowu tí iwọ bá sì tún ná ju eyi lọ, emi yoo san án padà fun ọ nigba ti mo bá padà wá sí ìhín yii.’”

Lẹhin tí ó sọ ìtàn naa, Jesu beere lọwọ amòfin naa pe: “Lójú rẹ ninu awọn mẹtẹẹta wọnyi ta ni sọ araarẹ̀ di aládùúgbò ọkunrin naa tí ó bọ́ sọ́wọ́ awọn ọlọ́ṣà?”

Bí ara rẹ̀ kò ti balẹ̀ nipa gbígbé iyìn eyikeyii fun ara Samaria kan, amòfin naa dáhùn ní ṣákálá pe: “Ẹni naa tí ó gbé ìgbésẹ̀ tàánútàánú síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”

“Lọ kí iwọ fúnraàrẹ maa ṣe bakan naa,” ni Jesu pari ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Bi o ba jẹ́ pe Jesu ti sọ fun amòfin naa ní tààràtà pe awọn tí kii ṣe Juu pẹlu jẹ́ awọn aládùúgbò rẹ̀, kii ṣe kìkì pe ọkunrin naa kò ní tẹ́wọ́gbà eyi, ṣugbọn eyi ti o pọ̀ jùlọ ninu awọn olùgbọ́ naa ni ó ṣeeṣe kí wọn ti ọkunrin naa lẹhin ninu ìjíròrò pẹlu Jesu. Ìtàn ohun ti o ṣẹlẹ gidi ninu igbesi-aye awọn eniyan yii, bí ó ti wù kí ó rí, ti mú un hàn gbangba ní ọ̀nà kan tí kò ṣeé jánírọ́ pe awọn aládùúgbò wa ní awọn eniyan tí wọn yàtọ̀ sí ti ìran ati orílẹ̀-èdè tiwa fúnraawa ninu. Ẹ wo ọ̀nà yíyanilẹ́nu ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Jesu ní! Luuku 10:25-37, NW; Iṣẹ 10:28, NW; Johanu 4:9; 8:48.

▪ Awọn ibeere wo ni amòfin naa beere lọwọ Jesu, ki ni ó sì hàn kedere pe ó jẹ́ ète ti o fi beere?

▪ Ta ni awọn Juu gbàgbọ́ pe o jẹ́ aládùúgbò wọn, ìdí wo sì ni ó wà lati gbàgbọ́ pe awọn ọmọ-ẹhin pàápàá ṣàjọpín ojú ìwòye yii?

▪ Bawo ni Jesu ṣe mú ojú ìwòye tí ó jánà naa ṣe kedere kí amòfin naa ma baa lè já a nírọ́?